ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 8 ojú ìwé 107-ojú ìwé 110 ìpínrọ̀ 2
  • Lílo Ohùn Bí Ó Ti Yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílo Ohùn Bí Ó Ti Yẹ
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Wíwo Ojú Àwùjọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 8 ojú ìwé 107-ojú ìwé 110 ìpínrọ̀ 2

Ẹ̀KỌ́ 8

Lílo Ohùn Bí Ó Ti Yẹ

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o fi ohùn tó ròkè tàbí èyí tó dún ketekete bó ṣe yẹ sọ̀rọ̀. Láti lè pinnu bí ó ṣe yẹ kí o lo ohùn, ronú nípa (1) bí àwọn olùgbọ́ rẹ ṣe pọ̀ tó àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́, (2) àwọn ariwo tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀, (3) ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àti (4) ohun tó o ní lọ́kàn.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bó bá lọ ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn kò lè gbọ́ nǹkan tí ò ń sọ dáadáa, ọkàn wọn lè máa ro tibí ro tọ̀hún, ohun tí ò ń sọ sì lè máà yé wọn. Bí o bá kígbe sọ̀rọ̀ jù, ó lè máa ta àwọn èèyàn létí, ó tiẹ̀ lè dà bí ìwà àfojúdi pàápàá.

BÍ ALÁSỌYÉ kan kò bá mọ bí a ṣe ń lo ohùn bó ṣe yẹ, àwọn kan nínú àwùjọ lè bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé. Bí akéde kan bá ń sọ̀rọ̀ lóhùn hẹ́rẹ́hẹ́rẹ́ lóde ẹ̀rí, bóyá lọ̀rọ̀ rẹ̀ á fi lè wọ onílé lọ́kàn. Tó bá sì wá jẹ́ ní ìpàdé, tí àwọn èèyàn inú àwùjọ bá ń dáhùn láìgbóhùn sókè tó, àwọn tó wà níbẹ̀ kò ní rí ìṣírí tó yẹ gbà. (Héb. 10:24, 25) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí olùbánisọ̀rọ̀ kan bá gbé ohùn rẹ̀ sókè nígbà tí kò yẹ, ó lè han àwọn olùgbọ́ létí, kódà ó lè bí wọn nínú.—Òwe 27:14.

Ronú Nípa Àwọn Olùgbọ́ Rẹ. Ta lò ń bá sọ̀rọ̀? ṣé ẹnì kan ni? ṣé ìdílé kan ni? ṣé àwùjọ kékeré kan tó pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ni? ṣé odindi ìjọ ni? Àbí àpéjọ ńlá kan ni? Ó dájú pé ohùn tó ròkè tó bá a mu níbì kan lè jẹ́ èyí tí kò ní bá a mu níbòmíràn.

Onírúurú ìgbà ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti bá àwùjọ ńlá sọ̀rọ̀. Nígbà ìfilọ́lẹ̀ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Sólómọ́nì, kò sí ẹ̀rọ gbohùngbohùn. Nítorí náà, orí pèpéle gíga kan ni Sólómọ́nì dúró sí, tó sì “fi ohùn rara” súre fún àwọn èèyàn náà. (1 Ọba 8:55; 2 Kíró. 6:13) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ni ògìdìgbó èèyàn bá pé jọ yí ká àwùjọ àwọn Kristẹni kéréje tó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn kan nínú wọn fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn, àwọn mìíràn sì ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà. Pétérù ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu, ó “dìde dúró . . . ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè.” (Ìṣe 2:14) Ó sì wàásù fún wọn dáadáa.

Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá o ń lo ohùn bo ṣe yẹ ní àkókò kan? Ìṣarasíhùwà àwọn olùgbọ́ rẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti fi mọ̀. Bí o bá kíyè sí i pé ńṣe làwọn kan nínú àwùjọ ń kẹ́tí kí wọ́n tó lè gbọ́rọ̀ rẹ, a jẹ́ pé ó yẹ kóo gbìyànjú láti gbóhùn sókè nìyẹn.

