Ẹ̀KỌ́ 33
Lo Ọgbọ́n Inú Síbẹ̀ Dúró Lórí Òtítọ́
BÍ ÈÈYÀN bá ń lo ọgbọ́n inú yóò mọ bí ó ṣe lè máa bá àwọn èèyàn lò láìní máa ṣèèṣì ṣẹ̀ wọ́n. Ìyẹn sì gba pé kéèyàn mọ bó ṣe yẹ kó sọ̀rọ̀ àti ìgbà tó yẹ kó sọ ọ́. Èyí kò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa gba ìgbàkugbà tàbí kí ó máa lọ́ òtítọ́ lọ́rùn. Àmọ́ ṣá o, lílo ọgbọ́n inú yàtọ̀ pátápátá sí bíbẹ̀rù èèyàn.—Òwe 29:25.
Téèyàn bá fẹ́ dẹni tó ń lo ọgbọ́n inú, ohun tó ti dára jù lọ ni pé kí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ látorí fífi èso ti ẹ̀mí kọ́ra ná. Nítorí pé ẹni tí ìfẹ́ ń sún ṣe nǹkan kì í fẹ́ ṣe ohun tó máa mú ọmọnìkejì rẹ̀ bínú rárá; ńṣe ló máa ń fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ni onínúure àti ọlọ́kàn tútù èèyàn máa ń ṣe nǹkan tirẹ̀. Èèyàn àlàáfíà a sì máa wá ọ̀nà láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn èèyàn yòókù. Kódà bí àwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń tọ́ onípamọ́ra èèyàn níjà, jẹ́jẹ́ tó ń ṣe náà ni yóò ṣì máa ṣe ní tirẹ̀.—Gál. 5:22, 23.
Àmọ́ ṣá o, bó ṣe wù kí á fi ọgbọ́n ṣàlàyé ìhìn inú Bíbélì tó, ó ṣì máa bí àwọn kan nínú ṣáá ni. Ọkàn burúkú tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ní mú kí Jésù Kristi di “òkúta ìkọ̀sẹ̀ àti àpáta ràbàtà ìdìgbòlù” lọ́dọ̀ wọn. (1 Pét. 2:7, 8) Ohun tí Jésù sọ nípa iṣẹ́ pípolongo Ìjọba Ọlọ́run tó ń ṣe ni pé: “Èmi wá láti dá iná kan sórí ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 12:49) Títí di ìsinsìnyí pàápàá, ìhìn nípa Ìjọba Jèhófà yìí, èyí tó kan yíyẹ tó yẹ kí aráyé tẹ́wọ́ gba Ẹlẹ́dàá wọn gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ṣì jẹ́ ọ̀ràn pàtàkì tó yẹ kí aráyé kọbi ara sí kíákíá. Lóòótọ́ ó máa ń bí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú láti gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí kúrò láìpẹ́. Síbẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run ló ní ká máa wàásù, a ò ní tìtorí èèyàn dáwọ́ ìwàásù yẹn dúró. Ṣùgbọ́n bí a ṣe ń bá ìwàásù wa nìṣó, a ò ní gbàgbé ìmọ̀ràn Bíbélì tó ní: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.
Lílo Ọgbọ́n Inú Nígbà Tí A Bá Ń Wàásù. Onírúurú ipò la ti máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wa. A mọ̀ pé a máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ tí a bá wà lóde ẹ̀rí, síbẹ̀ a tún máa ń wá bí a ó ṣe láǹfààní láti bá àwọn ìbátan wa, àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ àti àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wa sọ̀rọ̀ tí a bá wà pẹ̀lú wọn. Gbogbo ipò tí a mẹ́nu kàn yìí ló sì gba ọgbọ́n inú.
Bí a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tí a ó fi jẹ́ kí wọ́n lérò pé ńṣe là ń dá wọn lẹ́jọ́, wọ́n lè kọ̀ ọ́. Ọ̀rọ̀ wa sì lè bí wọn nínú tí a bá ń sọ ọ́ bíi pé ńṣe la wá bá wọn wí, wọn ò kúkú wá bẹ̀ wá pé ká ran àwọn lọ́wọ́, bóyá wọ́n tiẹ̀ lè máà rí i pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ pàápàá. Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n ṣì wá lóye? Ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ ní pé ká kọ́ bí a ṣe ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́.
