ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ojú ìwé 71-ojú ìwé 73 ìpínrọ̀ 3
  • Fífi Lẹ́tà Báni Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Lẹ́tà Báni Sọ̀rọ̀
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Lẹ́tà Wàásù
  • Àlàyé Ṣókí Nípa Bí Lẹ́tà Yẹn Ṣe Rí
  • Lo Gbólóhùn Tó Tọ́
  • Àpẹẹrẹ Lẹ́tà Tá A Lè Fi Wàásù
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Kọ Lẹ́tà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ojú ìwé 71-ojú ìwé 73 ìpínrọ̀ 3

Fífi Lẹ́tà Báni Sọ̀rọ̀

LẸ́TÀ ti tún ayé àti ìwà ẹgbàágbèje èèyàn ṣe láyé yìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ló jẹ́ pé lẹ́tà ni wọ́n pilẹ̀ jẹ́. Lóde òní, àwa náà lè kọ lẹ́tà láti fi gbé ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ró, láti fi kàn sí àwọn ọ̀rẹ́ wa, láti fi fún àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin tó gba ẹrù iṣẹ́ pàtàkì níṣìírí, láti fi fún ẹni tó wà nínú ìṣòro lókun, àti láti fi fún ìjọ ní ìsọfúnni tí wọ́n nílò fún ìgbòkègbodò wọn.—1 Tẹs. 1:1-7; 5:27; 2 Pét. 3:1, 2.

Lẹ́tà kíkọ tún jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ láti gbà jẹ́rìí. Ní àwọn ibì kan, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn abúlé kan tàbí àwọn ibòmíràn wà tí wọn kì í gbani láyè láti wàásù fàlàlà. Àwọn kan kì í sábà gbélé, nípa bẹ́ẹ̀ a kì í rí wọn bá sọ̀rọ̀ nígbà tí a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Àdádó làwọn mìíràn sì ń gbé.

Àìsàn, ojú ọjọ́ tí kò dáa, tàbí òfin kó-nílé-gbélé lè há ọ mọ́lé. Ǹjẹ́ o lè lo àsìkò yẹn láti kọ lẹ́tà láti fi wàásù síwájú sí i fún ẹbí rẹ kan tàbí ẹnì kan tí o ti bá sọ̀rọ̀ rí? Ṣé ọ̀kan lára ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ ṣí lọ síbòmíràn ni? Ó lè jẹ́ lẹ́tà tó o bá kọ sí i gan-an lohun tí yóò mú kí ìfẹ́ tó ní sí nǹkan tẹ̀mí máa bá a lọ. Bóyá o sì lè kọ ìsọfúnni tó bá a mu látinú Ìwé Mímọ́ ránṣẹ́ sí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, àwọn tó di ọlọ́mọ, tàbí ẹnì kan téèyàn rẹ̀ kú.

Fífi Lẹ́tà Wàásù

Tó bá di pé o ń kọ̀wé láti fi wàásù fún ẹni tí o kò tíì bá pàdé rí, kọ́kọ́ sọ ẹni tó o jẹ́ ná. O lè ṣàlàyé pé ńṣe lò ń kópa nínú iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni kan tó ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé. Bó o bá rí i pé ó yẹ, o lè mẹ́nu kàn án pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́. Sọ ìdí tó o fi ń kọ̀wé sí i dípò tó ò bá fi wá sí ilé rẹ̀. Kọ lẹ́tà rẹ lọ́nà tí yóò fi dà bíi pé ńṣe lò ń bá a sọ̀rọ̀ lójúkojú. Àmọ́ ṣá o, bí Jésù ti sọ fún wa pé a gbọ́dọ̀ ‘jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí á jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà,’ ronú dáadáa nípa ìwọ̀n ohun tó o máa sọ nípa ara rẹ fún onítọ̀hún.—Mát. 10:16.

