ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 5/15 ojú ìwé 16-20
  • Ẹ ni Ipamọra fun Gbogbo Eniyan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ ni Ipamọra fun Gbogbo Eniyan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jijẹ Onipamọra Pẹlu Awọn Arakunrin Wa
  • Laaarin Agbo Idile
  • Pẹlu Awọn Wọnni Lẹhin Ode
  • Igbagbọ ati Ireti Nṣe Iranlọwọ ninu Fifi Ipamọra Han
  • Adura, Irẹlẹ ọkan, ati Ifẹ Yoo Ṣeranlọwọ
  • Jẹ Onipamọra Pẹlu Ayọ Kẹ̀?
  • ‘Ẹ Fi Ìpamọ́ra Wọ Ara Yín Láṣọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Gbé Awọn Àwòkọ́ṣe Ipamọra Yẹ̀wò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Onípamọ́ra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìpamọ́ra
    Kọrin sí Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 5/15 ojú ìwé 16-20

Ẹ ni Ipamọra fun Gbogbo Eniyan

“Awa gbà yin niyanju, ẹyin ara, ẹ maa ṣí awọn oní ségesège leti, ẹ sọrọ ìtùnú fun awọn ọkan ti wọn sori kọ́, ẹ ṣe atilẹhin fun awọn alailera, ẹ ni ipamọra fun gbogbo eniyan.”—1 TẸSALONIKA 5:14, NW.

1. Nibo ati labẹ awọn ipo wo ni awọn Ẹlẹrii Jehofa ti fi ipamọra han?

IRU apẹẹrẹ wo ni awọn Ẹlẹrii Jehofa ode oni ti pese ninu jijẹ onipamọra! Wọn ti farada ọpọlọpọ inira ati inunibini ni awọn ilẹ Nazi ati Fascist ti igbakan ri ati ni awọn orilẹ-ede iru bii Malawi titi di akoko yii. Awọn wọnni ti wọn ngbe ninu agbo-ile ti o pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ niti isin tun nlo ipamọra pẹlu.

2. Awọn koko abajọ meji wo ni o fa paradise tẹmi tí awọn eniyan Jehofa ngbadun?

2 Laika inunibini ati awọn inira ti wọn ńnírìírí rẹ si, awọn eniyan Jehofa ti wọn ti ṣe ìyàsímímọ́ ti ngbadun awọn ibukun paradise tẹmi kan. Nitootọ, awọn otitọ fihan pe awọn Kristian ẹni ami-ororo bẹrẹ si gbadun rẹ ni ọdun 1919. Ki ni idi fun paradise tẹmi yii? Lakọọkọ na, awọn ipo ti paradise wọnyi wà laaarin awọn eniyan Jehofa nitori pe Ọlọrun ti mu awọn iranṣẹ rẹ ẹni ami-ororo padabọ si “ilẹ,” tabi ipo wọn, ti ijọsin mimọgaara. (Aisaya 66:7, 8) Paradise tẹmi gbilẹ pẹlu nitori olukuluku ti wọn wà ninu rẹ nfi awọn eso ẹmi ti Ọlọrun han. Ipamọra jẹ ọkan ninu ìwọ̀nyí. (Galatia 5:22, 23) Ijẹpataki animọ yii nigba ti o ba kan Paradise tẹmi wa ni a le ri lati inu gbolohun ọrọ yii lati ẹnu ọmọwe William Barclay: “Ko le si iru nǹkan bẹẹ gẹgẹ bii idapọ Kristian laisi makrothumia [ipamọra]. . . . Idi fun iyẹn si wulẹ jẹ eyi—pe makrothumia jẹ ami animọ titobi ti Ọlọrun (Roomu 2.4; 9.22).” (A New Testament Wordbook, oju-iwe 84) Bẹẹni, ipamọra ṣe pataki tóbẹ́ẹ̀!

Jijẹ Onipamọra Pẹlu Awọn Arakunrin Wa

3. Ẹkọ wo nipa nini ipamọra ni Jesu fi kọ Peteru?

