Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Orin Sólómọ́nì
“BÍ ÒDÒDÓ lílì láàárín àwọn èpò ẹlẹ́gùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi láàárín àwọn ọmọbìnrin.” “Bí igi ápù láàárín àwọn igi igbó, bẹ́ẹ̀ ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọkùnrin.” “Ta ni obìnrin yìí tí ń bojú wolẹ̀ bí ọ̀yẹ̀, tí ó lẹ́wà bí òṣùpá àrànmọ́jú, tí ó mọ́ gaara bí oòrùn tí ń ràn yòò?” (Orin Sólómọ́nì 2:2, 3; 6:10) Àwọn ẹsẹ tá a fà yọ látinú ìwé Orin Sólómọ́nì yìí mà fani lọ́kàn mọ́ra gan-an o! Ewì ni gbogbo orin náà látòkèdélẹ̀, ó kún fún ẹ̀kọ́ ó sì gbádùn mọ́ni débi tí wọ́n fi pè é ní “orin tí ó dùn jù lọ,” tó dùn yùngbà yungba.—Orin Sólómọ́nì 1:1.
Sólómọ́nì, ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ló kọ orin náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ní nǹkan bí ọdún 1020 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ ológójì ọdún ló kọ ọ́. Orin ìfẹ́ tó dá lórí ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan àti omidan Ṣúlámáítì tó wá láti ìgbèríko. Àwọn míì tí ewì náà tún mẹ́nu bà ni ìyá ọmọbìnrin yìí àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, àwọn “ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù [àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin],” àtàwọn “ọmọbìnrin Síónì [àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù].” (Orin Sólómọ́nì 1:5; 3:11) Ó ṣòro fún ẹnì kan tó ń ka Bíbélì láti dá gbogbo àwọn tó sọ̀rọ̀ nínú Orin Sólómọ́nì mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe láti mọ̀ wọ́n bá a bá ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí wọ́n sọ tàbí ohun tí ẹlòmíì sọ sí wọn.
Níwọ̀n bí Orin Sólómọ́nì ti jẹ́ ara Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an fún ìdí méjì. (Hébérù 4:12) Lákọ̀ọ́kọ́, ó jẹ́ ká mọ ohun tá a lè pè ní ìfẹ́ tòótọ́ láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Èkejì sì ni pé orin náà jẹ́ àpẹẹrẹ irú ìfẹ́ tó wà láàárín Jésù Kristi àti ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró.—2 Kọ́ríńtì 11:2; Éfésù 5:25-31.
Ẹ MÁ ṢE GBÌYÀNJÚ LÁTI “RU ÌFẸ́ SÓKÈ NÍNÚ MI”
“Kí ó fi ìfẹnukonu ẹnu rẹ̀ kò mí lẹ́nu, nítorí àwọn ìfìfẹ́hàn rẹ dára ju wáìnì.” (Orin Sólómọ́nì 1:2) Ọmọbìnrin kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, tó ti ìgbèríko wá, tí wọ́n wá mú lọ sínú àgọ́ ọba Sólómọ́nì ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Orin Sólómọ́nì yìí. Báwo ló tiẹ̀ ṣe dénú àgọ́ Sólómọ́nì?
Ó sọ pé: “Àwọn ọmọ ìyá mi bínú sí mi; wọ́n yàn mí ṣe olùtọ́jú àwọn ọgbà àjàrà.” Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin bínú sí i nítorí pé ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ sí ní kó jẹ́ káwọn jọ nasẹ̀ lọ lákòókò kan tí ojú ọjọ́ dára nígbà ìrúwé. Kó má bàa lọ, àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ní kó lọ máa ṣọ́ “àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèké tí ń fi àwọn ọgbà àjàrà ṣe ìjẹ.” Iṣẹ́ tí wọ́n fún un ṣe yìí ló gbé e dé ẹ̀gbẹ́ ọgbà Sólómọ́nì. Àwọn tó wà níbẹ̀ kíyè sí ẹwà rẹ̀ nígbà tó lọ síbi “ọgbà àwọn igi oníkóró èso,” wọ́n sì mú un wọnú ọgbà.—Orin Sólómọ́nì 1:6; 2:10-15; 6:11.