Wá kọ ohun tó o máa sọ fún ẹni náà tó bá jẹ́ pé ńṣe lo lọ sí ilé rẹ̀ sínú lẹ́tà rẹ. O lè lo ìsọfúnni inú ìwé Reasoning tàbí kó o lo ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ tá a ti ṣètò sínú ẹ̀dà Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ lọ́nà tó bá ohun tó o fẹ́ sọ mu. O lè béèrè ìbéèrè kí o wá gba onítọ̀hún níyànjú láti ronú lé e lórí. Ọgbọ́n táwọn akéde kan máa ń dá ni pé wọ́n á kàn ṣàlàyé pé a ní ìṣètò fún dídáhùn ìbéèrè tí àwọn èèyàn bá ní lórí Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, wọn a sì wá tọ́ka sí àwọn orí kan nínú àwọn ìwé tí a ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Àpẹẹrẹ irú lẹ́tà tá a kọ láti fi jẹ́rìí wà lójú ewé 73. Ó lè là ọ́ lóye, àmọ́ ohun tó dára ni pé kó o má ṣe jẹ́ kí àwọn lẹ́tà rẹ máa jẹ́ ọ̀rọ̀ kan náà ṣáá. Bó bá lọ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn gba irú lẹ́tà kan náà léraléra.

Àwọn èèyàn kan kì í fẹ́ ka lẹ́tà gígùn tó bá ti ọ̀dọ̀ àjèjì wá. Torí náà, á dára kí lẹ́tà rẹ mọ ní ṣókí. Má ṣe jẹ́ kí lẹ́tà rẹ gùn jù, kó má di pé á sú ẹni tó gbà á kó tó kà á tán. Yóò jẹ ohun tó bá a mu pé kí o fi ìwé ìkésíni wá sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba sínú lẹ́tà rẹ. O lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ, tàbí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! pẹ̀lú rẹ̀ kí o sì wá ṣàlàyé pé ó lè máa rí nǹkan wọ̀nyẹn gbà déédéé tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. O sì tún lè bi onítọ̀hún bóyá o lè wá a wá sílé láti wá bá a sọ̀rọ̀ síwájú sí i lórí kókó tí o sọ̀rọ̀ lé lórí.

Àlàyé Ṣókí Nípa Bí Lẹ́tà Yẹn Ṣe Rí

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 73

Wo lẹ́tà tí a fi ṣe àpẹẹrẹ wàyí. Kíyè sí nǹkan wọ̀nyí: (1) Ó wà létòlétò, kò lọ́jú pọ̀. (2) Kódà bí ẹni tó gba lẹ́tà kò bá rí àpò ìwé tá a fi lẹ́tà ọ̀hún sí mọ́, yóò ṣì lè mọ orúkọ àti àdírẹ́sì tí ẹni tó kọ ọ́ fi ń gba lẹ́tà. (3) Ìpínrọ̀ kìíní la ti ṣàlàyé ète lẹ́tà yẹn ní wẹ́rẹ́ lọ́nà tó ṣe ṣàkó. (4) Kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan la bójú tó ní ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan. (5) Nítorí iṣẹ́ tí a fẹ́ kí lẹ́tà yẹn ṣe, a kò kọ ọ́ gẹ́gẹ́ bíi lẹ́tà sí ojúlùmọ̀ ẹni, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi gbogbo ara ṣọ́ èdè lò bí ẹni ń kọ lẹ́tà tó jẹ mọ́ ọ̀ràn iṣẹ́.

Tó bá jẹ́ lẹ́tà tó jẹ mọ́ ọ̀ràn iṣẹ́, bí irú èyí tí akọ̀wé ìjọ máa ń kọ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka, orúkọ ìjọ yóò wà níbẹ̀, pẹ̀lú orúkọ akọ̀wé fúnra rẹ̀, àdírẹ́sì tó fi ń gba lẹ́tà, àti ọjọ́ tó kọ lẹ́tà. Orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni tàbí àjọ tí a ń kọ lẹ́tà sí yóò wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Ìkíni tó tọ́ yóò wá tẹ̀ lé e. Gbólóhùn bí, “Èmi ni tiyín ní tòótọ́” ló máa ń parí lẹ́tà yẹn ní àwọn èdè kan, tí onítọ̀hún yóò sì wá buwọ́ lù ú lẹ́yìn náà. Ọwọ́ ni ká fi kọ àmì ìbuwọ́lùwé wa o.