3 Lọna hihan gbangba apọsteli Peteru ni iṣoro diẹ ni fifi ipamọra han, nitori oun beere lọwọ Jesu lẹẹkanri: “Oluwa, nigba meloo ni arakunrin mi yoo ṣẹ mi, ti emi o si fi ji? Titi di igba meje?” Jesu gbà á nimọran pe: “Emi ko wi fun ọ pe, titi di igba meje, bikoṣe titi di igba aadọrin meje.” (Matiu 18:21, 22) Ni ede miiran, ko si opin si iye igba ti awa nilati faradà á fun ara wa ẹnikinni keji ki a si dariji ẹnikan ti o ṣẹ wa. O ṣetan, awa ko le ronu pe ẹnikan yoo maa baa lọ ni kika iye ti o pọ to igba 77! Sibẹ jijẹ adarijini de iwọn yẹn dajudaju beere fun ipamọra.

4. Eeṣe ti awọn alagba ni pataki fi nilati ni ipamọra?

4 Nigba ti o ba kan ọran fifi ipamọra han lati ọdọ awọn arakunrin tẹmi, ko si iyèméjì pe awọn alagba ijọ nilati jẹ awofiṣapẹẹrẹ. Suuru wọn ni a le danwo nitori pe awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn kan lè jẹ alaibikita tabi onidagunla. Awọn miiran le maa fi akoko ṣofo nigba ti o ba kan ọran ṣiṣatunṣe awọn iwa baraku ti ko dara. Awọn alagba gbọdọ ṣọra ki wọn má tete maa binu tabi jẹ ẹni ti a ṣẹ si nitori awọn ailera Kristian arakunrin ati arabinrin wọn. Dipo bẹẹ, awọn oluṣọ agutan tẹmi wọnyi, nilati ranti imọran naa pe: “Njẹ o yẹ ki awa ti o lera iba ru ẹru ailera awọn alailera, ki a ma si ṣe ohun ti o wu araawa.”—Roomu 15:1.

5. Ki ni awa le farada bi a ba ni ipamọra?

5 Lẹhin naa, awọn iforigbari iwa animọ le dide nitori awọn ailera ati ìkù-díẹ̀ káàtó eniyan. Nitori awọn ikuna tabi iṣarasihuwa ti o yatọ, a mu awọn arakunrin wa binu lọna odi, ki a sọ ọ́ lọna bẹẹ, awọn pẹlu si le ṣe bẹẹ si wa. Nitori naa, bawo ni imọran naa ti baa mu tó pe: “Ẹ maa baa lọ ni fifarada fun ara yin ẹnikinni keji ati didariji ara yin ẹnikinni keji lọfẹẹ bi ẹnikẹni ba ni idi fun ìráhùn si ẹnikeji. Ani gẹgẹ bi Jehofa ti ndariji yin lọfẹẹ, bẹẹ ni ki ẹyin pẹlu maa ṣe.” (Kolose 3:13, NW) ‘Fifarada fun arawa ẹnikinni keji’ tumọ si jijẹ onipamọra, bi o tilẹ jẹ pe a le ni idi ti o lẹsẹ nilẹ fun ìráhùn lodisi ẹnikan. Awa ko gbọdọ gbẹsan tabi fiya jẹ arakunrin wa, ani ki a ma tilẹ mí ìmí ẹdun lodisi i paapaa.—Jakọbu 5:9.

6. Eeṣe ti jijẹ onipamọra fi jẹ ipa ọna ọgbọn?

6 Pẹlu itumọ kan naa ni imọran ti a ri ni Roomu 12:19 (NW): “Ẹ maṣe gbẹsan ara yin, olufẹ, ṣugbọn ẹ yago fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe: ‘Temi ni ẹsan; emi yoo san pada, ni Jehofa wi.’” ‘Yiyago fun ibinu’ tumọsi jijẹ alọra lati binu, tabi onipamọra. Fifi animọ yii han jẹ ipa ọna ọgbọn, nitori o ṣanfaani fun wa ati awọn elomiran. Bi iṣoro kan ba dide, awa funraawa yoo nimọlara lọna ti o daraju nipa jijẹ onipamọra, nitori pe awa ko mu ki awọn ọran tubọ buruju. Ẹni naa ti a lo ipamọra fun yoo tun nimọlara didaraju nitori pe awa ko fiya jẹ ẹ tabi gbẹsan ni ọna kan. Abajọ ti Pọọlu fi gba awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ niyanju lati ‘sọrọ itunu fun awọn ọkan ti wọn soríkọ́, ṣe atilẹhin fun awọn alailera, ni ipamọra fun gbogbo eniyan.’—1 Tẹsalonika 5:14, NW.

