ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 26 ojú ìwé 170-ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 4
  • Ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Lẹ́sẹẹsẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Lẹ́sẹẹsẹ
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣe Ìlapa Èrò
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Mú Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Mú Ọ̀rọ̀ Rẹ Jáde Láti Ibi Tí A Ti Yanṣẹ́ fún Ọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 26 ojú ìwé 170-ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 4

Ẹ̀KỌ́ 26

Ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Lẹ́sẹẹsẹ

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o to ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tí yóò fi yé àwọn èèyàn, kí o tò ó bí àwọn kókó inú rẹ̀ ṣe so pọ̀ mọ́ra àti bí wọ́n ṣe wé mọ́ ìparí ọ̀rọ̀ tàbí ohun tí ò ń fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yẹn sún àwọn èèyàn ṣe.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bí èèyàn bá ṣàlàyé ọ̀rọ̀ lẹ́sẹẹsẹ, yóò tètè yé àwùjọ, wọ́n á tètè lè tẹ́wọ́ gbà á, wọ́n á sì tètè rántí rẹ̀.

KÍ O tó lè ṣètò ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ lẹ́sẹẹsẹ, o ní láti ní ohun kan pàtó lọ́kàn tí o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ yẹn ṣe. Ṣé o kàn fẹ́ sọ nǹkan kan fún àwọn èèyàn nípa kókó kan pàtó ni, irú bí ohun kan téèyàn gbà gbọ́, ìṣesí kan, ànímọ́ kan, ìwà kan, tàbí irú ìgbé ayé kan? Ṣé ohun tí o fẹ́ ṣe ni pé o fẹ́ fi ẹ̀rí tó ti èrò kan lẹ́yìn hàn tàbí pé o fẹ́ já èrò kan ní koro? Ṣé ńṣe lo fẹ́ mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọyì nǹkan kan tàbí ńṣe lo fẹ́ ta wọ́n jí láti ṣe nǹkan kan? Ì báà jẹ́ ẹnì kan tàbí àwùjọ ńlá lo fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ rẹ fún, o ní láti kọ́kọ́ ronú nípa ohun tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa kókó yẹn àti ohun tó jẹ́ ìṣarasíhùwà wọn nípa rẹ̀ kí ọ̀rọ̀ rẹ tó lè ṣe iṣẹ́ tí o fẹ́ kí ó ṣe. Lẹ́yìn tí o bá ti ṣe èyí tán, kí o wá ṣètò ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tí wàá lè fi ṣe ohun tí o fẹ́ kí ó ṣe.

Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Sọ́ọ̀lù (Pọ́ọ̀lù) ṣe ní Damásíkù, Ìṣe 9:22 sọ pé ó “ń mú ẹnu àwọn Júù tí ń gbé ní Damásíkù wọhò bí ó ti fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu pé èyí ni Kristi náà.” Kí làwọn nǹkan tó wé mọ́ ẹ̀rí ìdánilójú tí ó fi hàn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu yẹn? Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ṣe lẹ́yìn ìyẹn ní Áńtíókù àti Tẹsalóníkà ti fi hàn, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ látorí kókó náà pé àwọn Júù tẹ́wọ́ gba Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti pé wọ́n tún sọ pé àwọn tẹ́wọ́ gba ohun tí ibẹ̀ sọ nípa Mèsáyà. Lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù wá yan àwọn apá ibi tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé Mèsáyà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí yóò ṣe nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyẹn. Ó fa ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn yọ, ó sì wá fi wọ́n wéra pẹ̀lú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jésù. Níkẹyìn, ó parí ọ̀rọ̀ sórí kókó tó fara hàn kedere, ìyẹn ni pé, Jésù ni Kristi, tàbí Mèsáyà náà. (Ìṣe 13:16-41; 17:2, 3) Bí ìwọ náà bá ṣàlàyé òtítọ́ inú Bíbélì lẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, ọ̀rọ̀ ìwọ náà lè wọ àwọn èèyàn létí dáadáa.

Bí O Ṣe Lè Ṣètò Ọ̀rọ̀ Rẹ Lẹ́sẹẹsẹ. Onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà to ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. O lè lo oríṣiríṣi ọ̀nà pa pọ̀ bí o bá rí i pé ìyẹn ló máa dára jù. Wo díẹ̀ nínú onírúurú ọ̀nà tí o lè lò.

