ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jr orí 2 ojú ìwé 14-192
  • Ṣíṣe Iṣẹ́ Ọlọ́run ní “Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣe Iṣẹ́ Ọlọ́run ní “Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́”
  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ NÍGBÀ AYÉ JEREMÁYÀ
  • ÌYÍPADÀ BÁ Ọ̀RỌ̀ ÌJỌSÌN NÍLẸ̀ JÚDÀ
  • “KÍ O SÌ KỌ GBOGBO Ọ̀RỌ̀” NÁÀ
  • ÌJỌBA BÁBÍLÓNÌ DI AGBÁRA AYÉ
  • ÌGBÀ TÍ ÌṢÀKÓSO ÀWỌN ỌBA LÁTI ÌLÀ ÌDÍLÉ DÁFÍDÌ FẸ́RẸ̀Ẹ́ DÓPIN
  • OHUN TÍ JEREMÁYÀ ṢE LÁÀÁRIN ÀWỌN ÈÈYÀN JÚDÀ TÓ ṢẸ́ KÙ
  • Àwọn Wo Ló Yẹ Kó O Yàn Lọ́rẹ̀ẹ́?
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi sí Ẹnu Rẹ”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Béèrè Lójoojúmọ́ Pé, “Jèhófà Dà?”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Jèhófà Ti Ṣe Ohun Tí ó Ní Lọ́kàn”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
Àwọn Míì
Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
jr orí 2 ojú ìwé 14-192

ORÍ KEJÌ

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ọlọ́run Ní “Apá Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọjọ́”

1, 2. (a) Ìran wo ni Jeremáyà rí tó jẹ́ kí irú ọ̀rọ̀ tó máa kéde tètè hàn kedere? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀ nípa ohun tí Jeremáyà kéde?

ỌLỌ́RUN bi Jeremáyà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di wòlíì rẹ̀ pé: “Kí ni ìwọ rí?” Ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà Jeremáyà bá dáhùn pé: “Ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀ tí a ń fẹ́ atẹ́gùn sí ni mo rí, ẹnu rẹ̀ sì wà níhà àríwá.” Ìran tó rí yìí jẹ́ kí irú ọ̀rọ̀ tó máa kéde tètè hàn kedere. (Ka Jeremáyà 1:13-16.) Kì í ṣe torí kí ìkòkò ìṣàpẹẹrẹ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí bàa lè tutù ni wọ́n ṣe ń fẹ́ atẹ́gùn sí i o, wọ́n ń fẹ́ atẹ́gùn náà láti fi fínná mọ́ ọn ni. Ní kúkúrú, ṣe ni Jèhófà ń sọ tẹ́lẹ̀ pé, ìyọnu tó dà bí ohun olómi gbígbóná tó ń hó yaya máa dà sórí ilẹ̀ Júdà látinú ìkòkò yìí, torí ìwà àìṣòótọ́ tó gbòde kan níbẹ̀. Kí lo rò pé ó jẹ́ kí wọ́n yí ẹnu ìkòkò yìí síhà gúúsù? Ìdí tí wọ́n fi yí i síbẹ̀ ni pé ìhà àríwá ni ìyọnu ti ń bọ̀ wá sórí wọn, apá ibẹ̀ ni Bábílónì ti máa gbógun wá jà wọ́n. Bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Láàárín àwọn ọdún tí Jeremáyà fi ṣe wòlíì, ọ̀pọ̀ ìgbà ló rí i pé wọ́n da ìyọnu jáde látinú ìkòkò yìí, títí tó fi yọrí sí ìparun Jerúsálẹ́mù.

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bábílónì kò sí mọ́ lónìí, ó yẹ kó o mọ̀ nípa àwọn ohun tí Jeremáyà kéde, èyí tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé a wà ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” tí ọ̀pọ̀ ti ń sọ pé Kristẹni làwọn, àmọ́ tínú Ọlọ́run kò dùn sí àwọn àti ṣọ́ọ̀ṣì wọn. (Jer. 23:20) Yàtọ̀ síyẹn, àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí dà bíi Jeremáyà, nítorí pé kì í ṣe ìdájọ́ tó ń bọ̀ nìkan là ń wàásù, a tún ń sọ ọ̀rọ̀ tó ń fún àwọn èèyàn nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14

3. (a) Báwo ni wọ́n ṣe to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé Jeremáyà? (b) Kí ni a fi Orí Kejì tá a wà yìí ṣe?

3 Ó jọ pé kì í ṣe pé Jeremáyà kọ àwọn ohun tó wà nínú ìwé rẹ̀ sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣẹlẹ̀, ìgbà tí iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ ń parí lọ ló sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ fún akọ̀wé kan pé kó kọ ọ́ sílẹ̀. (Jer. 25:1-3; 36:1, 4, 32) Jeremáyà ò kọ ìwé rẹ̀ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kọ ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ bí kókó ọ̀rọ̀ wọn ṣe tẹ̀ léra. Nítorí náà, o máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú bá a ṣe fi Orí Kejì tá a wà yìí ṣe àkópọ̀ ìtàn ohun tó fa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ìwé Jeremáyà àti Ìdárò àti bí nǹkan wọ̀nyẹn ṣe ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 19. Tó o bá mọ ẹni tó jẹ́ ọba Júdà bí ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe ń wáyé, tó o sì tún mọ ohun tó ń lọ nílẹ̀ Júdà àti àgbègbè rẹ̀ nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtó wáyé, wàá túbọ̀ lóye ìdí tí Jeremáyà fi sọ àwọn ohun tó sọ àti ìdí tó fi ṣe àwọn ohun tó ṣe. Èyí á jẹ́ kó o lè túbọ̀ jàǹfààní nínú àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kí Jeremáyà jẹ́ fáwọn èèyàn òun.

ÀWỌN OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ NÍGBÀ AYÉ JEREMÁYÀ

4-6. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú kí Jeremáyà tó di wòlíì, báwo ni ipò nǹkan ṣe rí láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run?

4 Ìgbà tí nǹkan ò fara rọ ni Jeremáyà sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Ó jẹ́ ìgbà tí ilẹ̀ Ásíríà, Bábílónì àti Íjíbítì jọ ń faga gbága. Nǹkan bí ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93] ṣáájú kí Jeremáyà tó di wòlíì ni ilẹ̀ Ásíríà ti ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá, tó sì kó púpọ̀ lára wọn lọ sí ìgbèkùn. Nígbà yẹn, Jèhófà dáàbò bo Jerúsálẹ́mù àti Hesekáyà olóòótọ́ ọba tó wà níbẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Ásíríà tó wá gbógun jà wọ́n. Wàá rántí pé Ọlọ́run ṣá ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] balẹ̀ lára ọmọ ogun Ásíríà lọ́nà ìyanu. (2 Ọba 19:32-36) Ara àwọn ọmọ Hesekáyà ni Mánásè. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọdún karùndínlọ́gọ́ta ìṣàkóso Mánásè yìí ni wọ́n bí Jeremáyà. Lákòókò yẹn, ilẹ̀ Júdà ti wà lábẹ́ ìjọba Ásíríà.—2 Kíró. 33:10, 11.

5 Jeremáyà yìí ló kọ ìwé Àwọn Ọba Kìíní àti Ìkejì, ó sì sọ níbẹ̀ pé Mánásè tún àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ pa run kọ́. Ó gbé àwọn pẹpẹ kalẹ̀ fún Báálì àti fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, kódà ó ṣe wọ́n sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ó sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀ ní ìwọ̀n púpọ̀, àní ó tiẹ̀ sun ọmọ ara rẹ̀ nínú iná sí òrìṣà. Ní kúkúrú, “ìwọ̀n púpọ̀ gan-an ni ó ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” Gbogbo ìwà burúkú yìí ló mú kí Ọlọ́run sọ pé irú àjálù tó bá Samáríà àti Ísírẹ́lì náà máa dé bá Jerúsálẹ́mù àti Júdà. (2 Ọba 21:1-6, 12-16) Lẹ́yìn ikú Mánásè, Ámọ́nì ọmọ rẹ̀ náà rawọ́ lé gbogbo àṣà ìbọ̀rìṣà baba rẹ̀, àmọ́ kò pẹ́ sígbà náà tí àyípadà fi dé. Ó ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn ọdún méjì, wọ́n pa Ámọ́nì, wọ́n sì fi ọmọ rẹ̀ Jòsáyà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ jọba lọ́dún 659 ṣáájú Sànmánì Kristẹni [Ṣ.S.K.].

6 Láàárín ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n tí Jòsáyà fi ṣàkóso, Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í borí Ásíríà. Jòsáyà wá lo àǹfààní èyí láti mú ilẹ̀ Júdà kúrò lábẹ́ ìṣàkóso àwọn ìjọba ilẹ̀ òkèèrè. Jòsáyà kò dà bí baba rẹ̀ àti baba ńlá rẹ̀. Ó jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn, ó mú káwọn èèyàn pa ìbọ̀rìṣà tì kí wọ́n sì máa ṣe ìsìn tòótọ́. (2 Ọba 21:19–22:2) Ní ọdún kejìlá ìṣàkóso rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ àwọn ibi gíga àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀ àti àwọn ère ní gbogbo ìjọba rẹ̀, lẹ́yìn náà ó pàṣẹ pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe. (Ka 2 Kíróníkà 34:1-8.) Ọdún kẹtàlá ìjọba Jòsáyà yìí (647 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) ni Ọlọ́run sọ Jeremáyà di wòlíì.

Ká ní pé o jẹ́ wòlíì nígbà ayé Jeremáyà, báwo làwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà náà ṣe máa rí lára rẹ?

7, 8. (a) Kí ló mú kí ìṣàkóso Jòsáyà Ọba yàtọ̀ sí ti Mánásè àti Ámọ́nì tó jọba ṣáájú rẹ̀? (b) Irú èèyàn wo ni Jòsáyà? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 20.)

7 Nígbà tí wọ́n ń ṣàtúnṣe tẹ́ńpìlì lọ́dún kejìdínlógún ìṣàkóso Jòsáyà ọba rere, àlùfáà àgbà rí “ìwé òfin gan-an.” Ọba ní kí akọ̀wé òun kà á fóun. Bí Jòsáyà ṣe wá rí i pé àwọn èèyàn òun ti dẹ́ṣẹ̀ gan-an, ó ní kí Húlídà wòlíì obìnrin bá òun wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ó sì rọ àwọn èèyàn ìjọba rẹ̀ pé kí wọ́n máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Húlídà sọ fún Jòsáyà pé Jèhófà yóò mú “ìyọnu àjálù” wá sórí àwọn ará Júdà torí ìwà àìṣòótọ́ wọn, àmọ́ nítorí pé Jòsáyà fẹ́ràn ìsìn tòótọ́, ìyọnu àjálù náà kò ní ṣẹlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀.—2 Ọba 22:8, 14-20.

Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 19

8 Ni Jòsáyà Ọba bá tẹra mọ́ mímú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà. Kódà, ìtara tó ní fún ìsìn tòótọ́ yìí gbé e dé àgbègbè tó wà lábẹ́ ìjọba àríwá Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀ rí, tó fi lọ wó ibi gíga àti pẹpẹ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì. Ó tún rí sí i pé wọ́n ṣe Ìrékọjá kan tó ta yọ. (2 Ọba 23:4-25) Èyí á sì dùn mọ́ Jeremáyà nínú gan-an ni! Ṣùgbọ́n ó ṣòro láti mú káwọn èèyàn náà yí ìṣe wọn pa dà. Mánásè àti Ámọ́nì ti jẹ́ kí ìbọ̀rìṣà tó burú jáì mọ́ àwọn èèyàn náà lára débi pé ìsìn tòótọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ sí lọ́kàn wọn mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jòsáyà ṣakitiyan gan-an láti mú ìsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò, Ọlọ́rùn ṣì ní kí Jeremáyà sọ fún àwọn ará Júdà pé bí ìlù ńlá wọn ṣe pọ̀ tó ni òrìṣà wọn ṣe pọ̀. Àwọn ará Júdà ìgbà ayé Jeremáyà dà bí aya aláìṣòótọ́ nítorí pé wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀ wọ́n lọ ń ṣe aṣẹ́wó lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà ilẹ̀ òkèèrè. Jeremáyà kéde pé: “Àwọn pẹpẹ tí ó sì pọ̀ bí àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù ti pọ̀ tó ni ẹ̀yin ti mọ fún ohun ìtìjú, àwọn pẹpẹ láti máa fi rú èéfín ẹbọ sí Báálì.”—Ka Jeremáyà 11:1-3, 13.

9. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè láwọn ọdún tó kẹ́yìn ìṣàkóso Jòsáyà?

9 Bí àwọn Júù kò ṣe yí pa dà pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ tí Jeremáyà jẹ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tó ń du gbogbo àgbègbè náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́ kò ṣe jáwọ́. Lọ́dún 632 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Bábílónì àti tàwọn ará Mídíà para pọ̀ ṣẹ́gun ìlú Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú Ásíríà. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, Fáráò Nékò ọba Íjíbítì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ síhà àríwá láti lọ ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn ará Ásíríà táwọn ọ̀tá gbógun tì. Fún ìdí tí Bíbélì kò sọ, Jòsáyà gbìyànjú láti dá àwọn ọmọ ogun Íjíbítì pa dà ní Mẹ́gídò, àmọ́ ṣe ló fara gbọgbẹ́ ikú. (2 Kíró. 35:20-24) Àyípadà wo ni ikú rẹ̀ máa wá mú bá ìjọba àti ọ̀rọ̀ ìjọsìn ní Júdà? Àwọn ìṣòro míì wo ni Jeremáyà bá pàdé?

ÌYÍPADÀ BÁ Ọ̀RỌ̀ ÌJỌSÌN NÍLẸ̀ JÚDÀ

10. (a) Báwo ni ìgbà tó yí pa dà lẹ́yìn ikú Jòsáyà ṣe jọra pẹ̀lú àkókò òde òní? (b) Àǹfààní wo la máa jẹ tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí Jeremáyà ṣe nígbà ìṣòro?

10 Ẹ wo bó ṣe máa dun Jeremáyà tó nígbà tó gbọ́ pé Jòsáyà kú. Ìbànújẹ́ yẹn mú kó kọrin arò lórí ikú ọba náà. (2 Kíró. 35:25) Lákòókò yẹn, ọkàn àwọn ará Júdà ò balẹ̀ rárá, rògbòdìyàn tó wà láàárín àwọn ọba ilẹ̀ òkèèrè alágbára tún kó ilẹ̀ Júdà sí wàhálà. Àwọn ọba yìí, ìyẹn ọba Íjíbítì, Ásíríà àti Bábílónì, ń bára wọn du ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní gbogbo àgbègbè Júdà. Bákan náà, lẹ́yìn ikú Jòsáyà, àwọn èèyàn Júdà kò kọbi ara sí ìsìn tòótọ́ mọ́. Bí àsìkò tí Jeremáyà ti lè ṣe iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ fàlàlà ṣe parí nìyẹn tí ìjọba tí kò fara mọ́ iṣẹ́ rẹ̀ sì gorí àlééfà. Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni irú àyípadà bẹ́ẹ̀ ti bá, tó jẹ́ pé nígbà kan wọ́n á lómìnira dé ìwọ̀n àyè kan láti máa ṣèjọsìn wọn lọ, àmọ́ tí nǹkan á kàn dédé yí pa dà tí wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sí wọn, tí wọ́n á sì fòfin de iṣẹ́ wọn. Irú àyípadà bẹ́ẹ̀ sì lè kan èyíkéyìí nínú wa nígbàkigbà. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ipa wo ló máa ní lórí wa? Kí la máa ní láti ṣe ká lè dúró ṣinṣin? Bá a ṣe ń ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìṣòro tí Jeremáyà bá pàdé tó sì borí wọn. Ìyẹn yóò fún ìgbàgbọ́ wa lágbára.

JÒSÁYÀ NI ỌBA RERE TÍ JÚDÀ NÍ GBẸ̀YÌN

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20

Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà nígbà tó di ọba lẹ́yìn ikú Ámọ́nì baba rẹ̀. Nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run, ó sì “ń rìn ní gbogbo ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀.” Nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wó ibi tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà ní Júdà àti Ísírẹ́lì, ó sì ń fọ́ òrìṣà wọn dà nù. Nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ó ní kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe.—2 Ọba 21:19–22:2; 2 Kíró. 34:2-8.

Bí wọ́n ti ń tún tẹ́ńpìlì ṣe, wọ́n rí ìwé Òfin, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ èyí tí Mósè fúnra rẹ̀ kọ gan-an. Wọ́n kà á sétígbọ̀ọ́ Jòsáyà. Ó wá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì sunkún. Jòsáyà ṣètò pé kí wọ́n ka ìwé náà sétígbọ̀ọ́ àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo èèyàn ìjọba rẹ̀, yálà ẹni ńlá tàbí ẹni kékeré. Ìtàn Bíbélì náà sọ pé ọba dá májẹ̀mú “pé òun yóò máa fi gbogbo ọkàn-àyà àti gbogbo ọkàn tọ Jèhófà lẹ́yìn àti pé òun yóò pa àwọn àṣẹ rẹ̀ . . . mọ́.” Lẹ́yìn èyí, Jòsáyà túbọ̀ lọ káàkiri ní Júdà àti Ísírẹ́lì láti mú ìbọ̀rìṣà kúrò. Ọba yìí sì ṣe Ìrékọjá ńlá kan sí Jèhófà, irú èyí tí wọn kò ṣe rí ní Ísírẹ́lì láti àwọn ọjọ́ Sámúẹ́lì.—2 Kíró. 34:14–35:19.

11. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Júdà lẹ́yìn ikú Jòsáyà?

