Ẹ̀KỌ́ 17
Lílo Makirofóònù
ÀWỌN Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá láti wá sáwọn ìpàdé Kristẹni. Bí a bá fẹ́ kí wọ́n jàǹfààní nínú ohun tí à ń sọ, a gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ sókè ketekete.
Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, kò sí ẹ̀rọ gbohùngbohùn kankan. Nígbà tí Mósè ń bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ lórí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, báwo ni gbogbo àwùjọ, tí wọ́n tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ó jọ pé ńṣe ni Mósè yan àwọn kan láti dúró sáàárín àwọn èèyàn káàkiri, láti máa ta ọ̀rọ̀ rẹ̀ látagbà jákèjádò ibùdó náà. (Diu. 1:1; 31:1) Láìpẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun ilẹ̀ tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì, Jóṣúà kó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jọ síwájú Òkè Gérísímù àti Òkè Ébálì, ó sì jọ pé àwọn ọmọ Léfì wà ní àfonífojì tó wà láàárín wọn. Gbogbo àwọn èèyàn náà gbọ́ tí a kéde àwọn ìbùkún àti ìfiré látẹnu Ọlọ́run sétígbọ̀ọ́ wọn níbẹ̀, wọ́n sì dáhùn. (Jóṣ. 8:33-35) Ó lè jẹ́ àwọn tí ń ta ọ̀rọ̀ látagbà ni wọ́n tún lò nígbà yẹn. Àmọ́ ó tún dájú pé bí ohùn ṣe máa ń dún lọ rére lágbègbè yẹn jẹ́ kí ohùn wọn túbọ̀ rìn jìnnà.
Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí “ogunlọ́gọ̀ ńláǹlà . . . kóra jọ” sẹ́bàá Òkun Gálílì láti gbọ́rọ̀ Jésù, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kan, ó sún sójú agbami, ó sì jókòó síbẹ̀ láti bá ogunlọ́gọ̀ náà sọ̀rọ̀. (Máàkù 4:1, 2) Kí ló dé tí Jésù fi ń sọ̀rọ̀ látinú ọkọ̀ ojú omi? Ó jẹ́ nítorí pé ohùn èèyàn máa ń rìn jìnnà, ó sì máa ń dún ketekete, téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ láti ojú omi títẹ́ bẹẹrẹ.
Kí ọ̀rúndún ogún tó wọlé dé, bí ohùn olùbánisọ̀rọ̀ bá ṣe ròkè, tó sì ṣe ketekete tó ló máa pinnu iye àwọn tí yóò gbọ́ ohun tó ń sọ fún àwùjọ. Àmọ́ o, bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún 1920 làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń lo àǹfààní ẹ̀rọ gbohùngbohùn ní àwọn àpéjọ wọn.
Ẹ̀rọ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́. Irú ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ lè gbé ohùn olùbánisọ̀rọ̀ ròkè lálá, síbẹ̀ kí dídún àti ìró ohùn náà máà yí padà. Olùbánisọ̀rọ̀ kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní máa ké tantan títí tí ohùn rẹ̀ á fi fẹ́rẹ̀ẹ́ há. Àwọn olùgbọ́ ò sì ní máa ga etí kí wọ́n tó lè gbọ́ ohun tó ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n á pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ń sọ fún wọn.
A ti ṣe gudugudu méje láti rí i dájú pé ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó dáa wà ní àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba ló ń lo ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kí gbogbo àwùjọ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tí ń sọ àsọyé, tàbí àwọn tí ń darí ìpàdé, tàbí àwọn tí ń kàwé látorí pèpéle. Àwọn ìjọ kan tún ní makirofóònù tí àwùjọ fi ń dáhùn ìbéèrè nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Bí ìjọ rẹ bá ní irú ohun èlò wọ̀nyẹn, kọ́ bá a ṣe ń lò ó dáadáa.
