Ẹ̀KỌ́ 31
Bíbọ̀wọ̀fúnni
ÌWÉ MÍMỌ́ sọ fún wa pé kí á “máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo” kí a sì “má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́.” (1 Pét. 2:17; Títù 3:2) Ní tòótọ́ gbogbo ẹni tí a bá bá pàdé ló jẹ́ ẹni tó ‘wà “ní ìrí Ọlọ́run.”’ (Ják. 3:9) Olúkúlùkù wọn ló jẹ́ ẹni tí Kristi kú fún. (Jòh. 3:16) Gbogbo wọn pátá ló yẹ kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ lé e lórí láti lè rí ìgbàlà. (2 Pét. 3:9) Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n ní ànímọ́ tàbí tí wọ́n wà nípò àṣẹ tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn.
Kí nìdí tí àwọn kan kì í fi í fẹ́ bọ̀wọ̀ fúnni bí Bíbélì ṣe gbà wá níyànjú pé ká ṣe? Ó lè jẹ́ ibi tí wọ́n ti wá ló fà á, bóyá ìran ẹni, àwọ̀, ẹ̀yà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin, ipò ìlera, ọjọ́ orí, ọrọ̀ tàbí ipò ẹni láwùjọ ni wọ́n fi ń díwọ̀n ẹni tó yẹ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún lọ́dọ̀ tiwọn. Ìwà ìbàjẹ́ tó gbilẹ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba mú káwọn èèyàn má fi bẹ́ẹ̀ bọ̀wọ̀ fàwọn aláṣẹ mọ́. Ní àwọn ilẹ̀ kan, inú àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ dùn nípa bí nǹkan ṣe rí fún wọn ní ìgbésí ayé, bóyá iṣẹ́ àṣekúdórógbó ni wọ́n tiẹ̀ ń ṣe láti ṣáà lè rí nǹkan bàṣírí ara wọn, tó sì tún jẹ́ pé àárín àwọn tí kì í bọ̀wọ̀ fúnni ni wọ́n ń gbé. Àwọn ojúgbà máa ń fúngun mọ́ àwọn èwe pé kí wọ́n bá àwọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn olùkọ́ àti àwọn aláṣẹ mìíràn tínú àwọn èèyàn ò dùn sí. Ọ̀pọ̀ èwe ló ń kọ́ àṣàkaṣà látorí tẹlifíṣọ̀n níbi tí wọ́n ti ń rí i bí àwọn ọmọdé ṣe ń purọ́ fún àwọn òbí wọn tí wọ́n sì ń pàṣẹ lé wọn lórí. Ó gba ìsapá gidi kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tó ṣàì yí ẹ̀mí ìbọ̀wọ̀fúnni tí a ní padà. Ṣùgbọ́n, bí a bá buyì kún àwọn èèyàn, ó máa ń jẹ́ kí àyè ṣí sílẹ̀ fún wa láti bá wọn jíròrò fàlàlà.
Fífi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Tọ Àwọn Èèyàn Lọ. Àwọn èèyàn máa ń retí pé kí àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ti ìsìn máa bọ̀wọ̀ fúnni nípa wíwọṣọ tó yẹ ọmọlúwàbí, kí wọ́n sì máa hùwà lọ́nà tó yẹ ọmọlúwàbí. Ohun tí a kà sí ìwà ọmọlúwàbí yàtọ̀ láti ibì kan síbòmíràn. Àwọn kan ka dídé fìlà sórí àti kíkiwọ́ sápò bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ sí ìwà àìfinipeni. Níbòmíràn, wọ́n lè má kà á sí ohun tí kò yẹ. Ńṣe ni kí o mọ ohun tí àwọn èèyàn ń fẹ́ níbi tí o wà kó má bàa di pé o ṣẹ̀ wọ́n. Tí o bá mọ̀ ọ́n, wàá lè yàgò fún ohun tó lè dènà sísọ ìhìn rere fúnni lọ́nà tó múná dóko.
Ohun kan náà ló kan ọ̀nà tí a ó gbà báni sọ̀rọ̀, pàápàá àwọn àgbàlagbà. Ní gbogbo gbòò àwọn èèyàn kà á sí ìwà àrífín pé kí ọmọdé dédé la orúkọ mọ́ àgbàlagbà lórí láìgbàṣẹ. Ní àwọn ibì kan, wọ́n gbà pé kò tọ́ kí àwọn àgbà pàápàá kàn la orúkọ mọ́ àlejò lórí. Bákan náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè máa ń lo ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ bí “ẹ,” “yín,” “ẹ̀yin,” tàbí àwọn ọ̀nà mìíràn láti fi bọ̀wọ̀ fún ẹni tó ṣàgbà ẹni tàbí ẹni tó wà nípò àṣẹ.
