Ẹ̀KỌ́ 27
Sísọ̀rọ̀ Láìgbáralé Àkọsílẹ̀
O LÈ ti sapá gidigidi láti múra ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ lè kún fún ẹ̀kọ́ gan-an. Àlàyé inú rẹ̀ lè yè kooro. O ṣeé ṣe kí o sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n bí àwùjọ ò bá pọkàn pọ̀ nígbà tí ò ń sọ̀rọ̀, bóyá ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ ló kàn ń bọ sí wọn létí nítorí pé ọkàn wọn ń ro àwọn nǹkan mìíràn, ǹjẹ́ a lè sọ pé ọ̀rọ̀ rẹ múná dóko? Bí ó bá ṣòro fún wọn láti máa fọkàn bá ohun tí ò ń sọ lọ, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ á lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn?
Kí ló lè fa irú ìṣòro yẹn? Onírúurú àwọn nǹkan ló lè fà á. Lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ, gbígbáralé àkọsílẹ̀ tó o bá ń sọ̀rọ̀ ló máa ń fà á. Ìyẹn ni pé, olùbánisọ̀rọ̀ ń wo àkọsílẹ̀ rẹ̀ láwòjù, tàbí pé ó ń sọ̀rọ̀ bí ìgbà téèyàn ń kàwé. Ọ̀nà téèyàn gbà múra ọ̀rọ̀ tó máa sọ sílẹ̀ ló sì máa ń fa ìṣòro wọ̀nyí.
Bí ó bá jẹ́ pé ńṣe lo ti kọ́kọ́ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó o máa sọ sílẹ̀ pátá kí o tó wá gbìyànjú láti yí ohun tí o ti kọ yẹn padà sí ìlapa èrò, ó ṣeé ṣe kí o rí i pé yóò ṣòro fún ọ láti sọ ọ̀rọ̀ yẹn láìgbáralé àkọsílẹ̀. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé o ti kọ́kọ́ yan gbogbo ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ pátá. Kódà bí ó bá wá jẹ́ ìlapa èrò yẹn lo tiẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ rẹ kà, wàá ṣì máa gbìyànjú láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí o ti kọ sínú àkọsílẹ̀ àkọ́kọ́. Bí o bá kọ ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀, ṣe ni wàá máa ṣọ́ èdè lò, bí o sì ṣe máa to gbólóhùn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò lọ́jú pọ̀ ju ọ̀nà tí ò ń gbà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ lọ. Ìyẹn á sì hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ nígbà tí o bá ń sọ ọ́.
Dípò tí gbogbo ọ̀rọ̀ tí o máa sọ pátá ì bá fi wà lákọsílẹ̀, gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí: (1) Yan àkòrí ọ̀rọ̀ kan àti àwọn kókó pàtàkì tí o máa lò láti fi gbé àkòrí ọ̀rọ̀ yìí yọ. Bí ó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ kúkúrú ni, kókó pàtàkì méjì ti tó. Ọ̀rọ̀ tó túbọ̀ gùn díẹ̀ lè ní bíi kókó mẹ́rin sí márùn-ún. (2) Kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o fẹ́ lò ní pàtàkì láti fi ṣàlàyé kókó kọ̀ọ̀kan sí ìsàlẹ̀ rẹ̀; kọ àwọn àpèjúwe àti àwọn lájorí àlàyé tí o fẹ̀ ṣe síbẹ̀ pẹ̀lú. (3) Ronú nípa bí o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. O tiẹ̀ lè kọ ọ́ sílẹ̀ ní gbólóhùn kan tàbí méjì. Ṣètò bí o ṣe máa parí ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú.
