ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kp ojú ìwé 9-11
  • Ibo Ni Ìgbésí Ayé Rẹ Forí lé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Ni Ìgbésí Ayé Rẹ Forí lé?
  • Ẹ Máa Ṣọ́nà!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
    Jí!—2011
  • Àtúnyẹ̀wò fún Ìdílé
    Jí!—2010
  • Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
    Jí!—2009
  • Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
    Jí!—2009
Ẹ Máa Ṣọ́nà!
kp ojú ìwé 9-11

Ibo Ni Ìgbésí Ayé Rẹ Forí lé?

• Kòó-kòó-jàn-ánjàn-án ojoojúmọ́ ti gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn débi pé wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú lórí ibi tí ìgbésí ayé wọn dorí kọ.

• Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Ó tún kìlọ̀ pé ìyípadà ńláǹlà máa dé bá àwọn àjọ ẹ̀dá èèyàn kárí ayé. Tá a bá fẹ́ jàǹfààní látinú ohun tí Bíbélì sọ tá a sì fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àjálù, a gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe ní kíákíá.

• Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n mọ ohun tí Bíbélì sọ tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti mú un lò àmọ́ tí wọ́n ń jẹ́ kí àníyàn ìgbésí ayé darí wọn síbòmíràn.

• Ṣé inú rẹ dùn sí ibi tí ìgbésí ayé rẹ forí lé? Tó o bá fẹ́ dáwọ́ lé àwọn nǹkan kan, ǹjẹ́ o máa ń ro bí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣe máa nípa lórí àwọn ohun pàtàkì tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Kí Lo Kà sí Pàtàkì Jù?

Ipò wo ni wàá to àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí sí? Tò wọ́n bí wọ́n ṣe ṣe pàtàkì sí.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà séyìí tí kò dára, àmọ́ èwo ni wàá fi sípò àkọ́kọ́? ipò kejì? àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

․․․ Eré ìnàjú tàbí eré ìtura

․․․ Iṣẹ́ mi

․․․ Ìlera mi

․․․ Ayọ̀ mi

․․․ Ọkọ tàbí aya mi

․․․ Àwọn òbí mi

․․․ Àwọn ọmọ mi

․․․ Ilé tó dùn ún wò, aṣọ tó gbayì

․․․ Jíjẹ́ ọ̀kanṣoṣo ọ̀gá nínú ohunkóhun tí mo bá ń ṣe

․․․ Ìjọsìn Ọlọ́run

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

Ǹjẹ́ Àwọn Ìpinnu Tó Ò Ń Ṣe Á Gbé Ọ Débi Tó Ò Ń Fẹ́?

GBÉ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ WỌ̀NYÍ YẸ̀ WÒ

ERÉ ÌNÀJÚ TÀBÍ ERÉ ÌTURA: Ṣé eré ìtura tí mò ń ṣe ń mára tù mí? Ǹjẹ́ ó láwọn ohun amóríyá kan nínú tó lè ṣèpalára fún ìlera mi tàbí kó tiẹ̀ sọ mí di aláàbọ̀ ara títí ayé? Ṣé kì í ṣe irú “fàájì” tó ń mára yá gágá fúngbà díẹ̀ àmọ́ tó lè kó mi sí ìbànújẹ́ ayérayé ni? Ká tiẹ̀ ní irú eré ìnàjú tí mo yàn kò burú, ṣé mo máa ń pẹ́ gan-an nídìí ẹ̀ débi pé n kì í ráyè ṣe àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ?

IṢẸ́ MI: Ṣé ohun tó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti gbọ́ bùkátà mi ni, àbí mo ti kúkú dẹrú iṣẹ́ ọ̀hún pátápátá? Ṣé ó máa ń gba àkókò àti okunra débi tó fi lè kó bá ìlera mi? Èwo ni mo máa ń nífẹ̀ẹ́ sí jù, kí n lo àfikún àkókò lẹ́nu iṣẹ́ tàbí kí n lọ sílé láti lè fara rora pẹ̀lú ọkọ tàbí aya àti àwọn ọmọ mi? Bí ẹni tó gbà mí síṣẹ́ bá ní kí n ṣe iṣẹ́ tí kò bá ẹ̀rí ọkàn mi mu tàbí tí kì í jẹ́ kí n ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ́pọ̀ ìgbà, ṣé màá gbà láti ṣe é torí kí iṣẹ́ má bàa bọ́ lọ́wọ́ mi?

ÌLERA MI: Ṣé mo máa ń ka ọ̀ràn ìlera mi sí nígbà gbogbo àbí n kì í bìkítà nípa rẹ̀? Ṣé òun nìkan ni mo máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣáá? Ṣé ọ̀nà tí mò ń gbà bójú tó ìlera mi fi hàn pé mò ń gba ti ìdílé mi rò?

AYỌ̀ MI: Ṣé ohun tí mo máa ń kọ́kọ́ gbájú mọ́ nìyẹn? Ṣé mo máa ń fi ṣáájú ayọ̀ ọkọ tàbí aya mi tàbí ti àwọn ará ilé mi? Ṣé ọ̀nà tí mò ń gbà wá ayọ̀ yìí bá jíjẹ́ tí mo jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ mu?

AYA TÀBÍ ỌKỌ MI: Ṣé ìgbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn nìkan ni mo máa ń ka aya tàbí ọkọ mi sí ẹnì kejì mi? Ṣé mo máa ń fi ọ̀wọ̀ tirẹ̀ wọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí iyì tọ́ sí? Ṣé ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run ń nípa lórí irú ojú tí mo fi ń wo aya tàbí ọkọ mi?

