Ẹ̀KỌ́ 25
Lílo Ìlapa Èrò
BÍ ÀWỌN èèyàn kan bá ti ń ronú pé àwọn máa lo ìlapa èrò láti fi sọ̀rọ̀, àyà wọn a là gààrà. Ṣùgbọ́n, ọkàn wọn túbọ̀ máa ń balẹ̀ bó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí wọ́n máa sọ pátá ló ti wà ní kíkọ sílẹ̀ tàbí pé wọ́n ti há a sórí.
Bẹ́ẹ̀, ká sòótọ́, ojoojúmọ́ ayé ni gbogbo wa ń sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé à ń kà á látinú àkọsílẹ̀. Nígbà tí a bá jọ ń sọ̀rọ̀ nínú ìdílé wa tàbí pẹ̀lú ọ̀rẹ́ wa, a kì í kà á látinú àkọsílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà la ṣe ń sọ̀rọ̀ tí a bá wà lóde ẹ̀rí. Tí a bá ń gbàdúrà àtọkànwá, yálà àdúrà àdágbà ni o tàbí èyí tí a ṣojú fún àwùjọ láti gbà, a kì í kà á látinú àkọsílẹ̀.
Yálà o ka ọ̀rọ̀ rẹ jáde látinú ìwé ni tàbí o lo àkọsílẹ̀ láti fi sọ ọ́, ǹjẹ́ ó mú ìyàtọ̀ kankan wá? Lóòótọ́, bí èèyàn bá ń ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ látinú ìwé, ó lè mú kí onítọ̀hún má fo ọ̀rọ̀, á sì mú kí onítọ̀hún lè lo àṣàyàn ọ̀rọ̀, àmọ́, àbùkù ibẹ̀ ni pé ọ̀rọ̀ yẹn kò ní wọ àwọn olùgbọ́ lọ́kàn tó bó ṣe yẹ. Nígbà tí o bá fi máa ka gbólóhùn bíi mélòó kan, ìwọ̀n tó o fi ń yára kàwé àti ìlò ohùn rẹ yóò ti mú ọ̀nà kan pàtó, èyí tó máa yàtọ̀ sí ọ̀nà tí o gbà ń sọ̀rọ̀ bó o bá ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ láìkàwé. Bó bá di pé o gbájú mọ́ ìwé rẹ jù, tí o kò fi lè wojú àwùjọ, ọ̀pọ̀ nínú àwùjọ lè máà tẹ́tí sí ọ tó bí wọn ì bá ti ṣe kà ní wọ́n rí i pé ò ń ronú nípa àwọn, tí o sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú ọ̀rọ̀ rẹ bá ipò àwọn mu. Bí ọ̀rọ̀ yóò bá tani jí ní tòótọ́, kéèyàn sọ́ ọ tààràtà láì máa kà á látinú ìwé ló ti dára jù.
Ohun tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run wà fún ni pé kí ó ṣèrànwọ́ fún wa nínú ìgbé ayé wa ojoojúmọ́. Nígbà tí a bá pàdé àwọn ọ̀rẹ́ wa, a kì í fa ìwé yọ kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí ka èrò inú wa sí wọn létí látinú rẹ̀ tìtorí pé a fẹ́ rí i pé a lo àṣàyàn ọ̀rọ̀ tó dára jù lọ. Lóde ẹ̀rí, a kì í torí ìbẹ̀rù pé a lè gbàgbé àwọn kókó kan tí a fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ kí á wá mú ìwé àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a fẹ́ kà dání láti kà á sétígbọ̀ọ́ wọn. Nígbà tí o bá ń ṣe àṣefihàn ní ilé ẹ̀kọ́ nípa bí o ṣe máa wàásù fúnni nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, fi kọ́ra láti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí o gbà ń sọ̀rọ̀ gan-an. Bí o bá múra sílẹ̀ dáadáa, wàá rí i pé ìlapa èrò nìkan, yálà èyí tí o mọ̀ sorí tàbí èyí tí o kọ sí ìwé, ti tó láti lè rán ọ létí àwọn kókó pàtàkì tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí. Ṣùgbọ́n báwo ni wàá ṣe dẹni tó ní ìgboyà tó láti lè máa lò ó?
