Ìgbésí Ayé Dídára Jù—Láìpẹ́!
RONÚ nípa alásọtẹ́lẹ̀ ojú ọjọ́ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sábà máa ń ṣẹ. Bí ó bá sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìròyìn ìrọ̀lẹ́ pé, òjò yóò rọ̀ ní ọjọ́ kejì, ìwọ kì í lọ́ra láti mú agbòjò rẹ dání nígbà tí o bá ń kúrò nílé ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ìṣáájú ti jẹ́ kí o gbẹ́kẹ̀ lé e. Ò ń ṣe ohun tí ó bá sọ.
Wàyí o, báwo ni ìlérí Jehofa nípa ìgbésí ayé dídára jù nínú Paradise orí ilẹ̀ ayé ti ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé tó? Tóò, kí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ìṣáájú fi hàn? Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fìdí ìjóòótọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Jehofa múlẹ̀ ní kedere. Òun jẹ́ Ọlọrun ìṣedéédéé àti òtítọ́ tí kì í yẹ̀. (Joṣua 23:14; Isaiah 55:11) Àwọn ìlérí Jehofa Ọlọrun ṣe é gbẹ́kẹ̀ lé débi pé, nígbà mìíràn, ó máa ń sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la bíi pé wọ́n ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Fún àpẹẹrẹ, tí a bá wo ìlérí rẹ̀ nípa ayé tuntun níbi tí ikú àti ọ̀fọ̀ kò ti ní sí mọ́, a kà pé: “Wọ́n [àwọn ìbùkún tí ó ṣèlérí] ti ṣẹlẹ̀!” Ní èdè mìíràn, “Wọ́n jẹ́ òkodoro òtítọ́!”—Ìṣípayá 21:5‚ 6, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW.
Bẹ́ẹ̀ ni, ìmúṣẹ àwọn ìlérí Jehofa tí ó ti kọjá ń fún wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú ìlérí rẹ̀ nípa ìgbésí ayé dídára jù fún aráyé ṣẹ. Ṣùgbọ́n nígbà wo ni ìgbésí ayé dídára jù yìí yóò dé?
Ìgbésí Ayé Dídára Jù—Nígbà Wo?
Ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ dára jù yóò dé láìpẹ́! Ó lè dá wa lójú nítorí pé, Bibeli sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan búburú yóò ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kété ṣáájú kí Paradise tó mú ìgbésí ayé dídára jù wá. Àwọn nǹkan búburú wọ̀nyẹn ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí.
Fún àpẹẹrẹ, Jesu Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé, ogun ńláǹlà yóò wà. Ó sọ pé: “Orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè ati ìjọba sí ìjọba.” (Matteu 24:7) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ní ìmúṣẹ. Ní ọdún 1914 sí 1945, ogun àgbáyé méjì jà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ogun mìíràn sì ti tẹ̀ lé èyí, nínú èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè ti bá ara wọn jà. “Ní ìpíndọ́gba ọdọọdún, iye àwọn abógunrìn tí ń kú nínú ogun ní sáà yìí [bẹ̀rẹ̀ láti Ogun Àgbáyé Kejì] ti ju ìlọ́po méjì àwọn tí wọ́n kú ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún lọ, ó sì fi ìlọ́po méje ju ti ọ̀rúndún kejìdínlógún lọ.”—World Military and Social Expenditures 1993.
Àrùn tí ń tàn kálẹ̀ tún jẹ́ ẹ̀rí mìíràn pé ìgbésí ayé dídára jù nínú Paradise ti sún mọ́lé. Jesu sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘àrùn lati ibi kan dé ibòmíràn’ yóò wà. (Luku 21:11) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ha ti ní ìmúṣẹ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àrùn gágá pa iye tí ó lé ní 20 mílíọ̀nù ènìyàn. Láti ìgbà náà wá, àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọkàn-àyà, ibà, àrùn AIDS, àti àwọn òkùnrùn mìíràn ti pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn. Ní àwọn ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà sókè, àwọn àrùn tí omi ìdọ̀tí ń fà (lára wọn ni àrunṣu àti èèràn aràn inú ìfun) ti gba ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn lọ́dọọdún.