Mímúra ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ sílẹ̀ tún ṣe pàtàkì bákan náà. Ṣùgbọ́n má ṣe ṣàtúnyẹ̀wò ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àkọsílẹ̀ náà nítorí àtilè há wọn sórí. Bó bá di pé kó o sọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀, èrò tó o fẹ́ gbé yọ ló ṣe pàtàkì pé kí o múra sílẹ̀ dáadáa, kì í ṣe ègé ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí o máa fi sọ ọ́. Ó yẹ kó o ṣàtúnyẹ̀wò àwọn èrò tó wà níbẹ̀ léraléra títí wọ́n á fi gún régé lọ́kàn rẹ. Bí o bá ti ṣètò ọ̀nà tí o máa gbà sọ̀rọ̀ rẹ lẹ́sẹẹsẹ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, èyí kò ní ṣòro fún ọ láti ṣe. Nígbà tí o bá wá ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ, wẹ́rẹ́ ni àwọn èrò náà á kàn máa wá sí ọ lọ́kàn.
Wo Àwọn Àǹfààní Rẹ̀. Àǹfààní pàtàkì kan tó wà nínú sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ ni pé, wàá máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tètè yé tọmọdé tàgbà, ìyẹn sì ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn máa ń ṣiṣẹ́ lé lórí ní kánmọ́. Wàá sọ̀rọ̀ lọ́nà tó túbọ̀ lárinrin, ìyẹn yóò sì dùn mọ́ àwùjọ nínú.
Sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ yóò jẹ́ kí o lè máa wo ojú olùgbọ́ rẹ̀ bó ṣe yẹ, ìyẹn á sì mú kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Nígbà tó ti jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ ni ò ń wo ìwé, àwọn olùgbọ́ rẹ á gbà pé o mọ kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí dáadáa àti pé tọkàntọkàn lo gba ohun tí ò ń sọ gbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ máa ń jẹ́ kí èèyàn lè fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀, kéèyàn sọ̀rọ̀ bí ẹni ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, èyí tí í ṣe ọ̀rọ̀ àtọkànwá tó ń wọ olùgbọ́ ẹni lọ́kàn ṣinṣin.
Sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ tún máa ń jẹ́ kí èèyàn lè tún ọ̀rọ̀ ṣe nígbàkigbà. O kò ní so àlàyé ọ̀rọ̀ mọ́ra jù débi pé kò ní ṣeé tún tò. Ká ní ó ṣẹlẹ̀ pé ní àárọ̀ ọjọ́ tí o máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ, wọ́n gbé ìròyìn pàtàkì kan jáde tó jẹ mọ́ kókó tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí. Ǹjẹ́ kò ní dára láti mẹ́nu kàn án? Tàbí bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, o wá rí i pé àwọn ọmọdé pọ̀ nínú àwọn olùgbọ́ rẹ. Yóò ti dára tó bí o bá yíwọ́ padà ní ti àwọn àpèjúwe tí o fẹ́ lò àti àlàyé wọn láti lè mú kí àwọn ọmọ wọ̀nyẹn rí bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe kan ìgbésí ayé wọn!
Àǹfààní mìíràn tó wà nínú sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ ni pé yóò mú kí ọpọlọ rẹ jí pépé. Nígbà tí àwọn olùgbọ́ rẹ bá mọrírì ọ̀rọ̀ rẹ tí wọ́n sì fi hàn pé àwọn ń gbádùn rẹ, orí ìwọ náà á yá gágá débi pé wàá túbọ̀ ṣàlàyé àwọn èrò rẹ síwájú sí i, tàbí kí o tún rí i pé o tún àwọn kókó kan sọ láti tẹnu mọ́ wọn. Bí o bá wá kíyè sí i pé àwùjọ ò fi bẹ́ẹ̀ fọkàn sí ọ̀rọ̀ rẹ mọ́, wàá lè ṣe nǹkan kan láti borí ìṣòro yẹn dípò kí o kàn máa sọ̀rọ̀ níwájú àwọn tí kò fọkàn bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ.
