MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Máa Lo Ìtara Tó O Bá Ń Kọ́ni
Tá a bá ń fìtara wàásù, á wu àwọn èèyàn láti gbọ́rọ̀ wa. Ìyẹn á tún fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ wa. Gbogbo wa la lè fìtara wàásù, láìka ibi tá a ti wá tàbí irú èèyàn tá a jẹ́ sí. (Ro 12:11) Báwo la ṣe lè ṣe é?
Ó yẹ ká kọ́kọ́ ronú nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ṣe pàtàkì tó, ká lè rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti kéde ìhìn rere àwọn ohun rere fáwọn míì! (Ro 10:15) Ó tún yẹ ká ronú nípa àǹfààní táwọn èèyàn máa rí tí wọ́n bá ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ jára mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. (Ro 10:13, 14) Lẹ́yìn náà, ká fìtara sọ̀rọ̀, ká fara ṣàpèjúwe, ká sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—TÚBỌ̀ JÁ FÁFÁ—MÁA LO ÌTARA TÓ O BÁ Ń KỌ́NI, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ló mú kí ìtara Neeta dín kù?
Kí ló ran Neeta lọ́wọ́ kó lè pa dà máa ló ìtara?
Ìtara wa lè ran àwọn míì lọ́wọ́
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wo ibi táwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa dáa sí?
Báwo ni ìtara wa ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àtàwọn míì lọ́wọ́?