Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí ni ó yẹ kí a ní lọ́kàn nígbà tí a bá ń kọ lẹ́tà sí onílé tí ó ṣòro fún wa láti bá nílé?
Fún onírúurú ìdí, ó túbọ̀ ń ṣòro fún wa, ní àwọn agbègbè kan, láti bá àwọn ènìyàn nílé, nígbà tí a bá ṣèbẹ̀wò sí ilé wọn. Àwọn akéde kan ti rí i pé, kíkọ lẹ́tà jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ láti kàn wọ́n lára. Bí èyí tilẹ̀ lè mú èso rere jáde, ó ṣe pàtàkì láti gbé àwọn ìránnilétí kan yẹ̀ wò, tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìṣòro kan:
Má ṣe lo àdírẹ́sì Society. Èyí yóò fi hàn lọ́nà tí kò tọ́ pé, ọ́fíìsì wa ni lẹ́tà náà ti wá, tí yóò sì fa àwọn ìṣòro tí kò yẹ kí ó wáyé rárá, àti àfikún ìnáwó nígbà míràn pàápàá.
Rí i dájú pé o ní àdírẹ́sì onílé náà lọ́wọ́, àti sítám̀pù tí yóò gbé e.
Má ṣe kọ “Onílé” sẹ́yìn lẹ́tà náà; lo orúkọ kan pàtó.
Má ṣe fi lẹ́tà há ẹnu ọ̀nà, nígbà tí kò bá sí ẹnikẹ́ni nílé.
Lẹ́tà ṣókí ni ó dára jù lọ. Fi àṣàrò kúkúrú kan sínú rẹ̀, dípò gbígbìyànjú láti kọ ọ̀rọ̀ gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ.
Lẹ́tà tí a fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tẹ̀ máa ń rọrùn láti kà, ó sì ń tẹ èrò tí ó dára mọ́ni lọ́kàn.
A kò lè ka lẹ́tà kíkọ sí ìpadàbẹ̀wò, àyàfi bí o bá ti rí ẹni náà sójú tẹ́lẹ̀ rí, tí o sì ti jẹ́rìí fún un.
Bí o bá ń kọ̀wé sí ẹnì kan tí ó ti fi ìfẹ́ hàn tẹ́ lẹ̀, o ní láti fún un ní àdírẹ́sì tàbí nọ́ḿbà fóònù rẹ, kí ó baà lè kàn sí ọ. Ṣàlàyé ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa fún un.
Ké sí i wá sí àwọn ìpàdé ìjọ àdúgbò. Fún un ní àdírẹ́sì ibẹ̀ àti àkókò ìpàdé.
Dáwọ fífi lẹ́tà ránṣẹ́ sí kò-sí-nílé dúró, lẹ́yìn tí o bá ti dá káàdì ìpínlẹ̀ náà padà; akéde tí ó ní káàdì ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ni ó ni ẹrù iṣẹ́ ṣíṣiṣẹ́ nínú rẹ̀.