Yálà ẹnì kan ṣoṣo là ń bá sọ̀rọ̀ tàbí àwùjọ kan, ó bọ́gbọ́n mu ká ronú nípa irú àwọn èèyàn tó ń gbọ́ wa. Bí o bá ń bá ẹni tí kì í gbọ́ràn dáadáa sọ̀rọ̀, ó yẹ kí o gbé ohùn sókè. Ṣùgbọ́n bí o bá ń kígbe sọ̀rọ̀, àwọn arúgbó tí kì í lè tara ṣàṣà ṣe nǹkan kò ní fẹ́ràn rẹ. Wọ́n tilẹ̀ lè gbà pé ńṣe lo ń hùwà àrífín. Lágbo àwọn ẹ̀yà kan, bí èèyàn bá ń kígbe sọ̀rọ̀, wọ́n gbà pé ńṣe ni inú ń bí onítọ̀hún tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni kò ní sùúrù.

Ronú Nípa Ariwo Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Pọkàn Pọ̀. Nígbà tí o bá wà lóde ẹ̀rí, ó dájú pé ipò tí o bá bá pàdé máa ń nípa lórí bí o ṣe máa gbé ohùn sókè tó nígbà tí o bá ń wàásù. Ó lè jẹ́ pé o ní láti sọ̀rọ̀ sókè kí ohùn rẹ lè borí ariwo ọkọ̀, ariwo àwọn ọmọdé, ariwo àwọn ajá tó ń gbó, orin aláriwo, tàbí tẹlifíṣọ̀n tó ń ké tantan. Àmọ́, ní àwọn àgbègbè tí ilé ti sún mọ́ra, ó lè ti ẹni tí ò ń wàásù fún lójú bí o bá ń sọ̀rọ̀ fatafata débi tí àwọn aládùúgbò yòókù fi ń gbọ́.

Àwọn arákùnrin tó máa ń sọ̀rọ̀ nínú ìjọ tàbí ní àwọn àpéjọ pẹ̀lú gbọ́dọ̀ mọ bí wọ́n ṣe ní láti lo ohùn ní onírúurú ipò. Bíbá àwùjọ sọ̀rọ̀ ní gbangba yàtọ̀ pátápátá sí sísọ̀rọ̀ nínú gbọ̀ngàn kan tí wọ́n kọ́ lọ́nà tó fi lè gbé ohùn yọ. Àní àwọn míṣọ́nnárì méjì kan tiẹ̀ pín àsọyé sọ ní àgbàlá ilé olùfìfẹ́hàn kan ní orílẹ̀-èdè Látìn Amẹ́ríkà lásìkò tí àwọn aláyẹyẹ kan ń pariwo gèè ní gbàgede ìlú tó wà nítòsí ibẹ̀, tí àkùkọ kan sì tún ń kọ ṣáá lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn!

Láàárín àsọyé kan, ohun kan lè ṣẹlẹ̀ táá béèrè pé kí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ dá ẹnu dúró títí dìgbà tí ohun ìdíwọ́ náà á fi lọ kúrò tàbí kí ó kúkú gbé ohùn sókè. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé abẹ́ ilé kan tí òrùlé rẹ̀ jẹ́ páànù ni a ti ń ṣe ìpàdé, bí òjò ńlá kan bá bẹ̀rẹ̀ lójijì, ó lè mú kó ṣòro fún àwùjọ láti gbọ́ ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ. Bí ọmọ kan bá ń sọkún tàbí bí àwọn apẹ́lẹ́yìn kan bá ń fa ìdíwọ́, ìyẹn á jẹ́ ìṣòro kan. Kọ́ bí o ṣe lè borí irú àwọn ohun tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀ bẹ́ẹ̀ kí àwọn olùgbọ́ rẹ lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú ohun tí ò ń sọ.

Bí gbohùngbohùn bá wà, yóò ṣèrànwọ́, ṣùgbọ́n ìyẹn kò wá sọ pé kí olùbánisọ̀rọ̀ má ṣe gbé ohùn sókè nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Láwọn ibì kan tí iná ti sábà máa ń ṣe mánamàna, ó di dandan fún àwọn olùbánisọ̀rọ̀ láti máa bá ọ̀rọ̀ wọn lọ láìlo makirofóònù.