Yíyẹ́nisí. Ní àwọn abúlé, wọ́n sábà máa ń retí pé kí o yẹ́ ẹni tí o bá bá pàdé sí, yálà lójú ọ̀nà tàbí nígbà tí o bá ń wọ ilé kan. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wàá kàn kí i, tàbí kí o rẹ́rìn-ín músẹ́, tàbí kí o rọra tẹrí ba, tàbí kí o tiẹ̀ ṣáà fojú kí i lásán. Wọ́n ka àìyẹ́nisí sí ìwà àìlọ́wọ̀.
Àmọ́ ṣá o, àwọn kan ṣì wà tó jẹ́ pé bí o bá tiẹ̀ kí wọn, wọn ò ní tíì gbà pé o ka àwọn sí rárá. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó lè hàn sí wọn pé àwọn ò jọ ọ́ lójú rárá. Kì í ṣe ohun àjèjì rárá pé àwọn èèyàn máa ń fi ìrísí ara dáni yà sọ́tọ̀. Ìyẹn làwọn èèyàn fi sábà máa ń yẹra fáwọn abirùn. Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa ní ọ̀nà tí a lè gbà fi ìfẹ́ hàn sí irú wọn ká sì buyì kún wọn. (Mát. 8:2, 3) Kò sí ẹnikẹ́ni lára wa tí ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù kò tàbùkù rẹ̀ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Bí ó bá jẹ́ pé àbùkù rẹ làwọn èèyàn fi ń pè ọ́ ṣe wàá gbà pé wọ́n buyì kún ọ? Ǹjẹ́ o kò ní fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn ànímọ́ dáadáa tí o ní làwọn èèyàn fi mọ̀ ọ́?
Bíbọ̀wọ̀ fún ipò orí tún jẹ́ ọ̀nà kan láti gbà bọ̀wọ̀ fúnni. Ní àwọn ibì kan o ṣe pàtàkì pé kí o kọ́kọ́ bá baálé ilé sọ̀rọ̀ kí o tó wàásù fún àwọn ará ilé rẹ̀ yòókù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni a ti gba àṣẹ pé ká lọ máa wàásù kí á sì máa kọ́ni, síbẹ̀ a mọ̀ pé àwọn òbí ni Ọlọ́run fún láṣẹ pé kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n bá wọn wí, kí wọ́n sì darí wọn. (Éfé. 6:1-4) Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá dé ilé kan, ó sábà máa ń bójú mu pé kí á kọ́kọ́ bá àwọn òbí sọ̀rọ̀ ká tó bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ gígùn pẹ̀lú àwọn ọmọ.
Àgbàlagbà máa ń ní ìrírí ayé nítorí náà, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹni tó ṣàgbà ẹni. (Jóòbù 32:6, 7) Ìbọ̀wọ̀fágbà yìí ló ran ọ̀dọ́mọbìnrin aṣáájú ọ̀nà kan ní ilẹ̀ Sri Lanka lọ́wọ́ nígbà tó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin àgbàlagbà kan. Ọkùnrin náà ò kọ́kọ́ fara mọ́ wíwá tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní: “Báwo ni ìwọ ọmọ kékeré á ṣe wá kọ́ mi ní Bíbélì?” Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin náà dáhùn pé: “Ẹ jọ̀ọ́ sà, kì í ṣe pé mo wá kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́ o. Ìròyìn ayọ̀ kan tí mo rí ló dùn mọ́ mi tí mo sì ń fẹ́ káráyé ó gbọ́, ẹ sáà mọ̀ pé inú ẹni kì í dùn ká pa á mọ́ra. Ìyẹn ló jẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ yín.” Ọ̀nà ọ̀wọ̀ tí aṣáájú ọ̀nà yìí gbà fèsì mú kí ọkùnrin yìí fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin yìí ní: “Ó dáa màá gbọ́, kí nìròyìn ọ̀hún?” Ọmọbìnrin náà wá sọ pé: “Mo ti rí ọ̀nà téèyàn fi máa wà láàyè títí láé.” Bí àgbàlagbà yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn o. Kì í ṣe gbogbo àwọn àgbàlagbà ló máa kúkú sọ ọ́ jáde lẹ́nu pé ká bọ̀wọ̀ fún àwọn lọ́nà bẹ́ẹ̀, àmọ́ inú ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń dùn sí i.
Ṣùgbọ́n àṣejù lè wọ ọ̀nà tí a gbà ń bọ̀wọ̀ fúnni o. Ní àwọn erékùṣù Pàsífíìkì àti àwọn ibòmíràn, bí Ẹlẹ́rìí kan bá dé ọ̀dọ̀ ọba tàbí ìjòyè kan tó sì kí i bí wọ́n ṣe ń kí tọba tìjòyé lágbègbè ibẹ̀, ìyẹn lè mú kó tẹ́tí gbọ́ ohun tó bá wá, kí ó sì tún lè wàásù fún òun àtàwọn èèyàn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, kò sídìí fún wa láti kíni lọ́nà ìpọ́nni ẹ̀tàn, kò tiẹ̀ sì tọ́ pàápàá. (Òwe 29:5) Bákan náà, ìlò èdè àpọ́nlé lè wà lára ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ tí àwọn elédè kan gbà pé ó yẹ nínú èdè àwọn, àmọ́ bíbọ̀wọ̀ tí Kristẹni ń bọ̀wọ̀ fúnni kò ní ká máa wá lo èdè ọ̀wọ̀ ní àlòjù.
