‘Wọn Kò Fiyè Sí i’
ṢÍṢÀÌKỌBIARA sí ìkìlọ̀ lè yọrí sí jàǹbá.
Àwọn èèyàn ìlú Darwin, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ń múra sílẹ̀ fún pọ̀pọ̀ ṣìnṣìn ọ̀dún ní 1974 nígbà tí ìkìlọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dún pé ìjì ńlá kan fẹ́ jà. Àmọ́ láti bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, ìjì kankan ò ba ìlú Darwin jẹ́. Kí ló wá dé tó fẹ́ jà nísinsìnyí? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó ń gbébẹ̀ kò ka ewu náà sí nǹkan bàbàrà àfìgbà tí ìjì líle bẹ̀rẹ̀ sí ṣí òrùlé ilé tó sì ń ya àwọn ògiri ilé táwọn èèyàn rọ́ jọ pọ̀ sí lulẹ̀. Nígbà tó fi máa di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ìlú náà ti dahoro.
Ní orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà, ní November ọdún 1985, òkè ayọnáyèéfín kan bú. Èyí mú kí àwọn yìnyín dídì yọ́ kó sì fa ẹrẹ̀ tó ń ṣàn bí àgbárá tó bo ohun tó lé ní ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn olùgbé ìlú Armero mọ́lẹ̀ ráúráú. Ṣé kò sí ìkìlọ̀ tẹ́lẹ̀ ni? Ọ̀pọ̀ oṣù kúkú ni òkè yẹn fi mì tìtì. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ìlú Armero ni kò kà á sí nítorí pé gbígbé lẹ́gbẹ̀ irú òkè ayonáyèéfín bẹ́ẹ̀ ti mọ́ wọn lára. Àwọn aláṣẹ gbọ́ ìkìlọ̀ pé jàǹbá ńlá máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, àmọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe nǹkan kan láti ki àwọn aráàlú nílọ̀. Wọ́n tiẹ̀ ṣe ìkéde lórí rédíò láti fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ̀ pé kò séwu. Wọ́n lo ẹ̀rọ gbohùngbohùn ṣọ́ọ̀ṣì láti rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máà jáyà. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, òkè náà bú gbàù lẹ́ẹ̀mejì. Bó o bá wà níbẹ̀, ṣé wàá fi àwọn nǹkan ìní rẹ sílẹ̀ tí wàá sì sá lọ? Ìwọnba èèyàn díẹ̀ péré ló gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ kó tó wá di pé ẹ̀pa ò bóró mọ́.
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ máa ń sọ àsọ́tẹ́lẹ̀ pípéye nípa ibi tí ìsẹ̀lẹ̀ ti máa ṣẹlẹ̀. Nǹkan tí wọn kì í sábà lè ṣe ni pé kí wọ́n sọ ìgbà tó máa ṣẹlẹ̀. Lọ́dún 1999, nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] èèyàn làwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé pa. Púpọ̀ nínú àwọn tó kú ló rò pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sáwọn láéláé.
Kí Lo Máa Ń Ṣe sí Àwọn Ìkìlọ̀ Tó Wá Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Fúnra Rẹ̀?
Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà ní ìkẹyìn ọjọ́. Nígbà tó ń sọ èyí, ó rọ̀ wá pé ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́ Nóà.” “Ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi,” ọwọ́ àwọn èèyàn dí fún oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n ń ṣe lójoojúmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àní-àní pé bí ìwà ipá ṣe gbòde kan nígbà náà ń dà wọ́n láàmú. Àmọ́ ní ti ìkìlọ tí Ọlọ́run fún wọn nípasẹ̀ Nóà, ìránṣẹ́ rẹ̀, ‘wọn kò fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ.’ (Mátíù 24:37-39) Ká ní pé o wà níbẹ̀ ni, ṣé ìwọ ì bá kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ ò ń kọbi ara sí i nísinsìnyí?
Ká ní ò ń gbé ní ìlú Sódómù nítòsí Òkun Òkú láyé ọkùnrin tó ń jẹ́ Lọ́ọ̀tì, àbúrò Ábúráhámù ńkọ́? Bíi Párádísè ni àgbègbè ibẹ̀ rí. Ìlú náà láásìkí. Ayé jẹ̀lẹ́ńkẹ́ làwọn èèyàn ibẹ̀ ń gbé. Láyé Lọ́ọ̀tì, “wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé.” Àárín àwùjọ tí wọ́n tún ń gbé kún fún ìṣekúṣe tó burú jáì. Ká ní pé o wà níbẹ̀, ṣé ìwọ ì bá fi ìkìlọ náà sọ́kàn nígbà tí Lọ́ọ̀tì ń ké tantan pé ìwà burúkú tí wọ́n ń hù kò dára? Ṣé ìwọ ì bá fetí sílẹ̀ nígbà tó ń sọ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ìlú Sódómù run? Àbí yẹ̀yẹ́ lo ò bá kà á sí, báwọn ọmọkùnrin tó fẹ́ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì ṣe ṣe? Àbí ńṣe lò bá kọ́kọ́ sá tí wàá sì tún wá ṣẹ́rí padà bíi ti ìyàwó Lọ́ọ̀tì? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò ka ìkìlọ̀ náà sí bàbàrà, lọ́jọ́ tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Sódómù, “òjò iná àti imí-ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run, ó sì pa gbogbo wọn run.”—Lúùkù 17:28, 29.
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn lónìí ni kò fiyè sí i. Àmọ́ Ọlọ́run pa àwọn àpẹẹrẹ yìí mọ́ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, kó sì tún lè fún wa ní ìṣírí láti MÁA ṢỌ́NÀ!
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ṣé Lóòótọ́ Ni Ìkún Omi Tó Kárí Ayé Ṣẹlẹ̀?
Ọ̀pọ̀ àwọn aṣelámèyítọ́ sọ pé kò ṣẹlẹ̀. Àmọ́ Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.
Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó sì wà láàyè nígbà tó ṣẹlẹ̀, ó ń wò ó látọ̀run.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣé Lóòótọ́ Ni Ọlọ́run Pa Sódómù àti Gòmórà Run?
Àwọn awalẹ̀pìtàn jẹ́rìí sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Àwọn ìwé ìtàn mẹ́nu kàn án.
Jésù Kristi fi hàn pé ó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, ìwé mẹ́rìnlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì ló sì sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀.