Orin 80
Ìwà Rere
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Báa ti ńrí oore Jèhófà,
Láéláé lá máa dùn mọ́ wa.
Òun Baba wa ọ̀run sì jẹ́
Olóore lọ́nà gbogbo.
Ó ńṣojúure, ó sì ńṣàánú,
Táa kò lẹ́tọ̀ọ́ sí fún wa;
Òun nìkan ló yẹ ká máa sìn,
Òun la sì ńfìdùnnú sìn.
2. Ó dá wa ní àwòrán rẹ̀
Kí àwa náà bàa lè ní
Gbogbo ìwà rere tó ní
Ká máa ṣoore bíi tirẹ̀.
Kíwà rere wa máa pọ̀ síi,
Ká fìwà jọ Ọlọ́run.
Ká máa tọrọ ẹ̀mí mímọ́,
Ká lè máa so èso rẹ̀.
3. Àwọn táa jọ jónígbàgbọ́,
Táa jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ará
Ló yẹ ká máa ṣoore fún jù,
Ká ṣoore fáwọn míì náà.
Báa ti ńsọ̀rọ̀ Ìjọba náà
Àti ìrètí táa ní,
Ká má fo ẹnikẹ́ni dá;
Ká máa ṣoore àṣepé.
(Tún wo Sm. 103:10; Máàkù 10:18; Gál. 5:22; Éfé. 5:9.)