Orin 86
Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Sárà, Màríà, Ẹ́sítérì, Rúùtù
Àtàwọn yòókù tó jẹ́ aya rere,
Ìfọkànsìn Ọlọ́run jẹ wọ́n lọ́kàn.
Wọ́n nígbàgbọ́, a sì forúkọ mọ̀ wọ́n.
Àwọn míì náà rójúure Jèhófà,
Bá ò morúkọ wọn,
olóòótọ́ ni wọ́n jẹ́.
2. Ìṣòtítọ́, ìgboyà, inú rere,
Ànímọ́ rere tí aráyé ń fẹ́,
Làwọn obìnrin dáadáa wọ̀nyí gbé wọ̀.
Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n fáráyé.
Ẹ̀yin obìnrin, tó ńtọpasẹ̀ wọn,
Iṣẹ́ ayọ̀ lẹ̀ ńṣe,
ilé ayọ̀ lẹ̀ ńgbé.
3. Ìyá, ọmọbìnrin, aya, àtopó,
Ẹ̀ ńfínnúfíndọ̀ ṣiṣẹ́, tayọ̀tayọ̀.
Onírẹ̀lẹ̀ òun ìtẹríba ni yín,
Ẹ rójúure Ọlọ́run, ẹ má bẹ̀rù.
Ẹ̀yin obìnrin, kí Jáà máa ṣọ́ yín
Ìgbàgbọ́ yín dájú,
èrè yín ti dé tán.
(Tún wo Fílí. 4:3; 1 Tím. 2:9, 10; 1 Pét. 3:4, 5.)