Bí omidan náà ṣe ń sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ọkàn rẹ̀ ń fà sí olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin sọ fún un pé kó fúnra ẹ̀ “tọ ojú ẹsẹ̀ agbo ẹran lọ” láti wá a lọ. Àmọ́ Sólómọ́nì ò jẹ́ kó lọ. Sólómọ́nì sọ bó ṣe gba ti ẹwà omidan náà tó, ó sì ṣèlérí pé òun á fún un ní “àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rìbìtì-rìbìtì ti wúrà . . . pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn òníní tí a fi fàdákà ṣe.” Ìyẹn ò mà jẹ ọmọbìnrin yẹn ṣá o. Ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà wọ́nà wọnú àgọ́ Sólómọ́nì lọ, ó rí i, ó sì fìtara sọ̀rọ̀ pé: “Wò ó! Ìwọ lẹ́wà, ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ mi. Wò ó! Ìwọ lẹ́wà.” Omidan náà wá fi àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin sábẹ́ ìbúra pé: “Ẹ má gbìyànjú láti jí tàbí ru ìfẹ́ sókè nínú mi, títí yóò fi ní ìtẹ̀sí láti ru sókè.”—Orin Sólómọ́nì 1:8-11, 15; 2:7; 3:5.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:2, 3—Kí nìdí tí rírántí àwọn ìfìfẹ́hàn ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà fi dà bíi wáìnì tí orúkọ rẹ̀ sì dà bí òróró? Bí wáìnì ṣe máa ń mú ọkàn èèyàn yọ̀ àti bí ara ṣe máa ń tuni bí wọ́n bá da òróró síni lórí, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé bí omidan yìí bá ṣe ń rántí ìfẹ́ ọmọkùnrin yìí àti orúkọ rẹ̀, ṣe ló máa ń fún un lókun tó sì máa ń tù ú nínú. (Sáàmù 23:5; 104:15) Bákan náà ló ṣe jẹ́ pé báwọn Kristẹni tòótọ́, pàápàá àwọn ẹni àmì òróró, ṣe ń ronú lórí ìfẹ́ tí Jésù Kristi ti fi hàn sí wọn, ó ń sọ agbára wọn dọ̀tun ó sì ń fún wọn níṣìírí.
1:5—Kí nìdí tí ọmọbìnrin tó wá láti ìgbèríko yìí fi fi àwọ̀ rẹ̀ tó dúdú wé “àwọn àgọ́ Kídárì”? Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n máa ń fi aṣọ irun ewúrẹ́ ṣe. (Númérì 31:20) Bí àpẹẹrẹ, “aṣọ tí a fi irun ewúrẹ́” ṣe ni wọ́n lò láti fi ṣe “ìbòrí àgọ́ ìjọsìn.” (Ẹ́kísódù 26:7) Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irun ewúrẹ́ dúdú ni wọ́n fi ṣe àwọn àgọ́ Kídárì, bó ṣe jẹ́ pé títí dòní olónìí irun ewúrẹ́ làwọn darandaran tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Bedouin fi ń ṣe àgọ́ wọn.
1:15—Kí ni ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ojú àdàbà ni ojú rẹ”? Ohun tí ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà ń sọ ni pé ojú ọ̀dọ́mọbìnrin alábàákẹ́gbẹ́ òun tutù ó sì fani mọ́ra bíi ti àdàbà.
2:7; 3:5—Kí nìdí tó fi fi àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin sábẹ́ ìbúra “nípasẹ̀ àwọn abo àgbàlàǹgbó tàbí nípasẹ̀ àwọn egbin inú pápá”? Àwọn àgbàlàǹgbó àti egbin máa ń wuni wò nítorí ìrìn ẹ̀yẹ àti ẹwà wọn. Nítorí náà, ńṣe ni omidan Ṣúlámáítì ń lo gbogbo ohun yòówù tó bá rẹwà tó sì dára láti fi àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin sábẹ́ ìbúra pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ wá sóun lọ́kàn.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:2; 2:6. Fífi ìfẹ́ hàn síra ẹni lè jẹ́ ohun tó bójú mu bí tọkùnrin tobìnrin bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Àmọ́, àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ kíyè sára kó bàa lè jẹ́ pé ìfẹ́ tó dénú ni wọ́n ń fi hàn síra wọn, kì í ṣe ìfẹ́ onígbòónára, èyí tó lè mú kí wọ́n bára wọn ṣèṣekúṣe.—Gálátíà 5:19.
