Gbé Awọn Àwòkọ́ṣe Ipamọra Yẹ̀wò
“Ọlọrun . . . fi ọpọlọpọ ipamọra faaye gba awọn koto ibinu ti a mu yẹ fun iparun.”—ROOMU 9:22, NW.
1. (a) Bawo ni Ọrọ Ọlọrun ti a mísí ṣe ṣiṣẹ fun anfaani wa? (b) Ni isopọ pẹlu eyi, eeṣe ti a fi gbé animọ ipamọra yẹwo nihin-in?
JEHOFA ỌLỌRUN, Ẹlẹdaa wa, fun wa ni Ọrọ onimiisi rẹ, Bibeli Mimọ. O jẹ lati ṣiṣẹ gẹgẹbi ‘fitila si ẹsẹ wa ati imọlẹ si ipa ọna wa.’ (Saamu 119:105) Ọrọ Ọlọrun tun ran wa lọwọ lati di awọn “ti a ti mura silẹ patapata fun iṣe rere gbogbo.” (2 Timoti 3:16, 17) Ọna kan ti o ngba mura wa silẹ ni nipa fifun wa ni awọn àwòkọ́ṣe ipamọra. Animọ yii jẹ ọkan lara awọn eso ẹmi Ọlọrun o si jẹ koṣeemani fun jijere itẹwọgba rẹ ki a si maa baa lọ ni iṣọkan pẹlu awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa.—Galatia 5:22, 23.
2. Ki ni itumọ ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “ipamọra,” ta si ni òléwájú ninu fifi animọ yii han?
2 Ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “ipamọra” lọna olowuuru tumọ si “gigun ti ẹmi.” Ipamọra ni a tumọ gẹgẹ bi “animọ ti kíká ara ẹni lọ́wọ́ kò loju ibinu eyi ti kii fi ikanju gbẹsan tabi fiya jẹni ni wàràǹṣeṣà.” (Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words, lati ọwọ W. E. Vine, Idipọ 3, oju-iwe 12) Lati jẹ onipamọra tumọsi lati lo ikora-ẹni-nijanu ki a si lọra lati binu. Ta ni ẹni ti o si gba ipo iwaju julọ lara awọn wọnni ti wọn lọra lati binu, ni fifi ipamọra han? Ko si ẹlomiiran ju Jehofa Ọlọrun. Nipa bayi, ni Ẹkisodu 34:6, a ka pe Jehofa jẹ “alaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ ni oore ati otitọ.” Niti tootọ, Jehofa ni a sọrọ rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o “lọra lati binu” ni igba mẹjọ sii ninu iwe mimọ.—Numeri 14:18; Nehemaya 9:17; Saamu 86:15; 103:8; 145:8; Joẹli 2:13; Jona 4:2; Nahumu 1:3.
3. Awọn animọ wo ni o ṣalaye idi fun jijẹ ti Jehofa jẹ onipamọra?
3 Jijẹ onipamọra, tabi alọra lati binu, wulẹ jẹ ohun ti a le reti lati ọdọ Jehofa Ọlọrun nitori oun jẹ alailopin ni agbara ati ọgbọn, ẹni pipe ni idajọ-ododo, ati apẹẹrẹ pipe ifẹ gan an. (Deuteronomi 32:4; Joobu 12:13; Aisaya 40:26; 1 Johanu 4:8) O ni iṣakoso lori awọn animọ rẹ ni pipa wọn mọ ni wiwadeedee pipe ni gbogbo igba. Ki ni Ọrọ rẹ ṣipaya nipa idi rẹ̀ ati bi oun ṣe fi ipamọra han si awọn eniyan alaipe?
