Ẹ̀KỌ́ 23
Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
YÁLÀ ẹnì kan ṣoṣo lò ń bá sọ̀rọ̀ ni o tàbí àwùjọ ńlá, kò bọ́gbọ́n mu láti kàn gbà pé kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí yóò wu olùgbọ́ rẹ, tàbí àwùjọ náà, kìkì nítorí pé ó ti wu ìwọ alára. Ohun tó o fẹ́ sọ ṣe pàtàkì, àmọ́ bí o kò bá fi bí ó ṣe wúlò hàn kedere, ó lè máà pẹ́ tí ọ̀kan àwùjọ yóò fi kúrò lórí ohun tí ò ń bá wọn sọ.
Kódà, ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba pàápàá. Wọ́n lè máa fọkàn bá ọ lọ bí o bá ń sọ àpèjúwe kan tàbí ìrírí kan tí wọn kò gbọ́ rí. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí wọ́n má fọkàn sí ọ̀rọ̀ rẹ bó bá jẹ́ ohun tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, pàápàá bí o kò bá fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé gbé e jókòó. O ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìdí tí ohun tí ò ń sọ yóò fi ṣe wọ́n ní àǹfààní gidi àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe wọ́n láǹfààní.
Bíbélì rọ̀ wá pé kí á máa ronú lọ́nà tó gbéṣẹ́, tó sì ṣeé mú lò. (Òwe 3:21) Jèhófà lo Jòhánù Olùbatisí láti darí àwọn èèyàn sí “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ ti àwọn olódodo.” (Lúùkù 1:17) Ọgbọ́n yìí jẹ́ èyí tó pilẹ̀ látinú ojúlówó ìbẹ̀rù fún Jèhófà. (Sm. 111:10) Àwọn tó mọrírì ọgbọ́n yìí ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti lè rí ọgbọ́n ta sí ọ̀ràn ìgbésí ayé ìsinsìnyí, kí ọwọ́ wọn sì tún tẹ ìyè tòótọ́, ìyẹn ìyè ayérayé tí ń bọ̀.—1 Tím. 4:8; 6:19.
Bí O Ṣe Lè Sọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Ṣeé Mú Lò. Bí ọ̀rọ̀ rẹ yóò bá ṣeé mú lò, kì í ṣe ọ̀rọ̀ yẹn nìkan lo máa ronú sí dáadáa, wàá tún ronú nípa àwọn olùgbọ́ rẹ pẹ̀lú. Má kàn kó wọn pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ nígbà tó o bá ń ronú nípa wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ìdílé kọ̀ọ̀kan ló para pọ̀ sínú àwùjọ yẹn. Àwọn ọmọdé, ọ̀dọ́, àgbà, àtàwọn tó jẹ́ arúgbó lè wà níbẹ̀. Àwọn ẹni tuntun lè wà níbẹ̀ àtàwọn tó tiẹ̀ ti ń sin Jèhófà kí wọ́n tó bí ọ pàápàá. Àwọn kan lè dàgbà dénú nípa tẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ ni ìwà àti ìṣe ayé ṣì lè wà lọ́kàn àwọn kan digbí. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Báwo ni ohun tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí yóò ṣe ṣe àwùjọ yìí láǹfààní? Báwo ni mo ṣe lè mú kí kókó ọ̀rọ̀ mi yé wọn?’ O lè yàn láti fún ọ̀kan tàbí méjì péré nínú àwọn olùgbọ́ tí a mẹ́nu kàn níhìn-ín láfiyèsí ní pàtàkì. Àmọ́ ṣá, máà gbàgbé àwọn tó kù o.
