ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 47 ojú ìwé 247-ojú ìwé 250 ìpínrọ̀ 1
  • Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Múná Dóko

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Múná Dóko
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpèjúwe Tí A Gbé Ka Ohun Táwọn Èèyàn Mọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Bíbọ̀wọ̀fúnni
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Máa Lo Fídíò Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 47 ojú ìwé 247-ojú ìwé 250 ìpínrọ̀ 1

Ẹ̀KỌ́ 47

Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Múná Dóko

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o lo oríṣiríṣi àwòrán àti àtẹ ìsọfúnni, tàbí àwọn nǹkan mìíràn láti túbọ̀ fi gbé àwọn kókó pàtàkì yọ kedere.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ohun tá a lè fojú rí máa ń jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ yéni. Kì í sì í jẹ́ kéèyàn tètè gbàgbé ọ̀rọ̀. Ó lágbára ju ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan.

KÍ NÌDÍ tó fi dáa kí o lo ohun tá a lè fojú rí nígbà tó o bá ń kọ́ni? Nítorí pé lílò ó lè jẹ́ kí ọ̀nà tí o gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ múná dóko. Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi lo àwọn ohun tá a lè fojú rí láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Nígbà tó o bá lo ohun tá a lè fojú rí, pa pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu, tojú tetí làwọn èèyàn á fi máa gba ìsọfúnni. Èyí lè jẹ́ kí àwùjọ pọkàn pọ̀, kí ọ̀rọ̀ rẹ sì túbọ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Báwo ni wàá ṣe lo ohun tá a lè fojú rí nígbà tó o bá ń wàásù ìhìn rere náà? Báwo ni wàá ṣe rí i dájú pé ò ń lò ó lọ́nà tó múná dóko?

Bí Àwọn Olùkọ́ni Títóbilọ́lá Ṣe Lo Ohun Tí A Lè Fojú Rí. Jèhófà lo ohun tí a lè fojú rí tó jẹ́ mánigbàgbé láti fi kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. Ó ní kí Ábúráhámù jáde síta lóru ọjọ́ kan, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, gbé ojú sókè sí ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, bí ó bá lè ṣeé ṣe fún ọ láti kà wọ́n. . . . Bẹ́ẹ̀ ni irú-ọmọ rẹ yóò dà.” (Jẹ́n. 15:5) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lójú èèyàn, ìlérí yẹn dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe, ó wú Ábúráhámù lórí gidigidi, ó sì gba Jèhófà gbọ́. Ní àkókò mìíràn, Jèhófà ní kí Jeremáyà lọ sílé amọ̀kòkò. Ó ní kó wọ ibi iṣẹ́ amọ̀kòkò náà, kí ó lọ wo bí ọkùnrin náà ṣe ń fi amọ̀ mọ oríṣiríṣi nǹkan. Ẹ wo ẹ̀kọ́ mánigbàgbé tí èyí fi kọ́ wa nípa agbára tí Ẹlẹ́dàá ní lórí àwa ẹ̀dá ènìyàn! (Jer. 18:1-6) Báwo sì ni Jónà ṣe lè gbàgbé ẹ̀kọ́ nípa níní ojú àánú, nínú èyí tí Jèhófà ti lo ìtàkùn tí ń so akèrègbè láti fi kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́? (Jónà 4:6-11) Jèhófà tilẹ̀ sọ pé kí àwọn kan nínú àwọn wòlíì rẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn lọ́nà àwòkẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì lo àwọn nǹkan yíyẹ tí a lè fojú rí. (1 Ọba 11:29-32; Jer. 27:1-8; Ìsík. 4:1-17) Àgọ́ ìjọsìn àti ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú tẹ́ńpìlì jẹ́ àwọn nǹkan ìṣàpẹẹrẹ tó jẹ́ kó rọrùn fún wa láti lóye àwọn ohun tí ń bẹ lọ́run. (Héb. 9:9, 23, 24) Ọlọ́run tún tàtaré àwọn ìsọfúnni pàtàkì nípa lílo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran.—Ìsík. 1:4-28; 8:2-18; Ìṣe 10:9-16; 16:9, 10; Ìṣí. 1:1.

