Takété Nígbà Tí Ewu Bá Fẹjúmọ́ Ọ
ÌWỌ̀NBA àwọn ènìyàn díẹ̀ ni wọ́n tètè ń fúra nípa ewu ju àwọn awakọ̀ ojú-omi lọ. Wọ́n gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí ìyípadà nínú ojú-ọjọ́, ìrusókè-òun-ìlọsílẹ̀ òkun, àti bí ọkọ̀ wọn ti súnmọ́ bèbè-etíkun tó. Nígbà tí ìrusókè-òun-ìlọsílẹ̀ òkun àti ẹ̀fúùfù bá parapọ̀ láti ti ọkọ̀ náà síhà èbúté, àwọn awakọ̀ ojú-omi ń dojúkọ iṣẹ́ àṣekára àti ewu.
Lábẹ́ àwọn ipò wọ̀nyí—tí a mọ̀ sí gbígbá ọkọ̀ kúrò lébùúté—awakọ̀ ojú-omi kan ń fi àyè ojú-òkun tí ó pọ̀ tó sílẹ̀ láàárín ọkọ̀ rẹ̀ àti bèbè-etíkun, ní pàtàkì bí ó bá jẹ́ pé ìgbòkun nìkan ni ó ń ti ọkọ̀ náà ṣíwájú. Ìwé atọ́nà kan lórí títukọ̀ ojú-omi ṣàlàyé pé ‘láti di ẹni tí a ká mọ́ àárín ẹ̀fúùfù líle nígbà tí gbígbá ọkọ̀ kúrò lébùúté bá ti wáyé ni ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀ràn ìṣòro tí ó burú jùlọ’ nínú èyí tí awakọ̀ ojú-omi kan lè bá araarẹ̀. Kí ni ojútùú tí a dábàá? ‘Máṣe yọ̀ǹda fún ọkọ-òkun rẹ láti bá araarẹ̀ nínú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ láé.’ Ọ̀nà tí ó rọrùn jùlọ láti yẹra fún rírì sínú yanrìn tí ó kọbèbè tàbí èbúté olókùúta ni láti takété gan-an sí ewu.
Àwọn Kristian gbọ́dọ̀ tètè máa fura nípa àwọn ewu tí ó lè ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn. (1 Timoteu 1:19) Ní òde-ìwòyí, àwọn ipò kò báradé rárá láti pa ọ̀nà-ìgbésẹ̀ tí ó dúró déédéé mọ́. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀fúùfù tàbí ìrusókè-òun-ìlọsílẹ̀ òkun ṣe lè ti ọkọ̀ kan kúrò ní ipa-ọ̀nà, bẹ́ẹ̀ ni ìgbésí-ayé wa tí a ti yà sí mímọ́ ṣe lè pàdánù ìdarísọ́nà nítorí ìjàkadì ìgbà gbogbo ti ẹran-ara wa aláìpé àti ìrọ́lù aláìdẹwọ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí ayé—tí ipá rẹ̀ ṣeéfiwéra pẹ̀lú ẹ̀fúùfù líle níti bí ó ti múná tó.
Ọkùnrin kan Tí Ó Gbé Lọ́nà Líléwu
Ẹ wo bí ó ti rọrùn tó láti dágbálé ewu láìròtẹ́lẹ̀ nínú àwọn omi líléwu nípa tẹ̀mí!
Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ kan tí ó wáyé níbi ìwọ́jọpọ̀ omi ti ilẹ̀ yíká kan, Òkun Òkú. A ń tọ́ka sí àpẹẹrẹ Loti. Ìpinnu rẹ̀ láti gbé ní Sodomu mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣòro àti ìkárísọ púpọ̀ wá bá a. Lẹ́yìn aáwọ̀ kan láàárín darandaran àwọn méjèèjì, Abrahamu àti Loti gbà láti gbé ní àwọn agbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. A sọ fún wa pé Loti yan Àgbègbè Jordani ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí àárín àwọn ìlú-ńlá tí ó wà ní Àgbègbè náà. Lẹ́yìn náà, ó pinnu láti gbé ní Sodomu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìgbésí-ayé àwọn ará Sodomu kódààmú bá a.—Genesisi 13:5-13; 2 Peteru 2:8.
