ORÍ KỌKÀNLÁ
Jèhófà Fẹ́ Káwọn Èèyàn Jèrè Ìyè—Ǹjẹ́ Ìwọ Náà Fẹ́ Bẹ́ẹ̀?
1, 2. (a) Kí la lè rí kọ́ nínú ìṣarasíhùwà Jónà nígbà tí Jèhófà pinnu pé òun ò ní pa àwọn ará Nínéfè run? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àánú Ọlọ́run àti ojú tó fi ń wo ẹ̀mí?
INÚ Jèhófà dùn gan-an. Àmọ́, ńṣe ni wòlíì Jónà dì kunkun, tínú ń bí i burúkú-burúkú. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ń gbé ìlú Nínéfè ni Jèhófà fàánú hàn sí nípa dídá tó dá ẹ̀mí wọn sí. Àmọ́ ká fi dídàá Jónà ni, àwọn èèyàn náà ì bá ti pa run! Jèhófà yàn láti dárí ji àwọn èèyàn yìí tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀, kò sì pa wọ́n run.
Kódà àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè má mọ ibi tí àánú rẹ̀ nasẹ̀ dé nígbà mìíràn
2 Ìṣarasíhùwà Jónà yìí jẹ́ ká rí i pé ó máa ń ṣòro gan-an fún àwa ẹ̀dá èèyàn nígbà míì láti mọ ibi tí ìpamọ́ra Ọlọ́run dé ká sì fẹ́ ohun tó fẹ́, ìyẹn ni pé káwọn èèyàn jèrè ìyè. “Kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú” nígbà tí Jèhófà pinnu láti dá ẹ̀mí àwọn ará Nínéfè sí. Ṣé kì í ṣe pé ire ara Jónà ló jẹ Jónà lógún ju bí Ọlọ́run ṣe fi àánú hàn sí àwọn èèyàn náà àti dídá ẹ̀mí wọn sí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ń rò ni pé táwọn ará Nínéfè ò bá pa run, àwọn èèyàn ò ní ka òun sí wòlíì gidi mọ́. (Jónà 4:1, 10, 11) Ǹjẹ́ èyí kan àkókò wa yìí tí ọjọ́ Jèhófà ń yára sún mọ́lé? Tóò, o lè bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè mú kí ìmọrírì tí mo ní fún ìdáríjì Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i, báwo sì ni mo ṣe lè ran àwọn tó ronú pìwà dà lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ jàǹfààní ìfẹ́ Ọlọ́run? Báwo ni mo ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jèrè ìyè?’
ÌDÁJỌ́ ÒDODO ÀTI ÀÁNÚ NÍTORÍ ÀTIGBA Ẹ̀MÍ LÀ
3. Ǹjẹ́ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run àti àánú rẹ̀ ta kora? Ṣàlàyé.
3 Àwọn kan rò pé ọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà yóò ṣe mú ìdájọ́ ṣẹ, ìyẹn bí yóò ṣe bínú sí àwọn èèyàn tí yóò sì fìyà jẹ wọ́n ló kúnnú ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá wọ̀nyí. Ó ṣeé ṣe kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ béèrè pé: ‘Ṣé a wá lè sọ pé aláàánú ni Jèhófà nígbà náà? Ǹjẹ́ ọ̀ràn dídá ẹ̀mí àwọn èèyàn sí tiẹ̀ jẹ ẹ́ lógún?’ Ká sòótọ́, ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run àti àánú rẹ̀ ò ta kora wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Ìdájọ́ òdodo àti àánú jẹ́ méjì lára àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó jẹ́ pípé, tí kò fì síbì kan ju ibì kan lọ. (Sáàmù 103:6; 112:4; 116:5) Bí Jèhófà bá mú ìwà búburú táwọn ẹni ibi ń hù kúrò, ó fi àánú hàn sí àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni rere nìyẹn. Ohun tí ìyẹn á fi hàn ni pé pípé ni ìdájọ́ òdodo rẹ̀. Ní ìdàkejì, torí pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà ò kù síbì kan, àánú tó ní kì í jẹ́ kó máa ka gbogbo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn èèyàn sí wọn lọ́rùn. Bó o ṣe lè ṣàlàyé rẹ̀ rèé: Jèhófà máa ń fìyà jẹ ẹni tí ìyà bá tọ́ sí, ó sì máa ń fi àánú hàn tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Nínú iṣẹ́ táwọn wòlíì náà jẹ́, wàá rí ọ̀pọ̀ gbólóhùn tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ànímọ́ méjèèjì wọ̀nyí wà déédéé lọ́nà pípé, ìkan ò pàkan lára, èyí tó fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn jèrè ìyè. Jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò èyí. Bá a bá sì ṣe ń ṣe àgbéyẹ̀wò náà, a óò máa kíyè sí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a lè fi sílò lónìí.
4. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn jèrè ìyè?
4 Iṣẹ́ ìdálẹ́bi ni wòlíì Jóẹ́lì jẹ́, àmọ́, ó tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run “jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Jóẹ́lì 2:13) Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Míkà tẹnu mọ́ bá a ṣe nílò ìdáríjì Jèhófà tó. Lẹ́yìn tí Míkà béèrè pé “Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ?” ó ṣàpèjúwe irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, ó ní: “Dájúdájú, òun kì yóò máa bá a lọ nínú ìbínú rẹ̀ títí láé, nítorí ó ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Òun yóò tún fi àánú hàn sí wa.” (Míkà 7:18, 19) Bá a ṣe rí i nínú àkọsílẹ̀ Jónà nípa àwọn ará Nínéfè, Ọlọ́run múra tán láti pèrò dà pé òun ò ní fìyà jẹ àwọn èèyàn tí wọ́n múnú bí òun mọ́, ìyẹn bí àwọn èèyàn náà bá ṣe ohun tó máa fi hàn pé òótọ́ ni wọ́n ronú pìwà dà.
5. Àwọn nǹkan wo nípa àánú Jèhófà àti ìfẹ́ tó ní láti dá ẹ̀mí àwọn èèyàn sí ló ń mọ́kàn rẹ yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ jù lọ? (Tún wo “Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn.”)
5 Ìgbà ayé àwọn wòlíì méjìlá náà kọ́ la wà yìí. Síbẹ̀, ǹjẹ́ a ò mọyì àkọsílẹ̀ wọn tó fi àánú Jèhófà àti ìfẹ́ tó ní láti gba ẹ̀mí là hàn? Tó o bá mọyì rẹ̀, á mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa á sì mú kó o túbọ̀ fẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí wọ́n lè jèrè ìyè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwàkiwà lọ̀pọ̀ èèyàn ń fìgbésí ayé wọn hù lónìí, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tí Hóséà sọ nígbà tó gba aya rẹ̀ tó ṣe panṣágà padà fi ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní yìí hàn. Jèhófà ‘bá ọkàn àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀.’ Kì í ṣe dandan ni pé kí Ọlọ́run dárí jì wọ́n, àmọ́ ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ “láti inú ìfẹ́ àtinúwá” rẹ̀. (Hóséà 1:2; 2:13, 14; 3:1-5; 14:4) Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí ìfẹ́ àtinúwá Ọlọ́run àti ohun tó ṣe láti dárí ji àwọn èèyàn náà fi ṣe pàtàkì? Ó ṣe pàtàkì nítorí pé ọ̀ràn tó mú ẹ̀mí lọ́wọ́ ni. Tó o bá wo inú ìjọ Kristẹni tó ń ṣe ohun kan tí ìwọ alára ń kópa nínú rẹ̀, wàá tún rí ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé aláàánú ni Ọlọ́run àti pé ó fẹ́ káwọn èèyàn jèrè ìyè.
BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ LÁTI JÈRÈ ÌYÈ
6. Ọ̀nà pàtàkì wo ni Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun fẹ́ káwọn èèyàn jèrè ìyè?