To Èrò Rẹ Lẹ́sẹẹsẹ. Láti lè lo ìlapa èrò nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, o ní láti kọ́kọ́ to èrò rẹ lẹ́sẹẹsẹ. Èyí kò túmọ̀ sí pé wàá yan ọ̀rọ̀ pàtó tí o fẹ́ máa sọ jáde lẹ́nu. Ohun tí ó kàn túmọ̀ sí ni pé kí o máa ronú kí o tó sọ̀rọ̀.
Nínú ìgbé ayé ojoojúmọ́, oníwàǹwára èèyàn lè rí i pé onírúurú ọ̀rọ̀ tí òun ì bá mọ̀ kí òun má sọ ló ti tẹnu òun jáde. Ẹlòmíràn kàn lè máa sọ̀rọ̀ tí kò lórí tí kò nídìí, tí yóò máa ti orí ọ̀rọ̀ kan já lu òmíràn. Èèyàn lè borí ìṣòro méjèèjì yìí bí ó bá ń dánu dúró láti kọ́kọ́ fi ọkàn ṣe àkójọ èrò díẹ̀ ná kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Kọ́kọ́ mọ kókó tí o fẹ́ gbé yọ lọ́kàn rẹ, kí o sì wá yan àwọn ìgbésẹ̀ tí o máa gbé láti fi lè gbé kókó náà yọ, lẹ́yìn náà kí o wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀.
Ṣé ò ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀ ni? Kì í ṣe àpò òde ẹ̀rí rẹ nìkan ló yẹ kí o wá àyè láti ṣètò dáadáa, tún wá àyè láti ṣètò èrò ọkàn rẹ pẹ̀lú. Bí o bá yàn láti lo ọ̀kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dámọ̀ràn sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ńṣe ni kí o kà á lọ́pọ̀ ìgbà kí kókó inú rẹ̀ lè ṣe kedere lọ́kàn rẹ. Fi gbólóhùn kan tàbí méjì tó ṣe ṣókí sọ kókó pàtàkì tí ibẹ̀ dá lé lórí. Tún ọ̀rọ̀ tí a lò nínú ìwé yẹn sọ lọ́nà tó bá bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ mu àti lọ́nà tó bá ipò ìpínlẹ̀ rẹ mu. Yóò dára tí o bá ṣe ìlapa èrò kan sórí. Kí ló lè wà nínú rẹ̀? (1) Láti nasẹ̀ ọ̀rọ̀, o lè mẹ́nu kan nǹkan kan tó jẹ àwọn èèyàn lógún ní ìpínlẹ̀ rẹ. Fọ̀rọ̀ lọ onílé kí ó lè dá sí i. (2) Fi ohun kan pàtó sọ́kàn tí o lè sọ nípa kókó yẹn, títí kan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì tó sọ ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò ṣe láti fi mú ìtura wá. Bí àyè bá ṣí sílẹ̀ kí o sọ ọ́ gbangba pé ohun tí Jèhófà yóò lò láti fi ṣe é ni Ìjọba rẹ̀, ìyẹn ìṣàkóso àtọ̀runwá. (3) Gba onítọ̀hún níyànjú pé kí ó ṣe nǹkan kan nípa ohun tí o sọ̀rọ̀ lé lórí. O lè fi ìwé tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, tàbí kí o tiẹ̀ ṣe méjèèjì, kí o sì ṣètò tó dájú nípa bí ẹ ṣe tún lè máa bá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn nìṣó.
Ìlapa èrò tí o ṣe sórí nìkan ṣoṣo ló ṣeé ṣe kí o nílò fún irú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ báyìí. Bí o bá fẹ́ wo ìwé ìlapa èrò kan kí o tó yà sọ́dọ̀ ẹni tí o ti kọ́kọ́ máa bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí, kò yẹ kí ohun tó máa wà nínú àkọsílẹ̀ yẹn ju ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan tí o máa fi ṣe ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì tí o yàn, àti ọ̀rọ̀ àkíyèsí ráńpẹ́ kan tí o máa fi parí ọ̀rọ̀ rẹ. Ṣíṣètò irú ìlapa èrò bẹ́ẹ̀, àti lílò ó kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa di àtamọ́-àtamọ̀ ṣùgbọ́n á ràn wá lọ́wọ́ láti lè sọ̀rọ̀ tó lọ geerege tó sì tètè ṣeé rántí.
