Orin 78
Ìpamọ́ra
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Aláṣẹ wa
Fọwọ́ ńlá mú orúkọ rẹ̀.
Ó ńwùú láti mú gbogbo
Ẹ̀gàn kúrò tán lórí rẹ̀.
Ó ti ńlo ìpamọ́ra
Bọ̀ látọdúnmọ́dún wá;
Sùúrù òun ìpamọ́ra
Tó ní kìí yára tán.
Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé ká gba
Onírúurú ènìyàn là.
Ìpamọ́ra òun sùúrù
Ọlọ́run kò ní já sásán.
2. A nílò ìpamọ́ra
Ká lè dúró lọ́nà ìyè.
Ó ńfi wá lọ́kàn balẹ̀,
Kìí jẹ́ kínú òdì bí wa.
A ńrí dáadáa ẹlòmíì,
A gbà pé ọ̀la yóò dáa.
Kìí jẹ́ ká ṣe àṣejù
Lákòókò ìnira.
Ìpamọ́ra àtàwọn
Ànímọ́ míì tẹ́mìí ńfún wa
Máa jẹ́ kí á lè tẹ̀ lé
Àpẹẹrẹ Ọlọ́run wa gan-an.
(Tún wo Ẹ́kís. 34:14; Aísá. 40:28; 1 Kọ́r. 13:4, 7; 1 Tím. 2:4.)