6 Kí nìdí tó o fi ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù? Ìdí kan pàtàkì tó o fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run tòótọ́. Ohun pàtàkì kan tó yẹ ká mọ̀ nípa Jèhófà ni pé: Ó máa ń kọ́kọ́ ṣe ìkìlọ̀ tó ṣe kedere kó tó fìyà jẹni. Èyí fi hàn pé ó láàánú àwọn èèyàn lójú, kò fẹ́ kí wọ́n kú, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fẹ́ kí wọ́n jèrè ìyè. Àwọn wòlíì méjìlá náà jẹ́ káwọn olùṣe búburú mọ̀ pé Ọlọ́run fún wọn láǹfààní láti ṣàtúnṣe kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìbínú òdodo rẹ̀. Àwa náà ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lónìí. Bó ṣe jẹ́ pé Kristẹni ni ọ́, o ní àǹfààní bàǹtà-banta láti máa kéde ìkìlọ̀ nípa ọjọ́ ẹ̀san Ọlọ́run tó ń bọ̀. Àmọ́ bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, máa ṣọ́ra o, kó o má lọ ní ẹ̀mí ìgbẹ̀san, kó o má dẹni tó ń nífẹ̀ẹ́ sí pé káwọn tí kò tẹ́tí sí iṣẹ́ Ọlọ́run tó ò ń jẹ́ “jìyà tó tọ́ sí wọn.” Máa rán ara rẹ létí pé ìdí pàtàkì tó o fi ń wàásù ni pé káwọn kan lè rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè kí wọ́n sì rìn nínú rẹ̀.—Jóẹ́lì 3:9-12; Sefanáyà 2:3; Mátíù 7:13, 14.
7. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí? (b) Táwọn èèyàn bá ń dágunlá, báwo ni ríronú nípa irú ẹ̀mí tí Jèhófà ní yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́?
7 Ìgbàkigbà tó o bá ń fi òtítọ́ Bíbélì han àwọn ẹlòmíràn láti ojúlé dé ojúlé, ní ilé ìwé, níbi iṣẹ́ rẹ, tàbí láwọn ibòmíràn, mọ̀ pé ńṣe lò ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò àánú Ọlọ́run àti ìdáríjì rẹ̀ ní kánjúkánjú. (Hóséà 11:3, 4) Òótọ́ ni pé ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn máa dágunlá tàbí kí wọ́n máà nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ò ń bá wọn sọ. Síbẹ̀, tó o bá ń forí tì í, tí o ò jẹ́ kí ìyẹn dá ọ dúró, ò ń fara wé Ọlọ́run aláàánú nìyẹn, ẹni tó tipasẹ̀ Sekaráyà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ oníwàkiwà pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ padà kúrò ní ọ̀nà búburú yín àti kúrò nínú ìbálò búburú yín.” (Sekaráyà 1:4) Ta ló mọ̀, bóyá àwọn kan lára àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nípa àánú Ọlọ́run tó o sì ń fi ọ̀nà ìyè hàn yóò ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe? Lẹ́ẹ̀kan sí i, máa gbìyànjú láti fi sọ́kàn pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn jèrè ìyè, àti pé ìwọ náà fẹ́ bẹ́ẹ̀.
8. Tá a bá rántí bí àwọn kan ṣe tẹ́wọ́ gba àánú Ọlọ́run, báwo ni yóò ṣe fún wa níṣìírí?
8 Tó o bá ń rántí òtítọ́ ọ̀rọ̀ kan, ó lè fún ọ níṣìírí. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni pé: Látìgbà ìwáṣẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máà sí ìgbà kan tí kò sí àwọn tó máa ń tẹ́tí sí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán sí wọn tí wọ́n sì máa ń ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ìdí nìyẹn tí wòlíì Hóséà fi lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan tí wọ́n rí i pé “àwọn ọ̀nà Jèhófà dúró ṣánṣán.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn olódodo sì ni yóò máa rìn nínú wọn.” (Hóséà 14:9) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó ti kọjá, ọ̀pọ̀ ló ti jẹ́ ìpè tí Ọlọ́run ń pè, pé: ‘Ẹ padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín.’ (Jóẹ́lì 2:12) Àwọn èèyàn tí wọ́n ti mọ Jèhófà tẹ́lẹ̀ ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ yìí fún, àmọ́ ó tún fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Dájúdájú, Ọlọ́run ò sọ̀rètí nù pé ó ṣeé ṣe kí ẹ̀dá èèyàn kábàámọ̀ àwọn ohun tí kò dára tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yíjú sí ṣíṣe ohun tó tọ́. Ìyẹn ló máa mú kí wọ́n ní ìrètí láti rí ìgbàlà.—1 Tímótì 4:16.