Títo ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí kókó inú rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra. Ìyẹn ni pé kí o ṣètò ọ̀rọ̀ rẹ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, kí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan sì ṣètìlẹ́yìn fún ète tí o fi ń sọ̀rọ̀. Àwọn ìsọ̀rí yìí lè jẹ́ àwọn kókó pàtàkì tí yóò mú kí òye ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí yéni. Wọ́n lè jẹ́ àlàyé kan pàtó tó ń fi ẹ̀rí nǹkan kan hàn tàbí tó ń já nǹkan kan ní koro. Àwọn kókó kan wà tó jẹ́ pé, bó tilẹ̀ jẹ mọ́ ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí, síbẹ̀ irú àwùjọ tí o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ tàbí iṣẹ́ tí o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe ló máa pinnu bóyá kí o fi wọn kún ọ̀rọ̀ tàbí kí o yọ wọ́n kúrò.

Wo àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ kan tí a tò gẹ́gẹ́ bí kókó inú rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra. Ká ní èèyàn fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ kúkúrú kan nípa orúkọ Ọlọ́run, ó lè sọ̀rọ̀ lórí (1) ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti fi orúkọ Ọlọ́run mọ̀ ọ́n, (2) ohun tí orúkọ Ọlọ́run jẹ́, àti (3) bí a ṣe lè bọlá fún orúkọ yẹn.

A lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ nípa bí a ṣe lè to ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí kókó inú rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” dìídì ṣe fún lílò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. (Mát. 24:45) Ìtẹ̀jáde wọ̀nyí sábà máa ń ní àwọn kókó ẹ̀kọ́ tàbí àwọn àkòrí nínú, tó lè ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ nípa àpapọ̀ òtítọ́ ìpìlẹ̀ tí Bíbélì fi kọ́ni. Àwọn ìwé ńlá máa ń pín àkòrí kọ̀ọ̀kan sí ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kéékèèké. Kókó ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan máa ń jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ tó máa kàn lẹ́yìn èyí tó ń kọ́ lọ́wọ́, ó sì tún máa ń jẹ́ kí ohun tí ìwé yẹn fẹ́ gbìn síni lọ́kàn ṣe kedere.

Ohun tó fa ọ̀ràn àti ibi tó yọrí sí. Ṣíṣàlàyé ohun tó fa ọ̀ràn kan àti ibi tó yọrí sí tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí a fi ń gbé ìsọfúnni jáde lẹ́sẹẹsẹ.

Ọ̀nà yìí lè wúlò gan-an nígbà tí o bá ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ tàbí àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tó yẹ kó túbọ̀ ronú dáadáa nípa àbájáde ohun kan tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ tàbí èyí tí wọ́n fẹ́ dáwọ́ lé. Àpẹẹrẹ títayọ kan nípa èyí wà nínú ìwé Òwe orí keje. Ó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àpèjúwe nípa bí ọ̀dọ́mọkùnrin aláìnírìírí kan tí “ọkàn-àyà kù fún” (ohun tó fa ọ̀ràn náà) ṣe kó sọ́wọ́ obìnrin aṣẹ́wó kan tó sì wá kàgbákò nígbẹ̀yìn (ibi tó yọrí sí).—Òwe 7:7.

Láti túbọ̀ tẹ ohun tí ò ń sọ mọ́ni lọ́kàn, o lè fi àjálù tó bá àwọn tó kọ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà wéra pẹ̀lú ire tó kan àwọn tó gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Ẹ̀mí Jèhófà bà lé Mósè, ó sì mú kí ó ṣe irú ìfiwéra yẹn nígbà tí ó ń bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Diu., orí kejìdínlọ́gbọ̀n.

Ní ìgbà mìíràn, ó máa ń dára jù lọ pé ìbẹ̀rẹ̀ àlàyé ọ̀rọ̀ ni kí o ti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ (ibi tí ọ̀ràn yọrí sí), lẹ́yìn náà kí o wá sọ ẹ̀rí tó tọ́ka sí àwọn nǹkan tó fà á (okùnfà ọ̀ràn). Èyí sábà máa ń wé mọ́ sísọ ohun kan tó jẹ́ ìṣòro àti wíwá ojútùú sí ìṣòro yẹn.

Ìṣòro àti ojútùú. Lóde ẹ̀rí, tí o bá sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tó ń da àwọn èèyàn láàmú tí o sì fi hàn pé ojútùú tó tẹ́ni lọ́rùn wà fún un, ìyẹn lè fún àwọn èèyàn níṣìírí láti fetí sílẹ̀. Ó lè jẹ́ ìṣòro tí o fúnra rẹ sọ tàbí èyí tí onítọ̀hún sọ.

