ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 111-ojú ìwé 114 ìpínrọ̀ 3
  • Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Lílo Ohùn Bí Ó Ti Yẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Sọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Sísọ̀rọ̀ Bí Ẹní Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 111-ojú ìwé 114 ìpínrọ̀ 3

Ẹ̀KỌ́ 9

Yíyí Ohùn Padà Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o jẹ́ kí ìyàtọ̀ wà nínú bí ohùn rẹ ṣe ń dún létí. Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a óò sọ̀rọ̀ nípa ìyípadà nínú bí ohùn ṣe ń relẹ̀ tó ń ròkè, bí a ṣe ń yára sọ̀rọ̀ tàbí bí a ṣe ń rọra sọ̀rọ̀, àti ìyípadà nínú ìró ohùn.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bí a bá yí ohùn padà bó ṣe yẹ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, ó máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tani jí, kó wọni lára, ó sì máa ń sún èèyàn ṣiṣẹ́ lórí ohun tó gbọ́.

Bí kò bá sí ìyípadà nínú ohùn rẹ, ó lè jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe ni o kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí kókó ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí.

TÍ O bá lo ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ tó rọrùn, ó máa ń ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ò ń sọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí o bá ń lo oríṣiríṣi ọ̀nà tó yẹ láti gbà gbóhùn sókè sódò, láti yára tàbí kí o rọra sọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́, àti láti máa yí ìró ohùn padà, ọ̀rọ̀ rẹ á dùn-ún gbọ́ gan-an ni. Ju ìyẹn lọ, ó lè jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ mọ èrò rẹ nípa ohun tí ò ń sọ. Ẹ̀mí tí o bá fi ń sọ ọ̀rọ̀ náà lè ní ipa lórí èrò tí wọ́n á ní nípa rẹ̀. Ì báà jẹ́ orí pèpéle lo ti ń sọ̀rọ̀ tàbí pé ò ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ohun kan náà yìí ló máa ń ṣẹlẹ̀.

Ohun èlò àgbàyanu ni ohùn ẹ̀dá èèyàn jẹ́, ó sì ṣeé lò lónírúurú ọ̀nà tó pọ̀ gidigidi. Bí a bá lò ó lọ́nà yíyẹ, ó lè mú kí ọ̀rọ̀ tani jí, kí ó wọni lọ́kàn, kí ó wọni lára, kí ó sì múni ṣiṣẹ́ lórí ohun tá a gbọ́. Ṣùgbọ́n, o kò lè ṣe èyí nípa wíwulẹ̀ fa ìlà sídìí ọ̀rọ̀ inú ìwé rẹ láti fi sọ ibi tó o ti máa gbé ohùn sókè tàbí rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, tàbí ibi tó o ti máa yára tàbí rọra sọ̀rọ̀, tàbí ibi tó o ti máa lo onírúurú ìró ohùn. Bí a bá ní ká fi àmì wọ̀nyẹn máa ṣe ìyípadà ohùn ní irú ibi wọ̀nyẹn, ọ̀rọ̀ wa kò ní dán mọ́rán. Dípò kí ó mú kí ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ tani jí kí ó sì lárinrin, ó lè mú kí ara ni àwọn olùgbọ́ rẹ. Inú ọkàn ẹni ni yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ lọ́nà yíyẹ ti ń wá.

Bí olùbánisọ̀rọ̀ bá yí ohùn padà lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀, kò ní pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìtumọ̀ kókó ẹ̀kọ́ tí ẹni tó ń báni sọ̀rọ̀ ń ṣàlàyé.

Ṣe Ìyípadà Nínú Bí O Ṣe Ń Gbóhùn Sókè Tàbí Bí O Ṣe Ń Rẹ Ohùn Sílẹ̀. Ọ̀nà kan láti fi ìyàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ ni nípa gbígbóhùn sókè tàbí rírẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n èyí kò gbọ́dọ̀ jẹ́ pé kó o kàn máa gbé ohùn sókè sódò ṣáá nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Ìyẹn kò ní jẹ́ kí ohun tí o ń sọ yéni. Bí o bá ń gbé ohùn sókè ṣáá, ohun tí àwọn olùgbọ́ á rò nípa rẹ kò ní dára.