Ipamọra Nitori Orukọ Rẹ
4. Fun awọn idi rere wo ni Ọlọrun ṣe fi ipamọra han si awọn ẹlẹṣẹ?
4 Eeṣe ti Jehofa fi ni ipamọra? Eeṣe ti oun ko fiya jẹ awọn ẹlẹṣẹ loju ẹsẹ? Kii ṣe nitori idagunla tabi ainitara fun iwa ododo. Bẹẹkọ, ṣugbọn fun awọn idi rere Jehofa lọra lati binu kii si fiya jẹ awọn eniyan ni wàràǹṣeṣà. Idi kan ni ki a ba le sọ orukọ rẹ di mimọ. Idi miiran ni pe ó gba akoko lati yanju awọn ariyanjiyan ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun ati iwatitọ araye, ti a gbe dide nipasẹ iṣọtẹ ni Edeni. Sibẹ idi miiran fun ipamọra Ọlọrun ni pe o fun awọn alaṣiṣe ni anfaani lati fi tun awọn ọna wọn ṣe.
5, 6. Eeṣe ti Jehofa ṣe fi ipamọra han ni isopọ pẹlu iṣọtẹ eniyan?
5 Jehofa ni ipamọra ninu biba awọn eniyan meji akọkọ lo ninu ọgba Edẹni. Nigba ti wọn ṣẹ si aṣẹ rẹ lodisi jijẹ eso igi imọ rere ati buburu, oun ti le fi iya iku jẹ awọn ati angẹli ẹlẹṣẹ naa ti o tan Efa jẹ lẹsẹkẹsẹ. Ko si iyemeji pe imọlara iwa ododo ati idajọ ododo Jehofa ni a ti mu binu, pe oun binu si awọn ọlọtẹ mẹta naa. Oun iba ti wà lori ẹtọ rẹ lọna pipe bi oun ba ti fiya iku jẹ wọn loju kan naa. Ọlọrun ti kilọ fun ọkunrin akọkọ Adamu pe: “Ninu igi imọ rere ati buburu nì, iwọ ko gbọdọ jẹ ninu rẹ: nitori pe ni ọjọ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ kiku ni iwọ o ku.” (Jẹnẹsisi 2:17) Lọjọ naa gan an ti Adamu dẹṣẹ, Ọlọrun pe awọn olùrélànà kọjá naa wa lati jihin o si kede aṣẹ ijiya iku. Lọna ti ó bá idajọ mu, Adamu ati Efa ku ni ọjọ yẹn. Sibẹ, Ẹlẹdaa wa onipamọra jẹ ki Adamu walaaye fun 930 ọdun.—Jẹnẹsisi 5:5.
6 Ọlọrun ni awọn idi rere fun jijẹ onipamọra, tabi alọra ati binu, ninu ọran yii. Bi oun ba ti fiya iku jẹ awọn ọlọtẹ wọnni loju ẹsẹ, eyi kì bá tí dahun ọrọ ẹgan Eṣu alaiṣe taarata naa pe Jehofa Ọlọrun ko yẹ lẹni ti a lè jọsin ati pe oun ko le ni awọn iranṣẹ eniyan ti wọn yoo pa iwatitọ wọn sii mọ́ laika awọn ipo ti o yí wọn ká si. Ju bẹẹ lọ, iru awọn ibeere gẹgẹ bi iwọnyi ni à bá ti fi silẹ laidahun: aṣiṣe ta ni o jẹ pe Adamu ati Efa dẹṣẹ? Njẹ Jehofa ha dá wọn lakọọkọ gẹgẹ bi alailera niti iwahihu debi pe wọn ko le kọju ija si adanwo ti o si wa fiya jẹ wọn fun kikuna lati ṣe bẹẹ? Idahun si gbogbo eyi ni o han gbangba lati inu akọsilẹ ti a ri ninu iwe Joobu, ori kìn-ínní ati keji. Nipa yiyọnda fun iran eniyan lati pọ̀ sii, Jehofa yọnda awọn eniyan lati ni anfaani lati fi awọn ẹsun Satani han bi eke.
