ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ll apá 9 ojú ìwé 20-21
  • Ìgbà Wo Ni Ayé Máa Di Párádísè?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ni Ayé Máa Di Párádísè?
  • Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Párádísè Sún Mọ́lé!
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Apa 9
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ìgbésí Ayé Dídára Jù—Láìpẹ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
ll apá 9 ojú ìwé 20-21

APÁ 9

Ìgbà Wo Ni Ayé Máa Di Párádísè?

Àwọn wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó dé. Lúùkù 21:​10, 11; 2 Tímótì 3:​1-5

Àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn​—tẹ́tẹ́ títa, ogun, àìsàn, àìtó oúnjẹ, àìgbọràn sí òbí àti tọkọtaya tó ń lu ara wọn

Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ni Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á máa ṣàìgbọràn sí òbí, wọ́n á burú gan-an, wọn ò sì ní mọ̀ ju fàájì lọ.

Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára, ogun, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn máa wà. Àwọn nǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún ẹnì kan

Bákan náà, Jésù sọ pé a ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé.​—Mátíù 24:14.

Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò. 2 Pétérù 3:13

Àwọn ẹni burúkú pa run ní ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù wá fìyà jẹ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀

Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo èèyàn burúkú run.

Jèhófà máa fìyà jẹ Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù.

Jésù wà lórí ìtẹ́ rẹ̀ lọ́run, inú àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà sì ń dùn

Àwọn tó bá tẹ́tí sí Ọlọ́run máa gbé nínú ayé tuntun tí òdodo wà, níbi tí kò ní sí ìbẹ̀rù mọ́, tí àwọn èèyàn máa finú tán ara wọn, tí wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

  • Kí ni Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa yìí?​—Mátíù 24:3-14.

  • Ọlọ́run máa pa àwọn ẹni burúkú run.​—2 Pétérù 3:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́