ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 6 ojú ìwé 9
  • Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Mi Ò Ní Fi Ìwà Títọ́ Mi Sílẹ̀!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóòbù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Èrè Jobu—Orísun kan Fún Ìrètí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 6 ojú ìwé 9
Eéwo wà ní gbogbo ara Jóòbù

Apá 6

Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́

Sátánì ò gbà pé tọkàntọkàn ni Jóòbù fi ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìyẹsẹ̀, àmọ́ Jóòbù ń bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jèhófà nìṣó

ǸJẸ́ a lè rí èèyàn èyíkéyìí tá máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, tó bá dojú kọ àdánwò dé góńgó, tó sì dà bíi pé ṣíṣègbọràn ò mú àǹfààní tara kankan wá? Ìbéèrè yìí àti ìdáhùn rẹ̀ ò ṣẹ̀yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì wà ní Íjíbítì, Jóòbù, tó jẹ́ ìbátan Ábúráhámù, ń gbé níbi tá a mọ̀ sí Arébíà lónìí. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run pé jọ níwájú Ọlọ́run, Sátánì ọlọ̀tẹ̀ sì wà láàárín wọn. Jèhófà jẹ́ káwọn áńgẹ́lì náà mọ̀ pé òun fọkàn tán Jóòbù, ìránṣẹ́ òun olóòótọ́. Kódà, Jèhófà sọ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn míì tó jẹ́ oníwà títọ́ bíi ti Jóòbù. Àmọ́, Sátánì wonkoko pé torí pé Ọlọ́run ń bù kún Jóòbù tó sì ń dáàbò bò ó ló mú kó máa sìn ín. Sátánì tẹnu mọ́ ọn pé bí Ọlọ́run bá gba gbogbo ohun tí Jóòbù ní kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ó máa bú Ọlọ́run.

Àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run pé jọ sọ́dọ̀ Jèhófà, Sátánì náà sì wà níbẹ̀

Ọlọ́run yọ̀ọ̀da fún Sátánì láti gbéjà ko Jóòbù, ó kọ́kọ́ pa ọrọ̀ rẹ̀ run, ó pa àwọn ọmọ rẹ̀, lẹ́yìn náà ló wá fi àìsàn kọ lù ú. Jóòbù ò mọ̀ pé Sátánì ló wà lẹ́yìn gbogbo àjálù yìí, torí náà ó ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó fà á tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn àdánwò yìí dé bá òun. Síbẹ̀, Jóòbù ò sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run.

Àwọn ọ̀rẹ́ àbòsí mẹ́ta wá sọ́dọ̀ Jóòbù. Nínú ọ̀rọ̀ jàn-ànràn jan-anran tí wọ́n sọ, èyí tó kúnnú ìwé Jóòbù, wọ́n fi àìmọ̀kan mọ̀kàn fẹ́ láti yí Jóòbù lérò pa dà kó lè gbà pé torí ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ tóun dá ni Ọlọ́run ṣe ń han òun léèmọ̀. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé inú Ọlọ́run kì í dùn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kì í sì í fọkàn tán wọn. Jóòbù ò fara mọ́ èrò òdì wọn. Pẹ̀lú ìdánilójú, Jóòbù polongo pé òun máa pa ìwà títọ́ òun mọ́ títí tóun fi máa kú!

Àmọ́, àṣìṣe tí Jóòbù ṣe ni pé ó dá ara ẹ̀ láre ju bó ṣe yẹ lọ. Ọkùnrin kan tó kéré lọ́jọ́ orí sí gbogbo wọn, ìyẹn Élíhù, tó ti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ tí gbogbo wọ́n sọ látòkè délẹ̀, wá sọ tẹnu ẹ̀ wàyí. Élíhù bá Jóòbù wí torí pé kò fiyè sí i pé ìdáláre ipò Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣe pàtàkì ju ìdáláre ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lọ fíìfíì. Élíhù tún bá àwọn ọ̀rẹ́ àbòsí wọ̀nyẹn wí gidigidi.

Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run bá Jóòbù sọ̀rọ̀, ìyẹn sì mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà. Jèhófà lo ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu tó wà nínú ìṣẹ̀dá láti mú kí Jóòbù rí i pé òun kéré sí Ọlọ́run, ẹni tí títóbi rẹ̀ ò láàlà. Jóòbù fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí Ọlọ́run fún un. Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti jẹ́ “oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni” àti “aláàánú,” ó mú kí ara Jóòbù yá, ó dá ọrọ̀ rẹ̀ pa dà fún un ní ìlọ́po méjì, ó sì bí ọmọ mẹ́wàá mìíràn. (Jákọ́bù 5:11) Bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́, nígbà tó wà lábẹ́ àdánwò líle koko, fi hàn pé irọ́ ni Sátánì pa pé kò sí ẹ̀dá èèyàn tá máa bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run nìṣó bó bá dojú kọ àdánwò.

​—A gbé e ka ìwé Jóòbù.

  • Látàrí ohun tí Sátánì sọ nípa Jóòbù, ìbéèrè wo ló wáyé?

  • Kí ni àbájáde bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ ẹ̀ sí Jèhófà mọ́?

ÀWỌN Ọ̀RÀN PÀTÀKÌ

Nígbà tí Sátánì sọ pé ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan ló mú kí Jóòbù, ọkùnrin aláìlẹ́bi tó bẹ̀rù Ọlọ́run jù lọ lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn máa sìn Jèhófà Ọlọrun, ohun tó ń sọ ni pé bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú gbogbo ẹ̀dá olóye yòókù náà nìyẹn. Sátánì tipa bẹ́ẹ̀ mú káwọn èèyàn máa ṣiyè méjì nípa ohun tó ń mú kí wọ́n máa pa ìwà títọ́ wọn sí Jèhófà mọ́. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀ràn pàtàkì tí Sátánì dá sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, pé bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ, àti pé bóyá ó ń lo ipò rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Ìwé Jóòbù fi hàn pé àwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì tí Ọlọ́run dá lè pa kún ìdáláre ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, bí wọ́n bá pa ìwà títọ́ wọn sí I mọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́