7. Eeṣe ti Jehofa ko fi fiya iku jẹ Farao loju ẹsẹ?
7 Nigba ti Jehofa fẹ dá awọn eniyan rẹ, awọn ọmọ Isirẹli nide kuro ninu oko ẹru Ijibiti, oun tun fihan pe oun jẹ ẹni ti o ni ipamọra. Jehofa ti lè pa Farao ati awọn ọmọ-ogun ologun rẹ run lẹsẹkẹsẹ. Bi o ti wu ki o ri, dipo ṣiṣe eyi, Ọlọrun faye gba wọn fun akoko kan. Fun awọn idi rere wo? O dara, bi akoko ti nlọ, Farao tubọ di alagidi sii ninu kíkọ̀ rẹ lati jẹki awọn ọmọ Isirẹli fi Ijibiti silẹ gẹgẹ bi awọn eniyan olominira ti Jehofa. Oun tipa bayii fihan pe oun jẹ́ ‘koto ibinu’ kan ti o lẹtọọ si iparun fun ṣíṣàyàgbàǹgbà pe Jehofa nija. (Roomu 9:14-24) Sibẹ, idi pupọ sii wa ti Ọlọrun fi ni ipamọran ninu ọran yii. Nipasẹ Mose, oun sọ fun Farao pe: “Nisinsinyi, emi iba na ọwọ mi, ki emi ki o le fi ajakalẹ arun lu ọ, ati awọn eniyan rẹ; a ba si ti ké ọ kuro lori ilẹ. Ṣugbọn nitori eyi paapaa ni emi ṣe mu ọ duro, lati fi agbara mi han lara rẹ; ati ki a le rohin orukọ mi ká gbogbo aye.”—Ẹkisodu 9:15, 16.
8. Fun idi wo ni Ọlọrun ko ṣe fiya iku jẹ awọn ọmọ Isirẹli ọlọtẹ ninu aginju?
8 Ipamọra Jehofa ni a tun fihan fun awọn idi rere nigba ti awọn ọmọ Isirẹli wà ninu aginju. Ẹ wò ó bi wọn ti dan suuru Ọlọrun wò tó nipa jijọsin ọmọ maluu oniwura ati nipa kikuna lati mu igbagbọ lò nigba ti awọn amí mẹwaa pada pẹlu irohin buruku! Ọlọrun kò nù wọn nù kuro gẹgẹ bi eniyan rẹ̀ niwọn bi o ti jẹ pe orukọ rere ati iyì rẹ̀ wepọ mọ́ ọn. Bẹẹni, Jehofa fi ipamọra han nititori orukọ rẹ̀.—Ẹkisodu 32:10-14; Numeri 14:11-20.
Ipamọra Nititori Awọn Eniyan
9. Eeṣe ti Jehofa fi fi ipamọra han ni awọn ọjọ Noa?
9 Jehofa ti jẹ onipamọra nititori iran eniyan lati igba ti Adamu ti ṣẹ gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ọjọ ọla, ni hihuwa àìbẹ́tọ̀ọ́mu nlanla si wọn nipa didẹṣẹ. Ipamọra Ọlọrun mu ki o ṣeeṣe fun aitọ yẹn lati di eyi ti a mú tọ́ niti pe o yọnda akoko fun awọn eniyan onironupiwada lati di onilaja pẹlu rẹ̀. (Roomu 5:8-10) Jehofa Ọlọrun tun fi ipamọra hàn si awọn eniyan ni ọjọ Noa. Ni akoko yẹn, “Ọlọrun [“Jehofa,” NW] sì rii pe iwa buburu eniyan di pupọ ni aye, ati pe gbogbo ero ọkan rẹ̀ kiki ibi ni lojoojumọ.” (Jẹnẹsisi 6:5) Bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ti lè run iran eniyan kuro gbàrà lẹhin ti oun ti ri ipo yii, oun ṣofin pe oun yoo mu opin wa si ipo yii ni 120 ọdun. (Jẹnẹsisi 6:3) Ifihan jade ipamọra yii yọnda akoko fun Noa lati ni awọn ọmọkunrin mẹta, fun wọn lati dagba ki wọn sì gbeyawo, ati fun idile yẹn lati kọ́ aaki fun igbala ọkan wọn ati fun pipa iṣẹda ẹranko mọ́ láàyè. Ni ọna yii o ṣeeṣe fun ète Ọlọrun fun ilẹ aye lati di eyi ti ọwọ́ tẹ̀.
