Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?
ÀWỌN Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé. Wíwà tí àwọn ohun àgbàyanu wà lọ́nà àrà nínú àgbáálá ayé tó yí wa ká, fi hàn gbangba pé Ẹlẹ́dàá olóye àti alágbára jù lọ ló ṣẹ̀dá gbogbo rẹ̀. Gẹ́lẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin ṣe máa ń fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń fi irú ẹni tó jẹ́ hàn. Bíbélì sọ fún wa pé “àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, láìsí ohùn tàbí ọ̀rọ̀, “àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 1:20; Sáàmù 19:1-4.
Èèyàn kì í mọ ìkòkò tàbí kó ṣe tẹlifíṣọ̀n àti ẹ̀rọ̀ kọ̀ǹpútà láìní ète kan lọ́kàn. Ayé àti àwọn ewéko àti ẹranko tó jẹ́ ẹ̀dá alààyè inú rẹ̀ tiẹ̀ tún jẹ́ ohun ìyanu jù bẹ́ẹ̀ lọ fíìfíì. Ìgbékalẹ̀ ara ẹ̀dá ènìyàn tòun ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú rẹ̀ ré kọjá òye wa, kódà ohun àgbàyanu tó ju òye ẹni lọ ni ọpọlọ tí a fi ń ronú pàápàá jẹ́! Bí àwọn èèyàn bá ni ète tí wọ́n fi ń ṣe àwọn ohun tí wọ́n hùmọ̀, èyí tí kò tó nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Ẹlẹ́dàá, dájúdájú Jèhófà Ọlọ́run ni ète tó fi dá àwọn ìṣẹ̀dá àgbàyanu tó dá! Òwe 16:4 sọ pé ó ní ète tó fi dá wọn, ó ní: “Ohun gbogbo ni Jèhófà ti ṣe fún ète rẹ̀.”
Ó ní ète tí Jèhófà fi dá ilẹ̀ ayé, nítorí ó sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé . . . , kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Nítorí pé tọkọtaya yìí di aláìgbọràn, wọn kò lè fi àwọn ìdílé olódodo, tó máa fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó ilẹ̀ ayé àti àwọn ewéko àti ẹranko inú rẹ̀, kún inú ayé. Àmọ́ ìkùnà wọn kò gbé ète Jèhófà wọmi. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, a kọ ọ́ pé: “Ọlọ́run . . . Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé . . . kò wulẹ̀ dá a lásán.” Ńṣe ni “ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” Kò wà fún píparun bí kò ṣe pé kí “aiye duro titi lai.” (Aísáyà 45:18; Oníwàásù 1:4, Bíbélì Mímọ́) Ohun tí Jèhófà pète fún ilẹ̀ ayé yóò ṣẹ, ó ní: “Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.”—Aísáyà 46:10.
Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé ayé yóò wà títí láé ni, àti pé gbogbo ẹni tó bá ti lè hùwà níbàámu pẹ̀lú ohun tí Jèhófà pète fún ilẹ́ ayé ẹlẹ́wà yìí, yálà ẹni yẹn ń bẹ láàyè tàbí ó ti kú, ni ó lè gbé ayé títí láé. Gbogbo aráyé jogún àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Bíbélì sọ fún wa pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Róòmù 6:23; Oníwàásù 9:5; Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20) Báwo ni wọn yóò ṣe wá padà tún wà láàyè láti lè pín nínú àwọn ìbùkún inú ayé? Ipasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù nìkan nìyẹn fi lè ṣeé ṣe, nítorí ó sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” “Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29; 11:25; Mátíù 20:28.