Yàgò fún Àwọn Ọ̀fìn. Ó yẹ kí o mọ̀ pé sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ ní àwọn ohun tó lè dà bí ọ̀fìn pẹ̀lú. Ọ̀kan nínú rẹ̀ ni pé ó lè mú kéèyàn jẹ àkókò. Bí o bá ti fi àfikún èrò tó ń sọ sí ọ lọ́kàn kún ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ lọ́wọ́ púpọ̀ jù, kò sí bó ò ṣe ní kọjá àkókò. O lè kọ ìwọ̀n àkókò tí o máa lò lórí apá kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀ rẹ sórí ìlapa èrò rẹ. Sì wá rí i dájú pé o tẹ̀ lé àkókò tí o kọ yìí láìyẹ̀.
Ọ̀fìn mìíràn tó tún wà, pàápàá fún àwọn tọ́jọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti ń bá ọ̀rọ̀ sísọ bọ̀, ni dídára-ẹni-lójú jù. Bí ó bá ti di pé ọ̀rọ̀ sísọ fún àwùjọ mọ́ àwọn kan lára, wọn á ti rí i pé kò ṣòro láti kàn sáré kó onírúurú èrò jọ láti sọ, kí àkókò tí a yàn fún iṣẹ́ wọn ó ṣáà fi pé. Àmọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọrírì fún àǹfààní tí a ní láti kópa nínú ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan níbi tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti jẹ́ Olùkọ́ni Atóbilọ́lá, yẹ kó sún wa láti ṣe iṣẹ́ yòówù tá a bá yàn fún wa tìtaratìtara àti tàdúrà-tàdúrà, kí á sì múra sílẹ̀ dáadáa.—Aísá. 30:20; Róòmù 12:6-8.
Bóyá olórí àníyàn ọ̀pọ̀ olùbánisọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ ni pé àwọn lè lọ gbàgbé ohun tí àwọn fẹ́ sọ. Má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù ìyẹn fà ọ́ sẹ́yìn nínú gbígbé ìgbésẹ̀ ìtẹ̀síwájú láti dẹni tó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó múná dóko. Múra ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀ dáadáa, kí o sì yíjú sí Jèhófà pé kí o fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn ọ́ lọ́wọ́.—Jòh. 14:26.
Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ mìíràn ń jẹ́ kí ṣíṣàníyàn púpọ̀ jù nípa bí àwọn yóò ṣe máa rí ọ̀rọ̀ tó ṣe wẹ́kú lò dí àwọn lọ́wọ́, tó bá di pé kí àwọn sọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀. Lóòótọ́, ẹní bá ń sọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ lè má lè ṣa ọ̀rọ̀ lò tàbí kí ó lo èdè lọ́nà tó péye bí ẹni tó ń ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ní tààràtà látinú ìwé, ṣùgbọ́n sísọ tó máa sọ̀rọ̀ lọ́nà ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó wúni lórí yóò bo gbogbo ìyẹn mọ́lẹ̀ pátá. Àwọn èèyàn máa ń tètè kọbi ara sí àwọn èrò tá a fi ọ̀rọ̀ tó tètè yé wọn àti gbólóhùn tí kò lọ́jú pọ̀ gbé jáde. Bí o bá múra ọ̀rọ̀ rẹ dáadáa, àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí o máa lò yóò kàn máa wá sí ọ lẹ́nu wẹ́rẹ́ ni, kì í ṣe nítorí pé o ti há wọn sórí o, ṣùgbọ́n torí pé o ti gbé èrò ibẹ̀ yẹ̀ wò dáadáa. Bí o bá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ ojoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ yóò ṣe máa wá sí ọ lẹ́nu wẹ́rẹ́ lórí pèpéle pẹ̀lú.