11 Lẹ́yìn ikú Jòsáyà, àwọn ará Júdà fi Jèhóáhásì ọmọ rẹ̀ jọba ní Jerúsálẹ́mù. Oṣù mẹ́ta péré ni Jèhóáhásì, tó tún ń jẹ́ Ṣálúmù, fi ṣàkóso. Bí Fáráò Nékò ṣe ń pa dà bọ̀ lápá gúúsù láti ogun tó lọ bá àwọn ará Bábílónì jà, ó rọ Jèhóáhásì ọba tuntun yìí lóyè, ó sì mú un lọ sí Íjíbítì. Jeremáyà sì sọ pé Jèhóáhásì “kì yóò padà mọ́.” (Jer. 22:10-12; 2 Kíró. 36:1-4) Nékò wá fi ọmọ Jòsáyà míì, ìyẹn Jèhóákímù, jọba nípò rẹ̀. Àmọ́ Jèhóákímù kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere baba rẹ̀. Dípò kó máa ṣe ìsìn tòótọ́ tí baba rẹ̀ mú bọ̀ sípò, òrìṣà ló ń bọ.—Ka 2 Ọba 23:36, 37.

12, 13. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ ìjọsìn ṣe rí nígbà ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Jèhóákímù? (b) Kí làwọn aṣáájú ìsìn àwọn Júù ṣe sí Jeremáyà?

12 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Jèhóákímù, Jèhófà ní kí Jeremáyà lọ sọ ọ́ gbangba gbàǹgbà ní tẹ́ńpìlì pé ìwà ibi táwọn ará Júdà ń hù kò dáa. Àwọn èèyàn náà ti gbà pé tẹ́ńpìlì Jèhófà máa dáàbò bo àwọn lábẹ́ ipòkípò. Ṣùgbọ́n tí wọn ò bá jáwọ́ nínú ‘jíjalè, ṣíṣìkàpànìyàn àti ṣíṣe panṣágà àti bíbúra lọ́nà èké àti rírú èéfín ẹbọ sí Báálì àti títọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn,’ Jèhófà yóò kọ tẹ́ńpìlì rẹ̀ sílẹ̀. Yóò kọ àwọn alágàbàgebè tó ń jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì náà sílẹ̀ bó ṣe kọ àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò sílẹ̀ nígbà ayé Élì Àlùfáà Àgbà. Ilẹ̀ Júdà yóò sì wá di “ibi ìparundahoro pátápátá.” (Jer. 7:1-15, 34; 26:1-6)a Ẹ ò rí i pé ó máa gba ìgboyà gan-an fún Jeremáyà láti lè jíṣẹ́ ìkìlọ̀ yẹn fáwọn èèyàn! Ó ṣeé ṣe kó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣojú àwọn èèyàn jàǹkàn jàǹkàn ló ti sọ ọ́ fáwọn èèyàn. Lóde òní, àwọn ará wa kan lọ́kùnrin àti lóbìnrin náà ti rí i pé àwọn nílò ìgboyà láti lè wàásù ní òpópónà tàbí láti bá àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn èèyàn jàǹkàn jàǹkàn sọ̀rọ̀. Àmọ́, ohun kan dá wa lójú: Ọlọ́run tó ti Jeremáyà lẹ́yìn náà ń bẹ lẹ́yìn wa.—Héb. 10:39; 13:6.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22

13 Kí làwọn aṣáájú ìsìn ṣe lórí ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ pẹ̀lú gbogbo bí ipò ọ̀rọ̀ ìjọsìn àti ti ìṣèlú ṣe wà ní Júdà nígbà yẹn? Ohun tí wòlíì Jeremáyà alára sọ ni pé: “Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà gbá [mi] mú, wọ́n wí pé: ‘Dájúdájú, ìwọ yóò kú.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, ṣe ni wọ́n gbaná jẹ, tí wọ́n ní: “Ìdájọ́ ikú tọ́ sí ọkùnrin yìí.” (Ka Jeremáyà 26:8-11.) Àmọ́ ṣá, àwọn ọ̀tá Jeremáyà kò rí i pa o. Jèhófà wà lẹ́yìn wòlíì rẹ̀ yìí gbágbáágbá láti gbà á sílẹ̀. Jeremáyà alára kò jẹ́ kí ojú àwọn alátakò rẹ̀ tó korò lágbárí wọn tàbí pípọ̀ tí wọ́n pọ̀ dẹ́rù ba òun. Má ṣe jẹ́ kí àwọn alátakò dẹ́rù ba ìwọ náà.

Ìyàtọ̀ wo lo wà nínú bí nǹkan ṣe rí nígbà ìjọba Mánásè, Ámọ́nì àti ti Jòsáyà? Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ nínú irú ọwọ́ tí Jeremáyà fi mú iṣẹ́ rẹ̀ tó gba ìgboyà gan-an?

“KÍ O SÌ KỌ GBOGBO Ọ̀RỌ̀” NÁÀ

14, 15. (a) Iṣẹ́ wo ni Jeremáyà àti Bárúkù akọ̀wé rẹ̀ ṣe ní ọdún kẹrin ìjọba Jèhóákímù? (b) Irú èèyàn wo ni Jèhóákímù? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 25.)

14 Ní ọdún kẹrin ìjọba Jèhóákímù, Jèhófà sọ pé kí Jeremáyà kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí òun ti sọ fún un láti ìgbà ayé Jòsáyà sínú ìwé. Nítorí náà, Jeremáyà sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti ń sọ fún un láti ọdún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn fún Bárúkù akọ̀wé rẹ̀, Bárúkù sì ń kọ ọ́ sílẹ̀. Ó tó ogún ọba àti ilẹ̀ ọba tó kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fún. Jeremáyà sì wá sọ fún Bárúkù pé kó lọ ka àkájọ ìwé tó kọ ọ̀rọ̀ náà sí létígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn nílé Jèhófà. Kí nìdí tó fi ní kó lọ kà á? Jèhófà sọ pé: “Bóyá àwọn ará ilé Júdà yóò fetí sí gbogbo ìyọnu àjálù tí mo ń ronú láti mú wá sórí wọn, kí olúkúlùkù wọn lè padà ní ọ̀nà búburú rẹ̀, kí n lè dárí ìṣìnà wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì ní ti gidi.”—Jer. 25:1-3; 36:1-3.