Irú lẹ́tà èyíkéyìí tí o bá fẹ́ kọ, rí i pé o lo ìlànà àkọtọ́ yíyẹ, èdè tó jíire, àti àwọn àmì ìpíngbólóhùn tó tọ̀nà, kí lẹ́tà yẹn sì wà létòlétò. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á buyì kún lẹ́tà rẹ àti iṣẹ́ tí o fẹ́ fi lẹ́tà náà jẹ́.

Máa kọ àdírẹ́sì ìdésìpadà sẹ́yìn àpòòwé nígbà gbogbo, ó sì dára kó jẹ́ àdírẹ́sì tí ìwọ fúnra rẹ fi ń gba lẹ́tà. Tí o bá ronú pé kò ní bọ́gbọ́n mu pé kí o kọ àdírẹ́sì tìrẹ gangan nígbà tí o bá ń kọ lẹ́tà ìjẹ́rìí sí ẹnì kan tó ò mọ̀ rí, bi àwọn alàgbà bóyá wọ́n á gbà kí o lo àdírẹ́sì tí ẹ fi ń gbàwé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yín. Má ṣe lo àdírẹ́sì Watch Tower Society fún ète yìí rárá, nítorí á mú kó dà bíi pé ọ́fíìsì Society ni wọ́n ti kọ lẹ́tà sí onítọ̀hún, kò sì dára bẹ́ẹ̀, nítorí ó máa ń fa ìdàrúdàpọ̀. Bó ò bá kọ àdírẹ́sì ìdésìpadà tí o sì fi ìwé ìròyìn ránṣẹ́ pẹ̀lú lẹ́tà yìí, ìyẹn náà lè mú kí wọ́n rò pé Society ló fi í ránṣẹ́, kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.

Rí i dájú pé o lo iye sítáǹbù tó yẹ, pàápàá tí o bá fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sínú lẹ́tà náà. Bí sítáǹbù tí o lò kò bá tó, ilé ìfìwéránṣẹ́ yóò gba ìyókù lọ́wọ́ ẹni tí o kọ̀wé sí, ìyẹn á sì bu iṣẹ́ tí o fẹ́ jẹ́ kù. Rántí pé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, tí o bá ti fi ìwé pẹlẹbẹ tàbí ìwé ìròyìn ránṣẹ́ pọ̀ mọ́ lẹ́tà, iye tí o máa san láti fi gbé e lọ yóò ju iye ti lẹ́tà nìkan lọ.

Lo Gbólóhùn Tó Tọ́

Tí o bá ti wá parí lẹ́tà rẹ, kí o kà á láti wo bí ohun tó o kọ síbẹ̀ ṣe rí. Báwo ló ṣe dún létí? Ṣé ó fìwà bí ọ̀rẹ́ hàn, ṣé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì bọ́gbọ́n mu? Ìfẹ́ àti inú rere jẹ́ ara àwọn ànímọ́ tá a máa ń ṣakitiyan láti lò nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Gál. 5:22, 23) Bí ó bá dà bíi pé ọ̀rọ̀ yẹn kò fẹ́ dáa tó tàbí pé ó fi hàn pé ohun tó o ń sọ kò dá ọ lójú, tún ọ̀rọ̀ yẹn ṣe.

Lẹ́tà lè dé àwọn ibi tó ò lè dé. Kókó yìí nìkan pàápàá mú kó jẹ́ ohun pàtàkì tí èèyàn lè lò fún iṣẹ́ ìwàásù. Ẹni tó ń ka lẹ́tà rẹ yóò gbà pé ìwọ gan-an lò ń bá òun sọ̀rọ̀, tí ò ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fóun, nípa bẹ́ẹ̀ ó yẹ kó o ronú dáadáa nípa ohun tí o máa kọ, bí lẹ́tà yẹn ṣe máa rí lójú, àti bí ó ṣe máa dún létí. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ gan-an lọ̀rọ̀ tí yóò mú kí ọkàn kan tó ṣeyebíye bẹ̀rẹ̀ sí rìn lọ́nà ìyè, tàbí tí yóò gbé e ró, tàbí tí yóò gbà á níyànjú láti máa rìn lójú ọ̀nà yẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́