1:6; 2:10-15. Lóòótọ́ làwọn ẹ̀gbọ́n omidan Ṣúlámáítì ò jẹ́ kó bá olólùfẹ́ rẹ̀ lọ síbi àdádó níbi àwọn òkè ńlá, àmọ́ kì í ṣe torí pé ó jẹ́ oníṣekúṣe tàbí eléròkerò ni wọn ò ṣe jẹ́ kó lọ. Ṣe ni wọ́n wulẹ̀ ń ṣe ohun tí wọ́n rò pé ó lè dáàbò bò ó, kó má bàa bá ara ẹ̀ nínú ohun tó máa dà bí ìdẹwò fún un. Ẹ̀kọ́ táwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà lè rí kọ́ nínú èyí ni pé kí wọ́n má máa wà níbi táwọn èèyàn ó ti ní rí wọn.
2:1-3, 8, 9. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé omidan Ṣúlámáítì rẹwà, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ mú kó máa wo ara ẹ̀ bí “ìtànná sáfúrónì [òdòdó kan] lásán-làsàn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ etí òkun.” Nítorí ẹwà àti ìṣòtítọ́ omidan yìí sí Jèhófà, ọmọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà máa ń ronú nípa ẹ̀ pé ṣe ló dà bí “òdòdó lílì láàárín àwọn èpò ẹlẹ́gùn-ún.” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà fúnra ẹ̀ wá ńkọ́ o? Nítorí pé òun náà lẹ́wà, “àgbàlàǹgbó” ló jọ lójú omidan náà. Ó dájú pé òun náà ní láti jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tó sì ń fi òtítọ́ sin Jèhófà. Omidan náà sọ nípa ẹ̀ pé: “Bí igi ápù [tó máa ń ṣíji boni tó sì máa ń so èso] láàárín àwọn igi igbó, bẹ́ẹ̀ ni olólùfẹ́ mi rí láàárín àwọn ọmọkùnrin.” Àbí òótọ́ kọ́ ni pé ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn Ọlọ́run làwọn ànímọ́ rere tó yẹ kéèyàn máa wá nínú ẹni téèyàn bá máa fẹ́?
2:7; 3:5. Ọkàn ọmọbìnrin tó ti ìgbèríko wá yìí ò fi ibì kankan fà sí Sólómọ́nì. Ó tún fi àwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin ọba sábẹ́ ìbúra pé kí wọ́n má ṣe ru ìfẹ́ sókè nínú òun fún ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà. Ọkàn èèyàn ò lè ṣàdédé máa fà sí ẹlòmíì láìnídìí, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ adúróṣinṣin nìkan ló yẹ kó wu Kristẹni àpọ́n tó ń gbèrò àtiṣègbéyàwó láti fẹ́.—1 Kọ́ríńtì 7:39.
‘KÍ NI Ẹ̀ Ń WÒ LÁRA OMIDAN ṢÚLÁMÁÍTÌ?’
Ohun kan “ń jáde bọ̀ láti aginjù bí àwọn ìṣùpọ̀ èéfín adúró bí ọwọ̀n.” (Orin Sólómọ́nì 3:6) Nígbà táwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù jáde lọ wòran, kí ni wọ́n rí? Wọ́n rí Sólómọ́nì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń padà bọ̀ wá sínú ìlú! Ọba sì mú omidan Ṣúlámáítì padà bọ̀.
Ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà tẹ̀ lé omidan yìí, kò sì pẹ́ tó fi rọ́nà débi tó ti lè rí i. Bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì ti ń sọ fún un pé iná ìfẹ́ tóun ní sí i ò tíì kú, bẹ́ẹ̀ lòun náà ń sọ bó ṣe wù ú pé kó fi ìlú náà sílẹ̀. Ó wí pé: “Títí ọjọ́ yóò fi fẹ́ yẹ́ẹ́, tí òjìji yóò sì sá lọ, èmi yóò bá ọ̀nà mi lọ sí òkè ńlá òjíá àti sí òkè kékeré oje igi tùràrí.” Ó ní kí olùṣọ́ àgùntàn náà “wá sínú ọgbà” òun, kó “jẹ àwọn èso rẹ̀ tí ó jẹ́ ààyò jù lọ.” Nìyẹn náà bá dá a lóhùn pé: “Mo ti dé sínú ọgbà mi, ìwọ arábìnrin mi, ìyàwó mi.” Àwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹun, ẹ̀yin alábàákẹ́gbẹ́! Ẹ mu, ẹ sì mu àwọn ìfìfẹ́hàn ní àmupara!”—Orin Sólómọ́nì 4:6, 16; 5:1.