Jesu tún sọ pé: “Àìtó oúnjẹ . . . yoo . . . wà.” (Matteu 24:7) Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, àwọn òtòṣì ní ayé kò rí oúnjẹ tí ó tó jẹ. Èyí jẹ́ apá mìíràn nínú ẹ̀rí náà pé ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ dára jù nínú Paradise yóò dé láìpẹ́.
Jesu sọ pé: “Ìmìtìtì-ilẹ̀ ńláǹlà yoo . . . wà.” (Luku 21:11) Èyí pẹ̀lú ti rí bẹ́ẹ̀ ní àkókò wa. Láti 1914 wá, ìparun tí ìmìtìtì ilẹ̀ runlérùnnà mú wá ti gba ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí.
Bibeli tún sọ síwájú sí i pé, ìyípadà àwọn ènìyàn ni a óò fi dá “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” mọ̀. Wọ́n yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn” àti “olùfẹ́ owó,” àwọn ọmọ yóò sì jẹ́ “aṣàìgbọràn sí òbí.” Àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò yóò jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun.” (2 Timoteu 3:1-5) Ìwọ kò ha gbà pé ọ̀pọ̀ bá àpèjúwe yìí mu bí?
Bí àwọn tí ń ṣe nǹkan búburú ti ń pọ̀ sí i, ìwà àìlófin ń pọ̀ sí i. Èyí pẹ̀lú ni a ti sọ tẹ́lẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú Matteu 24:12, Jesu sọ̀rọ̀ nípa “pípọ̀ sí i ìwà-àìlófin.” Ó ṣeé ṣe kí o gbà pé ìwà ọ̀daràn burú sí i nísinsìnyí ju bí ó ti rí ní àwọn ọdún tí ó ti kọjá lọ. Àwọn ènìyàn níbi gbogbo ń bẹ̀rù pé a óò jà wọ́n lólè, rẹ́ wọn jẹ, tàbí pa wọ́n lára ní àwọn ọ̀nà kan.
Ogun, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀, ìwà ọ̀daràn tí ń pọ̀ sí i, àti ìṣesí ẹ̀dá ènìyàn sí ara wọn tí ń burú sí i—gbogbo èyí ṣe kedere lónìí, gan-an bí Bibeli ti sọ tẹ́lẹ̀. O lè béèrè pé, ‘Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wọ̀nyí kò ha ti ṣẹlẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìtàn ẹ̀dá ènìyàn bí? Kí ni ohun tí ó yàtọ̀ nípa ọjọ́ wa?’
Àwọn apá pàtàkì gidi gan-an wà nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Bibeli kò sọ pé apá èyíkéyìí kan, bí àìtó oúnjẹ, fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ ẹ̀rí, pé a ń gbé ní àkókò òpin àti pé ìgbésí ayé dídára jù kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli nípa àkókò ìkẹyìn ní láti ní ìmúṣẹ sórí ìran aláìgbọlọ́rungbọ́.—Matteu 24:34-39; Luku 17:26‚ 27.
Síwájú sí i, kò wọ́ pọ̀ pé àwọn apá kan àsọtẹ́lẹ̀ Jesu—ní pàtàkì, àwọn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn—ń ṣẹ lónìí. Èé ṣe? Nítorí àṣeyọrí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tíì fìgbà kankan tó báyìí rí. Ìmọ̀ ìṣègùn àti ọ̀nà ìtọ́jú kò tíì fìgbà kankan lọ sókè tàbí tàn kálẹ̀ tó báyìí rí. Ọlọrun nìkan ni ó ti lè sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, pé ní àkókò báyìí, àrùn àti ìyàn yóò burú sí i, kì yóò sunwọ̀n sí i.
Níwọ̀n bí gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli nípa àkókò òpin tàbí “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti ń ní ìmúṣẹ, ìparí èrò wo ni a lè dé? Pé ìgbésí ayé dídára jù ti sún mọ́lé! Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe ṣẹlẹ̀?
Ìgbésí Ayé Dídára Jù—Báwo?
Ìwọ ha rò pé ