Ibo Tiẹ̀ Layé Yìí Ń Lọ?
À ń gbọ́ ìròyìn àgbọ́sọgbánù lójoojúmọ́ kárí ayé! Kí ni gbogbo rẹ̀ túmọ̀ sí?
Ọ̀RÀN ÀÀBÒ: Oró ò! Wọ́n ju bọ́ǹbù sáàárín ọjà. Èèmọ̀! apààyàn yìnbọn pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtolùkọ́ níléèwé. Ìbòòsí ò! Gbọ́mọgbọ́mọ jí ọmọ gbé káwọn òbí ẹ̀ tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́. Àwọn adigunjalè kọjú àwọn èèyàn sóòrùn alẹ́, wọ́n ń ja tarúgbó tomidan lólè lọ́sàn-án gangan.
Ọ̀RÀN ÌSÌN: Ṣọ́ọ̀ṣì ń gbè sẹ́yìn àwọn tó ń bá ara wọn jà. Àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì ń jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìpẹ̀yàrun. Kàyéfì ńlá! Àwọn àlùfáà ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe; ṣọ́ọ̀ṣì ń bò wọ́n láṣìírí. Èrò ò wá sí ilé ìsìn mọ́; Ṣọ́ọ̀ṣì di gbàǹjo.
Ọ̀RÀN ÀYÍKÁ: Ó parí! Igbó ẹgàn ò sí mọ́, àwọn olówò pákó ti gbàgboro. Háà! Àwọn aṣẹ́gità ti ṣẹ́ gbogbo igi tán nígbó. Omi abẹ́lẹ̀ ń di ẹlẹ́gbin, kò sì ṣeé mu mọ́. Ìdọ̀tí iléeṣẹ́ ńláńlá àti ọ̀nà ìgbàlódé tí wọ́n gbà ń pẹja kò jẹ́ kẹ́ja ó sí lódò mọ́. Èéfín inú afẹ́fẹ́ ń séni léèémí.
GBÍGBỌ́ BÙKÁTÀ: Ìpíndọ́gba iye tó ń wọlé lọ́dún fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní Gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà ní Áfíríkà kò tó nǹkan. Àwọn jẹgúdújẹrá ọ̀gá ti jẹ iléeṣẹ́ run, ọ̀pọ̀ di aláìníṣẹ́lọ́wọ́. Àwọn tó kówó ilé iṣẹ́ jẹ ti kọjú àwọn olùdókòwò sóòrùn alẹ́.
ÀÌTÓ OÚNJẸ: Háà! nǹkan bí ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù èèyàn yíká ayé ló ń sùn lébi.
OGUN: Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn tó bógun lọ ní ọ̀rúndún ogún. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun ìjà runlérùnnà ló wà láti pa ìran èèyàn lápatúnpa. Ogun abẹ́lé. Àwọn apániláyà sọ pó ku ibi táráyé máa gbé e gbà.
ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN ÀTÀWỌN ÀÌSÀN MÌÍRÀN: Àrùn gágá tó bẹ́rẹ́ sí í jà ní ọdún 1918 pa mílíọ̀nù mọ́kànlélógún èèyàn. Àrùn éèdì ti di “àjàkálẹ̀ àrùn tó burú jù lọ nínú ìtàn ọmọ èèyàn.” Àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn ń fa ìbànújẹ́ jákèjádò ayé.
Gbogbo àkọlé ìròyìn wọ̀nyẹn ni kó o wò pa pọ̀. Ṣé ohun tá ò gbọ́ rí ni wọ́n, àbí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ karí ayé tó sì ní ìtumọ̀ pàtàkì?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ǹjẹ́ Ọlọ́run Tiẹ̀ Bìkítà Nípa Wa?
Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tàbí àwọn àdánù tó ń bà wọ́n nínú jẹ́, ọ̀pọ̀ ló ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run kì í fi í ṣe nǹkan kan láti má ṣe jẹ́ kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀.
Ọlọ́run kúkú bìkítà. Ó ń pèsè ojúlówó ìtọ́sọ́nà àti ìtura lákòókò yìí. (Mátíù 11:28-30; 2 Tímótì 3:16, 17) Ó ti ṣe ètò tí yóò mú kí ìwà ipá, àìsàn àti ikú di ohun ìgbàgbé títí ayé. Àwọn ètò tó ti ṣe fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ló jẹ ẹ́ lógún, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ahọ́n ká a lára.—Ìṣe 10:34, 35.
Báwo làwa náà ṣe bìkítà tó nípa Ọlọ́run? Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé jẹ́? Kí lorúkọ rẹ̀? Kí ni ète rẹ̀? Ó dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú Bíbélì. Ibẹ̀ ló ti sọ fún wa nípa àwọn nǹkan tó ń ṣe láti fòpin sí ìwà ipá títí kan àìsàn àti ikú. Ká tó lè jàǹfààní, kí la ní láti ṣe? A ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe. Àbí báwo la ṣe lè retí pé a ó jàǹfààní nínú àwọn ìpèsè tó ti ṣe bá ò [bá] gbà wọ́n gbọ́? (Jòhánù 3:16; Hébérù 11:6) Ó tún pọn dandan pé ká máa ṣe àwọn ohun tó ní ká ṣe. (1 Jòhánù 5:3) Ṣé o bìkítà nípa Ọlọ́run débi tí wàá fi máa ṣe nǹkan wọ̀nyí?
Ká tó lè lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí, a gbọ́dọ̀ lóye ọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì gan-an. Bíbélì ṣàlàyé ọ̀ràn ọ̀hún. Ní ojú ìwé 15 ìwé yìí, wàá rí ohun tí ọ̀ràn náà jẹ́.