Laaarin Agbo Idile

7. Eeṣe ti awọn ẹni ti o ti gbeyawo fi nilati ni ipamọra?

7 A ti sọ ọ daradara pe igbeyawo alayọ jẹ isopọ awọn oludarijini rere meji. Ki ni iyẹn tumọ si? Pe awọn eniyan ti wọn ni igbeyawo alayọ jẹ onipamọra ninu ibalo wọn pẹlu araawọn. Awọn ẹnikọọkan saba maa ńfà mọ ara wọn nitori awọn iwa ẹda wọn ti ó jẹ odikeji gan-an sira. Awọn iyatọ wọnyi le fani lọkan mọra, sibẹ wọn tun le jẹ orisun èdèkòyedè ti o dakun awọn ikimọlẹ ati aniyan ti o ti nfa ki awọn Kristian ti wọn ti ṣegbeyawo ni “wahala nipa ti ara.” (1 Kọrinti 7:28) Fun apẹẹrẹ, ki a sọ pe ọkọ kan jẹ ẹni ti ndagunla si awọn kulẹkulẹ tabi ti o ni nitẹsi lati dabi ẹni ti ko bikita tabi ẹni ti o ri wúruwùru. Eyi le jẹ adanwo gan an fun aya rẹ. Ṣugbọn bi awọn imọran ti a fi inurere sọ ko ba ṣaṣeyọrisi rere kankan, oun le wulẹ nilati farada awọn ailera rẹ nipa jijẹ onipamọra.

8. Eeṣe ti awọn ọkọ fi le nilo ipamọra?

8 Ni ọwọ keji ẹwẹ, aya kan le maa ṣaniyan lori lori awọn kulẹkulẹ jù kí ó sì ṣeeṣe fun lati maa wijọ lé e lori. Eyi le mu iwe mimọ naa wa sọka daradara pe: “O dara lati gbe lori àjà ju lati ṣajọpin ile pẹlu aya ti nwijọ leni lori.” (Owe 25:24, Today’s English Version) Ni iru ọran kan bẹẹ, ipamọra ni a beere fun lati gba pẹlu imọran Pọọlu pe: “Ẹyin ọkọ, ẹ maa fẹran awọn aya yin, ẹ má si ṣe koro si wọn.” (Kolose 3:19) O tun gba ipamọra fun ọkọ lati kọbiara si imọran apọsteli Peteru pe: “Ẹyin ọkọ, ẹ maa fi oye ba awọn aya yin gbé, ẹ maa fi ọla fun aya, bi ohun èèlò ti ko lagbara, ati pẹlu bii ajumọ jogun ore-ọfẹ iye; ki adura yin ki o maa baa ni idena.” (1 Peteru 3:7) Nigba miiran awọn ailera aya le dan ọkọ kan wo, ṣugbọn ipamọra yoo ran án lọwọ lati farada wọn.

9. Eeṣe ti a fi nilo ipamọra ni iha ọdọ awọn obi?

9 Awọn obi nilati jẹ onipamọra bi wọn ba nilati ṣaṣeyọri si rere ninu titọ awọn ọmọ wọn. Awọn ọdọmọde le ṣe awọn aṣiṣe kan naa leralera. Wọn le dabii olori kunkun tabi ki wọn lọra lati kẹkọọ wọn si le maa dán awọn obi wọn wò leralera. Ni iru awọn ipo bẹẹ, awọn obi Kristian ni o jẹ ọranyan fun lati lọra ati binu, ni kiko itẹsi wọn lati binu tabi ipo ọkan wọn ni ìjánu ṣugbọn ki wọn ṣe jẹjẹ bi o ti lẹ jẹ pe wọn duro gbọyin fun awọn ilana ododo. Awọn baba nilati ranti pe awọn pẹlu ti jẹ ọmọde nigba kan ri ti wọn si ti ṣe aṣiṣe pẹlu. Wọn nilati fi imọran Pọọlu silo: “Ẹyin baba, ẹ maṣe mu awọn ọmọ yin binu, ki wọn maa baa rẹwẹsi.”—Kolose 3:21.

Pẹlu Awọn Wọnni Lẹhin Ode

10. Bawo ni a ṣe nilati huwa ni ibi ti a ti gbà wá siṣẹ, gẹgẹ bi a ti ríi nipa iriri wo?

10 Nitori aipe ati imọtara ẹni nikan eniyan, awọn ipo ti ko barade le dide ni ibi iṣẹ Kristian kan. O jẹ ipa ọna ọgbọn lati jẹ ọlọgbọn ẹwẹ ki a si farada awọn aitọ nitori alaafia. Ni fifi bi eyi ti le jẹ ọlọgbọn ninu tó han ni iriri Kristian kan ti o jẹ ojiya ọpọlọpọ aifohunṣọkan ti ẹni-agbà-síṣẹ́ ẹlẹgbẹ ti o jẹ onilara kan fà. Nitori pe arakunrin naa ko ka eyi si bàbàrà ṣugbọn o jẹ onipamọra, laipẹ oun lè bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu ẹni-agbà-síṣẹ́ naa ti o ti jẹ oniwahala.

11. Nigba wo ni pataki ni a ti nilati jẹ onipamọra, eesitiṣe?

11 Ni pataki ni awọn eniyan Jehofa fi nilati jẹ onipamọra nigba ti wọn bá njẹrii fun awọn wọnni ti wọn wà lẹhin ode ijọ Kristian. Leralera, awọn Kristian nṣalabaapade idahun pada alafojudi ti o lekoko. Yoo ha bojumu tabi ba ọgbọn mu lati dahun pada lọna ti o farajọra bi? Bẹẹkọ, nitori iyẹn ki yoo fi ipamọra han. Ipa ọna ọgbọn ni lati ranti ki a si tẹle owe ọlọgbọn naa pe: “Idahun pẹlẹ yi ibinu pada; ṣugbọn ọrọ lile ni iru ibinu soke.”—Owe 15:1.

Igbagbọ ati Ireti Nṣe Iranlọwọ ninu Fifi Ipamọra Han

12, 13. Awọn animọ wo ni wọn yoo ran wa lọwọ lati ni ipamọra?

12 Ki ni o le ran wa lọwọ lati fi ipamọra han, lati faradà á pẹlu ipo ti nbani ninu jẹ́? Ohun kan ni igbagbọ ninu awọn ileri Ọlọrun. A gbọdọ gba ọrọ Ọlọrun gbọ. Iwe mimọ sọ pe: “Ko si idanwo kan ti o tii ba yin, bikoṣe iru eyi ti o mọniwọn fun eniyan: Ṣugbọn olododo ni Ọlọrun, ẹni ti ki yoo jẹ ki a dan yin wo ju bi ẹyin ti le gba a; ṣugbọn ti yoo si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwo naa, ki ẹyin ki o le gbà á.” (1 Kọrinti 10:13) Ni ede miiran, gẹgẹbi alakoko pipẹ kan ti sọ ọ: “Bi Ọlọrun ba faye gba a, mo le gba a.” Bẹẹni, awa le gba a bi a ba jẹ onipamọra.

13 Eyi ti o tan mọ igbagbọ pẹkipẹki ni ireti ninu Ijọba Ọlọrun. Nigba ti ó ba gba iṣakoso lori ilẹ-aye, gbogbo awọn ipo buburu ti o nfa idaamu fun wa ni a o mu kuro. Ni ọna yii, Dafidi onisaamu naa wipe: “Dakẹ inu bibi, ki o si kọ ikannu silẹ: Maṣe ikanra, ki o maa baa ṣe buburu pẹlu. Nitori a o ké awọn oluṣe buburu kuro: Ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yoo jogun aye.” (Saamu 37:8, 9) Ireti didaju pe Ọlọrun yoo mu awọn ipo adanniwo wọnyi kuro laipẹ ran wa lọwọ lati jẹ onipamọra.

14. Iriri wo ni o fi idi ti a fi nilati ni ipamọra si olubaṣegbeyawo alaigbagbọ kan han?

14 Bawo ni awa ṣe nilati huwa pada bi olubaṣegbeyawo alaigbagbọ kan ba kó idaamu ba wa? Maa baa lọ ni wiwa iranlọwọ Ọlọrun, ki o si maa baa lọ ni nini ireti pe aṣodisini naa yoo di olujọsin Jehofa. Aya Kristian kan maa ńkọ́ nigba miiran lati gbọ́ ounjẹ fun ọkọ rẹ ki o si fọ awọn aṣọ rẹ. O nlo ede ẹlẹgbin, ko si ni bá a sọrọ fun ọpọlọpọ ọjọ, koda o tilẹ gbiyanju lati fèèdì mu un nipasẹ iṣe àjẹ́. Ọkunrin naa wipe, “Ṣugbọn mo yiju si Jehofa ninu adura ni gbogbo igba, mo si nigbẹkele ninu Rẹ lati ran mi lọwọ lati mu animọ rere ti ipamọra dagba ki nma baa sọ iwadeedee Kristian mi nu. Mo tun nireti pe ni ọjọ kan ipo ọkan rẹ yoo yipada.” Lẹhin 20 ọdun iru iwahihu sini bẹẹ, aya rẹ bẹrẹ sii yipada, ọkunrin naa si wipe: “Bawo ni mo ti kun fun ọpẹ si Jehofa to pe o ran mi lọwọ lati mu eso tẹmi, ipamọra dagba, nitori pe mo le ri iyọrisi naa nisinsinyi: Aya mi ti bẹrẹ sii rin ni oju ipa ọna iye!”

Adura, Irẹlẹ ọkan, ati Ifẹ Yoo Ṣeranlọwọ

15. Eeṣe ti adura fi le ran wa lọwọ lati ni ipamọra?

15 Adura tun jẹ iranlọwọ titobi miiran ninu fifi ipamọra han. Pọọlu rọni pe: “Ẹ maṣe aniyan ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ maa fi ibeere yin han fun Ọlọrun. Ati alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ, yoo ṣọ ọkan ati ero yin ninu Kristi Jesu.” (Filipi 4:6, 7) Tun ranti lati kọbiara si iṣileti naa pe: “Ko ẹru rẹ lọ si ara Oluwa [“Jehofa,” NW], oun ni yoo si mu ọ duro.”—Saamu 55:22.

16. Ninu jijẹ onipamọra, bawo ni irẹlẹ ọkan ṣe le ran wa lọwọ?

16 Irẹlẹ ọkan tun jẹ iranlọwọ titobi miiran ninu mimu ipamọra ti o jẹ eso ti ẹmi dagba. Onigberaga kan kii farabalẹ. Oun ni a tete maa nṣẹ si, o tete maa nbinu, ki yoo si faye gba hihuwa ti ko barade sini. Gbogbo eyi jẹ idakeji jijẹ onipamọra. Ṣugbọn onirẹlẹ kan ki yoo ka ara rẹ si pataki ju. Oun yoo duro de Jehofa, gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe nigba ti a ndọdẹ rẹ lati ọwọ Ọba Sọolu ti a si takubu sii lati ọdọ Ṣimei ara Bẹnjamẹni naa. (1 Samuẹli 24:4-6; 2 Samuẹli 16:5-13) Nipa bayi, awa nilati nifẹẹ ọkan lati rin ‘pẹlu irẹlẹ ero inu pipeperepere ati iwa pẹlẹ, pẹlu ipamọra, ni fifarada a fun ara wa ẹnikinni keji ninu ifẹ.’ (Efesu 4:2, NW) Ju bẹẹ lọ, awa nilati ‘rẹ araawa silẹ ni oju Jehofa.’—Jakọbu 4:10, NW.

17. Eeṣe ti ifẹ yoo fi ran wa lọwọ lati ni ipamọra?

17 Ni pataki ni ifẹ alainimọtara ẹni nikan nran wa lọwọ lati jẹ onipamọra. Nitootọ, “ifẹ a maa nipamọra,” nitori o nmu ki a ni ire didarajulọ ti awọn ẹlomiran ni ọkan. (1 Kọrinti 13:4) Ifẹ fun wa lagbara lati ni igbatẹniro, lati fi ara wa sinu ipo awọn ẹlomiran, ki a sọ bẹẹ. Ju bẹẹ lọ, ifẹ ran wa lọwọ lati jẹ onipamọra nitori pe “o nmu ohun gbogbo mọra, o ngba ohun gbogbo gbọ́, o nreti ohun gbogbo, o nfara da ohun gbogbo. Ifẹ kii kuna lae.” (1 Kọrinti 13:7, 8, NW) Bẹẹni, gẹgẹ bi orin Ijọba nọmba 200 ninu iwe naa Kọrin Iyin Si Jehofah ti sọ ọ:

“Ifẹ nwo ohun rere.

Ifẹ ngbe ara wọn ró.

Ifẹ ṣeun fun aṣako,

O ntọ wọn sọna rere.”

Jẹ Onipamọra Pẹlu Ayọ Kẹ̀?