15 Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ láàfin ka àkájọ ìwé náà fún Jèhóákímù, ńṣe ni ọba yìí fa ìwé yìí ya, tó sì sọ ọ́ sínú iná. Ó wá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Jeremáyà àti Bárúkù wá. “Ṣùgbọ́n Jèhófà fi wọ́n pa mọ́.” (Ka Jeremáyà 36:21-26.) Nítorí bí ìwà Jèhóákímù ṣe burú jáì, Jèhófà gbẹnu wòlíì rẹ̀ kéde fún ọba yẹn pé, “bí a ṣe ń sin akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a ó sin ín.” Ńṣe ni wọ́n máa wọ́ òkú rẹ̀ káàkiri, tí wọ́n á sì gbé e sọ nù ré kọjá àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù. (Jer. 22:13-19) Ǹjẹ́ o rò pé àsọdùn lásán ni àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà tó sọ ohun to máa ṣẹlẹ̀ kedere yìí?

16. Ọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí wo ni Jeremáyà kéde?

16 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó pọn dandan kí Jeremáyà kéde irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ sórí àwọn èèyàn Júdà, kì í ṣe wòlíì tí kò mọ̀ ju pé kó máa kéde ègbé lọ. Ó tún máa ń kéde ọ̀rọ̀ tó ń fún àwọn èèyàn nírètí. Bí àpẹẹrẹ, ó ní Jèhófà yóò dá àṣẹ́kù Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, á sì mú wọn pa dà sórí ilẹ̀ wọn, níbi tí wọ́n á ti máa gbé láìséwu. Pé Ọlọ́run yóò bá àwọn èèyàn rẹ̀ dá “májẹ̀mú tuntun” kan “tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,” yóò sì kọ òfin rẹ̀ sínú ọkàn wọn. Ó máa dárí àwọn ìṣìnà wọn jì wọ́n, kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. Àti pé, àtọmọdọ́mọ Dáfídì kan yóò “mú ìdájọ́ òdodo àti òdodo ṣẹ ní kíkún ní ilẹ̀ náà.” (Jer. 31:7-9; 32:37-41; 33:15) Yàtọ̀ sí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Jeremáyà sọ wọ́n, ó tún ṣẹ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà. Kódà ìmúṣẹ rẹ̀ kan ìgbésí ayé wa lónìí, ó sì tún mú ká máa retí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. Àmọ́ ṣá o, ní ìgbà ayé Jeremáyà lọ́hùn-ún, àwọn ọba alágbára tó jẹ́ ọ̀tá Júdà ṣì ń du àgbègbè náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́ nìṣó.—Ka Jeremáyà 31:31, 33, 34; Hébérù 8:7-9; 10:14-18.

ÌJỌBA BÁBÍLÓNÌ DI AGBÁRA AYÉ

17, 18. Kí làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ní apá ìgbẹ̀yìn ìṣàkóso Jèhóákímù tó sì kan ìgbà ìṣàkóso Sedekáyà?

17 Lọ́dún 625 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Íjíbítì ja ogun àjàmọ̀gá ní Kákémíṣì, létí Odò Yúfírétì, èyí tó wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] kìlómítà sí àríwá Jerúsálẹ́mù. Nebukadinésárì Ọba sì ṣá àwọn ọmọ ogun Fáráò Nékò balẹ̀, ó sì wá gba gbogbo àgbègbè náà mọ́ ilẹ̀ Íjíbítì lọ́wọ́. (Jer. 46:2) Bí ilẹ̀ Júdà ṣe bọ́ sábẹ́ àkóso Nebukadinésárì nìyẹn, tí Jèhóákímù sì di ìránṣẹ́ rẹ̀ tipátipá. Àmọ́ Jèhóákímù ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinésárì lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tó ti ń ṣàkóso lábẹ́ rẹ̀. (2 Ọba 24:1, 2) Nebukadinésárì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá ṣígun wá sí Júdà lọ́dún 618 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n sì yí Jerúsálẹ́mù ká. Fojú inú wo bí àwọn èèyàn ṣe máa wà ní inú fu ẹ̀dọ̀ fu lásìkò náà, títí kan Jeremáyà wòlíì Ọlọ́run. Ó jọ pé ìgbà ìsàgatì yẹn ni ikú pa Jèhóákímù.b Oṣù mẹ́ta péré ni Jèhóákínì ọmọ rẹ̀ fi jọba ní Júdà tó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn ará Bábílónì. Nebukadinésárì kó dúkìá àwọn ará Jerúsálẹ́mù, ó sì kó Jèhóákínì, ìdílé ọba àti ìdílé àwọn ọ̀tọ̀kùlú ilẹ̀ Júdà, àwọn akíkanjú ilẹ̀ náà àtàwọn oníṣẹ́ ọnà nígbèkùn. Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà wà lára àwọn tó kó nígbèkùn.—2 Ọba 24:10-16; Dán. 1:1-7.

18 Nebukadinésárì wá fi ọmọ Jòsáyà míì, ìyẹn Sedekáyà jẹ ọba Júdà. Òun ni ọba tó jẹ kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé láti ìlà ìdílé Dáfídì. Ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run ni ìṣàkóso rẹ̀ dópin. (2 Ọba 24:17) Ní gbogbo ọdún mọ́kànlá tí Sedekáyà fi ṣàkóso, ìlú ò rójú, rògbòdìyàn sì wà láàárín àwọn alákòóso ní ilẹ̀ Júdà. Ó dájú pé lákòókò yìí, Jeremáyà máa ní láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó sọ ọ́ di wòlíì.

JÈHÓÁKÍMÙ NI ỌBA TÓ PA WÒLÍÌ JÈHÓFÀ

Picture on page 25

Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni Jèhóákímù nígbà tó di ọba Júdà, ó jọba fún ọdún mọ́kànlá. Àkópọ̀ àwọn ohun tó ṣe, èyí tó wà nínú ìwé 2 Kíróníkà 36:5-8 fi hàn pé “àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí,” tó jẹ́ pé ó burú jáì ló ṣe. Jèhóákímù kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ Jeremáyà, ó sì jẹ́ alọ́nilọ́wọ́gbà, apààyàn àti ọba tí kì í ṣèdájọ́ òdodo. Nígbà tí wòlíì Úríjà jẹ́ iṣẹ́ tó dà bíi ti Jeremáyà fún Jèhóákímù, ṣe ló ní kí wọ́n pa á. Ó jọ pé ìgbà táwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù ni ikú pa ọba yìí.—Jer. 22:17-19; 26:20-23.

