Ẹ̀KỌ́ 30
Bó O Ṣe Lè Fi Hàn Ré Ire Àwọn Ẹlòmíràn Jẹ Ọ́ Lógún
NÍGBÀ tí a bá ń sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn, ojúṣe wa ju pé kí á kàn rí i pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. A ní láti rí i pé ọ̀rọ̀ wa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ọ̀nà kan tí a lè gbà ṣe èyí ni pé kí a jẹ́ kí ire àwọn olùgbọ́ wa jẹ wá lọ́kàn lóòótọ́. Oríṣiríṣi ọ̀nà la sì lè gbà fi ìyẹn hàn.
Gba Èrò Àwọn Olùgbọ́ Rẹ Yẹ̀ Wò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba ipò ìgbésí ayé àti bí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ṣe ń ronú yẹ̀ wò. Ó ṣàlàyé pé: “Fún àwọn Júù mo dà bí Júù, kí n lè jèrè àwọn Júù; fún àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin mo dà bí ẹni tí ń bẹ lábẹ́ òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi kò sí lábẹ́ òfin, kí n lè jèrè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin. Fún àwọn tí wọ́n wà láìní òfin mo dà bí aláìní òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò wà láìní òfin sí Ọlọ́run ṣùgbọ́n lábẹ́ òfin sí Kristi, kí n lè jèrè àwọn tí wọ́n wà láìní òfin. Fún àwọn aláìlera mo di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là. Ṣùgbọ́n mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.” (1 Kọ́r. 9:20-23) Báwo ni a ṣe lè “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” lóde òní?
Bó bá ṣeé ṣe fún ọ láti ṣàkíyèsí àwọn èèyàn, bó tiẹ̀ jẹ́ fúngbà kúkúrú, kí o tó bá wọn sọ̀rọ̀, o lè rí àwọn ẹ̀rí tó fi ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àti irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé hàn. Ǹjẹ́ o lè sọ irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe? Ǹjẹ́ o rí ohun tó fi irú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe hàn? Ǹjẹ́ o rí ohun tó fi bí nǹkan ṣe rí nínú ìdílé wọn hàn? Pẹ̀lú àwọn nǹkan tí o ṣàkíyèsí, ǹjẹ́ o lè yí bí o ṣe fẹ́ sọ̀rọ̀ padà láti jẹ́ kí ó fa àwọn olùgbọ́ rẹ mọ́ra?
Láti mú kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ fa àwọn èèyàn tí o máa bá pàdé nínú ìpínlẹ̀ rẹ mọ́ra, o ní láti kọ́kọ́ ronú nípa àwọn èèyàn yẹn ṣáájú. Ní àwọn ìpínlẹ̀ kan, àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè tó ṣí wá sí ìpínlẹ̀ náà lè jẹ́ ara àwọn tí o máa ronú nípa wọn. Bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá ń gbé ní ìpínlẹ̀ rẹ, ǹjẹ́ o ti rí ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí o lè gbà wàásù fún wọn? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé, ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” máa wá ọ̀nà tí wàá fi lè máa wàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tí yóò fa gbogbo àwọn tí o bá bá pàdé mọ́ra.—1 Tím. 2:4.
Tẹ́tí Sílẹ̀ Bẹ̀lẹ̀jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ arínúróde, ó ṣì máa ń tẹ́tí gbọ́rọ̀ àwọn mìíràn. Wòlíì Mikáyà rí ìran kan níbi tí Jèhófà ti ń fún àwọn áńgẹ́lì níṣìírí láti sọ èrò ọkàn wọn nípa ọ̀nà tí wọn yóò gbà bójú tó ọ̀ràn kan. Ọlọ́run sì gbà kí ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì yìí lo àbá tí áńgẹ́lì ọ̀hún fúnra rẹ̀ dá nípa ọ̀ràn náà. (1 Ọba 22:19-22) Nígbà tí Ábúráhámù ń sọ ìdààmú ọkàn rẹ̀ nípa ìdájọ́ tí ń bọ̀ wá sórí Sódómù, Jèhófà fi inúure tẹ́tí gbọ́rọ̀ rẹ̀. (Jẹ́n. 18:23-33) Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí à ń ṣe, báwo la ṣe lè máa fetí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti Jèhófà?
Gba àwọn èèyàn níyànjú láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Béèrè ìbéèrè tó bá a mu, kí o sì fàyè tí ó tó sílẹ̀ fún wọn láti fèsì. Tẹ́tí sí wọn dáadáa. Bí o ṣe fara balẹ̀ ń gbọ́rọ̀ wọn yóò fún wọn níṣìírí láti sọ̀rọ̀ fàlàlà. Bí èsì ẹnu wọn bá jẹ́ kí o mọ nǹkan kan tó wù wọ́n, fọgbọ́n wádìí nípa èyí síwájú sí i. Wá bí wàá ṣe tipa bí ọ̀rọ̀ ṣe pa yín pọ̀ yìí mọ̀ wọ́n síwájú sí i láìjẹ́ pé ò ń béèrè ìbéèrè bí ẹni pé ò ń fẹ́ kí onílé wá sọ tẹnu rẹ̀. Fi òtítọ́ inú yìn wọ́n fún sísọ èrò ọkàn wọn. Ká tiẹ̀ sọ pé o ò fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ, ṣì lo inúure láti fi hàn pé o gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn yé.—Kól. 4:6.
Àmọ́ ṣá, a ní láti kíyè sára kí àṣejù má wọ ìfẹ́ tá a lá a ní sí àwọn èèyàn. Bí ire àwọn èèyàn ṣe jẹ wá lógún kò ní ká máa wá ṣàtojúbọ̀ sí ọ̀ràn wọn. (1 Pét. 4:15) A ní láti ṣọ́ra kí ẹni tó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì má lọ gba bí a ṣe jẹ́ kí ire àwọn èèyàn jẹ wá lógún yìí sódì. Ẹ̀wẹ̀, bí ó ṣe jẹ́ pé ìwọ̀n àfiyèsí tí kálukú ń fẹ́ yàtọ̀ síra láti ilẹ̀ kan sí òmíràn, a ní láti fi làákàyè díwọ̀n ibi tó yẹ kí ọ̀ràn ọmọnìkejì wa ká wa lára dé nítorí báyìí là á ṣe nílẹ̀ yìí, èèwọ̀ ni níbòmíràn.—Lúùkù 6:31.
Ìmúrasílẹ̀ máa ń jẹ́ kí èèyàn lè tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Bí ọ̀rọ̀ tí a fẹ́ sọ bá ṣe kedere lọ́kàn wa, ìyẹn á mú ká lè fara balẹ̀ kí a sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àwọn èèyàn bó ṣe yẹ. Èyí á jẹ́ kí ara tù wọ́n, ó sì lè jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fẹ́ láti bá wa fọ̀rọ̀ wérọ̀.
Fífetí sí àwọn èèyàn jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà bọlá fún wọn. (Róòmù 12:10) Ó ń fi hàn pé a ka èrò wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn sí. Ó tiẹ̀ lè mú kí wọ́n tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ohun tí a fẹ́ sọ. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi fún wa nímọ̀ràn pé ‘kí á yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, kí á lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, kí á sì lọ́ra nípa ìrunú.’—Ják. 1:19.
Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú. Jíjẹ tí ire àwọn èèyàn ń jẹ wá lọ́kàn yóò mú ká máa bá a lọ láti ronú nípa àwọn tó bá kọbi ara sí ọ̀rọ̀ wa, ká sì padà tọ̀ wọ́n lọ láti sọ òtítọ́ inú Bíbélì tó dá lórí ohun tí wọ́n nílò ní tààràtà fún wọn. Nígbà tí o bá ń ronú nípa ìgbà tí o tún máa padà lọ bẹ̀ wọ́n wò, ronú nípa ohun tí o ti mọ̀ nípa wọn látinú ìbẹ̀wò rẹ àtẹ̀yìnwá. Múra ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lórí kókó kan tó jẹ wọ́n lọ́kàn. Ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè lo ọ̀rọ̀ tí o wá bá wọn sọ yìí, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tí wọ́n ń kọ́.—Aísá. 48:17.