18. Bawo ni o ti ṣeeṣe lati ni ipamọra pẹlu ayọ?

18 Pọọlu gbadura pe ki a kún awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ ni Kolose pẹlu imọ pipeye nipa ifẹ-inu Ọlọrun ki wọn baa le maa rin ni yiyẹ ti Jehofa, ki wọn wù ú, ki wọn si so eso ninu iṣẹ rere gbogbo. A o tipa bayi ‘sọ wọn di alagbara pẹlu gbogbo agbara titi de agbara iwọn ologo rẹ ki wọn ba le farada a ni kikun ki wọn si ni ipamọra pẹlu ayọ.’ (Kolose 1:9-11) Sibẹ, bawo ni ẹnikan ṣe le ni “ipamọra pẹlu ayọ”? iyẹn ko takora, nitori nini ayọ ti a mẹnukan ninu Iwe mimọ kii wulẹ ṣe ọran jijẹ ọlọkan fifuyẹ tabi ọlọyaya. Eso ayọ ti ẹmi naa ni imọlara itẹlọrun jijinlẹ lori ṣiṣe ohun ti o tọna niwaju Ọlọrun ninu. O tun jẹ ifihan ireti ti ireti gbigba ere ti a ṣe ileri rẹ gẹgẹ bi iyọrisi lilo ipamọra. Idi niyẹn ti Jesu fi wipe: “Alayọ ni ẹyin nigba ti awọn eniyan ba nkẹgan yin ti wọn si nṣe inunibini si yin ti wọn si nfi irọ sọrọ ohun buruku gbogbo lodisi yin nitori mi. Ẹ maa yọ̀ ki ẹ si fo soke fun idunnu, niwọn bi ere yin ti pọ ni inu awọn ọrun; nitori pe ni ọna yẹn ni wọn ṣe inunibini si awọn wolii ti wọn wà ṣaaju yin.”—Matiu 5:11, 12, NW.

19. Awọn apẹẹrẹ wo ni o fihan pe o ṣeeṣe lati ni ipamọra ki a si kun fun ayọ lẹẹkan naa?

19 Jesu ni iru ayọ bẹẹ. Nitootọ, “nitori ayọ ti a gbeka iwaju rẹ, o farada igi oró, o tẹmbẹlu itiju.” (Heberu 12:2, NW) Ayọ yẹn fún Jesu lagbara lati ni ipamọra. Lọna ti o farajọra, gbe ohun ti o ṣẹlẹ yẹwo nigba ti a na awọn apọsteli lọ́rẹ́ ti a si paṣẹ fun wọn lati “maṣe sọrọ ni orukọ Jesu mọ.” Wọn “lọ kuro niwaju ajọ igbimọ: wọn nyọ nitori ti a ka wọn yẹ si iya ijẹ nitori orukọ rẹ. Ati ni ojoojumọ ni tẹmpili ati ni ile, wọn ko dẹkun kikọni ati lati waasu Jesu Kristi.” (Iṣe 5:40-42) Iru apẹẹrẹ rere wo ti o fihan pe awọn ọmọlẹhin Kristi le ni ipamọra pẹlu ayọ!

20. Bi a ba fi ipamọra han, bawo ni eyi ṣe le nipa lori ibatan wa pẹlu awọn ẹlomiran?

20 Dajudaju Ọrọ Ọlọrun funni ni imọran ọlọgbọn nigba ti o gbà wá niyanju lati maṣe gbẹsan, lati lọra ati binu nigba ti a nwọna fun ohun didara julọ—bẹẹni, lati ni ipamọra! A nilo adura deedee ati eso ẹmi Ọlọrun yii lati wa ni alaafia pẹlu awọn arakunrin ati arabinrin wa ninu ijọ, pẹlu awọn wọnni ninu agbo idile, pẹlu awọn eniyan ni ibi iṣẹ wa, ati pẹlu ẹnikọọkan ti a nba pade ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian. Ki ni o si le ran wa lọwọ lati fi ipamọra han? Igbagbọ, ireti, irẹlẹ ọkan, ayọ, ati ifẹ. Nitootọ, pẹlu iru awọn animọ bẹẹ awa le ni ipamọra fun gbogbo eniyan.

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Eeṣe ti ipamọra fi ṣe pataki fun ṣiṣajọpin wa ninu paradise tẹmi?

◻ Eeṣe ti awọn alagba ni pataki fi nilo ipamọra?

◻ Eeṣe ti awọn ọkọ ati aya fi nilati mu ipamọra dagba?

◻ Awọn animọ miiranwo ni yoo ran wa lọwọ lati ni ipamọra?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Imọran wo lati ọdọ Jesu ni o ran Peteru lọwọ lati ni ipamọra?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́