19. Kí làwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà ṣe nípa iṣẹ́ tó jẹ́ fún wọn, kí sì nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀ nípa rẹ̀?

19 Ìwọ fi ara rẹ sípò Jeremáyà. Látìgbà ìṣàkóso Jòsáyà ni Jeremáyà ti ń fojú rí rògbòdìyàn òṣèlú àti bí àwọn èèyàn Ọlọ́run kò ṣe kọbi ara sí ìsìn tòótọ́. Ó sì mọ̀ dájú pé ńṣe ni gbogbo nǹkan á túbọ̀ máa burú sí i. Àwọn ará ìlú rẹ̀ gan-an sọ fún un pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà, kí o má bàa kú ní ọwọ́ wa.” (Jer. 11:21) Kódà nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà ṣẹ, àwọn Júù sọ pé: “Ní ti ọ̀rọ̀ tí o bá wa sọ ní orúkọ Jèhófà, àwa kì yóò fetí sí ọ.” (Jer. 44:16) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu o, àní bí ẹ̀mí àwọn èèyàn òde òní náà ṣe wà nínú ewu. Lónìí, ohun tí Jèhófà sọ là ń polongo bí Jeremáyà náà ṣe kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà. Níwọ̀n bí ipò àwa àti Jeremáyà sì ti jọra, iná ìtara wa fún iṣẹ́ ìwàásù á túbọ̀ máa jó fòfò tá a bá ṣàyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe dáàbò bo wòlíì rẹ̀ yìí nígbà tó kù díẹ̀ kí Jerúsálẹ́mù pa run.

Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tí Jeremáyà ṣe nígbà ìṣàkóso Jèhóákímù? Àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì wo ni Jeremáyà sọ, èyí tó kàn wá lóde òní?

ÌGBÀ TÍ ÌṢÀKÓSO ÀWỌN ỌBA LÁTI ÌLÀ ÌDÍLÉ DÁFÍDÌ FẸ́RẸ̀Ẹ́ DÓPIN

20. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà ìṣàkóso Sedekáyà ló nira jù fún Jeremáyà? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 29.)

20 Àfàìmọ̀ ni kò ní jẹ́ pé ìgbà ìṣàkóso Sedekáyà ló nira jù fún Jeremáyà ní gbogbo àkókò tó fi jẹ́ wòlíì. Sedekáyà “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà” bíi táwọn ọba tó jẹ ṣáájú rẹ̀. (Jer. 52:1, 2) Abẹ́ ìjọba Bábílónì ló ti ń ṣàkóso. Nebukadinésárì sì ti mú kó fi Jèhófà búra pé òun kò ní kúrò lábẹ́ ọba Bábílónì. Síbẹ̀síbẹ̀, Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ nígbà tó yá. Ní gbogbo àkókò náà, ṣe làwọn ọ̀tá Jeremáyà ń fúngun mọ́ Jeremáyà pé kó bá àwọn lẹ̀dí àpò pọ̀ nínú ìṣọ̀tẹ̀ náà.—2 Kíró. 36:13; Ìsík. 17:12, 13.

21-23. (a) Ọ̀nà méjì tó ta kora wo ni ilẹ̀ Júdà pín sí nígbà ìṣàkóso Sedekáyà? (b) Kí ni wọ́n ṣe sí Jeremáyà torí pé kò bá wọn lọ́wọ́ sí ìṣọ̀tẹ̀ wọn, kí sì nìdí tó fi yẹ kó o mọ̀ ọ́n?

21 Ẹ̀rí fi hàn pé lápá ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Sedekáyà, àwọn ọba Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì rán oníṣẹ́ wá sí Jerúsálẹ́mù. Bóyá ńṣe ni wọ́n fẹ́ kí Sedekáyà dara pọ̀ mọ́ àwọn kí wọ́n lè jọ bá Nebukadinésárì jà. Àmọ́ Jeremáyà rọ Sedekáyà pé kó máa sin ilẹ̀ Bábílónì. Èyí náà ló jẹ́ kí Jeremáyà fún àwọn ońṣẹ́ ọba tó wá sí Jerúsálẹ́mù ní ọ̀pá àjàgà láti fi sọ fún àwọn orílẹ̀-èdè yẹn pé káwọn náà sin àwọn ará Bábílónì. (Jer. 27:1-3, 14)c Àwọn èèyàn kò fẹ́ ohun tí Jeremáyà ń sọ pé kí wọ́n ṣe yìí. Hananáyà sì tún dá kún báwọn èèyàn ò ṣe fojúure wo ìhìn tí Jeremáyà agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run ń jẹ́ fún wọn. Hananáyà yìí ni wòlíì èké tó ń sọ fáwọn èèyàn pé Ọlọ́run rán òun láti sọ fún wọn pé òun yóò ṣẹ́ àjàgà àwọn ará Bábílónì. Àmọ́, Jèhófà gbẹnu Jeremáyà sọ pé kí ọdún kan tó pé, Hananáyà yóò kú, ó sì kú lóòótọ́.—Jer. 28:1-3, 16, 17.

22 Ilẹ̀ Júdà wá dá sí méjì. Apá kan ń sọ pé káwọn máa sin ilẹ̀ Bábílónì, apá kejì sì ń sọ pé ṣe ni káwọn kúrò lábẹ́ wọn. Lọ́dún 609 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Sedekáyà ṣọ̀tẹ̀ lóòótọ́, ó lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì pé kí wọ́n wá ran òun lọ́wọ́. Ló bá di pé kí Jeremáyà máa bá wàhálà àwọn tó gbà pé kí Júdà ṣọ̀tẹ̀ yẹn yí. (Jer. 52:3; Ìsík. 17:15) Nebukadinésárì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pa dà wá sí ilẹ̀ Júdà láti fòpin sí ìṣọ̀tẹ̀ náà. Ó ṣẹ́gun gbogbo ìlú Júdà, ó sì tún sàga ti Jerúsálẹ́mù. Jeremáyà sì sọ fún Sedekáyà àtàwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ní àsìkò tí ọ̀rọ̀ dójú ẹ̀ fún wọn yẹn pé Bábílónì máa ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù. Ó ní ikú máa pa àwọn tó bá jókòó pa sínú ìlú náà. Ṣùgbọ́n àwọn tó bá lọ jọ̀wọ́ ara wọn fún àwọn ará Kálídíà yóò yè.—Ka Jeremáyà 21:8-10; 52:4.