Báwo ni Jésù ṣe lo àwọn nǹkan tá a lè fojú rí? Nígbà táwọn Farisí àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù ń wá ọ̀nà láti ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, Jésù ní kí wọ́n bá òun mú owó dínárì kan wá. Ó ní kí wọ́n wo àwòrán Késárì tó wà lára owó náà. Ó wá sọ fún wọn pé kí wọ́n san ohun ti Késárì fún Késárì, ṣùgbọ́n kí wọ́n san ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run. (Mát. 22:19-21) Nígbà tí Jésù ń kọ́ wa pé ká máa fi gbogbo ohun tá a ní bọlá fún Ọlọ́run, ó tọ́ka sí tálákà opó kan, tó jẹ́ pé gbogbo owó tó ní pátá, ìyẹn owó ẹyọ wẹ́wẹ́ méjì, ló mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ. (Lúùkù 21:1-4) Nígbà mìíràn, ó fi ọmọ kékeré kan ṣàpèjúwe bó ṣe yẹ kéèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì jẹ́ ẹni tí kì í lépa ipò ọlá. (Mát. 18:2-6) Òun alára tún fi ohun tí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ túmọ̀ sí hàn, nígbà tó wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Jòh. 13:14.

Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tí A Lè Fojú Rí. Níwọ̀n bí a kì í ti í ṣe Jèhófà, a kò lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní ojúran. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwòrán tí ń múni ronú jinlẹ̀ ló wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fi àwòrán wọ̀nyí ran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ láti máa fojú inú wo bí Párádísè ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe máa rí. Nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, o lè pe àfiyèsí akẹ́kọ̀ọ́ sí àwòrán tó bá ohun tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mu, kí o sì ní kí ó sọ ohun tó rí. Ó yẹ fún àfiyèsí pé nígbà tí Jèhófà fún Ámósì wòlíì ní àwọn ìran kan, Jèhófà bi í pé: “Ámósì, kí ni ìwọ rí?” (Ámósì 7:7, 8; 8:1, 2) Ìwọ náà lè béèrè irú ìbéèrè yẹn nígbà tó o bá ń pe àfiyèsí sí àwòrán tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

Bí o bá ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣirò kan lẹ́sẹẹsẹ tàbí tí o ṣe àtẹ ìsọfúnni nípa àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan, èyí lè jẹ́ káwọn èèyàn tètè lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bí “ìgbà méje” tí ìwé Dáníẹ́lì 4:16 sọ àti “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” inú Dáníẹ́lì 9:24. Irú àwọn àtẹ ìsọfúnni tá a lè fojú rí bẹ́ẹ̀ ń bẹ nínú ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.

Nígbà tí ìdílé yín bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ lè mú kí àlàyé lórí àwọn nǹkan bí àgọ́ ìjọsìn, tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran túbọ̀ rọrùn láti lóye bí ẹ bá lo àwòrán. Ẹ lè rí irú àwòrán bẹ́ẹ̀ nínú ìwé Insight on the Scriptures àti nínú àfikún ẹ̀yìn Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References àti onírúurú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́.

Máa lo àwòrán dáadáa nígbà tí ìwọ àti ìdílé rẹ bá ń ka Bíbélì pa pọ̀. Fara balẹ̀ wo ọ̀nà tí Ábúráhámù tọ̀ láti Úrì dé Háránì tó fi dé ìlú Bẹ́tẹ́lì. Wo ọ̀nà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbà nígbà tí wọ́n fi Íjíbítì sílẹ̀, tí wọ́n forí lé Ilẹ̀ Ìlérí. Fojú wá ibi tí ogún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Kíyè sí ibi tí ìṣàkóso Sólómọ́nì nasẹ̀ dé. Fojú bá ọ̀nà tí Èlíjà tọ̀ lọ, bó ṣe sá kúrò ní Jésíréélì tó kọrí sí iyàn-níyàn aginjù ní ìkọjá Bíá-ṣébà, nígbà tí Jésíbẹ́lì halẹ̀ mọ́ ọn. (1 Ọba 18:46–19:4) Wá àwọn ìlú ńláńlá àti ìlú kéékèèké tí Jésù ti wàásù kàn. Wo àwọn ibi tí ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì sọ pé Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò dé.

Àwọn ohun tá a lè fojú rí wúlò gan-an nígbà tó o bá ń ṣàlàyé ìgbòkègbodò ìjọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O lè fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ han akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, kí o ṣàlàyé irú ìsọfúnni tá à ń gbọ́ ní àpéjọ àyíká àti àgbègbè fún un. Inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ dùn gan-an nígbà tá a mú wọn rìn kiri Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí lè jẹ́ ọ̀nà tó dára láti jẹ́ kí wọ́n ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ wa àti ìdí tá a fi ń ṣe é. Nígbà tó o bá ń mú wọn rìn kiri Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣàlàyé bó ṣe yàtọ̀ sí àwọn ilé ìjọsìn mìíràn. Jẹ́ kí ó yé wọn pé bí Gbọ̀ngàn Ìjọba kì í tilẹ̀ ẹ́ ṣe ilé olówó ńlá, ó jẹ́ ibi tó dára fún ẹ̀kọ́ kíkọ́. Ṣàlàyé àwọn ètò tá a ṣe ní pàtàkì fún ìtìlẹyìn iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe fún gbogbo èèyàn, ìyẹn àwọn ibi tí à ń pín ìwé wa dé, àwòrán ìpínlẹ̀ àtàwọn àpótí ọrẹ (nítorí pé a kì í gbé igbá owó kiri ní tiwa).