Lẹ́yìn tí omidan Ṣúlámáítì ti rọ́ àlá tó lá fáwọn ọmọbìnrin tó wà láàfin, ó sọ fún wọn pé: “Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.” Àwọn náà bi í pé: “Báwo ni olólùfẹ́ rẹ ṣe ju olólùfẹ́ mìíràn lọ?” Ó dá wọn lóhùn pé: “Olólùfẹ́ mi ń dán gbinrin, ó sì jẹ́ apọ́nbéporẹ́, ẹni tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà jù lọ láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.” (Orin Sólómọ́nì 5:2-10) Nígbà tí Sólómọ́nì yìn ín ní àyìntúnyìn, ó béèrè tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Kí ni ẹ ń wò lára Ṣúlámáítì?” (Orin Sólómọ́nì 6:4-13) Ọba rí èyí bí ọ̀nà tóun lè gbà fa ojú rẹ̀ mọ́ra, ló bá kúkú túbọ̀ rọ̀jò ọ̀rọ̀ àpọ́nlé lé e lórí. Àmọ́, ọmọbìnrin náà ò jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní fún ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà yingin. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Sólómọ́nì yọ̀ǹda ẹ̀ kó padà sílé.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
4:1; 6:5—Kí nìdí tá a fi fi irun omidan náà wé “agbo àwọn ewúrẹ́”? Àfiwé yìí fi hàn pé ńṣe ni irun rẹ̀ ń dán gbinrin tó sì ṣù pọ̀ ṣìkìtì bí irun ewúrẹ́ dúdú.
4:11—Kí ló ṣe pàtàkì nínú “afárá oyin [tó] ń kán tótó ní ètè” omidan Ṣúlámáítì àti wíwà tí “oyin àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n [rẹ̀]”? Oyin inú afárá máa ń dùn ju oyin tí afẹ́fẹ́ ti fẹ́ sí lọ. Nítorí náà, ńṣe ni àfiwé yìí àti gbólóhùn náà pé oyin àti wàrà wà lábẹ́ ahọ́n omidan náà, ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa létí pé ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ tó dùn mọ́ni ló máa ń tẹnu omidan Ṣúlámáítì jáde.
5:12—Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà “àwọn ojú rẹ̀ dà bí àwọn àdàbà tí ó wà lẹ́bàá ipa ojú ọ̀nà omi, tí ń fi wàrà wẹ̀,” gbé wá síni lọ́kàn? Omidan náà ń sọ nípa rírẹwà tí ojú olólùfẹ́ rẹ̀ rẹwà. Ó ṣeé ṣe kó máa lo ọ̀rọ̀ ewì yìí láti fi dúdú inú ẹyinjú wé àwọn àdàbà aláwọ̀ eérú tó ń wẹ̀ nínú wàrà.
5:14, 15—Kí nìdí tí omidan náà fi ṣàpèjúwe àwọn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn náà lọ́nà yìí? Ó ní láti jẹ́ pé àwọn ọmọọ̀ka olùṣọ́ àgùntàn yìí ni omidan náà pè ní òbìrípo wúrà, tó sì pe àwọn èékánná rẹ̀ ní kírísóláítì. Ó fi àwọn ẹsẹ rẹ̀ wé “ọwọ̀n òkúta mábílì” nítorí pé wọ́n lágbára wọ́n sì lẹ́wà.
6:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW—Ṣé Jerúsálẹ́mù ni “Ìlú Ńlá Wíwuni” túmọ̀ sí? Rárá o. “Tírísà” ni “Ìlú Ńlá Wíwuni.” Jóṣúà ló gba ìlú àwọn ará Kénáánì yìí, lẹ́yìn ìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì ló sì di olú ìlú àkọ́kọ́ fún ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá Ísírẹ́lì. (Jóṣúà 12:7, 24; 1 Àwọn Ọba 16:5, 6, 8, 15) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé “ó ti ní láti jẹ́ ìlú kan tó lẹ́wà gan-an, tá a fi lè mẹ́nu kàn án níbí yìí.”
6:13—Kí ni “ijó ibùdó méjì”? A tún lè túmọ̀ gbólóhùn yìí sí “ijó Máhánáímù.” Ìlú tó ń jẹ́ orúkọ yẹn wà ní apá ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì lẹ́bàá àfonífojì ọ̀gbàrá Jábókù. (Jẹ́nẹ́sísì 32:2, 22; 2 Sámúẹ́lì 2:29) “Ijó ibùdó méjì” tún lè tọ́ka sí irú ijó kan báyìí tí wọ́n máa ń jó ní ìlú yẹn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀.
7:4—Kí nìdí tí Sólómọ́nì fi fi ọrùn omidan Ṣúlámáítì wé “ilé gogoro eyín erin”? Sólómọ́nì ti kọ́kọ́ ṣe àpọ́nlé ọmọbìnrin náà báyìí pé: “Ọrùn rẹ dà bí ilé gogoro Dáfídì.” (Orin Sólómọ́nì 4:4) Ilé gogoro máa ń ga, ó máa ń tọ́ san-gban-dan, ara eyín erin sì máa ń dán bọ̀rọ́bọ̀rọ́. Ńṣe ni gígùn ọrùn ọmọbìnrin náà àti dídán tó ń dán ń wu Sólómọ́nì.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
4:1-7. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Ṣúlámáítì, kíkọ̀ tó kọ̀ láti gbà kí Sólómọ́nì fa òun lójú mọ́ra fẹ̀rí hàn pé kò sí ìwàkíwà kankan lọ́wọ́ ẹ̀. Ìwà ọmọlúwàbí tó ń hù wá tipa bẹ́ẹ̀ gbógo ẹwà ara ẹ̀ yọ. Bó ṣe yẹ kọ́rọ̀ gbogbo obìnrin Kristẹni náà rí nìyẹn.
4:12. Bí ọgbà ẹlẹ́wà tí wọ́n ta okùn tàbí tí wọ́n mọ ògiri yí ká téèyàn ò lè wọnú ẹ̀ àfi bó bá gba ẹnu ọ̀nà tí wọ́n ń fi kọ́kọ́rọ́ tì pa, bẹ́ẹ̀ ni omidan Ṣúlámáítì ò ṣe fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ hàn sí ẹlòmíì ju ẹni tó máa di ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lọ. Àpẹẹrẹ àtàtà gbáà lèyí jẹ́ fáwọn àpọ́n Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin!
“ỌWỌ́ INÁ JÁÀ”
Nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n omidan Ṣúlámáítì rí i tó ń padà bọ̀ wálé, wọ́n béèrè pé: “Ta ni obìnrin yìí tí ń jáde bọ̀ láti aginjù, tí ó fara ti olólùfẹ́ rẹ̀?” Kó tó dìgbà yẹn, ọ̀kan nínú wọn ti sọ pé: “Bí òun bá jẹ́ ògiri, a ó mọ odi orí òrùlé tí ó jẹ́ fàdákà lé e lórí; ṣùgbọ́n bí òun bá jẹ́ ilẹ̀kùn, a ó fi pátákó kédárì dí i pa.” Ní báyìí tó ti jẹ́ pé ipò tó dojú kọ omidan Ṣúlámáítì ti jẹ́ kó dájú pé ìfẹ́ dídúró ṣinṣin ni ìfẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Ògiri ni mí, ọmú mi sì dà bí ilé gogoro. Nínú ọ̀ràn yìí, lójú rẹ̀ mo dà bí ẹni tí ó rí àlàáfíà.”—Orin Sólómọ́nì 8:5, 9, 10.
“Ọwọ́ iná Jáà” ni ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Lọ́nà wo? Nítorí pé Jèhófà ni orísun irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Òun ni Ẹni tó dá wa nídàá tá a fi lè máa nífẹ̀ẹ́. Ó jẹ́ ọwọ́ iná tó ń jó fòfò, tí ò sì ṣeé pa. Orin Sólómọ́nì ṣàpèjúwe lọ́nà tó dùn-ún gbọ́ sétí pé ìfẹ́ tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin lè “lágbára [kì í yí padà] bí ikú.”—Orin Sólómọ́nì 8:6.
Orin títayọ tí Sólómọ́nì kọ tún tànmọ́lẹ̀ sórí ìdè tó wà láàárín Jésù Kristi àtàwọn tó jẹ́ ara “ìyàwó” rẹ̀ ti ọ̀run. (Ìṣípayá 21:2, 9) Ìfẹ́ tí Jésù ní fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ré kọjá ìfẹ́ èyíkéyìí tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Kò sí ohun tó lè yí ìfọkànsìn àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ ìyàwó Kristi padà. Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jésù fi fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí “àwọn àgùntàn mìíràn” pẹ̀lú. (Jòhánù 10:16) Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo àwọn tó ń fòótọ́ sin Ọlọ́run fara wé àpẹẹrẹ Ṣúlámáítì, ẹni tí ìfẹ́ àti ìfọkànsìn rẹ̀ kì í yẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Kí ni Orin Sólómọ́nì kọ́ wa pé ká máa wá nínú ọkọ tàbí aya tá a bá fẹ́ fẹ́?