23 Àwọn ọmọ aládé Júdà wá fẹ̀sùn kan Jeremáyà pé ó fẹ́ lọ bá àwọn ará Bábílónì lẹ̀dí àpò pọ̀. Ó sọ fún wọn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, síbẹ̀, wọ́n lù ú wọ́n sì fi sí àtìmọ́lé. (Jer. 37:13-15) Àmọ́, Jeremáyà kò torí ìyẹn bomi la ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi rán an sí wọn. Làwọn ọmọ aládé bá ní kí Sedekáyà pa Jeremáyà. Bí wọ́n ṣe ju wòlíì náà sínú ìkùdu tí kò lómi nìyẹn. Inú ẹrẹ̀ ìkùdu náà ni Jeremáyà ì bá kú sí bí kì í bá ṣe ti Ebedi-mélékì ará Etiópíà, òṣìṣẹ́ láàfin ọba, tó lọ fà á jáde níbẹ̀. (Jer. 38:4-13) Àìmọye ìgbà náà ni àwọn èèyàn Jèhófà lónìí ti wà nínú ewu nítorí pé wọ́n kọ̀ láti dá sí ọ̀ràn ìṣèlú èyíkéyìí. Láìsí àní-àní, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà lè jẹ́ kó o nígboyà tí wàá fi lè borí àdánwò èyíkéyìí tó o bá bá pàdé.

SEDEKÁYÀ LÓ JẸ ỌBA JÚDÀ GBẸ̀YÌN NÍ AYÉ

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29

Ojo àti dọ̀bọ̀sìyẹsà ọba tó ń bẹ̀rù ṣáá, táwọn ọmọ aládé rẹ̀ sì ń darí ni Sedekáyà. Nígbà ìsàgatì ìkẹyìn tí àwọn ará Bábílónì fi pa Jerúsálẹ́mù run, Sedekáyà tọ Jeremáyà lọ láti wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Àmọ́, nígbà tí Jeremáyà jíṣẹ́ fún un pé ṣe ni kó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fáwọn ará Bábílónì, kò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà yẹn. Sedekáyà wá fi Jeremáyà sẹ́wọ̀n torí pé inú rẹ̀ kò dùn sí iṣẹ́ tó jẹ́ fún un. (Jer. 21:1-9; 32:1-5) Síbẹ̀, Sedekáyà tún ṣì lọ ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jeremáyà, àmọ́ ṣe ló ń yọ́ kẹ́lẹ́ lọ káwọn ọmọ aládé Júdà má bàa bínú sí i. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé kó jẹ́ kí àwọn pa Jeremáyà, ó fi ìbẹ̀rù gbà láìjanpata, ó ní: “Ó wà ní ọwọ́ yín. Nítorí kò sí nǹkan kan rárá nínú èyí tí ọba ti lè borí yín.” Nígbà tí wọ́n wá mú Jeremáyà kúrò ní àtìmọ́lé tí ì bá kú sí, ọba tún lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì jẹ́wọ́ fún un pé ẹ̀rù ń bá òun pé tóun bá ṣe bí Ọlọ́run ṣe sọ, àwọn èèyàn lè fìyà jẹ òun.—Jer. 37:15-17; 38:4, 5, 14-19, 24-26.

Síbẹ̀, Sedekáyà “kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ní tìtorí Jeremáyà . . . , ó sì ń bá a nìṣó ní mímú ọrùn rẹ̀ le àti ní sísé ọkàn-àyà rẹ̀ le kí ó má bàa padà sọ́dọ̀ Jèhófà.”—2 Kíró. 36:12, 13; Ìsík. 21:25.

24. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

24 Níkẹyìn, lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì ya odi Jerúsálẹ́mù lulẹ̀, wọ́n sì gba ìlú náà. Àwọn ọmọ ogun Nebukadinésárì dáná sun tẹ́ńpìlì Jèhófà, wọ́n wó odi ìlú náà, wọ́n sì pa àwọn ọmọ aládé Júdà. Sedekáyà fẹ́ sá lọ, àmọ́ wọ́n lé e bá, wọ́n sì mú un wá síwájú Nebukadinésárì tó ṣẹ́gun ìlú yẹn. Ló bá pa àwọn ọmọ Sedekáyà lójú rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n fọ́ ojú Sedekáyà lẹ́yìn náà. Wọ́n wá fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì. (Jer. 39:1-7) Bí ọ̀rọ̀ Jeremáyà tó sọ nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù ṣe ṣẹ nìyẹn. Àmọ́ wòlíì Ọlọ́run yìí kò bẹ̀rẹ̀ sí í yọ àwọn èèyàn rẹ̀ yìí rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló kédàárò àjálù tó bá wọn. A lè rí ìdárò rẹ̀ kà nínú ìwé Ìdárò. Ọ̀rọ̀ wọn máa ṣe wá láàánú gan-an ni, bá a ṣe ń ka ìwé náà.

OHUN TÍ JEREMÁYÀ ṢE LÁÀÁRIN ÀWỌN ÈÈYÀN JÚDÀ TÓ ṢẸ́ KÙ

25, 26. (a) Kí làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà sí ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù pa run?

25 Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Jeremáyà láàárín àsìkò tí nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀? Ṣe làwọn ọmọ aládé Jerúsálẹ́mù fi í sẹ́wọ̀n, ṣùgbọ́n àwọn ará Bábílónì tó ṣẹ́gun wọn ṣe inú rere sí i, wọ́n sì tú u sílẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n ṣèèṣì kó Jeremáyà pọ̀ mọ́ àwọn Júù tí wọ́n ń kó lọ sí ìgbèkùn, àmọ́ wọ́n tún tú u sílẹ̀. Ọlọ́run ṣì níṣẹ́ tó pọ̀ fún un láti ṣe láàárín àwọn Júù tí wọn ò kó lọ sígbèkùn. Nebukadinésárì ọba Bábílónì fi Gẹdaláyà jẹ gómìnà lórí Júdà tí wọ́n ṣẹ́gun, ó sì wá jẹ́ kó dá àwọn ará Júdà lójú pé òun ò ní yọ wọ́n lẹ́nu tí wọ́n bá ti ń sin òun. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan tí kò fara mọ́ ohun tí ọba yìí ṣe pa Gẹdaláyà. (Jer. 39:13, 14; 40:1-7; 41:2) Jeremáyà wá rọ àwọn èèyàn Júdà tó ṣẹ́ kù pé kí wọ́n má ṣe kúrò ní Júdà tí wọ́n ń gbé, kí wọ́n má sì bẹ̀rù nítorí ọba Bábílónì. Ṣùgbọ́n àwọn aṣáájú wọn sọ pé irọ́ ni Jeremáyà ń pa, wọ́n sì sá lọ sí Íjíbítì, wọ́n wá fi tipátipá mú Jeremáyà àti Bárúkù bá wọn lọ. Síbẹ̀, Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Nebukadinésárì ń bọ̀ wá gbógun ja ilẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n sá lọ, pé yóò sì han àwọn ará Júdà tó sá wá síbẹ̀ léèmọ̀.—Jer. 42:9-11; 43:1-11; 44:11-13.

26 Lọ́tẹ̀ yìí náà, ṣe làwọn Júù tó sá lọ sí Íjíbítì kọ etí dídi sí ohun tí Jeremáyà wòlíì Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún wọn. Kí nìdí rẹ̀? Wọ́n ní: “Láti ìgbà tí a sì ti ṣíwọ́ rírú èéfín ẹbọ sí ‘ọbabìnrin ọ̀run’ àti dída ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí i ni a ti ṣaláìní ohun gbogbo, àti nípasẹ̀ idà àti nípasẹ̀ ìyàn sì ni a ti wá sí òpin wa.” (Jer. 44:16, 18) Ó mà ṣe o, ẹ ò rí i pé àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà yìí ti kẹ̀yìn sí ìsìn tòótọ́ pátápátá! Àmọ́, a rí ìṣírí gbà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, pé èèyàn aláìpé ṣì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bó tiẹ̀ wà láàárín àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.

27. Kí la mọ̀ nípa iṣẹ́ wòlíì Jeremáyà lápá ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀?

27 Ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jeremáyà kọ sílẹ̀ gbẹ̀yìn ni èyí táwọn kan sọ pé ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 580 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìyẹn, bí Efili-méródákì tó jọba lẹ́yìn Nebukadinésárì ṣe mú Jèhóákínì kúrò lẹ́wọ̀n. (Jer. 52:31-34) Lákòókò tá à ń wí yìí, Jeremáyà á ti tó ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún. A ò rí àkọsílẹ̀ tó ṣeé gbára lé nípa ìgbẹ̀yìn ayé rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilẹ̀ Íjíbítì ló darúgbó, tó sì kú sí, lẹ́yìn tó ti fi ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ́nà àkànṣe. Ó sì dájú pé ó jẹ́ olóòótọ́ dópin. Ó ṣe iṣẹ́ wòlíì nígbà táwọn èèyàn ń gbé ìsìn tòótọ́ lárugẹ àti ìgbà tí ìbọ̀rìṣà gbòde kan láàárín àwọn èèyàn tó ń gbé. Àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ ló kọ etí dídi sí ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ, tí wọ́n tiẹ̀ tún dojú ìjà kọ ọ́ pàápàá. Ṣé ìyẹn wá fi hàn pé àṣedànù ni Jeremáyà ṣe ni? Rárá o! Àtìbẹ̀rẹ̀ ni Jèhófà ti sọ fún un pé: “Ó . . . dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ.’” (Jer. 1:19) Irú iṣẹ́ tí Jeremáyà jẹ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń jẹ́ lóde òní. Èyí tó fi hàn pé irú ọwọ́ táwọn èèyàn fi mú ọ̀rọ̀ Jeremáyà ni wọ́n máa fi mú tiwa náà. (Ka Mátíù 10:16-22.) Ẹ̀kọ́ wo la wá lè rí kọ́ lára Jeremáyà, irú ọwọ́ wo ló sì yẹ ká fi mú iṣẹ́ ìwàásù wa? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè yìí.

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sedekáyà àtàwọn èèyàn ìjọba rẹ̀ bí wọ́n ṣe kọ iṣẹ́ tí Jeremáyà jẹ́ fún wọn? Kí ni èrò rẹ nípa Jeremáyà?

a Bí Jeremáyà 7:1-15 àti 26:1-6 ṣe jọra mú kí àwọn kan gbà pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà ni ẹsẹ Bíbélì méjèèjì ń ṣàlàyé.

b Dáníẹ́lì 1:1, 2 sọ pé Jèhófà fi Jèhóákímù lé Nebukadinésárì lọ́wọ́ ní ọdún kẹta ìjọba Jèhóákímù, bóyá ìyẹn sì jẹ́ lọ́dún kẹta tó ti ń ṣàkóso lábẹ́ Bábílónì. Èyí lè fi hàn pé ìgbà ìsàgatì tí wọ́n fi ṣẹ́gun ìlú yẹn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni ọba yìí kú. Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bíbélì tó ti ìtàn tí ọ̀gbẹ́ni Josephus kọ pé Nebukadinésárì pa Jèhóákímù, ó sì ní kí wọ́n ju òkú rẹ̀ sẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù láì sin ín.—Jer. 22:18, 19; 36:30.

c Ó ní láti jẹ́ pé àṣìṣe látọwọ́ àwọn adàwékọ ló fà á tí orúkọ Jèhóákímù fi wà nínú Jeremáyà 27:1, torí pé ọ̀rọ̀ Sedekáyà ni ẹsẹ kẹta àti ìkejìlá ń sọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́