Àwọn Ìtọ́sọ́nà Pàtàkì Mélòó Kan. Láti mọ ohun èlò wọ̀nyẹn lò dáadáa, fi kókó tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí sọ́kàn: (1) Ó yẹ kí makirofóònù wà ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ẹnu rẹ. Bí makirofóònù bá sún mọ́ ẹnu rẹ jù, ọ̀rọ̀ rẹ lè máà dún ketekete. Bó bá sì jìnnà jù, ohùn rẹ kò ní ṣe kedere. (2) Makirofóònù gbọ́dọ̀ wà ní iwájú rẹ gan-an, kì í ṣe pé kó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o gbórí sọ́tùn-ún tàbí sósì, ìgbà tó o bá tó gbẹ́nu síwájú makirofóònù ni kí o tó sọ̀rọ̀. (3) Jẹ́ kí ìró ohùn rẹ ròkè díẹ̀ sí i, kí ìtara ọ̀rọ̀ sísọ rẹ sì pọ̀ díẹ̀ sí i ju bó ti máa ń rí nígbà tó o bá kàn ń fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n kò sídìí fún ọ láti kígbe. Wẹ́rẹ́ ni ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ máa gbé ohùn rẹ dé ọ̀dọ̀ àwọn tó wà ní ìpẹ̀kun àwùjọ. (4) Bí o bá fẹ́ ha ọ̀nà ọ̀fun, tàbí o fẹ́ húkọ́, tàbí o fẹ́ sín, rí i dájú pé o gbẹ́nu kúrò níwájú makirofóònù.
Nígbà Tó O Bá Ń Sọ Àsọyé. Nígbà tó o bá déwájú tábìlì ìbánisọ̀rọ̀, arákùnrin kan sábà máa ń wà tí yóò báni gbé makirofóònù síbi tó yẹ. Dúró bí o ṣe máa ń dúró, kí o sì kọjú sí àwùjọ nígbà tí arákùnrin náà bá ń tún un ṣe lọ́wọ́. Fi ìwé rẹ sórí tábìlì ìbánisọ̀rọ̀, kí o sì rí i dájú pé makirofóònù ò dí ọ lójú láti rí i kà.
Nígbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, fetí sí bí ohùn rẹ ṣe ń dún jáde látinú ẹ̀rọ gbohùngbohùn. Ṣé kò pariwo jù, ṣé àwọn ọ̀rọ̀ kan kò sì bẹ̀rẹ̀ sí dún pù-pù-pù? Ó lè di dandan láti sún sẹ́yìn díẹ̀, ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà méjì ààbọ̀ sí sẹ̀ǹtímítà márùn-ún. Nígbà tó o bá rọra ń wo àkọsílẹ̀ rẹ, rántí pé kìkì ìgbà tí makirofóònù bá wà níwájú rẹ tààrà, tàbí tí ojú rẹ bá wà lókè rẹ̀ díẹ̀ ló tó yẹ kó o sọ̀rọ̀ tàbí kó o kàwé, kì í ṣe ìgbà tó bá wà nísàlẹ̀ rẹ̀.
Nígbà Tó O Bá Ń Kàwé Látorí Pèpéle. Ó dáa kó o gbé Bíbélì tàbí ìwé mìíràn tó o bá fẹ́ kà dání kí àwùjọ lè máa rí ojú rẹ. Níwọ̀n bí makirofóònù ti máa wà níwájú rẹ tààrà, ó lè di dandan kí o rọra gbé ìwé tó o fẹ́ kà sẹ́gbẹ̀ẹ́ díẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé ó yẹ kí o gbórí síhà kejì makirofóònù díẹ̀. Tó o bá wá ń kàwé ní ipò yẹn, ńṣe ni ohùn rẹ á máa lọ tààrà sínú makirofóònù.
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn arákùnrin tó ń kàwé nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ máa ń dúró kà á ni, wọn a máa kà á sínú makirofóònù tó wà lóòró. Ipò yìí máa ń jẹ́ kí mímí rọrùn, kí ó sì rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti kàwé náà lọ́nà tó já geere. Má gbàgbé pé kíkà tí à ń ka àwọn ìpínrọ̀ yìí jẹ́ apá pàtàkì nínú ìpàdé náà. Bí àwùjọ yóò ṣe jàǹfààní tó sinmi púpọ̀ lórí ohun tí wọ́n bá gbọ́ tí a kà jáde.
Nígbà Tó O Bá Ń Dáhùn Nínú Ìpàdé. Bí ìjọ rẹ bá ń lo makirofóònù fún dídáhùn ìbéèrè, rántí pé ó ṣì yẹ kó o sọ̀rọ̀ ketekete pẹ̀lú ohùn tí ó ròkè tó. Nígbà tó o bá ń dáhùn, gbìyànjú láti jẹ́ kí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí Bíbélì rẹ wà lọ́wọ́ rẹ. Èyí á jẹ́ kí o rí ìwé náà dáadáa bó o ti ń sọ̀rọ̀ sínú makirofóònù.