Bí olùgbọ́ rẹ bá sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tàbí ìṣòro kan tó ti ń da ọkàn rẹ̀ láàmú, ka èyí sí àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan tí o fi lè sọ ìhìn rere fún un. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó jẹ́ pé kò sígbà tí kì í múra tán láti tu àwọn tó wà nínú ìpọ́njú nínú. (Máàkù 6:31-34) Má ṣe máa kù gìrì sọ ojútùú kan nípa ìṣòro wọn tàbí kí o kàn fún wọn ní ìmọ̀ràn ṣákálá kan. Ìyẹn lè mú kí onítọ̀hún máa rò ó pé ire òun kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ ọ́ lógún ní ti gidi. Dípò ìyẹn, ńṣe ni kí o bá a dárò. (1 Pét. 3:8) Lẹ́yìn náà, kí o wá ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, kí o sì lo ìsọfúnni tó ń gbéni ró tí o rí níbẹ̀ láti fi ran ẹni yẹn lọ́wọ́ láti bójú tó ọ̀ràn rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, jíjẹ tí ire olùgbọ́ rẹ jẹ ọ́ lógún dénúdénú kò ní jẹ́ kí o lọ sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tó bá ọ sọ fún ẹlòmíràn, àyàfi bí ìdí tó ṣe gúnmọ́ kan bá wà tó fi yẹ kí o sọ ọ́.—Òwe 25:9.
Ó yẹ kí á jẹ́ kí ire àwọn tí a ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ wá lógún ní pàtàkì. Fi tàdúràtàdúrà ronú nípa ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan nílò, kí o múra ẹ̀kọ́ tí o fẹ́ kọ́ ọ lọ́nà tí wàá fi lè mú un bá ohun tí ó nílò mu. Bí ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni ohun tó kàn tó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ mi yìí ṣe láti lè máa tẹ̀ síwájú sí i nípa tẹ̀mí?’ Fi ìfẹ́ ran akẹ́kọ̀ọ́ yẹn lọ́wọ́ láti mọyì ohun tí Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” wí nípa ọ̀ràn náà. (Mát. 24:45) Ní ìgbà mìíràn ṣá, àlàyé ṣíṣe nìkan lè ṣàìtó. Ó lè gba pé kí o fi han akẹ́kọ̀ọ́ náà bí ó ṣe lè lo àwọn ìlànà Bíbélì kan, kí ẹ tiẹ̀ jọ ṣe àwọn nǹkan kan pa pọ̀ láti jẹ́ kí ó rí bí ìlànà yẹn ṣe wúlò.—Jòh. 13:1-15.
Nígbà tí a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ìlànà Jèhófà mu, a ní láti lo ẹ̀mí ìwọ̀ntúnwọ̀nsì kí á sì lo òye. Ìgbésí ayé kálukú látilẹ̀wá àti ohun tí kálukú lè ṣe yàtọ̀ síra, ìwọ̀n tí kálukú fi ń tẹ̀ síwájú sì yàtọ̀ síra. Jẹ́ kí ìwọ̀n ohun tí ò ń retí pé kí àwọn èèyàn ṣe bọ́gbọ́n mu. (Fílí. 4:5) Máà fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n yí ìgbésí ayé wọn padà tipátipá. Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ sún wọn ṣe é. Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ni pé kí àwọn èèyàn sin òun tọkàntọkàn, kò mú wọn ní dandan gbọ̀n. (Sm. 110:3) Yẹra fún gbígbé èrò tìrẹ kà wọ́n lórí nínú àwọn ọ̀ràn tó yẹ kí wọ́n fúnra wọn ṣèpinnu lé lórí, kódà bí àwọn kan bá ní kí o sọ èrò tìrẹ nípa rẹ̀, ṣọ́ra kí o má ṣe ìpinnu fún wọn.—Gál. 6:5.