Ìṣòro yẹn lè dá lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú, bí ìwà ọ̀daràn ṣe gbilẹ̀, tàbí wíwà tí àìsí ìdájọ́ òdodo wà. Kò sídìí fún ṣíṣàlàyé jàn-àn-ràn láti fi hàn pé irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ wà nítorí ohun tó ti hàn gbangba ni. Kàn sọ ìṣòro ọ̀hún, kí o sì wá sọ ohun tí Bíbélì sọ pé yóò yanjú rẹ̀.

Àmọ́ ṣá, ó lè jẹ́ ìṣòro ti onítọ̀hún fúnra rẹ̀, bóyá ìṣòro ti òbí anìkàntọ́mọ, ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí àìsàn lílekoko, tàbí ìnira tó bá ẹnì kan nítorí bí ọmọnìkejì rẹ̀ ṣe ń fojú ẹ̀ gbolẹ̀. Ọ̀nà tí o lè gbà ṣe onítọ̀hún lóore jù lọ ni pé kí o kọ́kọ́ tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa ná. Bíbélì pèsè ìsọfúnni tó wúlò gidigidi nípa gbogbo ìṣòro wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí èèyàn fi òye sọ ọ́. Bí ọ̀rọ̀ rẹ yóò bá ṣe onítọ̀hún lóore ní tòótọ́, wàá ní láti sọ̀rọ̀ sí ibi tí ọ̀rọ̀ wà. Jẹ́ kí ibi tó o ń bá àlàyé ọ̀rọ̀ lọ ṣe kedere, bóyá ohun tó máa yanjú ìṣòro yẹn pátápátá lò ń sọ o, tàbí ohun tó máa fún onítọ̀hún ní ìtura fúngbà díẹ̀, tàbí pé o kàn fẹ́ sọ bí yóò ṣe fara da ipò kan tí kò lè yí padà nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Kókó ibẹ̀ sáà ni pé kí o rí i dájú pé àlàyé inú Ìwé Mímọ́ tí o bá ṣe yóò tó láti ṣètìlẹ́yìn fún ẹ̀kọ́ tí o fà yọ láti ibẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tí o sọ pé ó jẹ́ ojútùú sí ìṣòro yẹn lè máà dà bí ohun tó mọ́gbọ́n dání lójú ẹni tí ò ń bá sọ̀rọ̀.

Bí ìtàn ọ̀rọ̀ ṣe tẹ̀ léra. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tó jẹ́ pé a ò lè ṣàlàyé rẹ̀ láìsọ bí ìtàn rẹ̀ ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Ẹ́kísódù, àlàyé nípa bí Ìyọnu Mẹ́wàá ṣe wáyé jẹ́ lọ́nà tó gbà ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Nínú Hébérù orí kọkànlá, ọ̀nà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà to orúkọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ bá bí wọ́n ṣe gbé ayé tẹ̀ léra mu.

Bí o bá sọ ìtàn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn lọ́nà tí ó gbà ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra, ó lè mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ lóye ohun tó fà á tí àwọn nǹkan kan fi ṣẹlẹ̀ bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀. Bí èyí ṣe kan ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láyé òde òní náà ló ṣe kan àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí à ń kọ Bíbélì. Nítorí náà, ó lè ṣẹlẹ̀ pé wàá lo ọ̀nà bí ìtàn ọ̀rọ̀ ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra pẹ̀lú ohun tó fa ọ̀ràn náà àti ibi tó yọrí sí nínú àlàyé rẹ. Bí o bá fẹ́ sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, títò wọ́n tẹ̀ léra lọ́nà bí wọn yóò ṣe ṣẹlẹ̀ ló ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọ̀nà tí yóò tètè yé àwọn olùgbọ́ rẹ tí wọn yóò sì tètè lè rántí jù lọ.

Lílo tí o fẹ́ lo ọ̀nà bí ìtàn ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra láti fi ṣàlàyé kò túmọ̀ sí pé dandan ni kí o máa lọ gbé ìtàn ọ̀rọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nígbà gbogbo. Ní ìgbà mìíràn, ohun tó dára jù lọ ni pé kí o bẹ̀rẹ̀ ìtàn kan láti ibi tó gbàfiyèsí jù lọ nínú ìtàn yẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí o ba ń sọ ìrírí ẹnì kan, o lè yàn láti sọ nípa ìgbà kan tí a dán ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run wò. Tí o bá ti wá fi apá yẹn nínú ìtàn yìí tọ́ àwùjọ lẹ́nu wò, o lè wá máa ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí ìtàn yẹn ṣe ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé títí tó fi kan apá tí o sọ níṣàájú.

Kìkì Ọ̀rọ̀ Tí Ó Bá Yẹ Nìkan Ni Kí O Lò. Bí ó ṣe wù kí o to ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ, kíyè sára pé o lo kìkì ọ̀rọ̀ tó yẹ nìkan. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tí o máa yàn láti lò bá àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ mu. Ó yẹ kí o sì tún ronú nípa irú àwọn èèyàn tó wà nínú àwùjọ tí o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú. Kókó kan lè wà tó ṣe pàtàkì gan-an láti lò fún àwùjọ kan, ṣùgbọ́n kí ó dà bí àsọdùn létí àwùjọ mìíràn. O sì ní láti rí i dájú pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí o yàn yóò pa pọ̀ mú kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe iṣẹ́ tí o fẹ́ kí ó ṣe. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọ̀rọ̀ rẹ lè lárinrin, àmọ́ ó lè máà sún àwọn olùgbọ́ rẹ ṣiṣẹ́ rárá.

Nígbà tí o bá ń ṣèwádìí, o lè rí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó wúni lórí tó jẹ mọ́ kókó tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn tí o máa mú lò nínú rẹ̀ pọ̀ tó? Bí o bá lọ rọ̀jò ọ̀rọ̀ sórí àwùjọ, o lè fi ìyẹn pa ara rẹ láyò. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ kì í kún agbọ̀n, afẹ́fẹ́ ní í gbé e lọ. Èèyàn kì í tètè gbàgbé ọ̀rọ̀ ṣókí tí àlàyé rẹ̀ sì yéni dáadáa bíi ti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọ̀rọ̀ tí a sáré dà wuuruwu sílẹ̀. Ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé o kò lè fi àyàbá ọ̀rọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kún àlàyé o. Ṣùgbọ́n, ńṣe ni kí o má ṣe jẹ́ kí ìyẹn gba ojú ọ̀rọ̀ mọ́ ọ lọ́wọ́. Ṣàkíyèsí bí a ṣe fọgbọ́n mú irú àwọn àyàbá bẹ́ẹ̀ wọnú ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ní Máàkù 7:3, 4 àti Jòhánù 4:1-3, 7-9.

Bí o ṣe ń bá ọ̀rọ̀ lọ látorí kókó kan sí òmíràn, ṣọ́ra kí o má máa dédé ti orí kókó kan ta mọ́ òmíràn tí ọ̀rọ̀ rẹ á fi dà rú mọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ lójú. Kí àwọn èrò tí ò ń gbé jáde nínú ọ̀rọ̀ rẹ lé so pọ̀ mọ́ra wọn bó ṣe tọ́, ó lè di dandan kí o fi ọ̀rọ̀ so èrò tí ò ń bá bọ̀ pọ̀ mọ́ èyí tó tẹ̀ lé e. Ó lè jẹ́ àpólà ọ̀rọ̀ tàbí odindi gbólóhùn tó sọ bí èrò méjèèjì ṣe tan mọ́ra wọn lo máa lò. Ní ọ̀pọ̀ èdè, èèyàn kàn lè lo ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tá a fi ń so ọ̀rọ̀ pọ̀ láti fi sọ bí èrò tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ sọ ṣe tan mọ́ èyí tó ti ń sọ bọ̀.

Bí o bá ti lo ọ̀rọ̀ tó yẹ, tí o sì tò ó lẹ́sẹẹsẹ, yóò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ohun tí o fẹ́ kí ó ṣe.

BI ARA RẸ LÉÈRÈ PÉ . . .

  • Kí ni iṣẹ́ tí mo fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ṣe?

  • Ǹjẹ́ kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan inú ọ̀rọ̀ mi jẹ mọ́ iṣẹ́ yẹn dáadáa bí?

  • Nígbà tí mo ń yan ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ lò, ǹjẹ́ mo ń ronú nípa ohun tí àwọn olùgbọ́ mi nílò bí?

  • Ǹjẹ́ mo ṣètò ọ̀rọ̀ mi lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwọn olùgbọ́ mi á lè máa fọkàn bá èrò ibẹ̀ lọ látorí ọ̀kan sí ìkejì ní tààràtà láìsí ìrújú kankan?

ÌDÁNRAWÒ: Tí o bá ti ka ẹ̀kọ́ yìí tán, fara balẹ̀ ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀, kí o sì sọ kókó ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpínrọ̀ ibẹ̀ lọ́kàn ara rẹ. Kíyè sí bí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe kọ́ni ní ohun tí ẹ̀kọ́ yìí lódindi fẹ́ kí á mọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́