Ní àwọn ìjọ kan, a yan àwọn arákùnrin kan tó ń gbé makirofóònù fáwọn tá a bá pè láti dáhùn. Bí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ tiyín, tí wọ́n bá pè ọ́, má tètè káwọ́ sílẹ̀, kí arákùnrin tó ń gbé makirofóònù lè mọ ibi tó o jókòó, kí ó sì lè tètè dé ọ̀dọ̀ rẹ. Bó bá jẹ́ makirofóònù tí wọ́n ń mú lọ́wọ́ ni, múra tán láti nawọ́ gbà á. Má bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ láìjẹ́ pé makirofóònù ti dé ẹnu rẹ. Tètè dá makirofóònù padà lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ tán.
Nígbà Tó O Bá Ń Ṣe Àṣefihàn. Lílo makirofóònù nígbà àṣefihàn ń béèrè fún ìmúrasílẹ̀ tó múná dóko. Bó bá jẹ́ pé makirofóònù tá a gbé nàró sójú kan ni, ìyẹn á jẹ́ kí o rọ́wọ́ ṣí Bíbélì rẹ àti àkọsílẹ̀ rẹ. Lílo makirofóònù tí a ń mú lọ́wọ́ lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti yí síhìn-ín sọ́hùn-ún, àmọ́ ó lè jẹ́ ẹnì kejì rẹ lo máa ní kó bá ẹ mú un dání. Ìyẹn á jẹ́ kó o rọ́wọ́ ṣí Bíbélì rẹ. Kí ìwọ àti onílé rẹ ti kọ́kọ́ fi dánra wò kí ẹnì kejì rẹ lè mọ bó ṣe yẹ kóun gbé e dání. Tún rántí pé kò dáa kó o kẹ̀yìn sí àwùjọ nígbà tó o bá wà lórí pèpéle, àgàgà nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀.
Àwọn tó fẹ́ ṣe àṣefihàn nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lè pọ̀ díẹ̀, ó sì lè jẹ́ pé wọ́n á rìn síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí pèpéle. Èyí lè wá jẹ́ kí wọ́n nílò makirofóònù mélòó kan. Ó yẹ ká ti fi àwọn makirofóònù náà sí ibi yíyẹ lórí pèpéle kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀, tàbí kí a nawọ́ rẹ̀ sí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ sórí pèpéle. Rírí i dájú pé àwọn makirofóònù wà ní ibi yíyẹ ní àkókò yíyẹ gba ìmúrasílẹ̀ ṣáájú. Fífi àṣefihàn dánra wò ká tó ṣe é ń jẹ́ kí ó ṣeé ṣe láti kọ́ àwọn tó fẹ́ ṣe é ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà lo makirofóònù bó ṣe yẹ. Bí wọn kò bá lè ṣe ìdánrawò náà lórí pèpéle, ó bọ́gbọ́n mu kí wọ́n mú ohun kékeré kan tó rí bíi makirofóònù dání, kí wọ́n fìyẹn kọ́ bó ṣe yẹ kí wọ́n dì í mú. Lẹ́yìn àṣefihàn náà, kí wọ́n rọra fi àwọn makirofóònù tí a ń mú lọ́wọ́ náà padà sí àyè rẹ̀, kí wọ́n sì fẹ̀sọ̀ ṣe kí àwọn okùn makirofóònù yòókù má bàa gbé wọn ṣubú bí wọ́n ti ń bọ́ọ́lẹ̀ lórí pèpéle.
Fífún tí a fún ìlò makirofóònù ní àfiyèsí ní í ṣe ní tààràtà pẹ̀lú ọ̀kan lára ohun pàtàkì tí àwọn ìpàdé wa wà fún, èyíinì ni, kí kálukú lè jàǹfààní nínú ohun tá à ń sọ̀rọ̀ lé lórí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Héb. 10:24, 25) Àwa náà lè ṣe ipa tiwa láti jẹ́ kí ọwọ́ tẹ ohun pàtàkì yìí, nípa mímọ bá a ṣe ń lo makirofóònù bó ṣe yẹ.