ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/02 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Lẹ́tà Tá A Lè Fi Wàásù
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Fífi Lẹ́tà Báni Sọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àwọn Ìbùkún Tó Ń Wá Látinú Fífi Ìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Wa—Apá Kejì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 5/02 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Kí nìdí tó fi yẹ ká lo ìṣọ́ra nígbà tá a bá ń jẹ́rìí nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ?

Jíjẹ́rìí nípasẹ̀ lẹ́tà kíkọ jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan tá a ti ń lò látọjọ́ pípẹ́ láti sọ ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. Àmọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí ti mú káwọn èèyàn máa sá fún jíjá àwọn lẹ́tà tí wọn ò bá mọ ẹni tó kọ wọ́n. Àwọn èèyàn sábàá máa ń fura sí àwọn àpòòwé tí kò bá ní àdírẹ́sì ẹni tó kọ ọ́ lára, àgàgà tó bá jẹ́ pé ọwọ́ ni wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ sára àpòòwé ọ̀hún tó sì rí dẹ̀ǹkù. Àwọn onílé lè wábi sọ irú àwọn lẹ́tà bẹ́ẹ̀ sí láìtiẹ̀ já a wò rárá. Kí la lè ṣe kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ má ṣẹlẹ̀?

Bó bá ṣeé ṣe, ńṣe ni kí a fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tẹ àwọn ọ̀rọ̀ lẹ́tà náà àti ti ara àpòòwé tá a fi sí. Kí a rí i pé a kọ orúkọ onílé náà sí àpòòwé lára. Má ṣe kọ “Onílé” sẹ́yìn àpòòwé náà. Láfikún sí i, rí i pé ò ń kọ àdírẹ́sì tìrẹ náà sí ara rẹ̀ nígbà gbogbo. Bí kò bá bọ́gbọ́n mu pé kó o kọ àdírẹ́sì rẹ sí i lára, tẹ orúkọ rẹ àti àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba yín sí i lára. Má ṣe fi lẹ́tà tí kò lórúkọ ránṣẹ́. Má ṣe lo àdírẹ́sì ẹ̀ka iléeṣẹ́ o.—Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù November 1996.

A lè rí àwọn ìdámọ̀ràn síwájú sí i àti àpẹẹrẹ irú lẹ́tà kan bẹ́ẹ̀ nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 71 sí 73. Àwọn ìlànà wọ̀nyí àtàwọn tó wà nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun, ojú ìwé 87, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lo lẹ́tà kíkọ lọ́nà tó gbéṣẹ́ láti wàásù ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́