Ẹ̀KỌ́ 10
Ìtara
ÌTARA máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ lárinrin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì pé kí ọ̀rọ̀ ẹni kún fún ẹ̀kọ́, ọ̀rọ̀ alárinrin tí a fi ìtara sọ ni yóò mú kí àwùjọ lè tẹ́tí sílẹ̀. Láìka ìran yòówù kí o ti wá tàbí irú ànímọ́ yòówù kí o ní sí, ìtara jẹ́ ohun kan tí o lè fi kọ́ra.
Fi Bí Nǹkan Yẹn Ṣe Rí Lára Hàn Nínú Ohùn Rẹ. Nígbà tí Jésù ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀, ó sọ pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòh. 4:24) Ìjọsìn wọn gbọ́dọ̀ wá látinú ọkàn tó kún fún ìmọrírì, kí ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí èèyàn bá ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ báyẹn, yóò fara hàn nínú bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Yóò hára gàgà láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bí ìrísí ojú rẹ̀ ṣe ń bá ọ̀rọ̀ mu, bó o ṣe ń fara ṣàpèjúwe, àti bí ohùn rẹ̀ ṣe rí yóò fi ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀ gan-an hàn.
Nígbà náà, kí wá nìdí tí olùbánisọ̀rọ̀ kan tó fẹ́ràn Jèhófà tó sì gba ohun tó ń sọ gbọ́ kò fi ní lo ìtara nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀? Kì í kàn án ṣe pé á múra ohun tó fẹ́ sọ sílẹ̀ nìkan ni. Kókó ẹ̀kọ́ tó fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí tún gbọ́dọ̀ yé e dáadáa, kí ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Ká ní wọ́n sọ pé kí ó sọ̀rọ̀ nípa ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ yìí bá ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kì í ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ń sọ nìkan ni kó wà lọ́kàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ìmọrírì fún ohun tí ìrúbọ Jésù túmọ̀ sí fún olùbánisọ̀rọ̀ fúnra rẹ̀ àti fún àwùjọ gbọ́dọ̀ kún inú ọkàn rẹ̀. Ó yẹ kó rántí bí òun ṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù tó fún ìpèsè àgbàyanu yìí. Ó yẹ kó ronú nípa ìrètí ìyè ọlọ́lá ńlá tí ó ṣí sílẹ̀ fún aráyé, ìyẹn ni ayọ̀ ayérayé nínú ìlera pípé nínú Párádísè tí a mú padà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé! Nípa báyìí, ọkàn rẹ̀ gbọ́dọ̀ wà níbi ọ̀rọ̀ ọ̀hún.
Ní ti Ẹ́sírà akọ̀wé, tó jẹ́ olùkọ́ni ní Ísírẹ́lì, Bíbélì sọ pé ó “múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́ àti láti máa kọ́ni ní . . . Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 7:10) Bí àwa pẹ̀lú bá ṣe bẹ́ẹ̀, tí kì í ṣe ọ̀rọ̀ nìkan là ń múra sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí a tún ń múra ọkàn wa sílẹ̀, á óò sọ̀rọ̀ látọkànwá. Sísọ òtítọ́ látọkànwá bẹ́ẹ̀ lè ṣe bẹbẹ láti mú kí àwọn tí à ń bá sọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ràn òtítọ́ ní ti gidi.
Ronú Nípa Àwùjọ Tó Ń Gbọ́rọ̀ Rẹ. Kókó pàtàkì mìíràn nípa fífi ìtara hàn ni níní ìdánilójú pé ó yẹ kí àwùjọ gbọ́ ohun tí o fẹ́ sọ. Èyí túmọ̀ sí pé, nígbà tí o bá ń múra ọ̀rọ̀ rẹ, yàtọ̀ sí ṣíṣàkójọ ọ̀rọ̀ tó yẹ, ó tún yẹ kí o gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó darí rẹ kí o lè lò ó láti fi ṣe àwọn tí o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ láǹfààní. (Sm. 32:8; Mát. 7:7, 8) Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìdí tó fi yẹ kí àwùjọ gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, bí yóò ṣe ṣe wọ́n láǹfààní, àti bí o ṣe lè sọ ọ́ lọ́nà kan tí wọ́n á fi rí i pé ó wúlò fún àwọn lóòótọ́.
Ka ibi tó o ti fẹ́ mú ọ̀rọ̀ rẹ títí tí o fi máa rí ohun kan tó dùn mọ́ ẹ nínú níbẹ̀. Ó lè máà jẹ́ ohun tuntun rárá ṣùgbọ́n ọ̀nà tí o tún gbà ṣàlàyé kókó ẹ̀kọ́ ọ̀hún lè jẹ́ àkọ̀tun. Bí o bá múra ohun kan tí yóò ran àwọn olùgbọ́ rẹ lọ́wọ́ ní tòótọ́ láti fún àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lókun, láti mọrírì àwọn ìpèsè rẹ̀, láti ṣàṣeyọrí nínú kíkojú àwọn pákáǹleke ìgbésí ayé nínú ètò ògbólógbòó yìí, tàbí láti dẹni tó dáńgájíá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, kò sídìí tó ò fi ní fi ìtara sọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún.
