ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 15
  • Ìyàwó Lọ́ọ̀tì Bojú Wẹ̀yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìyàwó Lọ́ọ̀tì Bojú Wẹ̀yìn
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ọlọ́run Bá Ábúráhámù Dá Májẹ̀mú
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Máa Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Takété Nígbà Tí Ewu Bá Fẹjúmọ́ Ọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 15
Ìyàwó Lọ́ọ̀tì bojú wẹ̀yìn wo ìlú Sódómù, ó sì di ọwọ̀n iyọ̀

ÌTÀN 15

Ìyàwó Lọ́ọ̀tì Bojú Wẹ̀yìn

LỌ́Ọ̀TÌ àti ìdílé rẹ̀ ń gbé pa pọ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù ní ilẹ̀ Kénáánì. Lọ́jọ́ kan Ábúráhámù sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: ‘Ilẹ̀ yìí kò gba gbogbo ẹran wa mọ́. Jọ̀wọ́, jẹ́ ká pínyà. Bí ìwọ bá gba apá ọ̀tún lọ, èmi á forí lé apá òsì.’

Lọ́ọ̀tì bojú wo gbogbo ilẹ̀ náà. Ó rí apá ibi tó dára púpọ̀, tó ní omi àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ koríko tútù fún àwọn ẹran ẹ̀. Àgbègbè Jọ́dánì ni ibẹ̀. Nítorí náà, Lọ́ọ̀tì kó ìdílé ẹ̀ àtàwọn ẹran ẹ̀ lọ síbẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n sọ ìlú Sódómù di ilé wọn.

Àwọn èèyàn ìlú Sódómù burú gan-an. Èyí ò dùn mọ́ Lọ́ọ̀tì nínú rárá nítorí pé ẹni rere ni. Inú Ọlọ́run pẹ̀lú ò dùn sí ohun táwọn ará ìlú yẹn ń ṣe. Nígbà tó yá, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì méjì láti lọ kìlọ̀ fún Lọ́ọ̀tì pé òun á pa Sódómù àti ìlú Gòmórà tó wà nítòsí ẹ̀ run nítorí ìwà búburú wọn.

Àwọn áńgẹ́lì náà sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: ‘Ṣe kíá! Mú ìyàwó rẹ àtàwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì jáde kúrò níhìn-ín!’ Nígbà tí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ ò tètè fẹ́ jáde, àwọn áńgẹ́lì náà di ọwọ́ wọn mú wọ́n sì mú wọn jáde kúrò ní ìlú náà. Ni ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì náà bá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín! Ẹ má ṣe bojú wẹ̀yìn. Ẹ sá lọ sórí àwọn òkè, kẹ́ ẹ má bàa kú.’

Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ń wo ọ̀ọ́kán bí wọ́n ṣe ń sá kúrò ní Sódómù

Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe ìgbọràn, wọ́n sá jáde kúrò ní Sódómù. Wọn ò dúró fún ìṣẹ́jú kan, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò bojú wẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n ìyàwó Lọ́ọ̀tì ṣàìgbọràn. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn díẹ̀ kúrò ní Sódómù, ìyàwó Lọ́ọ̀tì dúró, ó sì bojú wẹ̀yìn. Ló bá di ọwọ̀n iyọ̀. Ṣó o rí i nínú àwòrán yìí?

A lè rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nínú èyí. Ó fi hàn wá pé Ọlọ́run máa ń gba àwọn tó bá gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu là, ṣùgbọ́n àwọn tó bá ṣàìgbọràn sí i yóò pàdánù ẹ̀mí wọn.

Jẹ́nẹ́sísì 13:5-13; 18:20-33; 19:1-29; Lúùkù 17:28-32; 2 Pétérù 2:6-8.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́