10, 11. Eeṣe ti Jehofa fi jẹ onipamọra tóbẹ́ẹ̀ pẹlu orilẹ-ede Isirẹli?
10 Itumọ miiran fun ipamọra niiṣe pẹlu awọn ibalo Ọlọrun pẹlu awọn eniyan rẹ̀ ni pataki. O jẹ “ifarada onisuuru ti iwa aitọ tabi imunibinu, ti a papọ pẹlu kíkọ̀ lati sọ ireti nù fun isunwọn sii ninu ipo ibatan ti o ti bajẹ naa.” (Insight on the Scriptures, Idipọ 2, oju-iwe 262; ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.) Eyi tọkasi afikun idi ti Ọlọrun fi jẹ onipamọra si awọn ọmọ Isirẹli. Leralera ni wọn yipada kuro lọdọ Jehofa ti wọn sì wá sinu oko ẹru awọn orilẹ-ede Keferi. Sibẹ, oun fi ipamọra han nipa dida awọn ọmọ Isirẹli nide ti o sì fun wọn ni anfaani lati ronupiwada.—Onidaajọ 2:16-20.
11 Eyi ti o pọ julọ ninu awọn ọba Isirẹli ṣamọna awọn ọmọ abẹ wọn sinu ijọsin eke. Njẹ Ọlọrun ha ta orilẹ-ede naa nù lẹsẹkẹsẹ bi? Bẹẹkọ, oun kò tete sọ ireti fun isunwọn sii nù ninu ipo ibatan ti a bajẹ naa. Kaka bẹẹ, Jehofa lọra lati binu. Ni fifi ipamọra han, leralera ni Ọlọrun fun wọn ni anfaani lati ronupiwada. A kà ni 2 Kironika 36:15, 16 pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun awọn baba wa sì ranṣẹ si wọn lati ọwọ́ awọn onṣẹ rẹ̀, o ndide ni kutukutu, o sì nranṣẹ, nitori ti o ni ìyọ́nú si awọn eniyan rẹ̀, ati si ibugbe rẹ̀. Ṣugbọn wọn fi awọn onṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, wọn sì kẹgan ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọn sì fi awọn wolii rẹ̀ ṣẹ̀sín, titi ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW] fi ru si awọn eniyan rẹ̀, ti kò fi si atunṣe.”
12. Ẹri wo ni Iwe mimọ Kristian lede Giriiki fifunni nipa idi ti Jehofa fi jẹ onipamọra?
12 Iwe mimọ Kristian lede Giriiki tun pese ẹri pe Jehofa fi ipamọra hàn lati ran awọn eniyan rẹ̀ ti wọn ti ṣakolọ lọwọ. Fun apẹẹrẹ, apọsteli Pọọlu beere lọwọ awọn Kristian olùrélànà kọja pe: “Tabi ẹyin ńgan ọrọ̀ oore ati ipamọra ati suuru rẹ̀, si àìmọ̀ pe oore Ọlọrun ti o fà yin lọ si ironupiwada?” (Roomu 2:4) Pẹlu itumọ kan naa ni awọn ọ̀rọ̀ Peteru pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] kò fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran ti nka ijafara; ṣugbọn o nmu suuru fun yin nitori kò fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbe, bikoṣe ki gbogbo eniyan ki o wà si ironupiwada.” (2 Peteru 3:9) Lọna yiyẹ julọ, a sọ fun wa lati “kà á si pe suuru Oluwa wa igbala ni.” (2 Peteru 3:15) Nipa bayii, a rii pe Jehofa jẹ onipamọra, kii ṣe nitori ailera tabi ìgbojú bọ̀rọ̀ idẹra, ṣugbọn nitori pe orukọ ati awọn ète rẹ̀ wémọ́ ọn oun sì jẹ alaanu ati onifẹẹ.