Èéṣe tí Loti fi ń gbé nìṣó nínú ìlú-ńlá oníwà pálapàla lọ́nà lílókìkí burúkú náà tí ń ṣe láìfí sí Jehofa lọ́nà jíjinlẹ̀ tí ó tilẹ̀ ṣokùnfà igbe-ẹkún láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé nítòsí rẹ̀? Sodomu ní aásìkí, kò sì sí iyèméjì pé aya Loti gbádùn àwọn àǹfààní ohun ti ara ti ìgbésí-ayé nínú ìlú-ńlá náà. (Esekieli 16:49, 50) Bóyá Loti pàápàá ni ètò ọrọ̀-ajé Sodomu tí ó jíire fà mọ́ra. Ìdí yòówù kí ó ní fún gbígbé níbẹ̀, ó ti yẹ kí ó kúrò níbẹ̀ ṣáájú ìgbà tí ó kúrò. Kìkì nígbà tí angẹli Jehofa fi dandangbọ̀n kán wọn lójú ni ìdílé Loti fi agbègbè eléwu náà sílẹ̀ ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín.
Ìròyìn Genesisi sọ pé: “Nígbà tí ọ̀yẹ̀ sì ń là, nígbà náà ni àwọn angẹli náà lé Loti ní iré wí pé, Dìde, mú aya rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín; kí ìwọ kí ó má baà run nínú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìlú yìí.” Àní lẹ́yìn ìkìlọ̀ kánjúkánjú náà pàápàá, Loti “ń lọ́ra.” Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín àwọn angẹli náà “mú un ní ọwọ́, àti ọwọ́ aya rẹ̀, àti ọwọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì; . . . wọ́n sì mú un jáde, wọ́n sì fi í sẹ́yìn odi ìlú náà.”—Genesisi 19:15, 16.
Lóde ẹ̀yìn-odi ìlú-ńlá náà, àwọn angẹli náà fún ìdílé Loti ní àwọn ìtọ́ni díẹ̀ tí ó kẹ́yìn: “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ; máṣe wo ẹ̀yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó máṣe dúró ní gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀; sá àsálà lọ́ sí orí òkè, kí ìwọ kí ó má baà ṣègbé.” (Genesisi 19:17) Síbẹ̀ náà, Loti bẹ̀bẹ̀ fún ìyọ̀ọ̀da láti lọ sí ìlú-ńlá Soari tí ó wà nítòsí dípò kí ó fi ẹkùn-ilẹ̀ náà sílẹ̀ pátápátá. (Genesisi 19:18-22) Ní kedere, Loti lọ́tìkọ̀ láti mú araarẹ̀ jìnnà sí ewu bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó.
Lójú ọ̀nà sí Soari, aya Loti bojúwẹ̀yìn wo Sodomu, ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé ó ń yánhànhàn fún àwọn nǹkan tí ó fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Nítorí ṣíṣàì ka àwọn ìtọ́ni angẹli náà sí, ó pàdánù ìwàláàyè rẹ̀. Loti—ọkùnrin olódodo—la ìparun ìlú-ńlá náà já pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì. Ṣùgbọ́n ẹ wo iye tí ó san fún yíyàn láti gbé nítòsí ewu!—Genesisi 19:18-26; 2 Peteru 2:7.
Yíyẹra fún Ewu
Ìrírí kíkorò tí Loti ní fi ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ hàn bí a bá súnmọ́ sàkáání eléwu tàbí jáfara níbẹ̀. Bíi ti àwọn ọ̀jáfáfá awakọ̀ ojú-omi, ọgbọ́n yóò sọ fun wa pé kí a máṣe fàyègba ara wa láti kó sínú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ láé. Kí ni díẹ̀ lára àwọn agbègbè eléwu tí a níláti yẹra fún? Àwọn Kristian kan ti ṣáko lọ nípa kíkówọnú àwọn ìgbòkègbodò iṣẹ́-ajé jù, nípa níní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ nínú ayé, tàbí nípa níní òòfà ọkàn sí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì nígbà tí wọn kò tíì ṣetán láti gbéyàwó.
Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ipa-ọ̀nà ọlọgbọ́n yóò jẹ́ láti takété sí ewu. Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a wà lójúfò sí àwọn ewu tẹ̀mí tí àǹfààní iṣẹ́-ajé títayọlọ́lá kan tí a fẹnu lásán pè bẹ́ẹ̀ lè mú wá bí? Àwọn arákùnrin kan ti ri araawọn bọnú àwọn ìdáwọ́lé iṣẹ́-òwò sí ìpalára ìdílé, ìlera, àti àwọn ẹrù-iṣẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun wọn. Nígbà mìíràn ìtànjẹ náà máa ń jẹ́ ọ̀nà ìgbésí-ayé dídẹrùn tí owó lè mú wá. Ní àwọn ìgbà mìíràn ó máa ń jẹ́ ìpèníjà ti fífi ẹ̀rí agbára ìfòyemọ̀ wọn nípa iṣẹ́-ajé hàn. Àwọn kan lè ronú pé ète ìsúnniṣe wọn ni láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ará mìíràn tàbí láti baà lè fi ìwà ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ púpọ̀ síi nítìtorí iṣẹ́ kárí-ayé náà. Bóyá wọ́n ronú pé nígbà tí iṣẹ́-ajé náà bá ń lọ dáradára, wọn yóò ni àkókò tí ó túbọ̀ pọ̀ síi láti yàsọ́tọ̀ fún ire Ìjọba náà.
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀fìn náà? Ipò-àyíká ètò-ọrọ̀-ajé tí kò dánilójú àti “èèṣì” lè dojú ìdáwọ́lé iṣẹ́-ajé tí a wéwèé lọ́nà dídára jùlọ dé. (Oniwasu 9:11) Jíjìjàkadì pẹ̀lú gbèsè wíwúwo lè mú làásìgbò wá ó sì lè ṣíji bo àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. Àti pé nígbà tí iṣẹ́-ajé kan bá ń fẹjú síi pàápàá, ó ṣeéṣe kí ó máa gba àkókò àti okun ti èrò-orí púpọ̀, ó sì lè béèrè fún ìbákẹ́gbẹ́ ti ayé tí ó pọ̀ gan-an.
Kristian alàgbà kan ní Spain wà nínú ìnira mímúná níti ọ̀ràn ìnáwó nígbà tí ilé-iṣẹ́ abánigbófò kan nawọ́ iṣẹ́ kan tí ń dẹniwò sí i. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfojúsọ́nà wà fún níní owó rẹpẹtẹ gẹ́gẹ́ bí aṣojú ilé-iṣẹ́ ìbánigbófò onígbà kúkúrú, ó kọ ìfilọni náà ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Kìí ṣe ìpinnu kan tí ó rọrùn, ṣùgbọ́n inú mi dùn pé mo sọ pé bẹ́ẹ̀kọ́. Ohun kan ni pé, mo lọ́tìkọ̀ láti wá owó—lọ́nà tí kò ṣe tààràtà pàápàá—nípasẹ̀ àjọṣepọ̀ mi pẹ̀lú àwọn ará. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ràn èrò náà pé kí n jẹ́ ọ̀gá araami, èmi ìbá ti níláti rìnrìn-àjò lọ́pọ̀lọpọ̀ kí n sì lo wákàtí gígùn lẹ́nu iṣẹ́ náà. Lọ́nà tí kò ṣeéyẹ̀sílẹ̀ ìbá ti túmọ̀sí ṣíṣàìnáání ìdílé mi àti ìjọ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo gbàgbọ́dájú pé bí mo bá ti tẹ́wọ́gba ìfilọni yẹn ni, kì bá tí ṣeéṣe fún mi láti darí ìgbésí-ayé mi mọ́.”
Kò sí Kristian kan tí yóò fẹ́ kí òun má lè darí ìgbésí-ayé òun. Jesu fi ìyọrísí ọlọ́ràn ìbìnújẹ́ ti irú ipa-ọ̀nà ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ hàn nípa sísọ òwe-àkàwé ọkùnrin kan tí ó kó ọrọ̀ púpọ̀ púpọ̀ jọ kí ó baà lè fẹ̀yìntì kí ó sì máa ṣe yọ̀tọ̀mì. Ṣùgbọ́n ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an tí ó pinnu pé òun ti kó owó tí ó pọ̀ tó jọ, ó kú. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún araarẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọrun,” ni Jesu kìlọ̀.—Luku 12:16-21; fiwé Jakọbu 4:13-17.
A tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra lòdìsí ìbákẹ́gbẹ́ gbígbòòrò pẹ̀lú àwọn ènìyàn ayé. Bóyá aládùúgbò kan, ọ̀rẹ́ kan ní ilé-ẹ̀kọ́, alábàáṣiṣẹ́ kan, tàbí alábàáṣòwòpọ̀ kan ni. A lè ronú pé, ‘Ó ní ọ̀wọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí, ó ní ìwàrere, a sì jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.’ Síbẹ̀, ìrírí àwọn ẹlòmíràn fi ẹ̀rí hàn pé nígbà tí ó bá yá àwa tilẹ̀ lè rí araawa tí a ń fẹ́ irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ayé bẹ́ẹ̀ ju ti arákùnrin tàbí arábìnrin tẹ̀mí kan. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ewu irú ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀?
A lè bẹ̀rẹ̀ sí fojúkéré ìjẹ́kánjúkánjú àwọn àkókò nínú èyí tí a ń gbé tàbí kí a ní ọkàn-ìfẹ́ tí ń pọ̀ síi nínú àwọn ohun ti ara dípò àwọn nǹkan tẹ̀mí. Bóyá, nítorí ìbẹ̀rù láti máṣe mú àwọn ọ̀rẹ́ wa nínú ayé bínú, àwa yóò tilẹ̀ fẹ́ kí ayé tẹ́wọ́gbà wá. (Fiwé 1 Peteru 4:3-7.) Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, olórin náà Dafidi, fẹ́ kí òun kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa. Ó kọ̀wé pé: “Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi: ní àwùjọ ìjọ ni èmi ó máa yìn ọ́.” (Orin Dafidi 22:22) A óò dáàbòbò wá bí a bá ṣàfarawé àpẹẹrẹ Dafidi, ní wíwá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ó lè gbé wa ró nípa tẹ̀mí.
Ipa-ọ̀nà ìgbésẹ̀ eléwu-ńlá mìíràn ni ti kíkówọnú òòfà ọkàn pẹ̀lú ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì nígbà tí ẹnìkan kò tíì ṣetán láti ṣe ìgbéyàwó. Ewu náà lè dìde nígbà tí ọkàn ẹni bá fàmọ ẹnìkan tí ó fanimọ́ra, tí ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ rẹ̀ máa ń runisókè, àní tí ó tilẹ̀ ní ojú-ìwòye àti òye-ìmọ̀lára ìdẹ́rìn-ín-pani kan-náà bí ẹni. Ẹnìkan lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin, ní ríronú pé, ‘Mo mọ ibi tí èmi yóò rìn jìnnà dé. A wulẹ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ ni.’ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní gbàrà tí a bá ti ru àwọn ìmọ̀lára sókè kìí rọrùn láti ṣàkóso rẹ̀.
Mary, arábìnrin ọ̀dọ́ kan tí ó ti lọ́kọ, gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Michael.a Arákùnrin kan tí ó dára ni ṣùgbọ́n ó ṣòro fún un láti ní ọ̀rẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni wọ́n máa ń ṣe ní ọ̀nà kan-náà, wọ́n sì ríi pé àwọn lè jùmọ̀ ṣàwàdà. Mary tan ara rẹ̀ jẹ pẹ̀lú ìrònú náà pé arákùnrin àpọ́n kan fẹ́ láti finú hàn-án. Láìpẹ́ púpọ̀, ohun tí ó dàbí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí kò léwu di òòfà ọkàn jíjinlẹ̀. Wọ́n ń lo àkókò tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi papọ̀ wọ́n sì hùwà pálapàla ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Mary mí ìmí-ẹ̀dùn pé: “Ó yẹ kí n ti mọ ewu náà dájú ní ìbẹ̀rẹ̀. Gbàrà tí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ náà ti dàgbàsókè, ó dàbí ẹrẹ̀ a sì túbọ̀ ń rì wọnú rẹ̀ jinlẹ̀ síi.”
A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìkìlọ̀ Bibeli náà láé: “Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó sì burú jáì! ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremiah 17:9) Ọkàn wa tí ó kún fún ẹ̀tàn, bí ìrusókè-òun-ìlọsílẹ̀ òkun ti ó ń ti ọkọ̀ ìgbòkun síhà àpáta, lè tì wá sínú ipò-ìbátan oníjàábá níti ẹ̀mí-ìrònú. Kí ni ojútùú náà? Bí ìwọ kò bá ṣetán láti ṣègbéyàwó, mọ̀ọ́mọ̀ ṣiṣẹ́ láti takété ní ọkàn rẹ sí ẹnìkan tí o rí pé ó fa ọ́ mọ́ra.—Owe 10:23.
Jíjàjàbọ́ Nínú Ewu àti Yíyẹra Fún Un
Bí ó bá jẹ́ pé a ti wà nínú ewu tẹ̀mí ńkọ́? Nígbà tí ẹ̀fúùfù àti ìrusókè-òun-ìlọsílẹ̀ òkun bá ń ti àwọn awakọ̀ ojú-omi lọ síhà èbúté alápàáta, wọ́n máa ń fi ìgbékútà dá ọwọ́ ọkọ̀ wọn padà sójú agbami, tàbí kí wọ́n yíwọ́ síhà ibi tí wọn kò ti ní lè rì, títí tí wọn yóò fi dé ibi tí omi kò ti léwu. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ jìjàkadì láti gba araawa sílẹ̀. Nípa kíkọbiara sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́, gbígbàdúrà taratara fún ìrànlọ́wọ́ Jehofa, àti wíwá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristian arákùnrin tí wọ́n dàgbàdénú, a lè padà sórí ipa-ọ̀nà tí kò léwu. A ó fi àlàáfíà èrò-inú àti ti ọkàn bùkún wa lẹ́ẹ̀kan síi.—1 Tessalonika 5:17.
Ohun yòówù kí àwọn àyíká-ipò wa jẹ́, àwa yóò jẹ́ ọlọgbọ́n láti yẹra pátápátá fún ‘àwọn nǹkan tí wọ́n jẹ́ ti ayé.’ (Galatia 4:3, NW) Ní ìyàtọ̀ sí Loti, Abrahamu yàn láti gbé jìnnàjìnnà sí àwọn ará Kenaani, bí ó tilẹ̀ túmọ̀ sí gbígbé nínú àgọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bóyá ó ṣaláìní àwọn ìtura ohun ti ara kan, ṣùgbọ́n ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ tí kò lọ́júpọ̀ dáàbòbò ó nípa tẹ̀mí. Kàkà kí ó jìyà rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó di “baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́.”—Romu 4:11.
Bí a ti yí wa ká pẹ̀lú ayé kan tí o ti kẹ́ra rẹ̀ bàjẹ́ èyí tí “ẹ̀mí” rẹ̀ túbọ̀ ń lágbára síi, a gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àpẹẹrẹ Abrahamu. (Efesu 2:2) Bí a bá tẹ́wọ́gba ìtọ́sọ́nà Jehofa nínú gbogbo ọ̀ràn, a óò bùkún wa nípa níní ìrírí ìdáàbòbò onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní tààràtà. Àwa yóò nímọ̀lára bíi Dafidi: “Ó tu ọkàn mi lára; ó mú mi lọ nípa ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Nítòótọ́, ire àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé mi gbogbo; èmi ó sì máa gbé inú ilé Oluwa láéláé.” Kò sí iyèméjì nípa rẹ̀, rírìn “nípa ọ̀nà òdodo,” dípò yíyàbàrá lọ sí ipa-ọ̀nà eléwu, yóò mú àwọn ìbùkún ayérayé wá.—Orin Dafidi 23:3, 6.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn orúkọ kan ni a ti yípadà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bí ìwọ kò bá tíì ṣetán láti ṣègbéyàwó, takété ní ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkan tí o rí pé ó fà ọ́ mọ́ra