Irú Àkọsílẹ̀ Tó Yẹ Kí O Lò. Láìpẹ́, bí o ṣe ń lo ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ yẹn léraléra, ìlapa èrò tí wàá máa kọ kò ní ju ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan péré tí o kọ nípa kókó kọ̀ọ̀kan tó wà ní inú ọ̀rọ̀ rẹ. O lè kọ ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ yìí àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o fẹ́ lò sórí ìwé pélébé tàbí abala ìwé kan tí yóò tètè ṣeé rí kà tí o bá fẹ́ wò ó. Ní ti òde ẹ̀rí, ọ̀pọ̀ ìgbà jù lọ ló jẹ́ pé ńṣe lo máa há ìlapa èrò kúkúrú kan sórí. Tí o bá ṣe ìwádìí lórí kókó kan tí o fẹ́ lò nígbà ìpadàbẹ̀wò, o lè kọ àkọsílẹ̀ kúkúrú kan nípa rẹ̀ sórí ìwé kékeré kan, kí o wá fi há inú Bíbélì rẹ. O sì tún lè lo ìlapa èrò tó wà nínú “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” tàbí àlàyé ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Reasoning From the Scriptures fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ.
Ṣùgbọ́n tó bá di pé a yan onírúurú apá bíi mélòó kan nínú ìpàdé fún ọ láti bójú tó láàárín ọ̀sẹ̀ mélòó kan péré, bóyá tí o tún ní láti sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn pẹ̀lú, ó lè gba pé kí o ṣe àkọsílẹ̀ tó túbọ̀ kún sí i. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé wàá lè mú ọ̀pọ̀ nǹkan wá sí ìrántí ṣáájú kí o tó dẹ́nu lé èyíkéyìí nínú ọ̀rọ̀ tí a yàn fún ọ láti sọ. Síbẹ̀, bí ó bá di pé àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ tí o ti kọ sínú àkọsílẹ̀ yẹn lo wá fẹ́ máa lò nígbà tí ò ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ, bóyá tó jẹ́ gbogbo ìgbà tí o bá fẹ́ sọ gbólóhùn kọ̀ọ̀kan lò ń wo àkọsílẹ̀ yẹn, wàá pàdánù àǹfààní tó wà nínú sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀. Bí o bá kọ àkọsílẹ̀ tó gùn, sàmì sí i lọ́nà tí wàá fi lè tètè rí kìkì ọ̀rọ̀ mélòó kan àti àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan tí o sàmì sí, èyí yóò sì wá dúró fún ìlapa èrò rẹ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ ló yẹ kí ẹnì kan tó ti pẹ́ tó ti ń bá ọ̀rọ̀ sísọ bọ̀ sábà máa lo, síbẹ̀ kò sóhun tó burú tó bá tún lo irú ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ mìíràn. Nígbà ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìparí ọ̀rọ̀, tó jẹ́ pé ó máa ń gba kéèyàn wojú àwùjọ dáadáa kí ó sì tún lo àwọn gbólóhùn tó rinlẹ̀ tí a fara balẹ̀ yàn, ó lè dára gan-an bí ó bá há gbólóhùn bíi mélòó kan tí o máa lò níbẹ̀ sórí. Níbi tó o bá ti fẹ́ lo àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì kan, tàbí iye àwọn ìṣirò kan, tàbí tí o fẹ́ fa àwọn ọ̀rọ̀ kan yọ láti ibì kan, tàbí pé o fẹ́ tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́, kò burú tó o bá kà á jáde, torí o tún lè lò ó láti fi kan ọ̀rọ̀ níṣòó.
Nígbà Tí Àwọn Èèyàn Bá Ní Ká Ṣàlàyé Ọ̀rọ̀. Nígbà mìíràn, àwọn èèyàn lè ní ká wá ṣàlàyé ohun tí a gbà gbọ́ láìjẹ́ pé a ráyè múra rẹ̀ sílẹ̀ ṣáájú. Ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan tí a bá pàdé lóde ẹ̀rí bá gbé ìbéèrè kò wá lójú. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè jẹ yọ láti ọ̀dọ̀ ẹbí wa, níbi iṣẹ́, tàbí nílé ẹ̀kọ́. Àwọn aláṣẹ pẹ̀lú lè sọ pé kí á ṣàlàyé ohun tí a gbà gbọ́ àti ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìgbé ayé wa. Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé: “Kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pét. 3:15.