Ká ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì téèyàn máa ń kọ́kọ́ mọ̀ ni a yàn fún ọ láti sọ̀rọ̀ lé lórí ńkọ́? Báwo ni wàá ṣe sọ ọ̀rọ̀ yẹn fún àwùjọ tó ti gba ẹ̀kọ́ yẹn gbọ́ tẹ́lẹ̀ kí ó sì ṣe wọ́n láǹfààní? Ńṣe ni kó o gbìyànjú láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn nípa rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Lọ́nà wo? Nípa ṣíṣàlàyé àwọn ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ tó tì í lẹ́yìn ni. O tún lè mú kí wọ́n túbọ̀ mọyì ẹ̀kọ́ Bíbélì yẹn sí i. O lè ṣe èyí nípa fífihàn bí ẹ̀kọ́ yẹn ṣe bá àwọn òtítọ́ Bíbélì yòókù mu, àti bí ó ṣe bá ànímọ́ Jèhófà alára mu. Lo àwọn àpẹẹrẹ, bóyá kí o sọ ìrírí pàápàá, nípa bí lílóye ẹ̀kọ́ tí ò ń sọ yìí ti ṣe àwọn èèyàn láǹfààní, tó sì ti nípa lórí irú ojú tí wọ́n fi ń wo ọjọ́ ọ̀la.
Má ṣe dúró dìgbà àlàyé kúkúrú tí o máa ṣe níparí ọ̀rọ̀ rẹ kí o tó máa sọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lo ohun tó ò ń sọ. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ló yẹ kí olúkúlùkù ẹni tó wà nínú àwùjọ rẹ ti mọ̀ ọ́n lára pé “ọ̀rọ̀ yìí kàn mí o.” Bí o bá sì ti wá fi ìpìlẹ̀ yẹn lélẹ̀, ńṣe ni kí o máa bá a nìṣó láti sọ bí àwùjọ náà ṣe lè lo àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ bí o ṣe ń ṣàlàyé wọn lọ́kọ̀ọ̀kan kí o sì tún sọ àwọn kókó pàtàkì yẹn níparí ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú.
Nígbà tó o bá ń sọ bí wọ́n ṣe lè lo ọ̀rọ̀ rẹ, rí i dájú pé o sọ ọ́ lọ́nà tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé kí o sọ ọ́ tìfẹ́tìfẹ́ lọ́nà tí yóò fi hàn pé o gba tẹni rò. (1 Pét. 3:8; 1 Jòh. 4:8) Kódà nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń gbìyànjú láti yanjú àwọn ìṣòro tó ta kókó ní Tẹsalóníkà, ó ṣì rí i dájú pé òun mẹ́nu kan àwọn ìhà tí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ tó wà níbẹ̀ ti ń tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí. Ó tún fi hàn pé òun fọkàn tán wọn pé wọ́n á fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun tí òun ń bá wọn sọ̀rọ̀ lé lórí. (1 Tẹs. 4:1-12) Àpẹẹrẹ tó dára gan-an nìyẹn fún wa láti tẹ̀ lé!
Ṣé wọ́n fẹ́ kó o fi ọ̀rọ̀ rẹ gba àwọn èèyàn níyànjú láti túbọ̀ jí gìrì sí iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni ní ìhìn rere ni? Ńṣe ni kí o mú kí ìtara àti ìmọrírì tí àwọn èèyàn ní fún àǹfààní yìí túbọ̀ pọ̀ sí i. Àmọ́ bí o ṣe ń ṣe èyí, fi í sọ́kàn pé ìwọ̀n tí oníkálùkù lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ yìí yàtọ̀ síra, Bíbélì sì fi ìyẹn hàn bẹ́ẹ̀. (Mát. 13:23) Má ṣe sọ òkò ọ̀rọ̀ lu àwọn arákùnrin rẹ láti mú wọn kárí sọ, pé àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ jìnnàjìnnà. Ohun tí Hébérù 10:24 rọ̀ wá láti ṣe ni pé kí á “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Bí a bá gbin ẹ̀mí ìfẹ́ sí àwọn èèyàn lọ́kàn, wọ́n á lẹ́mìí àtiṣe iṣẹ́ látọkànwá. Dípò tí wàá fi máa gbìyànjú láti pàṣẹ pé dandan ni kí iṣẹ́ tẹ́nì kan ṣe bá tẹnì kejì dọ́gba, mọ̀ pé ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ni pé kí á jẹ́ kí “ìgbàgbọ́” sún àwọn èèyàn láti ṣe “ìgbọràn.” (Róòmù 16:26) Bí á bá fi ìyẹn sọ́kàn, ńṣe la óò máa wá ọ̀nà láti máa fún ìgbàgbọ́ tiwa àti tàwọn arákùnrin wa lókun.
Jíjẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Bí Ọ̀rọ̀ Náà Ṣe Wúlò. Bí o ṣe ń wàásù fún àwọn èèyàn, má ṣe kùnà láti mẹ́nu kan bí ìhìn rere ṣe wúlò fún wọn. Bí o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó gba pé kí o mọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ. Báwo lo ṣe lè mọ̀ ọ́n? Máa tẹ́tí sí ìròyìn orí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n. Máa wo ojú ewé àkọ́kọ́ nínú ìwé ìròyìn. Bákan náà, máa gbìyànjú láti fa àwọn èèyàn wọnú ìfọ̀rọ̀wérọ̀, kí o sì tẹ́tí gbọ́ wọn bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. O lè wá rí i pé wọ́n ní àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí, bóyá iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn ni, àìrí owó ilé san ni, àìsàn ni, ẹbí wọn kan kú ni, ewu ìwà ọ̀daràn ni, ẹni tí wọ́n fi ọwọ́ ọlá gbá lójú ni, ìdílé wọn dà rú ni, ọ̀nà tí yóò gbà kápá àwọn ọmọ ni, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ǹjẹ́ Bíbélì lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ó dájú pé ó lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Nígbà tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀, ó ṣeé ṣe kí kókó kan ti wà lọ́kàn rẹ tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí. Àmọ́, tí ẹni yẹn bá fi hàn pé nǹkan mìíràn wà tó jẹ òun lógún ní lọ́ọ́lọ́ọ́, má ṣe lọ́tìkọ̀ láti kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ lórí ìyẹn ná bí o bá mọ ohun tó o lè sọ, tàbí kí o sọ fún un pé wàá padà wá bá a sọ ohun tó lè ràn án lọ́wọ́. Lóòótọ́, a kò ní máa ‘tojú bọ ohun tí kò kàn wá,’ ṣùgbọ́n tayọ̀tayọ̀ la ó fi mẹ́nu kan àwọn ìmọ̀ràn wíwúlò tó wà nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn. (2 Tẹs. 3:11) Dájúdájú, ohun tó máa wú àwọn èèyàn lórí jù lọ ni pé kí wọ́n rí ìmọ̀ràn inú Bíbélì tó kan ọ̀ràn ìgbésí ayé tiwọn fúnra wọn.
Bí àwọn èèyàn ò bá rí ọ̀nà tí ohun tí à ń bá wọn sọ gbà kàn wọ́n, wọ́n lè dá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn dúró kíákíá. Bí wọ́n bá sì tiẹ̀ jẹ́ ká sọ̀rọ̀, sísọ tí a kò sọ bí wọ́n ṣe lè lo ọ̀rọ̀ tí a bá wọn sọ lè mú kí ọ̀rọ̀ wa má fi bẹ́ẹ̀ yí ìgbésí ayé wọn padà. Ṣùgbọ́n, bí a bá mú kí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lo ohun tí a bá wọn sọ yé wọn kedere, ìgbésí ayé wọn lè bẹ̀rẹ̀ sí yí padà látorí ohun tí a bá wọn sọ wẹ́rẹ́ yẹn.
Nígbà tí o bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, máa sọ fún wọn bí wọn yóò ṣe mú ọ̀rọ̀ ibẹ̀ lò. (Òwe 4:7) Mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lóye ìmọ̀ràn, àwọn ìlànà, àti àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ tó fi bí èèyàn ṣe lè máa rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà hàn. Tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní téèyàn máa jẹ bí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísá. 48:17, 18) Èyí á sún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe àyípadà tó yẹ nínú ìgbésí ayé wọn. Kọ́ wọn ní bí wọ́n ṣe lè máa fẹ́ràn Jèhófà kí wọ́n sì fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wù ú, kí o sì wá jẹ́ kí ọkàn àwọn fúnra wọn sún wọn láti fi ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò.