Orin 18
Ìfẹ́ Ọlọ́run Tó Dúró Ṣinṣin
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.
Òótọ́ yìí ńfún wa láyọ̀.
Ìfẹ́ mú kó rán ’mọ rẹ̀,
Pé kó wá rà wá pa dà,
Ká lè jèrè òdodo,
Ká sì láyọ̀ títí láé.
(ÈGBÈ)
Wá, ẹ̀yin tí òùngbẹ ńgbẹ,
Wá mu omi ’yè lọ́fẹ̀ẹ́.
Wá mu, ẹ̀yin tóùngbẹ ńgbẹ;
Oore Ọlọ́run ni.
2. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.
Gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ fi hàn.
Ó tún fìfẹ́ hàn sí wa,
Ó fún Kristi ní ìtẹ́
Kó lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
Wòó! A bí Ìjọba rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Wá, ẹ̀yin tí òùngbẹ ńgbẹ,
Wá mu omi ’yè lọ́fẹ̀ẹ́.
Wá mu, ẹ̀yin tóùngbẹ ńgbẹ;
Oore Ọlọ́run ni.
3. Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.
Kífẹ̀ẹ́ rẹ̀ mú ká nífẹ̀ẹ́.
Ká ran ońrẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́,
Kí wọ́n lè rí òdodo.
Ká fi ìrẹ̀lẹ̀ wàásù,
Ká tu aráyé nínú.
(ÈGBÈ)
Wá, ẹ̀yin tí òùngbẹ ńgbẹ,
Wá mu omi ’yè lọ́fẹ̀ẹ́.
Wá mu, ẹ̀yin tóùngbẹ ńgbẹ;
Oore Ọlọ́run ni.