Apẹẹrẹ Ipamọra ti Jesu
13. Ẹri ti o ba Iwe mimọ mu wo ni o wà nibẹ pe Jesu Kristi jẹ onipamọra?
13 Kiki eyi ti o ṣekeji si apẹẹrẹ ipamọra tí Ọlọrun filelẹ jẹ ti Ọmọkunrin rẹ̀, Mesaya naa, Jesu Kristi. Oun jẹ apẹẹrẹ titayọ ti ikara ẹni lọ́wọ́kò laifi ikanju gbẹsan loju imunibinu si.a Pé Mesaya naa yoo jẹ onipamọra ni a sọtẹlẹ ṣaaju lati ẹnu wolii Aisaya ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: “A jẹ ẹ́ ni ìyà, a sì pọ́n ọn loju, ṣugbọn oun kò ya ẹnu rẹ̀: a mú un wa bi ọdọ agutan fun pipa, ati bi agutan ti o yadi niwaju olùrẹ́run rẹ̀, bẹẹ ni kò ya ẹnu rẹ̀.” (Aisaya 53:7) Eyi ti njẹri si otitọ kan naa ni gbolohun ọrọ Peteru: “Ẹni, nigba ti a kẹgan rẹ̀, ti kò sì pada kẹgan; nigba ti o jiya, ti kò sì kilọ, ṣugbọn o fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ le ẹni ti nṣe idajọ ododo lọwọ.” (1 Peteru 2:23) Bawo ni awọn ọmọ ẹhin Jesu ti gbọdọ ti dán an wò tó pẹlu asọ̀ wọn igbagbogbo lori ẹni ti o tobi julọ! Sibẹ, ẹ wòó bi oun ti jẹ onipamọra ati onisuuru pẹlu wọn tó!—Maaku 9:34; Luuku 9:46; 22:24.
14. Ki ni apẹẹrẹ Jesu ti jijẹ onipamọra nilati sún wa lati ṣe?
14 Awa nilati tẹle apẹẹrẹ ti Jesu filelẹ ni jijẹ onipamọra. Pọọlu kọwe pe: “Ẹ jẹ ki awa pẹlu mu gbogbo ẹru wiwuwo ati ẹ̀ṣẹ̀ ti o fi tirọruntirọrun wepọ mọ wa kuro, ẹ sì jẹ ki a fi ifarada sá eré ìje ti a gbeka iwaju, gẹgẹ bi a ti ntẹjumọ Olori Aṣoju ati alaṣepe igbagbọ wa, Jesu. Nitori ayọ̀ ti a gbeka iwaju rẹ̀, o farada igi oró, o tẹmbẹlu itiju, o sì ti jokoo ni ọwọ́ ọtun itẹ Ọlọrun. Nitootọ, ẹ gbé e yẹwo finnifinni ẹni naa ti o ti farada iru ọ̀rọ̀ òdì bẹẹ lati ẹnu awọn ẹlẹṣẹ lodisi anfaani ire tiwọn funraawọn ki ẹ ma baa ṣàárẹ̀ ki ẹ si rẹwẹsi ninu ọkan yin.”—Heberu 12:1-3, NW.
15. Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu jẹ onipamọra pe ó sì farada awọn idanwo pẹlu imuratan?