Bí o bá ní àwọn fídíò tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gbé jáde, lò ó láti jẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ túbọ̀ fọkàn tán Bíbélì, kí wọ́n túbọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sì lò ó láti fi fún wọn níṣìírí láti máa gbé ìgbé ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu.

Lílo Ohun Tí A Lè Fojú Rí Níwájú Àwùjọ Ńlá. Àwọn ohun tá a lè fojú rí máa ń kọ́ àwùjọ ńlá lẹ́kọ̀ọ́ gidi, bí a bá múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, tá a sì gbé e kalẹ̀ lọ́nà tó gbámúṣé. Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti pèsè ọ̀kan-kò-jọ̀kan irú àwọn ohun tí a lè fojú rí bẹ́ẹ̀.

Àwọn àpilẹ̀kọ tá à ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ sábà máa ń ní àwọn àwòrán nínú, èyí tí olùdarí lè lò láti fi tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwòrán ń bẹ nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá à ń lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

Àwọn àlàyé kan tá a ṣe nínú àwọn ìwé àsọyé kan lè jẹ́ kí ó dà bíi pé yóò bójú mu láti lo àwọn ohun tá a lè fojú rí láti fi ṣe àpèjúwe àwọn kókó kan níbẹ̀. Àmọ́, ohun tó ṣàǹfààní jù lọ ni pé kéèyàn darí àfiyèsí sí ohun tó wà nínú Bíbélì. Nítorí pé àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú àwùjọ ni yóò ní Bíbélì lọ́wọ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tó o bá rí i pé ó pọn dandan láti lo àwòrán tàbí àtẹ ìsọfúnni tó ṣe ṣókí láti fi ṣàlàyé kókó pàtàkì tàbí kókó mélòó kan nínú àsọyé, kọ́kọ́ rí i dájú pé àwọn tó wà lẹ́yìn pátápátá nínú ilé ìpàdé yẹn á rí àwòrán tàbí àtẹ ìsọfúnni náà dáadáa tàbí wọn á lè kà á dáadáa. Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ló yẹ kí á máa lo irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Kì í ṣe tìtorí àtidá àwọn èèyàn lára yá la ṣe ń lo àwọn ohun tá a lè fojú rí nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀, tá a sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tá a bá lo èyí tó bójú mu, ó yẹ kó túbọ̀ tẹ àwọn èrò tó yẹ fún àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ mọ́ni lọ́kàn. A lè sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní bó bá mú kí ọ̀rọ̀ tá a sọ túbọ̀ ṣe kedere, tó jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn láti lóye, tàbí tó bá fẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ti ohun tá a sọ lẹ́yìn. Bí a bá lò ó bó ṣe tọ́, irú àwọn ohun tá a lè fojú rí bẹ́ẹ̀ máa ń wọni lọ́kàn débi pé a lè má gbàgbé ohun tá a fojú rí náà àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ wa, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá.

Agbára ìgbọràn àti ìríran ń kó ipa pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́. Rántí bí àwọn Olùkọ́ títóbilọ́lá náà, Jèhófà àti Jésù, ṣe lo ànímọ́ méjèèjì yìí, kí o sì gbìyànjú láti fara wé wọn bó o ṣe ń sapá láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn.

ÀWỌN OHUN TÍ A LÈ FOJÚ RÍ TÓ GBÉṢẸ́ . . .

  • Yẹ kí ó ṣàlàyé àwọn ohun tó gba àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀, kí wọ́n sì yéni.

  • Yẹ kí ó jẹ́ èyí tí a lò ní pàtàkì fún kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

  • Yẹ kí ó jẹ́ èyí tí gbogbo àwùjọ yóò rí kedere bí a bá lò ó látorí pèpéle.

ÌDÁNRAWÒ: To àwọn ohun tí a lè fojú rí tó o fẹ́ lò sísàlẹ̀ yìí . . .

Láti mú káwọn èèyàn túbọ̀ mọyì ètò Jèhófà

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

Láti mú kí ọmọ kan lóye àwọn òtítọ́ kan látinú Bíbélì

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․․

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́