Báwo ni èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Àlàyé bí yóò ṣe ṣẹlẹ̀ wà nínú “ìhìn rere ìjọba náà” tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí polongo nígbà tó wà láyé. (Mátíù 4:17-23) Àmọ́ lóde òní, ọ̀nà àkànṣe pàtàkì kan ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń wàásù ìhìn rere yìí.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 13]
OHUN TÍ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ GBÀ GBỌ́
Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Ìdí Látinú Ìwé Mímọ́
Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ó sì 2 Tím. 3:16, 17; 2 Pét. 1:20, 21;
jẹ́ òtítọ́ Jòh. 17:17
Bíbélì ṣeé gbára lé ju àṣà Mát. 15:3; Kól. 2:8
àtọwọ́dọ́wọ́ lọ
Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run Sm. 83:18; Aísá. 26:4; 42:8, AS; Ẹ́kís. 6:3
Kristi jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run ipò rẹ̀ Mát. 3:17; Jòh. 8:42; 14:28;
kò sì tó ti Ọlọ́run Jòh 20:17; 1 Kọ́r. 11:3; 15:28
Kristi ni àkọ́dá gbogbo ìṣẹ̀dá Kól. 1:15; Ìṣí. 3:14
Ọlọ́run
Orí òpó igi ni Kristi ti kú, Gál. 3:13; Ìṣe 5:30
kì í ṣe orí àgbélébùú
Kristi fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Mát. 20:28; 1 Tím. 2:5, 6;
ènìyàn ṣe ìràpadà fún àwọn 1 Pét. 2:24
onígbọràn nínú ọmọ aráyé
Ẹbọ kan ṣoṣo tí Kristi rú ti Róòmù 6:10; Héb. 9:25-28
yanjú ọ̀ràn pátápátá
Ọlọ́run jí Kristi dìde sípò 1 Pét. 3:18; Róòmù 6:9;
ẹni ẹ̀mí aláìleèkú Ìṣí. 1:17, 18
Wíwà níhìn-ín Kristi jẹ́ nípa Jòh. 14:19; Mát. 24:3;
tẹ̀mí 2 Kọ́r. 5:16; Sm. 110:1, 2
‘Àkókò òpin’ la wà nísinsìnyí Mát. 24:3-14; 2 Tím. 3:1-5;
Ìjọba tó wà níkàáwọ́ Kristi Aísá. 9:6, 7; 11:1-5;
yóò fi òdodo àti àlàáfíà Dán. 7:13, 14; Mát. 6:10
ṣàkóso ayé
Ìjọba yẹn yóò mú kí ayé tòrò, Sm. 72:1-4; Ìṣí. 7:9, 10, 13-17;
kó sì tura Ìṣí 21:3, 4
Ayé ò ní pa rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kò ní Oníw. 1:4; Aísá. 45:18; Sm. 78:69
dahoro láé
Ọlọ́run yóò pa ètò àwọn nǹkan Ìṣí. 16:14, 16; Sef. 3:8;
ìsinsìnyí rẹ́ nígbà ogun Dán. 2:44;
Ha-Mágẹ́dọ́nì Aísá. 34:2; 55:10, 11
Ìparun ayérayé ni yóò bá àwọn Mát. 25:41-46; 2 Tẹs. 1:6-9
ẹni ibi
Àwọn ẹni tí Ọlọ́run bá tẹ́wọ́ Jòh. 3:16; 10:27, 28; 17:3;
gbà yóò gba ìyè ayérayé Máàkù 10:29, 30
Ọ̀nà kan ṣoṣo péré ló ń sinni Mát. 7:13, 14; Éfé. 4:4, 5
lọ sí ìyè
Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló fà á tí aráyé Róòmù 5:12; 6:23
fi ń kú
Béèyàn bá ti kú ọkàn kú nìyẹn Ìsík. 18:4; Oníw. 9:10; Sm. 6:5;