Bó bá jẹ́ pé kíkàwé níwájú àwùjọ ni iṣẹ́ tí a yàn fún ọ ńkọ́? Láti lè fi ìtara kà á, ohun tó o máa ṣe á ju pé kí o kàn mọ bí o ti máa pe àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ pa pọ̀ bó ṣe yẹ. Mọ àkójọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún dáadáa. Bí o bá máa ka ibì kan nínú Bíbélì, ṣe ìwádìí díẹ̀ nípa rẹ̀. Rí i dájú pé o lóye ohun tó ò ń sọ ní pàtàkì. Ronú nípa bó ṣe ṣàǹfààní fún ìwọ àti àwọn olùgbọ́ rẹ, kí o sì wá fi ẹ̀mí pé o fẹ́ kó ṣàǹfààní fáwọn tó ń fetí sí ọ kà á.
Ṣé ò ń múra òde ẹ̀rí ni? Ṣàtúnyẹ̀wò kókó ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o fẹ́ lò. Sì tún ronú nípa ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn. Kí lohun tí ìròyìn sọ? Irú ìṣòro wo ló ń kò wọ́n lójú? Nígbà tí o bá gbára dì láti fi han àwọn èèyàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ojútùú sí àwọn ohun tó jẹ́ ìṣòro wọn gan-an, ìwọ yóò hára gàgà láti lọ sọ fún wọn nípa rẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kó o lo ìtara láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Fi Ìtara Hàn Nípa Fífi Ara Yíyá Gágá Sọ̀rọ̀. Fífi ara yíyá gágá sọ̀rọ̀ ni ọ̀nà tó ṣe kedere jù lọ tí o lè gbà fi ìtara hàn. Ó yẹ kí èyí hàn kedere nínú bó o ṣe ń jẹ́ kí ìrísí ojú rẹ bá ọ̀rọ̀ mu. Ó yẹ kí ó hàn bí o ṣe ń sọ̀rọ̀, pé ohun tó ò ń sọ dá ọ lójú, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kí o máa sọ̀rọ̀ fatafata.
Ó gba kó o wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn kan lè fẹ́ máa fi ìháragàgà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọn. Ó yẹ kí a ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé nígbà tí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ fatafata tàbí tí ọ̀rọ̀ bá ká a lára jù, òun gan-an làwọn olùgbọ́ rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí wò, wọn kò ní ronú nípa ohun tó ń sọ mọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tó máa ń tijú ń fẹ́ ìṣírí kí wọ́n lè túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ dáadáa.
Ìtara máa ń ranni. Bí o bá ń wo ojú àwùjọ dáadáa tí o sì ń fi ìtara sọ ọ̀rọ̀ rẹ, ìtara rẹ yóò ran àwọn olùgbọ́ rẹ. Àpólò máa ń fi ara yíyá gágá sọ̀rọ̀, a sì ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. Bí iná ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń jó nínú rẹ, ara yíyá gágá tí wàá máa fi sọ̀rọ̀ yóò mú kí àwọn tí ó bá fetí sí ọ ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́.—Ìṣe 18:24, 25; Róòmù 12:11.
Ìtara Bá Ohun Tí À Ń Sọ Mu. Ṣọ́ra kí o má ṣe lo ìtara gíga jálẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí o ń sọ débi tí ọ̀rọ̀ náà á fi sú àwọn olùgbọ́ rẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀rọ̀ ìyànjú yòówù kí o sọ, láti mú kí wọ́n ṣe ohun tó o bá wọn sọ, kò ní wọ̀ wọ́n létí. Èyí mú kó o túbọ̀ rí ìdí tó fi yẹ láti múra àkójọ ọ̀rọ̀ tí yóò jẹ́ kí o lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Gbìyànjú kí o má ṣe sọ̀rọ̀ bí ẹni tí kò bìkítà. Bí o bá fara balẹ̀ yan ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ, á wù ọ́ sọ gan-an. Ṣùgbọ́n àwọn kókó kan wà tó máa ń gba pé kèèyàn túbọ̀ fi ìtara sọ wọ́n ju àwọn mìíràn lọ, ńṣe ló yẹ kí o fi òye mú wọn wọnú ọ̀rọ̀ rẹ látòkèdélẹ̀.
Ní pàtàkì, o yẹ kí o fi ìtara ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì. Ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́dọ̀ ní àwọn góńgó pàtàkì tí àlàyé rẹ ń darí sí. Níwọ̀n bí ìwọ̀nyí ti jẹ́ kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ, àwọn ló máa jẹ́ kókó tí o fẹ́ lò láti fi sún àwọn olùgbọ́ rẹ láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́. Bí o bá ti mú kí ọ̀rọ̀ dá àwọn olùgbọ́ rẹ lójú, ó yẹ kí o ta wọ́n jí, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ àǹfààní tó wà nínú fífi ohun tí o ti bá wọn jíròrò sílò. Ìtara tí o bá fi hàn ni yóò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ àwọn tó ń fetí sí ọ lọ́kàn. Fífi ara yíyá gágá sọ̀rọ̀ kì í ṣe ohun àfipáṣe. Ìdí gbọ́dọ̀ wà fún un, ọ̀rọ̀ tí o sì fẹ́ sọ ni yóò pèsè ìdí yẹn.