Láti bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀, ńṣe ni kó o sọ̀rọ̀ nípa kókó kan tí onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ sí. Bí onítọ̀hún bá jẹ́ ìbátan rẹ tàbí ará ibi iṣẹ́ yín tàbí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yín, ó ṣeé ṣe kí o tiẹ̀ ti mọ ohun tó lè nífẹ̀ẹ́ sí. Ká tiẹ̀ wá ní o ò tíì bá onítọ̀hún pàdé rí, o lè sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó o gbọ́ nínú ìròyìn orí rédíò tàbí ohun kan tí o kà nínú ìwé ìròyìn tàbí ọ̀rọ̀ kan tó ń lọ láàárín ìlú. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ mọ́ ohun tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn. Máa fojú sílẹ̀ nígbà tí o bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ ara ilé, ohun ìṣeré ọmọdé tó wà lọ́ọ̀dẹ̀ ilé, àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ti ìsìn àti àwọn ọ̀rọ̀ tí a lẹ̀ mọ́ ara mọ́tò tó wà níbẹ̀ lè jẹ́ kí o túbọ̀ mọ ohun tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí. Nígbà tí onílé bá ń jẹ́ ọ, fetí sí ohun tó ń sọ. Ọ̀rọ̀ onílé lè fi hàn pé ohun tó o rò pé ó nífẹ̀ẹ́ sí náà ló nífẹ̀ẹ́ sí lóòótọ́, tàbí kó fi hàn pé ohun tó yàtọ̀ sí èyí tí ìwọ rò lọ́kàn ló nífẹ̀ẹ́ sí àti pé èrò tirẹ̀ yàtọ̀ sí tìrẹ, ìyẹn yóò sì túbọ̀ jẹ́ kí o mọ ohun tí o máa ronú lé lórí kí o lè wàásù fún un.
Bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn ṣe ń tẹ̀ síwájú, wá fa àwọn kókó kan tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ jáde látinú Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì. Ṣùgbọ́n má ṣe gba ọ̀rọ̀ yòókù sọ mọ́ ọn lẹ́nu o. (Oníw. 3:7) Jẹ́ kí onílé rẹ lóhùn sí ọ̀rọ̀ náà bí ó bá ń fẹ́ láti sọ sí ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Tẹ́tí gbọ́ èrò tirẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yẹn. Ìyẹn lè ṣamọ̀nà rẹ láti mọ bí o ṣe máa lo ọgbọ́n inú.
Kí o tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, kọ́kọ́ ronú nípa bí ohun tí o fẹ́ sọ ṣe máa rí lára olùgbọ́ rẹ. Òwe 12:8 gbóríyìn fún “ẹnu . . . tí ó fi ọgbọ́n inú hàn.” Nínú èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò níhìn-ín wé mọ́ àwọn nǹkan bíi lílo ìjìnlẹ̀ òye àti làákàyè. Nípa báyìí, lílo ọgbọ́n inú nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ wé mọ́ fífọgbọ́n ṣẹ́ ọ̀rọ̀ ẹni kù mọ́nú nítorí pé a gbé ọ̀rọ̀ wa yẹ̀ wò dáadáa kí á lè hùwà ọlọgbọ́n. Òwe 12:18 kìlọ̀ pé kí á má ṣe jẹ́ ẹni “tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” Ó dájú pé a lè gbé òtítọ́ Bíbélì lárugẹ láìjẹ́ pé a ṣẹ àwọn èèyàn.
Bí o bá fi òye yan irú ọ̀rọ̀ tí o máa lò ìyẹn lè mú ọ yẹra fún ṣíṣèèṣì ṣe ohun tí yóò dènà gbígbọ́ táwọn èèyàn ì bá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Tí àwọn èèyàn ò bá fẹ́ máa gbọ́ gbólóhùn náà, “Bíbélì,” nínú ọ̀rọ̀ rẹ, o lè máa lo gbólóhùn bí “Ìwé Mímọ́” tàbí “ìwé kan tó ti wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún méjì lọ báyìí.” Bí ó bá wá di pé o tọ́ka sí Bíbélì, o lè béèrè ohun tí olùgbọ́ rẹ rò nípa rẹ̀, kí o wá fi ohun tí ó sọ sọ́kàn bí ẹ ṣe ń bá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn nìṣó.
Lílo ọgbọ́n inú tún sábà máa ń kan mímọ ìgbà tó yẹ kí èèyàn sọ ọ̀rọ̀ kan. (Òwe 25:11) Ó lè máà jẹ́ gbogbo ohun tí ẹni tí ẹ jọ ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ sọ lo fara mọ́, ṣùgbọ́n kò sídìí láti máa já gbogbo nǹkan tí kò bá ṣáà ti bá Ìwé Mímọ́ mu nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní koro. Má ṣe gbìyànjú láti sọ gbogbo nǹkan pátá fún ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.”—Jòh. 16:12.
Nígbà tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti fi tọkàntọkàn yin àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀. Àní bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àríyànjiyàn ni onítọ̀hún ń ṣe ṣáá, o ṣì lè yìn ín pé ó tiẹ̀ sọ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ yẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yin àwọn èèyàn lọ́nà bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń bá àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí sọ̀rọ̀ ní Áréópágù ti Áténì. Ńṣe làwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí yẹn ń “bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àríyànjiyàn.” Ọ̀nà wo ni yóò wá gbà sòótọ́ ọ̀rọ̀ fún wọn láìní mú inú bí wọn? Ó ti kọ́kọ́ rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ pẹpẹ tí wọ́n ṣe fún àwọn òrìṣà wọn. Dípò kí ó máa wá fi ìyẹn bẹnu àtẹ́ lu àwọn ará Áténì yìí pé wọ́n jẹ́ abọ̀rìṣà, ńṣe lo fọgbọ́n yìn wọ́n pé wọ́n mà lẹ́mìí ìsìn gan-an o. Ó ní: “Mo ṣàkíyèsí pé nínú ohun gbogbo, ó jọ pé ẹ kún fún ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún ju àwọn mìíràn lọ.” Ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ yìí mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́. Nípa bẹ́ẹ̀ àwọn kan lára wọn di onígbàgbọ́.—Ìṣe 17:18, 22, 34.
Bí ẹnì kan bá ṣàtakò má ṣe da ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú. Fọkàn balẹ̀. Ka èyí sí àǹfààní láti fi túbọ̀ mọ èrò inú onítọ̀hún. O lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún sísọ tí ó sọ èrò ọkàn rẹ̀. Tí ẹnì kan bá kàn dáhùn pé: “Mo lẹ́sìn tèmi” ńkọ́? O lè fọgbọ́n béèrè pé: “Ǹjẹ́ kò ti pẹ́ gan-an tí ẹ ti ń ṣe ẹ̀sìn yín yìí bọ̀?” Tí ó bá fèsì tán, wá sọ̀rọ̀ síwájú sí i pé: “Ǹjẹ́ ẹ rò pé aráyé yóò lè fìmọ̀ ṣọ̀kan láti máa ṣe ẹ̀sìn kan ṣoṣo láé bí?” Ó ṣeé ṣe kí èyí mú kí ẹ lè túbọ̀ jọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ síwájú sí i.
Bí a kò bá jọ ara wa lójú jù, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti máa lo ọgbọ́n inú. Ó dá wa lójú hán-únhán-ún pé àwọn ọ̀nà Jèhófà tọ́ àti pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jóòótọ́. A sì máa ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fúnni lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n dá wa lójú. Ṣùgbọ́n kò sídìí fún wa láti wá sọ ara wa di olódodo lójú ara ẹni. (Oníw. 7:15, 16) A dúpẹ́ pé a mọ òtítọ́ àti pé à ń rí ìbùkún Jèhófà gbà, ṣùgbọ́n a mọ̀ dájú pé nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ àti ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Kristi la fi rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, kì í ṣe nípa òdodo tiwa fúnra wa. (Éfé. 2:8, 9) A mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí á ‘máa dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́, kí á sì máa wádìí ohun tí àwa fúnra wa jẹ́.’ (2 Kọ́r. 13:5) Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa ṣe ohun tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ wọn, a ó lo ìrẹ̀lẹ̀ láti fi hàn pé ìmọ̀ràn Bíbélì tí à ń sọ fún wọn kan àwa pẹ̀lú. A kò fún wa láṣẹ láti máa dá ọmọnìkejì wa lẹ́jọ́. Jèhófà “ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọ lọ́wọ́,” iwájú ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ la ó sì ti jẹ́jọ́ ohun tí a bá ṣe.—Jòh. 5:22; 2 Kọ́r. 5:10.