15 Pe Jesu jẹ onipamọra ati pe o farada awọn adanwo pẹlu imuratan ni a lè ri lati inu ihuwasi ti o fihan ni akoko ti a ifaṣẹ ọba mu un. Lẹhin biba Peteru wi fun gbigbe idà soke lati daabobo Ọ̀gá rẹ̀, Jesu wipe: “Iwọ ṣe bi emi kò lè kepe Baba mi, oun ìbá sì fun mi ju legioni angẹli mejila lọ loju kan naa yii? Ṣugbọn Iwe Mimọ yoo ha ti ṣẹ, pe bẹẹ ni yoo rí?”—Matiu 26:51-54; Johanu 18:10, 11.
Awọn Apẹẹrẹ Miiran Ti Ipamọra
16. Bawo ni Iwe mimọ ṣe fihan pe Josẹfu ọmọkunrin Jakọbu jẹ onipamọra?
16 Ani awọn eniyan alaipe, ti wọn kun fun ẹ̀ṣẹ̀ paapaa le fi ipamọra hàn. Iwe mimọ lede Heberu ni awọn apẹẹrẹ ifarada onisuuru fun awọn aitọ ni iha ọdọ awọn eniyan alaipe. Fun apẹẹrẹ, a ní Josẹfu, ọmọkunrin Jakọbu olori idile Heberu naa. Bawo ni o ti fi suuru farada awọn aiṣedajọ ododo ti a hù sii lati ọwọ́ awọn arakunrin ọmọ baba rẹ̀ ati lati ọwọ́ aya Pọtifari tó! (Jẹnẹsisi 37:18-28; 39:1-20) Josẹfu ko yọnda awọn adanwo wọnyi lati mú un banujẹ. Eyi ni a fihan gbangba nigba ti o sọ fun awọn arakunrin rẹ̀ pe: “Ẹ maṣe banujẹ, ki ẹ ma sì ṣe binu si araayin, niti pe ẹyin tà mi si ihin: nitori pe Ọlọrun ni o ran mi siwaju yin lati gba ẹ̀mí là.” (Jẹnẹsisi 45:4, 5) Iru apẹẹrẹ rere wo ti ipamọra ni Josẹfu fi lelẹ!
17, 18. Ẹri ipamọra wo ni a ní ninu ọran Dafidi?
17 Dafidi jẹ apẹẹrẹ miiran ti iranṣẹ Jehofa oluṣotitọ ti o farada awọn aitọ pẹlu suuru, ni fifi ipamọra han. Bi o ti jẹ pe oun ni Ọba Sọọlu òjòwú ńlé kiri bi aja, ni igba meji ni Dafidi ìbá ti gbẹsan nipa pípa á. (1 Samuẹli 24:1-22; 26:1-25) Ṣugbọn Dafidi duro de Ọlọrun, gẹgẹ bi a ti lè ríi lati inu awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ si Abiṣai pe: “Oluwa yoo pa [Sọọlu], tabi ọjọ rẹ̀ yoo sì pe ti yoo ku, tabi oun yoo sọkalẹ lọ si ibi ija a sì ṣègbé nibẹ. Oluwa ma jẹ ki emi na ọwọ́ mi si ẹni ami ororo Oluwa.” (1 Samuẹli 26:10, 11) Bẹẹni, o wà ni agbara Dafidi lati fi opin si idọdẹ rẹ̀ lati ọwọ́ Sọọlu. Kaka bẹẹ, Dafidi yàn lati jẹ onipamọra.
18 Tun gbe ohun ti o ṣẹlẹ yẹwo nigba ti Ọba Dafidi nsalọ kuro lọwọ Absalomu ọmọkunrin rẹ̀ aládàkàdekè. Ṣimei, ara Bẹnjamin kan lati ile Sọọlu, sọ okuta lu Dafidi ó sì nfi í ré, ni pipariwo pe: “Jade, jade, iwọ ọkunrin ẹ̀jẹ̀, iwọ ọkunrin Beliali.” Abiṣai fẹ ki a pa Ṣimei, ṣugbọn Dafidi kọ̀ lati gbẹsan. Bi o ti wu ki o ri, dipo ṣiṣe iyẹn, oun tun fi animọ ipamọra han lẹẹkan sii.—2 Samuẹli 16:5-13.