Bí o ṣe ń gbóhùn sókè sódò gbọ́dọ̀ bá ọ̀rọ̀ rẹ mu. Bóyá ńṣe lò ń ka àṣẹ kan tó jẹ́ kánjúkánjú, bí irú èyí tó wà ní Ìṣípayá 14:6, 7 tàbí ní Ìṣípayá 18:4, tàbí ọ̀rọ̀ ohun tó dáni lójú ṣáká, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Ẹ́kísódù 14:13, 14, ó dára kí o gbé ohùn sókè bó ṣe yẹ. Bákan náà, bó o bá ń ka ibì kan tó jẹ́ ìbáwí mímúná nínú Bíbélì, irú bí èyí tó wà ní Jeremáyà 25:27-38, gbígbé ohùn sókè sódò bó ṣe tọ́ yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ kan dún ju àwọn yòókù lọ.

Tún ronú nípa ohun tí o ní lọ́kàn pẹ̀lú. Ṣé o fẹ́ sún àwọn olùgbọ́ rẹ láti ṣe nǹkan kan ni? Ṣé o fẹ́ mú kí àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ hàn kedere ni? Bí o bá túbọ̀ ń gbé ohùn sókè bí o ṣe rí i pé ó yẹ, ọwọ́ rẹ á lè tẹ nǹkan wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n, kí o kàn máa gbóhùn sókè lásán lè ṣèdíwọ́ fún ohun tí o ní lọ́kàn. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó lè jẹ́ pé ohùn tó tura àti ohùn tó fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹni hàn ni ọ̀rọ̀ tí o ń sọ ń béèrè dípò gbígbé ohùn sókè. A óò ṣàlàyé èyí ní Ẹ̀kọ́ 11.

Bí o bá fi òye rẹ ohùn rẹ sílẹ̀ nígbà tó yẹ, ó lè mú kí àwọn olùgbọ́ fẹ́ mọ ohun tó o fẹ́ sọ tẹ̀ lé e. Ṣùgbọ́n ìyẹn sábà máa ń béèrè pé kó jẹ́ ohùn tó túbọ̀ ró gbọnmọgbọnmọ lèèyàn yóò lò kété lẹ́yìn náà. A lè lo ohùn rírẹlẹ̀ pa pọ̀ mọ́ èyí tó túbọ̀ ró gbọnmọgbọnmọ láti fi sọ ìdààmú ẹni tàbí ìbẹ̀rù jáde. A tún lè lo ohùn rírẹlẹ̀ láti lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ tí a sọ yìí kò ṣe pàtàkì tó àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká. Ṣùgbọ́n, bí o bá ń rẹ ohùn sílẹ̀ sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo, èyí lè mú kí àwọn èèyàn rò pé ohun tí o ń sọ kò dá ọ lójú tàbí pé o kò gba ohun tí ò ń sọ gbọ́ tàbí pé o kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Ó ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ fi òye mọ ìgbà tó tọ́ láti lo ohùn tó rẹlẹ̀ gan-an.

Máa Yí Ìwọ̀n Ìyárasọ̀rọ̀ Rẹ Padà. Nínú bí a ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, ńṣe lohun tá a bá fẹ́ sọ kàn máa ń wá sí wa lẹ́nu bí a ti ń sọ èrò inú wa. Bí inú wa bá dùn, a sábà máa ń yára sọ̀rọ̀ ni. Nígbà tí a bá fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn rántí ohun tí a sọ gẹ́lẹ́, ńṣe ni a máa ń rọra sọ̀rọ̀.

Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lórí pèpéle ló kàn máa ń sọ̀rọ̀ wọn lọ gbuurugbu láìní mọ ìgbà tó yẹ kí wọ́n yára tàbí kí wọ́n rọra sọ̀rọ̀. Kí ló fà á? Wọ́n á ti fẹ̀sọ̀ yan gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ kalẹ̀ pátá. Wọ́n lè ti kọ gbogbo rẹ̀ sílẹ̀. Kódà bí wọn kò bá ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ jáde látinú ìwé, wọ́n ti lè há gbogbo rẹ̀ sórí pátá. Nítorí èyí, ńṣe ni wọ́n kàn máa ń sọ ọ̀rọ̀ lọ gbuurugbu láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Kíkọ́ bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa lílo ìlapa èrò yóò ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnṣe ìkùdíẹ̀-káàtó yìí.

Yẹra fún ṣíṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí yára sọ̀rọ̀ táá fi wá dà bí ìgbà tí èkúté tó rọra ń rìn lọ tẹ́lẹ̀ dédé tú kẹ̀kẹ́ eré sílẹ̀ nígbà tó fojú kan ológbò. Má sì ṣe yára sọ̀rọ̀ jù débi tí o kò fi ní lè pe àwọn ọ̀rọ̀ ketekete.

Ọ̀nà láti gbà mú kí ìwọ̀n ìyárasọ̀rọ̀ rẹ yàtọ̀ síra kì í ṣe ọ̀ràn pé kó o sáà ti máa yára kó o sì tún wá máa rọra sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà. Ńṣe ni irú ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò bu ọ̀rọ̀ tí o ń sọ kù dípò kí ó mú kó sunwọ̀n sí i. O gbọ́dọ̀ mú kí ìyípadà nínú ìyárasọ̀rọ̀ rẹ bá ohun tí ò ń sọ mu, kí ó bá bí o ṣe fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ rí lára àwọn olùgbọ́ rẹ mu, kí ó sì bá ohun tí o ní lọ́kàn mu. Jẹ́ kí ìwọ̀n ìyárasọ̀rọ̀ rẹ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó ń mú inú ẹni dùn, yára sọ ọ́ lọ́nà tí o máa ń gbà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́. Èyí tún yẹ bẹ́ẹ̀ nígbà tí o bá ń sọ àwọn kókó tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tàbí nígbà tí o bá ń ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ pé kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn kò ṣe kókó. Èyí á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ lárinrin kò sì ní máa sú àwọn ènìyàn. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àlàyé tó ṣe pàtàkì, àwọn kókó pàtàkì, àti ibi tó bá jẹ́ ojú ọ̀rọ̀ ń béèrè pé kí èèyàn rọra sọ ọ́.

Lo Onírúurú Ìró Ohùn. Fojú inú wò ó pé ẹnì kan ń fi ohun èlò orin kọrin fún nǹkan bíi wákàtí kan. Ní gbogbo ìgbà yẹn, ìró kan ṣoṣo ló ń lò ṣáá, ó kọ́kọ́ mú kí dídún ìró yẹn ròkè, lẹ́yìn náà ó lọ sílẹ̀, nígbà mìíràn, yóò yá kánkán, lẹ́yìn náà yóò tún wá falẹ̀. Dídún ìró yẹn ń lọ sókè sódò, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ̀n ìyákánkán rẹ̀ yàtọ̀ síra lóòótọ́, ṣùgbọ́n ìró kan náà ló ń dún, ìyẹn kò sì mú kí “ohùn orin” náà fi bẹ́ẹ̀ dùn mọ́ni. Bákan náà, bó bá jẹ́ ìró kan ṣoṣo là ń gbé jáde ṣáá bí a ti ń sọ̀rọ̀, ohùn wa kò ní fani mọ́ra.

Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé iṣẹ́ kan náà kọ́ ni yíyí ìró ohùn padà máa ń ṣe nínú gbogbo èdè. Nínú èdè tó jẹ́ pé ìró ló ń fún ọ̀rọ̀ ní ìtumọ̀, bí èdè Yorùbá, yíyí ìró ohùn padà lè yí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ padà. Síbẹ̀, àní nínú irú èdè bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tí èèyàn lè ṣe láti mú kí ìyàtọ̀ púpọ̀ wà nínú ohun tó ń sọ. Ó lè mú kí bí òun ṣe máa yí ohùn padà sunwọ̀n sí i síbẹ̀ kí ìró ohùn kọ̀ọ̀kan ṣì dún bó ṣe yẹ kó dún. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè mú kí ìró ohùn òkè túbọ̀ ròkè sí i, kí ohùn ìsàlẹ̀ sì túbọ̀ rẹlẹ̀ sí i.

Àní nínú àwọn èdè tí kì í ṣe ìró ló ń fún ọ̀rọ̀ ní ìtumọ̀ pàápàá, yíyí ìró ohùn padà lè gbé onírúurú èrò yọ. Bí àpẹẹrẹ, èèyàn lè lo ìró ohùn òkè díẹ̀ kí o sì tún wá gbóhùn sókè dáadáa fún ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀. Tàbí kẹ̀, a lè lo ìyípadà nínú ìró ohùn láti fi bí nǹkan ṣe tóbi tó tàbí bí ó ṣe jìnnà tó hàn. Jíjẹ́ kí ìró ohùn lọ sókè ní òpin gbólóhùn kan lè fi hàn pé ìbéèrè la béèrè. Ó lè jẹ́ ìró ohùn tó lọ sílẹ̀ la máa lò láwọn èdè kan.

A lè lo ìró ohùn òkè láti fi ìdùnnú àti ìtara hàn. (Nínú èdè tó jẹ́ pé ìró ló ń fún ọ̀rọ̀ ní ìtumọ̀, ìyẹn lè béèrè fún yíyí ohùn padà lóríṣiríṣi ọ̀nà.) Ìbànújẹ́ àti àníyàn lè béèrè ohùn ìsàlẹ̀. (Tàbí nínú èdè tó jẹ́ pé ìró ló ń fún ọ̀rọ̀ ní ìtumọ̀, a lè má fi bẹ́ẹ̀ yí ohùn padà.) Lílo onírúurú ànímọ́ bí nǹkan ṣe rí lára tí a mẹ́nu kàn yìí ló ń jẹ́ kí olùbánisọ̀rọ̀ lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń wọni lọ́kàn. Nígbà tí o bá fẹ́ gbé ànímọ́ wọ̀nyẹn yọ, má kàn sọ̀rọ̀ lọ́nà ṣákálá. Lo ohùn rẹ lọ́nà kan tí yóò fi hàn pé ìwọ pẹ̀lú mọ bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe rí lára.

Fífi Ìpìlẹ̀ Lélẹ̀. Ibo wá ni yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ ti ń bẹ̀rẹ̀? Ìgbà tí o bá ń kó ọ̀rọ̀ tí o máa sọ jọ ni. Bó bá jẹ́ pé àlàyé nìkan tàbí ọ̀rọ̀ ìyànjú nìkan lo kó kún inú ọ̀rọ̀ rẹ, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sáyè fún ọ láti ṣe onírúurú ìyípadà ohùn nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀. Nítorí náà, ṣe àyẹ̀wò ìlapa èrò rẹ, kí o sì rí i dájú pé o ní àwọn èròjà táá mú kí ọ̀rọ̀ rẹ lárinrin kó sì kún fún ẹ̀kọ́.