ÀWỌN ÒBÍ MI: Bó bá jẹ́ pé ọmọdé ṣì ni mí, ṣé mo máa ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, ṣé mò ń dá wọn lóhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ṣé mò ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi nínú ilé, ṣé mo máa ń délé ní àkókò tí wọ́n bá ní kí n dé, ṣé mò ń yẹra fáwọn ẹgbẹ́ tàbí àwọn ìgbòkègbodò tí wọ́n ti kìlọ̀ ẹ̀ fún mi? Bí mo bá ti dàgbà, ṣé mo máa ń tẹ́tí sáwọn òbí mi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tí mò ń ṣèrànwọ́ fún wọn nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀? Ṣé ohun tó bá rọ̀ mí lọ́rùn ló ń pinnu bí mo ṣe ń bá wọn lò àbí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń darí mi?

ÀWON ỌMỌ MI: Ṣé mo gbà pé ojúṣe mi ni láti kọ́ àwọn ọmọ mi ní ìwà rere àbí iléèwé ni mo fẹ́ kí wọ́n ti bá mi kọ́ wọn? Ṣé mo máa ń ráyè fáwọn ọmọ mi, àbí ohun ìṣeré, tẹlifíṣọ̀n, tàbí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ni mo máa ń ní kí wọ́n lọ jókòó tì? Ṣé mo máa ń fún àwọn ọmọ mi ní ìbáwí nígbàkigbà tí wọn ò bá tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run, àbí kìkì ìgbà tí wọ́n bá ṣe ohun tó bí mi nínú ni mò ń bá wọn wí?

ILÉ TÓ DÙN ÚN WÒ, AṢỌ TÓ GBAYÌ: Kí ló ń pinnu irú àfíyèsí tí mò ń fún ìrísí mi àtàwọn nǹkan tí mo ní? Ṣé bí mo ṣe fẹ́ káwọn aládùúgbò máa wò mí ni? àbí ohun tó máa ṣe ìdílé mi láǹfààní? àbí jíjẹ́ ti mo jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run?

JÍJẸ́ Ọ̀KANṢOṢO Ọ̀GÁ NÍNÚ OHUNKÓHUN TÍ MO BÁ Ń ṢE: Ǹjẹ́ mo gbà pé ó ṣe pàtàkì láti máa ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó dára? Ṣé mo máa ń tiraka láti ṣáà rí i pé mo ta àwọn ẹlòmíràn yọ? Ṣé inú mi kì í bà jẹ́ bí ẹlòmíràn bá ṣe nǹkan lọ́nà tó dára ju tèmi lọ?

ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN: Ṣé níní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ṣe pàtàkì sí mi ju ìtẹ́wọ́gbà aya tàbí ọkọ mi, àwọn ọmọ mi, àwọn òbí mi tàbí agbanisíṣẹ́ mi? Kí n lè máa gbé ìgbé ayé onígbẹdẹmukẹ, ṣé mi ò kọ̀ láti fi iṣẹ́ ìsìn mi sí Ọlọ́run sí ipò kejì?

GBÉ ÌMỌ̀RÀN BÍBÉLÌ YẸ̀ WÒ DÁADÁA

Ipò wo lo fi Ọlọ́run sí nínú ìgbésí ayé rẹ?

Oníwàásù 12:13: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”

BI ARA RẸ LÉÈRÈ: Ǹjẹ́ bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni mò ń ṣe? Ṣé ìgbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run ló ń pinnu ọ̀nà tí mò ń gbà bójú tó ojúṣe mi nínú ilé, níbi iṣẹ́ àti níléèwé? Àbí ṣé àwọn nǹkan mìíràn tàbí àwọn pákáǹleke ìgbésí ayé ló ń pinnu bóyá mò ń ya àkókò sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run?

Báwo ni àárín ìwọ àti Ọlọ́run ṣe rí?

Òwe 3:5, 6: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”

Mátíù 4:10: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.”

BI ARA RẸ LÉÈRÈ: Ṣé èrò mi nípa Ọlọ́run nìyẹn? Ṣé àwọn ìgbòkègbodò mi ojoojúmọ́, títí kan ọ̀nà tí mò ń gbà bójú tó ìṣòro, fi hàn pé mo ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀?

Báwo ni kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì sí ọ tó?

Jòhánù 17:3: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”

BI ARA RẸ LÉÈRÈ: Ǹjẹ́ ipò tí mo fi kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ríronú jinlẹ̀ lórí rẹ̀ sí fi hàn pé lóòótọ́ ni mo gba èyí gbọ́?

Báwo ni lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ Kristẹni ṣe ṣe pàtàkì sí ọ tó?

Hébérù 10:24, 25: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, . . . pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”

Sáàmù 122:1: “Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé: ‘Jẹ́ kí a lọ sí ilé Jèhófà.’”

BI ARA RẸ LÉÈRÈ: Ǹjẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé mi fi hàn pé mo mọrírì ìtọ́sọ́nà tó wá látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí? Lóṣù tó kọjá, ǹjẹ́ mo pa ìpàdé Kristẹni èyíkéyìí jẹ nítorí pé mo jẹ́ kí ohun mìíràn gba ipò rẹ̀?

Ṣé ò ń fi ìtara kópa nínú bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe?

Mátíù 24:14: “A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí . . . , nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”

Mátíù 28:19, 20: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”

Sáàmù 96:2: “Ẹ kọrin sí Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀. Ẹ máa sọ ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.”

BI ARA RẸ LÉÈRÈ: Ǹjẹ́ lóòótọ́ ni mo fi iṣẹ́ yìí sí ipò pàtàkì tó yẹ kó wà ní ìgbésí ayé mi? Ṣé ipa tí mò ń kó nínú rẹ̀ fi hàn pé mo lóye bí àkókò tí à ń gbé báyìí ti ṣe pàtàkì tó?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́