Bí irú ìbéèrè tàbí àtakò kan náà bá ń jẹ yọ léraléra ní ìpínlẹ̀ rẹ, o lè rí i pé á dára kí o ṣèwádìí lórí rẹ̀. Ohun tó o máa lò kò ní ju bíi kókó pàtàkì méjì tàbí mẹ́ta àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tì wọ́n lẹ́yìn. “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” tàbí àwọn àkòrí kéékèèké tí a fi àwọn lẹ́tà tó dúdú ju àwọn yòókù lọ kọ nínú ìwé Reasoning From the Scriptures lè pèsè irú ìlapa èrò tí o nílò. O lè rí àlàyé tó bá a mu látinú ìwé mìíràn tí o lè fi kún ìyẹn. Wá kọ ìlapa èrò ṣókí kan pa pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ tí o fà yọ látinú ìwé mìíràn yìí, kí o sì fi í sínú ohun tí o máa gbé lọ sóde ẹ̀rí. Nígbà tí onílé bá béèrè ìbéèrè tàbí tó gbé àtakò yẹn wá, jẹ́ kí ó yé e pé ó dùn mọ́ ọ bí o ṣe rí àyè láti ṣàlàyé ohun tí o gbà gbọ́. (1 Pét. 3:15) Wá lo ohun tó wà nínú ìlapa èrò yẹn láti fi dá a lóhùn.
Bí o bá máa ṣojú ìdílé, àwùjọ inú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, tàbí gbogbo ìjọ láti gbàdúrà, ó ṣe pàtàkì pẹ̀lú pé kí o to èrò rẹ lẹ́sẹẹsẹ. Gẹ́gẹ́ bí Lúùkù 11:2-4 ṣe wí, Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ṣókí nípa bí wọ́n ṣe lè gbàdúrà tó nítumọ̀. Nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, Sólómọ́nì gba àdúrà gígùn. Ó dájú pé ó ti ronú nípa kókó tó fẹ́ gbàdúrà lé lórí ṣáájú. Ọ̀rọ̀ tó kan Jèhófà àti ìlérí tó ṣe fún ilé Dáfídì ló kọ́kọ́ gbàdúrà lé lórí; lẹ́yìn náà, ó gbàdúrà nípa tẹ́ńpìlì; kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbẹ́nu lé onírúurú ipò àti àwùjọ èèyàn lọ́kọ̀ọ̀kan. (1 Ọba 8:22-53) A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn àpẹẹrẹ yìí.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìlapa Èrò Rẹ Lọ́jú Pọ̀. Ṣé o fẹ́ kọ ìlapa èrò láti fi sọ àsọyé ni? Kí làwọn nǹkan tó yẹ kí o kọ sínú rẹ̀?
Rántí pé ète ìlapa èrò ni láti mú kí o rántí àwọn èrò rẹ. O lè rí i pé á dára kí o ṣàkọsílẹ̀ gbólóhùn bíi mélòó kan tí o máa fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìyẹn, èrò tí ọ̀rọ̀ rẹ fẹ́ gbé yọ ló yẹ kí o gbájú mọ́, kì í ṣe ẹyọ ọ̀rọ̀ ibẹ̀. Bí o bá fẹ́ kọ èrò wọ̀nyẹn sílẹ̀ ní gbólóhùn ọ̀rọ̀, kọ ọ́ ní gbólóhùn ṣókí ṣókí. Ó yẹ kí àwọn kókó pàtàkì mélòó kan tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí hàn gedegbe nínú ìlapa èrò rẹ. O lè jẹ́ kí ó hàn nípa fífi lẹ́tà ńlá kọ ọ́, nípa fífa ìlà sí kókó wọ̀nyẹn nídìí, tàbí nípa fífi irú àwọ̀ kan kùn ún. To àwọn èrò tí o fẹ́ fi gbé kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan yọ sí ìsàlẹ̀ rẹ̀. Kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o fẹ́ kà nípa rẹ̀ síbẹ̀. Ó sábà máa ń dára pé kí èèyàn kà á jáde látinú Bíbélì ní tààràtà. Kọ àwọn àpèjúwe tí ó fẹ́ lò sí i. O tún lè ní àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tí o fà yọ láti orísun mìíràn tí o rí pé ó bá a mu láti lò. Kọ ohun tó pọ̀ tó, tí yóò jẹ́ kí o ní àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó ṣe gúnmọ́ láti sọ fún àwùjọ. Ìlapa èrò yẹn yóò túbọ̀ rọrùn fún ọ láti lò bí ó bá wà létòlétò.