Ká sọ pé bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, o rí i pé ó yẹ kí o bẹ̀rẹ̀ sí lo oríṣiríṣi ìyípadà ohùn nítorí pé ọ̀rọ̀ rẹ ń falẹ̀. Kí ló yẹ kí o ṣe? Yí ọ̀nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀ padà. Lọ́nà wo? Ọ̀nà kan ni nípa ṣíṣí Bíbélì, kí o wá sọ pé kí àwùjọ ṣí tiwọn, kí o sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan dípò tí wàá fi máa sọ̀rọ̀ lọ gbuurugbu. Tàbí kí o sọ àwọn gbólóhùn kan di ìbéèrè, kí o sì dá ẹnu dúró díẹ̀ kí ọ̀rọ̀ rẹ lè wọni lọ́kàn. Tún lo àpèjúwe kan tí ó rọrùn. Ọgbọ́n tí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ máa ń dá nìyí. Ṣùgbọ́n o, láìka bí o ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ tó sí, o lè lo ọgbọ́n kan náà yìí nígbà tí o bá ń múra ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀.

A lè sọ pé yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ ni adùn ọ̀rọ̀. Bí o bá yí ohùn padà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, yóò gbé gbogbo kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ yọ, yóò sì mú kí ó dùn mọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Gbóhùn sókè-sódò bó ti yẹ nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ tó jẹ́ kánjúkánjú, ohun tó dájú hán-únhán-ún, tàbí ìbáwí mímúná. Ronú dáadáa lórí àwọn apá tó ń béèrè pé kí o gbóhùn sókè.

  • Yí ìwọ̀n ìyákánkán ọ̀rọ̀ rẹ padà nípa yíyára sọ̀rọ̀ nígbà tí o bá dórí àwọn kókó tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, kí o sì rọra sọ̀rọ̀ nígbà tí o bá dórí àwọn àlàyé pàtàkì àti àwọn kókó pàtàkì. Tó o bá fẹ́ fi ìdùnnú hàn, kó o yára sọ̀rọ̀.

  • Lo onírúurú ìró ohùn, bí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀, láti fi gbé bí nǹkan ṣe káni lára sí yọ láti jẹ́ kó wọni lọ́kàn. Nínú èdè tó jẹ́ pé ìró ló ń fún ọ̀rọ̀ nítumọ̀, yí ohùn rẹ padà lóríṣiríṣi ọ̀nà tàbí kí o dín ìwọ̀n tó o fi ń yí i padà kù.

  • Ibi kíkó ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ jọ ni yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ ti ń bẹ̀rẹ̀.

ÌDÁNRAWÒ: (1) Ka 1 Sámúẹ́lì 17:17-53 sínú, kí o kíyè sí àwọn ibi tó o ti láǹfààní láti lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti gbà ṣe ìyípadà yíyẹ nínú bí o ṣe ń gbóhùn sókè tàbí bí o ṣe ń rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, àti nínú ìwọ̀n ìyárasọ̀rọ̀ tàbí ìrọrasọ̀rọ̀, àti nínú ìró ohùn. Lẹ́yìn náà, kà á sókè kó o wá fi ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí i bó ṣe yẹ ṣùgbọ́n má ṣe àṣejù o. Ṣe èyí lọ́pọ̀ ìgbà. (2) Láti kọ́ bí o ṣe lè máa fi ìrọ̀rùn yí ohùn rẹ padà, ka 1Sá 17 ẹsẹ 48-51 sókè, kí o sì yára kà á bí o bá ṣe lè yára tó láìṣi ọ̀rọ̀ pè. Láìsí pé o ń pe ọ̀rọ̀ ní àpèlù, kà á lọ́pọ̀ ìgbà, kí o sì túbọ̀ máa yára kà á sí i ju tàtẹ̀yìnwá. Lẹ́yìn náà, ka àkójọ ọ̀rọ̀ kan náà yẹn, kó o rọra kà á bí o bá ṣe lè rọra kà á tó, kí o ránnu mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ibẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, yára kà á, kí o tún rọra kà á kí o sì máa gba ọ̀nà méjì yẹn kà á títí tí ohùn rẹ á fi ṣe bó o ṣe fẹ́ kí ó ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́