Ètò Sísọni Di Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti Olùkọ́ni
Ì BÁÀ jẹ́ ọmọdé ni ọ́ tàbí àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin, ètò ẹ̀kọ́ yìí lè sọ ọ́ di ẹni tó lè ṣàlàyé ara rẹ̀ lọ́nà tó múná dóko, kí o sì di ọ̀jáfáfá nínú kíkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ni yóò máa yan iṣẹ́ fúnni nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí. Wàá rí ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ tìrẹ ní ojú ewé 79 sí 81. Àwọn nọ́ńbà tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ kókó ìmọ̀ràn kọ̀ọ̀kan tọ́ka sí nọ́ńbà ẹ̀kọ́ tó dá lórí kókó yẹn tí a óò rí níwájú. Inú ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn lo ti máa rí àlàyé ohun tí èèyàn lè ṣe láti mọ àwọn ẹ̀ka ọ̀rọ̀ sísọ àti ìkọ́ni wọ̀nyí àti ìdí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fi ṣe pàtàkì. Wàá tún rí ìtọ́ni tó wúlò gbà nípa béèyàn ṣe lè ṣe ohun tí a dámọ̀ràn.
Onírúurú àwọ̀ tó wà lórí ìwé ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ yẹn ń tọ́ka sí àwọn kókó tó kan iṣẹ́ tó dá lórí (1) ìwé kíká fún àwùjọ, (2) àṣefihàn tí ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ yóò ṣe, àti (3) ọ̀rọ̀ tí a ó sọ fún àwùjọ ní tààràtà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni yóò yan kókó tó o bá máa ṣiṣẹ́ lé lórí. Yóò dára pé kó jẹ́ kókó kan ni wàá máa ṣiṣẹ́ lé lórí lẹ́ẹ̀kan. Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ ìdánrawò tá a dábàá rẹ̀ níparí ẹ̀kọ́ tá a yàn fún ọ, yóò ṣe ọ́ láǹfààní. Bí o bá jẹ́ kó hàn pé o ti yege nínú fífi ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n yàn fún ọ sílò, olùdámọ̀ràn á tún yan kókó mìíràn fún ọ.
Bí iṣẹ́ rẹ bá jẹ́ èyí tó o máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣefihàn, yóò béèrè pé kí o ní ìgbékalẹ̀ kan. A to oríṣiríṣi ìgbékalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ sójú ewé 82, àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ lo lè lò o. Olùdámọ̀ràn lè dábàá pé kí o dán àwọn ìgbékalẹ̀ kan wò kí o fi lè nírìírí, tàbí kí ó jẹ́ kó o fúnra rẹ yan èyí tó bá wù ọ́.
Tí o bá ń ka ìwé yìí tó o sì ń ṣe àwọn ìdánrawò ibẹ̀, kódà láìjẹ́ pé ò ń múra iṣẹ́ sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́, ó lè mú kó o túbọ̀ tẹ̀ síwájú dáadáa. Bóyá kó o tiẹ̀ máa parí nǹkan bí ẹ̀kọ́ kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Bó ti wù kó pẹ́ tó tí o ti ń kópa nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí tàbí tó o ti ń lọ sóde ẹ̀rí, àwọn ibì kan yóò ṣì wà tó yẹ kó o ti tẹ̀ síwájú. Àdúrà wa ni pé kó o lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.