Orin 31
Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá!
1. Aráyé ńbọgi bọ̀pẹ,
Wọn kò m’Ọlọ́run òótọ́.
Òun l’Olódùmarè,
Ó sì fi hàn bẹ́ẹ̀.
Kò sí ọlọ́run mìíràn
Tó lè mọ ọjọ́ ọ̀la.
Kò sí ẹlẹ́rìí kankan fún wọn,
Torí wọn kò já mọ́ nǹkan kan.
(ÈGBÈ)
Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.
A ńjẹ́rìí lọ láìbẹ̀rù.
Ọlọ́run wa alásọtẹ́lẹ̀;
Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ńṣẹ.
2. A ńfayọ̀ pòkìkí Jáà,
A ńfi ìjẹ́rìí gbée ga.
A ńkéde Ìjọba,
Pẹ̀lú ìgboyà.
Káwọn èèyàn lè mòótọ́
Kí wọ́n sì dòmìnira.
Tí wọ́n bá ti wá dalágbára,
Aó jọ máa yin Ọlọ́run wa.
(ÈGBÈ)
Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.
A ńjẹ́rìí lọ láìbẹ̀rù.
Ọlọ́run wa alásọtẹ́lẹ̀;
Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ńṣẹ.
3. Ìjẹ́rìí ńgbóókọ rẹ̀ ga,
Ó ńmẹ́gàn gbogbo kúrò.
Ó ńkìlọ̀ fẹ́ni ’bi,
Tí ńgàn oókọ Jáà.
Ìdáríjì wà fún wọn,
Bí wọ́n bá wá Ọlọ́run.
Ìjẹ́rìí ńmáyọ̀, àlááfíà wá
Àtìrètí ìyè láéláé.
(ÈGBÈ)
Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.
A ńjẹ́rìí lọ láìbẹ̀rù.
Ọlọ́run wa alásọtẹ́lẹ̀;
Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ńṣẹ.
(Tún wo Aísá. 37:19; 55:11; Ìsík. 3:19.)