Orin 47
Polongo Ìhìn Rere
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ó pẹ́ tí òótọ́ Ìjọba
náà ti pa mọ́.
A ti wá mòótọ́ nípa Irú-Ọmọ náà.
Jèhófà aláàánú tó fẹ́ ohun tó tọ́
Ṣàánú aráyé tó wà ní ipò ẹ̀ṣẹ̀.
Ó pinnu pé kọ́mọ òun
ṣàkóso ayé;
Pé aó bí Ìjọba náà lákòókò
tí ó tọ́.
Kó bàa lè ṣètò ìyàwó fún Ọmọ rẹ̀,
Ó yan agbo kékeré kan tó ṣe lógo.
2. Ìhìn rere ta ńpolongo
ti wà tipẹ́.
Àkókò yìí ni Jèhófà ńfẹ́ káyé gbọ́ọ.
Àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ńfayọ̀ kópa níbẹ̀,
Wọ́n ńtì wá lẹ́yìn báa ṣe ńkéde òtítọ́.
A ní àǹfààní àti ojúṣe lónìí
Láti ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́ ká sì yìnín.
Fún àwa Ẹlẹ́rìí tó ń jẹ́ orúkọ rẹ̀,
Ọlá ńlá ni pípolongo ìhìn rere.
(Tún wo Máàkù 4:11; Ìṣe 5:31; 1 Kọ́r. 2:1, 7.)