Fífi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Bá Àwùjọ Sọ̀rọ̀. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa fi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” ṣàlàyé ìdí tí a fi ní irú ìrètí tí a ní. (1 Pét. 3:15) Nípa bẹ́ẹ̀, bí ọ̀nà tí a fi lè túdìí àwọn àṣìṣe inú èrò tẹ́nì kan ń sọ síta bá tiẹ̀ ń bẹ ní àtẹ́lẹwọ́ wa, ṣé ó bọ́gbọ́n mu pé ká wá ṣe é lọ́nà tí a ó fi dójú ti onítọ̀hún? Ǹjẹ́ kò ní sàn pé ká fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀, bóyá kí á tún béèrè ìdí tó fi ní irú èrò tí ó ní, kí á sì wá fi èrò rẹ̀ yìí sọ́kàn bí a ṣe ń ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ wí fún un?
Ó yẹ kí irú ọ̀wọ̀ tí à ń fi hàn nígbà tí a bá ń bá ẹnì kan ṣoṣo sọ̀rọ̀ yìí tún hàn gbangba nígbà tí a bá ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ látorí pèpéle. Bí olùbánisọ̀rọ̀ bá bọ̀wọ̀ fún àwùjọ rẹ̀, kò ní fi ìkanra sọ̀rọ̀ gún wọn lára ṣàkàṣàkà tàbí kó máa bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò fi dà bíi pé ó ń fi yé wọn pé: “Àfi ẹni tí àìníkan-ánṣe bá ń yọ lẹ́nu lára yín ni yóò sọ pé òun ò lè ṣe ohun tí mo wí yìí.” Ìrẹ̀wẹ̀sì ni irú ọ̀rọ̀ báyìí máa ń kó bá àwọn èèyàn. Ì bá mà dára o pé kí á ka àwọn olùgbọ́ wa sí àpéjọ àwọn èèyàn tó fẹ́ràn Jèhófà tí wọ́n sì ń fẹ́ láti sìn ín! Ó yẹ kí á tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù kí á sì lo òye nígbà tí a bá ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ aláìlera tàbí ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí nípa tẹ̀mí tàbí ẹni tí kò lè tètè fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò.
Bí olùbánisọ̀rọ̀ bá ka ara rẹ̀ mọ́ àwọn tó yẹ kí ó túbọ̀ fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò síwájú sí i, àwùjọ yóò gbà pé ó bọ̀wọ̀ fún àwọn. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣe kanni, kí á yẹra fún lílo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ tó dúró fún ẹnì kan péré bí “ìwọ,” “ọ,” àti “o.” Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí ìyàtọ̀ tó wà nínú ìbéèrè yìí, “Ǹjẹ́ o ń ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ ká?” àti ọ̀rọ̀ yìí, “Ó dára kí olúkúlùkù wa bí ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo ń ṣe gbogbo ohun tí agbára mi ká?’” Kókó kan náà ni ìbéèrè méjèèjì ń sọ ṣùgbọ́n tàkọ́kọ́ fi hàn pé olùbánisọ̀rọ̀ kò ka ara rẹ̀ mọ́ àwùjọ náà. Ìkejì ń gba olúkúlùkù níyànjú, títí kan olùbánisọ̀rọ̀ alára, láti fúnra rẹ̀ yẹ ipò ara rẹ̀ àti ẹ̀mí tó fi ń ṣe nǹkan wò.
Yẹra fún ṣíṣàwàdà láti kàn dẹ́rìn-ín pa àwùjọ. Ìyẹn máa ń dín iyì ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí à ń sọ kù. Lóòótọ́ ó yẹ kí iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run máa mú inú wa dùn. Àwọn apá kan tiẹ̀ lè wà nínú ọ̀rọ̀ tí a fẹ́ sọ tó lè pani lẹ́rìn-ín díẹ̀. Síbẹ̀, láti sọ ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì di ọ̀rọ̀ ẹ̀rín kò fi hàn pé onítọ̀hún bọ̀wọ̀ fún àwùjọ tàbí fún Ọlọ́run rárá.
Ǹjẹ́ kí ọ̀nà tí a gbà tọ àwọn èèyàn lọ, ìṣarasíhùwà wa àti ọ̀nà tí a gbà ń sọ̀rọ̀ máa fi hàn nígbà gbogbo pé a ti dẹni tó ń wo àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe kọ́ wa pé ká máa wò wọ́n.