9. Kí ni ohun táwọn ará Nínéfè ṣe fi hàn pé ó pọn dandan?
9 A tún rí ohun mìíràn nínú dídá tí Jèhófà dárí ji àwọn ará Nínéfè. Ìwé Jónà sọ fún wa pé àwọn èèyàn náà fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí wọn, wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.” (Jónà 3:5) Níní ìbẹ̀rù fún ìdájọ́ Ọlọ́run nìkan ò lè gbà wọ́n là, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ kí wọ́n tó lè máa wà láàyè nìṣó. Nítorí pé Jèhófà fẹ́ tọkàntọkàn pé káwọn èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n sì fi ìgbàgbọ́ ṣe ohun tó yẹ, ó jẹ́ ká máa wàásù, ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ yàn. Kí ló sì máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ohun tí ìwé Jónà sọ nípa àwọn ará Nínéfè ni pé: “Ọlọ́run tòótọ́ sì wá rí àwọn iṣẹ́ wọn, pé wọ́n ti yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn; nítorí náà, Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá.” (Jónà 3:10) Jèhófà kì í ṣe ẹni téèyàn lè fi ọ̀rọ̀ lásán tàbí ìṣesí tí kò dénú tàn jẹ. Ó ti ní láti jẹ́ pé tọkàntọkàn làwọn ará Nínéfè kábàámọ̀ ìwàkiwà wọn, wọ́n sì fi èyí hàn nínú ohun tí wọ́n ṣe. Ọlọ́run rí i pé wọ́n ti yí padà lóòótọ́; pé ojúlówó ni ìrònúpìwàdà wọn, wọ́n sì tún ní ìgbàgbọ́.
10. Sọ díẹ̀ lára àwọn ìgbà tí Jèhófà ti jẹ́ káwọn èèyàn rí ìgbàlà.
10 Láé, ká má ṣe rò pé àwọn ará Nínéfè nìkan ló jàǹfààní nínú ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní láti dá ẹ̀mí àwọn èèyàn sí. Nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn lẹ́yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Ọbadáyà, Náhúmù àti Hábákúkù, Jèhófà jẹ́ kí Jeremáyà àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí wọ́n jẹ́ onígbọràn la ìparun náà já. (Jeremáyà 39:16-18) Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àṣẹ́kù tó ronú pìwà dà yóò padà wá láti Bábílónì wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn tòótọ́ padà. (Míkà 7:8-10; Sefanáyà 3:10-20) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn ti ní ìmúṣẹ tó pabanbarì lóde òní. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí ọ̀pọ̀ lára wọn ti dẹwọ́ nínú ìjọsìn mímọ́, tún fi ìtara bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn padà, wọ́n padà rí ojú rere Jèhófà, wọ́n sì ń retí ìyè. Lónìí pẹ̀lú, àwọn èèyàn láti “ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè” ń “dara pọ̀ mọ́ Jèhófà.” (Sekaráyà 2:11) Àwọn wọ̀nyí ní ìrètí láti la òpin ètò àwọn nǹkan yìí tó ti sún mọ́lé já. Nítorí náà, kò yẹ kó jẹ́ tìtorí àtipa àṣẹ tá a pa fáwa Kristẹni mọ́ nìkan lo ṣe ń wàásù. Bẹ́ẹ̀ sì ni kì í kàn án ṣe torí àtimú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ìdí pàtàkì tó o fi ń wàásù ni kó o lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n nígbàgbọ́, kí wọ́n sì jèrè ìyè.
ÌYÈ WÀ FÚN ÀWỌN TÍ WỌ́N PADÀ SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ
11, 12. Báwo ni àánú Ọlọ́run ṣe lè ṣe àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan jẹ́ olùjọsìn rẹ̀ láǹfààní?
11 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ ó sì fẹ́ kí wọ́n jèrè ìyè, síbẹ̀, kò gbàgbé àwọn tí wọ́n ti ń sìn ín bọ̀ tipẹ́. Ó yẹ káwa náà nífẹ̀ẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ká sì fẹ́ kí wọ́n máa rìn nìṣó lójú ọ̀nà ìyè. Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ tá a ní sí wọn hàn láwọn ọ̀nà pàtàkì?
12 Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà rí, tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n sì fi ìtara jọ́sìn rẹ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, wọn ò sìn ín mọ́. Iṣẹ́ tí Jèhófà fi rán àwọn wòlíì méjìlá náà fi hàn pé, nígbà yẹn, Jèhófà fẹ́ láti fàánú hàn sí àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ àmọ́ tí wọ́n ti fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. Bí Jèhófà ṣe ń fàánú hàn lóde òní náà nìyẹn o, yálà ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti sú lọ, tàbí kí ohun kan ti fà wọ́n lọ, tàbí kí wọ́n ti ṣubú sínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sì ní láti ronú pìwà dà. (Hébérù 2:1; 3:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ayọ̀ wọn ti wọmi bí wọn kò ṣe sí lọ́dọ̀ Jèhófà mọ́, ó lè ṣòro fún wọn láti padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọlọ́run pàrọwà fún wọn nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: ‘Ẹ padà sọ́dọ̀ mi,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.’” (Sekaráyà 1:3) Ọ̀rọ̀ Hóséà mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Ó ní: “Padà wá, ìwọ Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí ìwọ ti kọsẹ̀ nínú ìṣìnà rẹ. Ẹ mú àwọn ọ̀rọ̀ dáni pẹ̀lú yín, kí ẹ sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Gbogbo yín, ẹ sọ fún un pé, ‘Kí o dárí ìṣìnà jì; kí o sì tẹ́wọ́ gba ohun rere.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, àní tí àwọn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ńlá bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n lè rí ìdáríjì rẹ̀ gbà, èyí tó máa mú kí wọ́n kọ́fẹ padà pátápátá. (Hóséà 6:1; 14:1, 2; Sáàmù 103:8-10) Bó ṣe rí nìyẹn nígbà ayé àwọn wòlíì náà, bó sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn.
Báwo lo ṣe lè ṣèrànwọ́ fún Kristẹni kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ onítara kó lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà?
13. Kí làwọn ìdí tó fi yẹ ká fi àánú hàn sí àwọn tí Ọlọ́run ti dárí jì?
13 Àmọ́, kí nìyẹn túmọ̀ sí fún Kristẹni tí kò kúrò lójú ọ̀nà ìyè rí? Báwo la ṣe lè fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlòmíì làwa náà fi ń wò wọ́n? Jèhófà fẹ́ ká máa fàánú hàn sáwọn ẹni tuntun àtàwọn tí ò sìn ín mọ́. Ọlọ́run tipasẹ̀ Hóséà sọ ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa, pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni mo ní inú dídùn sí, kì í sì í ṣe ẹbọ.” Jésù Kristi fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ohun tí Hóséà sọ yìí, ó ní: “Ẹ lọ, nígbà náà, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ‘Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.’” (Hóséà 6:6; Mátíù 9:13) Ó pọn dandan pé ká fi irú àánú bẹ́ẹ̀ hàn tá a bá fẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run máa bá a lọ. Kíyè sí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé dídáríjini àti fífarawé Ọlọ́run kan ara wọn. Ó sọ pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà. Nítorí náà, ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.” (Éfésù 4:32–5:2) Báwo lo ṣe ń fara wé Ọlọ́run sí lọ́nà yìí?
14, 15. Irú àwọn ipò wo ló ṣeé ṣe kó fi èrò tá a ní nípa bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini hàn?
14 Bí Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ ńlá ò bá ronú pìwà dà ńkọ́, tó wá di pé wọ́n ní láti yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní; nígbà yẹn, ńṣe ni wọ́n máa ń yọ àwọn Kristẹni tí kò bá ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Tí ìyẹn bá lè ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn àpọ́sítélì Jésù ṣì wà láyé, a jẹ́ pé kò yẹ kó yani lẹ́nu pé irú rẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lónìí. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn onígbọràn tó wà nínú ìjọ máa ń tẹ̀ lé àṣẹ Bíbélì tó sọ pé kí wọ́n má ṣe bá ẹni tá a ti yọ kúrò nínú ìjọ kẹ́gbẹ́. Jíjẹ́ tí wọ́n bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà lè jẹ́ kí oníwàkiwà náà rí bí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá ṣe burú tó, ìyẹn sì lè mú kó ronú pìwà dà. A rí i kà nínú Bíbélì pé, nígbà tó ṣe, ọkùnrin kan tí wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ Kọ́ríńtì ronú pìwà dà ó sì tún yíwà padà, ni wọ́n bá gbà á padà sínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 2 Kọ́ríńtì 2:5-8) Tá a bá gba ẹnì kan padà bẹ́ẹ̀ lónìí, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ, báwo lo sì ṣe lè fi hàn pé o fẹ́ káwọn ẹlòmíì jèrè ìyè?