Ronú Nípa Àkójọ Ọ̀rọ̀ Tí Ò Ń Sọ̀rọ̀ Lé Lórí. Irú ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí tún ń ní ipa lórí bí o ṣe ní láti gbé ohùn sókè tó. Bí ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ wé mọ́ bá ń béèrè pé kí o sọ ọ́ lọ́nà tó le, má ṣe sọ ọ̀rọ̀ yẹn di yẹpẹrẹ nípa sísọ̀rọ̀ lọ́nà tó tutù jù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí o bá ń ka ibi tó jẹ́ ìbáwí mímúná nínú Ìwé Mímọ́, ó yẹ kí ohùn rẹ lágbára ju ìgbà tí o bá ń ka ibi tó jẹ́ ìmọ̀ràn lórí fífi ìfẹ́ hàn lọ. Jẹ́ kí ohùn rẹ bá irú ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ mu, ṣùgbọ́n ṣọ́ra o, kó má lọ di pé ò ń pe àfiyèsí sí ara rẹ.

Ronú Nípa Ohun Tó Jẹ́ Ète Rẹ. Bí ó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ ta àwọn olùgbọ́ rẹ jí kí wọ́n lè fi ìtara kópa nínú ìgbòkègbodò kan, ó yẹ kí ohùn rẹ túbọ̀ rinlẹ̀. Bó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ yí ìrònú wọn padà, má ṣe fi igbe lé wọn sá. Bó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ tù wọ́n nínú, ohùn pẹ̀lẹ́ ló yẹ kí o lò.

Ọ̀nà Tó Dára Láti Gbà Gbóhùn Sókè. Bí o bá ń gbìyànjú láti pe àfiyèsí ẹni tọ́wọ́ rẹ̀ dí, ó sábà máa ń dára láti gbóhùn sókè. Àwọn òbí mọ èyí, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń gbóhùn sókè tí wọ́n bá fẹ́ pe àwọn ọmọ wọn nígbà tó bá tó àkókò pé kí wọ́n ṣíwọ́ eré kí wọ́n sì wálé. Ohùn tó ròkè tún lè pọn dandan nígbà tí alága bá ń fẹ́ kí àwọn ará dákẹ́ ariwo ní ìpàdé ìjọ tàbí àpéjọ. Bí àwọn akéde bá wà lóde ẹ̀rí, wọ́n lè gbóhùn sókè láti kí àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ níta.

Kódà nígbà tí o bá pe àfiyèsí ẹnì kan tán, ó ṣe pàtàkì pé kí o gbóhùn sókè tó bó ṣe yẹ. Ohùn tó lọ sílẹ̀ jù lè mú kí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ rò pé ẹni tó ń bá òun sọ̀rọ̀ kò múra sílẹ̀ tó tàbí pé ohun tó ń sọ kò dá a lójú.

Bí ó bá jẹ́ pé àṣẹ la fẹ́ pa, tí a sì gbóhùn sókè sọ ọ́, ìyẹn lè mú kí àwọn èèyàn ṣe bí a ṣe wí. (Ìṣe 14:9, 10) Bákan náà, kíkígbe pa àṣẹ kan lè dènà jàǹbá. Ní ìlú Fílípì, onítúbú kan fẹ́ pa ara rẹ̀ nítorí ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n òun ti sá lọ. Ni “Pọ́ọ̀lù [bá] ké ní ohùn rara pé: ‘Má ṣe ara rẹ lọ́ṣẹ́, nítorí pé gbogbo wa wà níhìn-ín!’” Bí ẹni yẹn kò ṣe para rẹ̀ nìyẹn. Ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà bá wàásù fún onítúbú yẹn àti agbo ilé rẹ̀, gbogbo wọn sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́.—Ìṣe 16:27-33.