Gbe Apẹẹrẹ Pọọlu Yẹwo
19, 20. Bawo ni apọsteli Pọọlu ṣe fi ara rẹ han lati jẹ onipamọra?
19 Ninu Iwe mimọ Kristian lede Giriiki, a ni apẹẹrẹ rere miiran ti ipamọra ni iha ọdọ eniyan alaipe kan—apọsteli Pọọlu. Oun fi ifarada onisuuru, ipamọra han, ni isopọ pẹlu awọn ọta rẹ̀ onisin ati pẹlu awọn ẹni kọọkan ti wọn fẹnujẹwọ pe awọn jẹ Kristian. Bẹẹni, Pọọlu fi ipamọra han bi o tilẹ jẹ pe awọn kan ninu ijọ ni Kọrinti wipe: “Iwe rẹ̀ wuwo wọn sì lagbara; ṣugbọn irisi rẹ̀ jẹ alailera, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ko nilari.”—2 Kọrinti 10:10; 11:5, 6, 22-33.
20 Nitori naa, pẹlu idi rere, Pọọlu sọ fun awọn ara Kọrinti pe: “Ni ohun gbogbo awa nfi ara wa han bi awọn iranṣẹ Ọlọrun, ninu ọpọlọpọ suuru, ninu ipọnju, ninu aini, ninu wahala, nipa ìnà, ninu tubu, nipa irukerudo, nipa ìṣẹ́, ninu iṣọra, ninu igbaawẹ; nipa iwa mimọ, nipa ìmọ̀, nipa ipamọra, nipa iṣeun, nipa ẹmi mimọ, nipa ifẹ aiṣẹtan.” (2 Kọrinti 6:4-6) Ni iru ọna ti o farajọra, apọsteli naa le kọwe si oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ Timoti pe: “Iwọ ti mọ ẹkọ mi, igbesi-aye mi, ipinnu, igbagbọ, ipamọra, ifẹni, suuru, inunibini, ìyà; . . . Oluwa si gbàmi kuro ninu gbogbo wọn.” (2 Timoti 3:10, 11) Iru apẹẹrẹ rere wo ni apọsteli Pọọlu fi lelẹ fun wa ninu jijẹ onipamọra!
21. Bawo ni ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e ṣe le ran wa lọwọ lati ṣe?
21 Ni kedere, Iwe mimọ kun fun awọn apẹẹrẹ rere ti ipamọra. Jehofa ati Ọmọkunrin rẹ aayo olufẹ jẹ́ awọn apẹẹrẹ titayọ. Ṣugbọn bawo ni o ti funni niṣiiri to lati ṣakiyesi pe animọ yii ni a ti fihan lati ọdọ awọn eniyan alaipe, iru bii Josẹfu, Dafidi, ati apọsteli Pọọlu! Ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e ni a pète lati ran wa lọwọ lati ṣafarawe iru awọn apẹẹrẹ rere bẹẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lati jẹ onipamọra ko tumọ ni ṣakala si lati jiya fun ìgbà pipẹ. Bi a ba pin ẹnikan ti njiya fun ìgbà pipẹ lẹmii tabi mú un banujẹ nitori ailagbara lati gbẹsan, oun ki yoo jẹ onipamọra.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni o tumọsi lati jẹ onipamọra?
◻ Jehofa ti jẹ onipamọra ni pataki fun awọn idi wo?
◻ Ni awọn ọna wo ni Jesu gbà fi ara rẹ han lati jẹ onipamọra?
◻ Ẹri ti o ba Iwe mimọ mu wo ni o wà nibẹ pe ipamọra ni a le fihan lati ọdọ awọn eniyan alaipe?
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Josefu, Jesu, Joobu, Dafidi, ati Pọọlu jẹ awọn àwòkọ́ṣe ipamọra
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jesu fi ipamọra han si awọn ọmọ-ẹhin rẹ