Orin 35
Ọpẹ́ fún Sùúrù Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọba alágbára,
O fẹ́ràn ohun tó dára.
Ìwà ibi ti gbayé kan,
A sì mọ̀ pé kò dùn mọ́ ọ.
Báwọn kan tiẹ̀ sọ pé o ńfalẹ̀;
O kò ní pẹ́ fòpin sí ibi.
A gbẹ́kẹ̀ lé ọ, a ńretí.
Ọpẹ́ fún sùúrù, òdodo rẹ.
2. Bí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá,
Bí ọjọ́ kan ni lójú rẹ.
Ọjọ́ ńlá rẹ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé;
Yóò sì dé láìjáfara.
Bí o tilẹ̀ kórìíra ẹ̀ṣẹ̀,
O fẹ́ ìyípadà ẹlẹ́ṣẹ̀.
A nírètí báa ti ńwọ̀nà.
Àwa fọpẹ́, ìyìn fóókọ rẹ.
(Tún wo Lúùkù 15:7; 2 Pét. 3:8, 9.)