Orin 110
Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run, o mọ bí mo ṣe ńsùn,
Bí mo ṣe máa ńjí, òun ìsinmi mi.
O rí èrò inú ọkàn mi lọ́hùn-ún,
O mọ ọ̀rọ̀ ẹnu mi,
àti ìrìn mi.
Àti bóo ṣe dá mi níkọ̀kọ̀,
Egungun mi kò pa mọ́ lójú rẹ.
Ẹ̀yà ara mi tún wà lákọọ́lẹ̀ rẹ.
Mo yìn ọ́ torí àgbàyanu
iṣẹ́ rẹ.
Ìmọ̀ rẹ jẹ́ ìyanu àti ẹ̀rù;
Ọkàn mi mọ èyí dáradára.
Bí ìbẹ̀rù òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀,
Ọlọrun, ẹ̀mí rẹ̀ lè kó mi yọ.
Jèhófà, kò síbi mo lè lọ,
Tí ojú rẹ kò fi ní lè tó mi.
Ì báà jẹ́ ibi gíga tàbí sàréè,
Ì báà jẹ́ inú òkùnkùn tàbí omi.
(Tún wo Sm. 66:3; 94:19; Jer. 17:10.)