Ṣàkíyèsí bí Pétérù àti Jòhánù ṣe dá àjọ Sànhẹ́dírìn àwọn Júù lóhùn nínú Ìṣe 4:19, 20. Gbólóhùn méjì péré ni wọ́n fi sọ ìpinnu wọn lọ́nà tó ṣe kedere. Ohun tó yẹ àwùjọ tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ ni wọ́n sì ṣe yẹn, ní fífi ìyẹn sọ ọ́ gbangba pé kókó pàtàkì kan náà tó dojú kọ àwọn àpọ́sítélì tún kan ilé ẹjọ́ yẹn pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn fẹ̀sùn èké kan Sítéfánù, wọ́n sì gbé e wá síwájú ilé ẹjọ́ yìí kan náà. Ka èsì mímúná dóko tí kò ronú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tó fún wọn ní Ìṣe 7:2-53. Báwo ló ṣe to ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ńṣe ló sọ ìtàn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó gbà ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Nígbà tó sọ ọ́ dé àárín kan tó yẹ, ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹnu mọ́ ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbé yọ. Ní paríparì rẹ̀, ó fi hàn pé irú ẹ̀mí kan náà ni àjọ Sànhẹ́dírìn fi hàn tí wọ́n fi ṣekú pa Ọmọ Ọlọ́run.
Nígbà tí a bá pè ọ́ láìròtẹ́lẹ̀ pé kí o wá ṣàlàyé ohun tí o gbà gbọ́, kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àlàyé lọ́nà tó múná dóko? Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nehemáyà, ẹni tó rọra gbàdúrà sínú kí ó tó dáhùn ìbéèrè tí Atasásítà Ọba bi í. (Neh. 2:4) Lẹ́yìn náà, wá fọkàn ṣètò ìlapa èrò kan ní kíákíá. A lè to ọ̀nà pàtàkì tí o lè gbà ṣe é báyìí: (1) Yan kókó kan tàbí méjì tó yẹ kí àlàyé yẹn wé mọ́ (o lè yan kókó ọ̀rọ̀ látinú ìwé Reasoning From the Scriptures). (2) Yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o máa fi ti kókó wọ̀nyẹn lẹ́yìn. (3) Wéwèé bí o ṣe máa fọgbọ́n gbé àlàyé rẹ kalẹ̀ tí ẹni tó bi ọ́ ní ìbéèrè yóò fi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Lẹ́yìn náà kí o wá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀.
Tí ọ̀rọ̀ bá dójú ẹ̀, ǹjẹ́ wàá rántí ohun tó yẹ kí o ṣe? Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ; nítorí a ó fi ohun tí ẹ ó sọ fún yín ní wákàtí yẹn; nítorí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí Baba yín ni ó ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.” (Mát. 10:19, 20) Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé wàá rí ẹ̀bùn sísọ “ọ̀rọ̀ ọgbọ́n” gbà lọ́nà ìyanu gẹ́gẹ́ bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní o. (1 Kọ́r. 12:8) Ṣùgbọ́n tí o bá ń fi tọkàntọkàn gba ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni, ẹ̀mí mímọ́ yóò mú kí ìsọfúnni tí o nílò padà sọ sí ọ lọ́kàn nígbà tí o bá nílò rẹ̀.—Aísá. 50:4.
Ó dájú ṣáká pé sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ máa ń mú kí ọ̀rọ̀ wọni lọ́kàn gan-an ni. Bí o bá ń lo ọ̀nà yẹn déédéé nígbà tí o bá ní ọ̀rọ̀ sísọ nínú ìjọ, tó bá dìgbà tí o ní láti dáhùn ìbéèrè aláìròtẹ́lẹ̀ kan kò ní ni ọ́ lára rárá nítorí pé ìlànà kan náà lo máa lò láti fi dáhùn. Má fà sẹ́yìn rárá o. Kíkọ́ láti sọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀ yóò jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù rẹ túbọ̀ múná dóko. Tí o bá sì wá láǹfààní ọ̀rọ̀ sísọ níwájú ìjọ, wàá tún lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tí àwùjọ yóò fi máa fọkàn bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ tí yóò sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn.