APÁ 3
“Ọlọ́gbọ́n ni”
Ọgbọ́n tòótọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ tó yẹ kéèyàn máa wá. Ọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ọgbọ́n yìí ti ń wá. Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà sọ pé “Ọlọ́gbọ́n ni” Jèhófà. Nínú apá yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ọgbọ́n Jèhófà tí kò láfiwé.—Jóòbù 9:4.