Lílo Ọgbọ́n Inú Nígbà Tí A Bá Wà Pẹ̀lú Ìdílé Wa Àtàwọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ́ Wa. Òde ẹ̀rí nìkan kọ́ ló ti yẹ kí á máa lo ọgbọ́n inú. Níwọ̀n bí lílo ọgbọ́n inú ti jẹ́ ọ̀nà kan tí à ń gbà fi èso ẹ̀mí Ọlọ́run hàn, ó yẹ kí á máa lo ọgbọ́n inú nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ará ilé wa bákan náà. Ìfẹ́ yóò sún wa láti máa gba bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn rò. Ọkọ Ẹ́sítérì ayaba kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà, àmọ́ Ẹ́sítérì bọ̀wọ̀ fún un, ó sì lo òye gidi nígbà tí ó ń sọ àwọn ọ̀ràn tó kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fún un. (Ẹ́sítérì, orí kẹta sí ìkẹjọ) Nígbà mìíràn, lílo ọgbọ́n inú nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ìbátan wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lè gba pé ká jẹ́ kí ìwà wa jẹ́ ohun tí yóò fi ọ̀nà òtítọ́ hàn wọ́n dípò tí a ó fi máa fẹnu ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wa fún wọn.—1 Pét. 3:1, 2.
Bákan náà, mímọ̀ tí a mọ àwọn ará nínú ìjọ dunjú kò ní ká torí ìyẹn máa nù wọ́n lọ́rọ̀ tàbí ká máa kanra mọ́ wọn. Kò yẹ kí á máa rò ó pé wọ́n kúkú dàgbà dénú nípa tẹ̀mí, nítorí náà ó yẹ kí wọ́n lè máa fara dà á nìṣó. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì yẹ ká máa wí àwíjàre pé: “Ẹ̀bi mi kọ́, bí ẹ̀dá tèmi ṣe rí nìyẹn.” Bí a bá rí i pé ọ̀nà tí a máa ń gbà ṣàlàyé ọ̀rọ̀ máa ń bí àwọn èèyàn nínú, ó yẹ ká rí i pé a yí padà. “Ìfẹ́ gbígbóná janjan” tí a ní ‘fún ara wa’ yẹ kó sún wa láti “máa ṣe ohun rere . . . sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—1 Pét. 4:8, 15; Gál. 6:10.
Lílo Ọgbọ́n Inú Nígbà Tí A Bá Ń Bá Àwùjọ Sọ̀rọ̀. Àwọn tó ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle pẹ̀lú ní láti lo ọgbọ́n inú. Onírúurú èèyàn ló wà nínú àwùjọ, ìgbésí ayé ò sì rí bákan náà fún gbogbo wọn. Ibi tí kálukú wọn dàgbà dé nípa tẹ̀mí yàtọ̀ síra. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí òmíràn lára wọn máa wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba nìyẹn. Àwọn mìíràn níbẹ̀ lè wà nínú ìnira tó ga èyí tí kò hàn sí olùbánisọ̀rọ̀. Kí ló lè ran olùbánisọ̀rọ̀ lọ́wọ́ kí ó má ṣẹ àwọn olùgbọ́ rẹ̀?
Ńṣe ni kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ fún Títù, ìyẹn ni pé kí o máa sapá “láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, . . . láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.” (Títù 3:2) Yẹra fún lílo àwọn gbólóhùn tó ń tàbùkù sí àwọn èèyàn tó wá láti ìran mìíràn tàbí tí wọ́n ń sọ èdè mìíràn tàbí tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn ayé ṣe máa ń ṣe. (Ìṣí. 7:9, 10) Sọ òkodoro ọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí èèyàn ṣe, kí o sì ṣàlàyé bí ó ṣe bọ́gbọ́n mu pé ká ṣe wọ́n; ṣùgbọ́n yẹra fún bíbú àwọn tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ máa tọ ọ̀nà Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa gba gbogbo èèyàn níyànjú láti fòye mọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó wù ú. Bí o bá ń báni wí, kọ́kọ́ fi ohùn tó tura yìn wọ́n látọkànwá láti jẹ́ kí ìbáwí yẹn fi ìrọ̀rùn wọlé sí wọn lára. Nínú ọ̀nà tí o gbà ń sọ̀rọ̀ àti ohùn tí o lò, máa fi ìfẹ́ni ará tó yẹ kí gbogbo wa ní fún ara wa hàn.—1 Tẹs. 4:1-12; 1 Pét. 3:8.