Àwọn kan máa ń lo ìlapa èrò tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò pọ̀ rẹpẹtẹ. Ohun tó wà nínú ìlapa èrò kan lè máà ju ìwọ̀nba kókó pàtàkì mélòó kan, àkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí olùbánisọ̀rọ̀ yóò kà láti orí láìṣíwèé, àti àwọn àwòrán tàbí fọ́tò tí yóò rán an létí àwọn kókó kan. Olùbánisọ̀rọ̀ lè wá lo àkọsílẹ̀ ṣókí yìí láti fi sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, lọ́nà ìfọ̀rọ̀wérọ̀. Ète tí ẹ̀kọ́ yìí sì wà fún gan-an nìyẹn.
Wàá rí àlàyé nípa “Ṣíṣe Ìlapa Èrò” ní ojú ewé 39 sí 42 nínú ìwé yìí. Yóò dára gidigidi pé kí o ka ìsọfúnni yẹn bí o ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀kọ́ “Lílo Ìlapa Èrò” yìí.
Bí O Ṣe Lè Lo Ìlapa Èrò. Àmọ́ ṣá, ohun tí ò ń lépa láti ṣe báyìí kò mọ sí kìkì bí wàá ṣe ṣètò ìlapa èrò lórí ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ. Ohun tí ò ń lépa ni pé kí o lo ìlapa èrò yẹn bó ṣe yẹ.
Ìgbésẹ̀ tí o kọ́kọ́ máa gbé tí o bá fẹ́ lo ìwé àsọyé rẹ ni pé kí o múra bí o ṣe máa lò ó láti fi sọ àsọyé. Wo àkòrí rẹ̀, ka kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan tí ó wà níbẹ̀, kí o sì sọ bí kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan yìí ṣe wé mọ́ àkòrí náà lọ́kàn ara rẹ. Kọ iye àkókò tí o lè lò láti fi ṣàlàyé kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan sílẹ̀. Wá padà lọ fara balẹ̀ ka kókó pàtàkì àkọ́kọ́. Gbé àwọn àlàyé, ẹsẹ Ìwé Mímọ́, àpèjúwe, àti àwọn àpẹẹrẹ tí o fẹ́ lò láti fi ṣàlàyé kókó yẹn yẹ̀ wò. Ka kókó yẹn léraléra títí apá yẹn nínú ọ̀rọ̀ rẹ á fi yé ọ yékéyéké. Ṣe ohun kan náà sí àwọn kókó pàtàkì yòókù lọ́kọ̀ọ̀kan. Wo ohun tí o lè yọ sílẹ̀ bí ó bá pọn dandan láti ṣe bẹ́ẹ̀ kí o lè parí rẹ̀ lákòókò. Wá ṣàtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yẹn látòkèdélẹ̀. Èrò tí ọ̀rọ̀ yẹn fẹ́ gbé yọ ni kí o fọkàn sí o, kì í ṣe ẹyọ ọ̀rọ̀ ibẹ̀. Má ṣe há ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ yìí sórí.
Nígbà tí o bá ń sọ àwíyé yẹn, ó yẹ kí o lè máa wojú àwùjọ dáadáa. Lẹ́yìn tí o bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ó sábà máa ń yẹ kí o lè lo Bíbélì láti fi ṣàlàyé rẹ̀ láìṣẹ̀ṣẹ̀ lọ máa wo ìlapa èrò rẹ. Bákan náà, bí o bá lo àpèjúwe kan, ńṣe ni kí o sọ ọ́ bíi pé ò ń sọ ọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dípò kí o máa kà á látinú ìlapa èrò. Bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, má fi gbogbo ìgbà lọ máa wo àkọsílẹ̀ rẹ láti sọ gbólóhùn kọ̀ọ̀kan. Sọ̀rọ̀ látọkànwá, ọ̀rọ̀ rẹ á sì wọ ọkàn àwọn tó ń gbọ́ ọ.
Nígbà tí o bá fi dẹni tó mọ bí a ṣe ń lo ìlapa èrò láti fi sọ̀rọ̀ dáadáa, wàá ti di ẹni tó ní ìtẹ̀síwájú pàtàkì nínú dídi olùbánisọ̀rọ̀ tó múná dóko.