Ṣèrànwọ́ fún Wọn Nípa Ti Ara. Lóòótọ́ ohun tó jẹ Jésù lógún jù lọ nípa àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ni ire wọn nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ ó kọbi ara sí àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n nílò pẹ̀lú. (Mát. 15:32) Kódà bí a kò bá fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, onírúurú ọ̀nà tó wúlò ṣì wà tí a ti lè ṣèrànwọ́.
Tí ire àwọn ẹlòmíràn bá jẹ wá lógún yóò sún wa láti máa gba tẹni rò. Bí àpẹẹrẹ, bí oòrùn, òtútù, òjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ bá ń da olùgbọ́ rẹ láàmú, sún sí ibòmíràn tó dára, tàbí kí o ṣètò láti tún padà wá máa bá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn lọ nígbà mìíràn. Tó bá jẹ́ àsìkò tí ọwọ́ wọ́n dí lo wá, sọ fún wọn pé wàá padà wá nígbà mìíràn. Bí ara aládùúgbò tàbí ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn kò bá dá tàbí tí ó wà ní ilé ìwòsàn, ṣaájò wọn nípa fífi káàdì ìgbaniníyànjú ránṣẹ́ tàbí kí o kọ lẹ́tà kúkúrú kan sí i tàbí kí o lọ kí i lọ́hùn-ún. O tiẹ̀ lè se oúnjẹ lọ tàbí kí o ṣe é lóore lọ́nà mìíràn bó bá yẹ bẹ́ẹ̀.
Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń tẹ̀ síwájú, àárò lè máa sọ ọ́ nítorí pé kò fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àtẹ̀yìnwá fara rora mọ́. Ńṣe ni kí o mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Máa wá àyè láti fi bá wọn fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ẹ bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tán àti ní àwọn àsìkò mìíràn. Gbà wọ́n níyànjú láti máa wá àwọn ọmọlúwàbí bá rìn. (Òwe 13:20) Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Bá wọn jókòó pọ̀ níbẹ̀, kí o sì bá wọn bójú tó ọmọ wọn kí wọn lè jàǹfààní ní kíkún nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn.
Jẹ́ Kí Ire Wọn Jẹ Ọ́ Lógún Dénúdénú. Inú ọkàn ní ẹ̀mí jíjẹ́ kí ire àwọn èèyàn jẹni lógún ti ń wá kì í ṣe pé à ń kọ ọ́ bí ẹnì kọ́ṣẹ́. Bí ire àwọn èèyàn ṣe ń jẹ wá lógún tó máa ń hàn lónírúurú ọ̀nà. Ó máa ń hàn nínú bí a ṣe ń fetí sílẹ̀ àti irú ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wa. Ó máa ń hàn nínú bí a ṣe ń fi inúure àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò hàn síni. Kódà bí a kò sọ̀rọ̀ tí a kò sì ṣe ohunkóhun rárá, ó máa ń hàn nínú ìṣarasíhùwà wa àti ìrísí ojú wa. Bí a bá bìkítà nípa àwọn èèyàn lóòótọ́, wọ́n kúkú máa mọ̀ dáadáa.
Ìdí pàtàkì jù lọ tí a fi ń jẹ́ kí ire àwọn èèyàn jẹ wá lógún ni pé, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ àti àánú Bàbá wa ọ̀run. Èyí máa ń fa àwọn olùgbọ́ wa mọ́ Jèhófà, ó sì ń fà wọ́n mọ́ iṣẹ́ tó ní ká máa jẹ́ fáwọn èèyàn níbi gbogbo. Nípa báyìí, bí o ṣe ń sọ ìhìn rere káàkiri, sapá láti má ṣe máa mójú tó “ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [rẹ] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílí. 2:4.