Orin 49
Jèhófà Ni Ibi Ìsádi Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
(Sáàmù 91)
1. Jèhófà ni ààbò wa,
Àtìgbẹ́kẹ̀lé wa.
Òjìji rẹ̀ lààbò wa;
Ibẹ̀ ni ká máa gbé.
Yóò pa wá mọ́ nínú ewu,
Ká gbẹ́kẹ̀ lé agbára rẹ̀.
Jèhófà lodi ààbò,
Tó ńpa gbogbo olóòótọ́ mọ́.
2. Bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ńṣubú
Ní ẹ̀gbẹ́ rẹ gan-gan,
Ewu kan kò ní wu ọ́,
Ní àárín olóòótọ́.
Ìwọ kò ní bẹ̀rùkẹ́rù,
Bíi pé ewu ńlá sún mọ́ ọ.
Ojú nìwọ yóò fi ríi,
Látabẹ́ ìyẹ́ Ọlọ́run.
3. Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí
O kó sí ìdẹkùn.
Ìbẹ̀rùbojo kò ní
Fa ìkọ̀sẹ̀ fún ọ.
O kì yóò bẹ̀rù kìnnìún;
Ìwọ yóò tẹ ṣèbé mọ́lẹ̀.
Jèhófà ni ààbò wa,
Tí yóò máa pa ọ̀nà wa mọ́.
(Tún wo Sm. 97:10; 121:3, 5; Aísá. 52:12.)