Bí O Ṣe Lè Máa Lo Ohùn Rẹ Lọ́nà Tó Túbọ̀ Dára Sí I. Ní ti àwọn kan, wọ́n gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kí wọ́n tó lè mọ bí wọ́n ṣe lè máa lo ohùn bó ṣe yẹ. Ẹnì kan lè má lè gbóhùn sókè tó nítorí pé ohùn rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ ròkè. Ṣùgbọ́n, bó bá sapá, ó lè túbọ̀ ṣe dáadáa sí i bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohùn rẹ̀ ṣì lè jẹ́ ohùn tí kò le. Fiyè sí bí o ṣe ń mí àti ìdúró rẹ. Fi jíjókòó àti dídúró láìtẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kọ́ra. Tẹ èjìká rẹ méjèèjì sẹ́yìn, kí o sì máa mí kanlẹ̀. Rí i dájú pé o ń jẹ́ kí èémí dé ìsàlẹ̀ ẹ̀dọ̀fóró rẹ lọ́hùn-ún. Tó o bá darí afẹ́fẹ́ tí ò ń mí sínú yìí bó ṣe yẹ, wàá lè lo ohùn bó o ṣe fẹ́ nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀.

Ní ti àwọn mìíràn, ìṣòro tiwọn ni pé wọ́n ti lè kígbe sọ̀rọ̀ jù. Bóyá nítorí pé gbangba ìta tàbí àyíká aláriwo ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ nìyẹn fi mọ́ wọn lára. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó lè jẹ́ pé àyíká tí olúkúlùkù ti máa ń kígbe sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ti máa ń já lu ọ̀rọ̀ ni wọ́n ti dàgbà. Nítorí èyí, wọ́n á rò pé bí wọ́n bá fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀, dandan ni kí wọ́n gbóhùn sókè ju àwọn yòókù lọ. Bí wọ́n bá ṣe ń bá a nìṣó láti máa kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí wọ́n fi “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra” wọ ara wọn láṣọ, wọn yóò ṣe àtúnṣe nínú bí wọ́n ṣe ń lo ohùn nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀.—Kól. 3:12.

Ìmúrasílẹ̀ dáadáa, ìrírí tó ń wá látinú kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, àti gbígbàdúrà sí Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa fi ohùn tó yẹ sọ̀rọ̀. Bóyá o ń sọ̀rọ̀ látorí pèpéle ni o tàbí o ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí, gbìyànjú láti ronú gidigidi nípa bí wàá ṣe ran olùgbọ́ rẹ lọ́wọ́ nípa jíjẹ́ kí ó gbọ́ ohun tí ò ń sọ.—Òwe 18:21.

ÌGBÀ TÍ Ó YẸ KÍ O GBÓHÙN SÓKÈ

  • Tó o bá fẹ́ mú kí àwùjọ ńlá kan fetí sí ohun tí à ń sọ.

  • Tó o bá fẹ́ borí àwọn ohun tí kì í jẹ́ kéèyàn pọkàn pọ̀.

  • Tó o bá fẹ́ pe àfiyèsí nígbà tí a bá ń sọ ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an.

  • Tó o bá fẹ́ súnni gbé ìgbésẹ̀.

  • Tó o bá fẹ́ fi pe àfiyèsí ẹnì kan tàbí àwùjọ kan.

BÍ A ṢE LÈ ṢE DÁADÁA SÍ I

  • Máa kíyè sí ìṣarasíhùwà àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀; lo ohùn bó ṣe yẹ kí wọ́n lè gbọ́rọ̀ rẹ dáadáa.

  • Kọ́ bí wàá ṣe máa jẹ́ kí èémí dé ìsàlẹ̀ ẹ̀dọ̀fóró rẹ lọ́hùn-ún nígbà tí o bá ń mí.

ÌDÁNRAWÒ: Kọ́kọ́ ka Ìṣe 19:23-41 sínú, kí o rí i pé bí ìtàn yẹn ṣe lọ yé ọ. Kíyè sí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ àti irú ẹ̀mí tó ń fi hàn. Lẹ́yìn náà, kà á sókè kí o sì lo ohùn tó yẹ fún apá kọ̀ọ̀kan.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́