15 Ojú lè máa ti oníwàkiwà tó ronú pìwà dà ó sì lè máa rò pé kò sí àtúnṣe kankan fóun mọ́. Ó nílò ọ̀rọ̀ tó máa fi í lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run àtàwa ará nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àti pé ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwa ará ni pé kó rí ìyè. Ọlọ́run fi àwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un tí wọ́n ṣe tán láti ronú pìwà dà lọ́kàn balẹ̀, pé: “Èmi yóò sì fẹ́ ọ fún ara mi ní ìṣòtítọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ Jèhófà.” (Hóséà 2:20) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹlẹ́ṣẹ̀ nìyẹn, ó yẹ káwa náà fi hàn pé a fìwà jọ ẹni tí Sekaráyà pè ní Ọlọ́run tó ń “fi àánú hàn.”—Sekaráyà 10:6.
16. Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe nígbà tí wọ́n bá gba ẹnì kan padà?
16 Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kéèyàn jèrè ìyè, ìdí nìyẹn tí inú rẹ̀ fi máa ń dùn tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà, tàbí tí ẹnì kan tí kò ní ìtara mọ́ bá sọ jí padà.a (Lúùkù 5:32) Nígbà tí wọn gba ará Kọ́ríńtì tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan padà, Pọ́ọ̀lù gba ìjọ níyànjú pé kí wọ́n dárí jì í kí wọ́n sì fún un níṣìírí, kí wọ́n jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénúdénú. Ó sọ pé: “Ìbáwí mímúná yìí tí ọ̀pọ̀ jù lọ fi fún un ti tó fún irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé, dípò èyí nísinsìnyí, kí ẹ fi inú rere dárí jì í, kí ẹ sì tù ú nínú, pé lọ́nà kan ṣáá, kí ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù má bàa gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ mì. Nítorí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ fìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín fún un múlẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 2:6-8) Rántí pé Hóséà fa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà kan rí yọ, ó ní: “Èmi yóò wo àìṣòótọ́ wọn sàn. Èmi yóò nífẹ̀ẹ́ wọn láti inú ìfẹ́ àtinúwá tèmi.” (Hóséà 14:4) Ǹjẹ́ a óò fara wé Jèhófà nípa fífayọ̀ ṣe ipa tiwa nínú ìwòsàn tẹ̀mí yìí àti ìyè àìnípẹ̀kun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀?
17, 18. Báwo la ṣe lè fìfẹ́ ran àwọn tí wọ́n padà sọ́dọ̀ Jèhófà tàbí àwọn ará ilé ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ lọ́wọ́?
17 Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere pé iyì lòun fi ń bá àwọn tó padà lò, ó máa ń tẹ́wọ́ gbà wọ́n ó sì máa ń nífẹ̀ẹ́ wọn jinlẹ̀, bí Hóséà ṣe fi tinútinú gba aya rẹ̀ tó di aláìṣòótọ́ padà. Jèhófà sọ ọ̀nà tó gbà bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò nígbà yẹn, ó ní: “Mo dà bí àwọn tí ó gbé àjàgà kúrò ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sì ni mo gbé oúnjẹ wá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Hóséà 11:4) Ẹ ò rí i pé inú àwọn tó padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run á dùn gan-an ni bó ṣe rọra fi ìfẹ́ fà wọ́n mọ́ra! Bá a ṣe lè fara wé Ọlọ́run ni pé, ká jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ sí ẹni tí inú rẹ̀ bà jẹ́ nítorí ìwàkiwà tó hù tó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ká má sì máa fi ojú tá a fi ń wò ó tẹ́lẹ̀ wò ó. Tí wọ́n bá ti lè gbà á padà sínú ìjọ, dípò ká máa bínú sí i tàbí ká máa dì í sínú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti ṣẹ̀ wá tẹ́lẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un nígbàkigbà tó bá nílò rẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 5:14.
18 Ǹjẹ́ o lè ronú àwọn ọ̀nà mìíràn tó o lè gbà fara wé Jèhófà nígbà tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ? Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, ǹjẹ́ a lè máa ṣèrànwọ́ fún àwọn adúróṣinṣin tó wà nínú ìdílé rẹ̀, irú bí aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀? Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń tiraka láti máa lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí. Ǹjẹ́ a lè ṣe àkànṣe ìrànwọ́ tí wọ́n nílò fún wọn? Ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà fi àánú hàn ni pé ká máa lo “ọ̀rọ̀ rere, ọ̀rọ̀ tí ń tuni nínú,” ká máa dá ìjíròrò tó máa fún irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ níṣìírí sílẹ̀. (Sekaráyà 1:13) A láǹfààní tó pọ̀ láti ṣe ìyẹn kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé, nígbà tá a bá jọ wà lóde ẹ̀rí, tàbí láwọn ìgbà mìíràn. Wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa àti ẹni ọ̀wọ́n tá a jọ wà nínú ìjọ, kò sì yẹ kó máa ṣe wọ́n bíi pé à ń lé wọn sá tàbí pé wọ́n dá nìkan wà. Nígbà míì, àwọn ọmọ ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ nìkan ló máa ń sapá láti sin Jèhófà. A fẹ́ tọkàntọkàn pé kí wọ́n jèrè ìyè. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ bẹ́ẹ̀?
‘Ó Ń FI ÀÁNÚ HÀN SÍ ỌMỌDÉKÙNRIN ALÁÌNÍBABA’
19. Báwo ni Sefanáyà ṣe ṣèrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí fún ẹnì kan tó ṣeé ṣe kí wọ́n kà sí ‘ọmọ aláìníbaba’?
19 Wàá rí àpẹẹrẹ bó o ṣe lè ṣèrànwọ́ nínú àgbéyẹ̀wò tá a fẹ́ ṣe báyìí nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Sefanáyà ní ìdajì ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ ìdílé tó ń jọba ní Júdà ni Sefanáyà, bóyá kó jẹ́ ẹbí Jòsáyà Ọba. Nítorí pé wọ́n pa ọba tó wà lórí ìtẹ́ nígbà yẹn, ó di dandan pé kí Jòsáyà ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ péré gorí ìtẹ́. Ọba tuntun yìí ní iṣẹ́ bàǹtà-banta kan tí kò rọrùn láti ṣe, nítorí pé ńṣe ni orílẹ̀-èdè yẹn ń yí gbiri nínú ìbọ̀rìṣà àtàwọn àṣà mìíràn tó ń kóni nírìíra. (Sefanáyà 3:1-7) Jòsáyà, tí bàbá rẹ̀ ti kú tó sì tún jẹ́ ọmọdé, ní láti rí ìtọ́sọ́nà tó múná dóko àti ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n kó bàa lè ṣàkóso orílẹ̀-èdè oníwàkiwà yẹn. Orí Kẹta sí Ìkarùn-ún ìwé yìí sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fún un ní ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ Jeremáyà àti Sefanáyà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Jèhófà gbẹnu wòlíì rẹ̀ bẹnu àtẹ́ lu “àwọn ọmọ aládé” Júdà, kò bẹnu àtẹ́ lu Jòsáyà Ọba. (Sefanáyà 1:8; 3:3) Èyí fi hàn pé ọ̀dọ́mọdé ọba yìí ti ní láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn mímọ́ kó tó di àkókò tí wòlíì náà jíṣẹ́ rẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìṣílétí wòlíì Sefanáyà ran Jòsáyà lọ́wọ́ kó lè dúró gbọn-in lórí ìpinnu tó ṣe láti mú àfẹ́kù bá ìjọsìn àìmọ́ ní Júdà.
20. Táwọn ọmọ “aláìníbaba” bá ní ẹnì kàn nínú ìjọ tó ń gbà wọ́n nímọ̀ràn, báwo lèyí ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
20 Ìfẹ́ tí Sefanáyà ní sí Jòsáyà jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìní, àwọn ọmọdé tí kò ní alábàárò, irú bí àwọn tá a ti yọ òbí wọn lẹ́gbẹ́. Hóséà kéde pé: “Nípasẹ̀ [Ọlọ́run] ni a ń fi àánú hàn sí ọmọdékùnrin aláìníbaba.” (Hóséà 14:3) Ǹjẹ́ o mọ àwọn ọmọkùnrin àtọmọbìnrin “aláìníbaba” tí wọ́n nílò ẹnì kan nínú ìjọ tí yóò máa tọ́ wọn sọ́nà tí yóò sì máa gbà wọ́n nímọ̀ràn? Wọ́n lè jẹ́ ọmọ òrukàn nípa tẹ̀mí, àwọn ọmọ tó wà nínú ìdílé olóbìí-kan, tàbí àwọn ọmọ tí wọ́n ń sin Jèhófà láìsí pé bàbá òun ìyá wọn tàbí àwọn ẹbí wọn ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa pinnu bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á ṣe fara mọ́ ìjọ sí àti bí wọ́n á ṣe máa tẹ̀ síwájú sí nípa tẹ̀mí ni bóyá wọ́n ní ẹnì kan nínú ìjọ tó ń gbà wọ́n nímọ̀ràn tàbí wọn ò ní. Ọ̀pọ̀ “ọmọdékùnrin aláìníbaba” ni wọ́n ti dàgbà di ẹni tẹ̀mí tó dúró déédéé lẹ́yìn táwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ ti fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 82:3.
Ǹjẹ́ o lè dẹni tó ń fìfẹ́ gba àwọn ọmọ “aláìníbaba” nímọ̀ràn?
21. Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí lè ṣe fáwọn ọmọdé?
21 Bí àpẹẹrẹ, ìrànlọ́wọ́ ló máa jẹ́ fún ìyá tó ń dá nìkan tọ́mọ táwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí bá fìfẹ́ ran àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. (Jákọ́bù 1:27) Àwọn alábòójútó àtàwọn mìíràn lè ṣèrànwọ́ tẹ̀mí fáwọn tó wà nínú ìdílé tí kò ní àbójútó tó péye, bí wọ́n sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n má gbàgbé láti fọ̀wọ̀ hàn fún ipò orí tí ìyá tó ń dá tọ́mọ nínú ìdílé náà wà, kí ìṣesí wọn pẹ̀lú fọ̀wọ̀ hàn kó sì bójú mu. Bóyá ó lè ṣeé ṣe kí ìwọ àtaya tàbí ọkọ rẹ tàbí ìdílé rẹ lódindi wá àyè láti wà pẹ̀lú ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin aláìníbaba. Ǹjẹ́ o lè fi ìgbatẹnirò hàn sí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n dá nìkan wà? Wọ́n lè nílò pé kéèyàn fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀-rora-ẹni-wò hàn sí wọn, wọ́n sì lè fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ àṣírí. O lè tẹ́tí sí wọn kí wọ́n sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ nígbà tó o bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Kò sí àní-àní pé ọwọ́ rẹ máa ń dí, nítorí náà, ṣíṣe irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ déédéé lè jẹ́ ‘ìdánwò bí ìfẹ́ rẹ ṣe jẹ́ ojúlówó sí.’ (2 Kọ́ríńtì 8:8) Ìsapá rẹ á fi hàn pé o fẹ́ káwọn ẹlòmíì jèrè ìyè.
22. Báwo ni bí Jèhófà ṣe fẹ́ káwọn èèyàn jèrè ìyè ṣe rí lọ́kàn rẹ?
22 Ẹ ò rí i pé ríronú lórí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó sì fẹ́ kí wọ́n jèrè ìyè ń tuni nínú! Ó wu Ọlọ́run láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí àwọn olódodo kó sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun ju pé kó fìyà jẹ àwọn tó pinnu pé àwọn ò ní yí padà tí wọn ò sì yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun. Bá a ṣe ń fi tọkàntara retí ọjọ́ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa fara wé Jèhófà, ká máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè kí wọ́n sì rìn nínú rẹ̀.
a Àkàwé mẹ́ta tó ń múni lọ́kàn yọ̀, ìyẹn àkàwé nípa àgùntàn tó sọ nù, àkàwé nípa ẹyọ owó tó sọ nù, àti àkàwé nípa ọmọ onínàákúnàá, fi hàn pé Ọlọ́run ń ṣàníyàn gidigidi nípa àwọn tó ti rìn gbéregbère lọ.—Lúùkù 15:2-32.