Sàréè ọmọ aráyé ni ọ̀run àpáàdì Jóòbù 14:13, Dy; Ìṣí. 20:13, 14,
AV (àlàyé etí ìwé)
Àjíǹde ni ìrètí tí ń bẹ fún 1 Kọ́r. 15:20-22; Jòh. 5:28, 29;
àwọn òkú Jòh 11:25, 26
Ikú táa jogún látọ̀dọ̀ Ádámù 1 Kọ́r. 15:26, 54; Ìṣí. 21:4;
yóò dópin Aísá. 25:8
Kìkì agbo kékeré tó jẹ́ ọ̀kẹ́ Lúùkù 12:32; Ìṣí. 14:1, 3;
méje ó lé ẹgbàajì ló ń lọ sí 1 Kọ́r. 15:40-53; Ìṣí. 5:9, 10
ọ̀run láti bá Kristi ṣàkóso
Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì 1 Pét. 1:23; Jòh. 3:3;
yẹn di àtúnbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ìṣí. 7:3, 4
Ọlọ́run nípa tẹ̀mí
A dá májẹ̀mú tuntun pẹ̀lú Jer. 31:31; Héb. 8:10-13
Ísírẹ́lì tẹ̀mí
Kristi kọ́ ìjọ rẹ̀ sórí òun Éfé. 2:20; Aísá. 28:16;
tìkára rẹ̀ Mát. 21:42
A kò gbọ́dọ̀ lo ère nínú ìjọsìn Ẹ́kís. 20:4, 5; Léf. 26:1;
Kí a yàgò fún bíbá ẹ̀mí lò Diu. 18:10-12; Gál. 5:19-21;
Sátánì ni ẹni àìrí tó ń 1 Jòh. 5:19; 2 Kọ́r. 4:4;
ṣàkóso ayé Jòh. 12:31
Kò yẹ kí Kristẹni lọ́wọ́ sí 2 Kọ́r. 6:14-17; 11:13-15;
àwọn ètò tó jẹ́ ti àmúlùmálà Gál. 5:9; Diu. 7:1-5
ìgbàgbọ́
Kristẹni ní láti ya ara rẹ̀ Ják. 4:4; 1 Jòh. 2:15;
sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé Jòh. 15:19; 17:16
Pa àwọn òfin èèyàn tí kò bá ti Mát. 22:20, 21; 1 Pét. 2:12;
forí gbárí pẹ̀lú ti Ọlọ́run mọ́ 1Pé 4:15
Jíjẹ tàbí mímu ẹ̀jẹ̀ yálà láti Jẹ́n. 9:3, 4; Léf. 17:14;
ẹnu tàbí fífà á gba inú Ìṣe 15:28, 29
iṣan rú àwọn òfin Ọlọ́run
A ní láti ṣègbọràn sí àwọn 1 Kọ́r. 6:9, 10; Héb. 13:4;
òfin ìwà híhù tí Bíbélì là 1 Tím. 3:2; Òwe 5:1-23
sílẹ̀
Ísírẹ́lì nìkan ni Ọlọ́run ní Diu. 5:15; Ẹ́kís. 31:13;
kí ó pa òfin Sábáàtì mọ́ ó Róòmù 10:4; Gál. 4:9, 10;
sì dópin pẹ̀lú Òfin Mósè Kól. 2:16, 17
Kò tọ́ láti ní àwùjọ àlùfáà àti Mát. 23:8-12; 20:25-27;
láti máa jẹ́ àkànṣe orúkọ oyè Jóòbù 32:21, 22
Èèyàn ò dédé wà fúnra rẹ̀ ẹnì Aísá. 45:12; Jẹ́n. 1:27;
kan ló dá a Mát. 19:4
Kristi fi àpẹẹrẹ tí a gbọ́dọ̀ tẹ̀ 1 Pét. 2:21; Héb. 10:7;
lé lélẹ̀ nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run Jòh. 4:34; 6:38
Batisí nípa rírini bọmi Máàkù 1:9, 10; Jòh. 3:23;
pátápátá jẹ́ àmì tó ṣàpẹẹrẹ Ìṣe 19:4, 5
ìyàsímímọ́
Tìdùnnú-tìdùnnú ni àwọn Róòmù 10:10; Héb. 13:15;
Kristẹni fi ń jẹ́rìí nípa Aísá. 43:10-12
òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ fáráyé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
AYÉ . . . Jèhófà ló dá a . . . kéèyàn máa bójú tó o . . . ká sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé