Àwòkọ́ṣe—Omidan Ará Ṣúnémù
Ọmọbìnrin ará Ṣúnémù, ìyẹn Ṣúlámáítì, mọ̀ pó yẹ kóun lo orí pípé bó bá dọ̀ràn ẹni tí ọkàn òun fẹ́. Ó sọ fáwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù pé: “Mo ti mú kí ẹ wá sábẹ́ ìbúra, . . . pé kí ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.” Omidan ará Ṣúnémù yìí mọ̀ pé kì í pẹ́ tí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni fi ń nípa lórí béèyàn ṣe ń ronú. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ̀ pé àwọn míì lè rọ òun láti gbà fẹ́ni tí kò yẹ kóun fẹ́. Àní bọ́rọ̀ ṣe rí lára òun fúnra ẹ̀ gan-an lè mú kó ṣe yíyàn tí kò tọ́. Nítorí náà, ọmọbìnrin ará Ṣúnémù náà dúró bí “ògiri.”—Orin Sólómọ́nì 8:4, 10.
Ṣéwọ náà máa ń ronú jinlẹ̀ bíi ti ọmọbìnrin ará Ṣúnémù, bó o bá ń ronú nípa ìfẹ́? Ṣóhun tó o bá mọ̀ pó tọ́ lo máa ń ṣe ni àbí bí nǹkan bá ṣe rí lára ẹ ló máa ń darí ẹ? (Òwe 2:10, 11) Nígbà míì, àwọn èèyàn lè tì ẹ́ pé kó o máa fẹ́ ẹnì kan, nígbà tó ò tíì ṣe tán láti ṣègbéyàwó. Ó sì lè jẹ́ ìwọ fúnra ẹ lo máa ki ọrùn ara ẹ bọ irú àjọṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá rí ọkùnrin àti obìnrin kan tí wọ́n jọ ń fara wọn lọ́wọ́ lọ, ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kíwọ náà rẹ́ni máa fà ẹ́ lọ́wọ́ kiri? Ṣé ẹni tí ẹ̀sìn ẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ lo fẹ́ fẹ́? Ọmọbìnrin ará Ṣúnémù yẹn mọ ohun tó tọ́ bó bá dọ̀rọ̀ níní ìfẹ́ tòótọ́. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀!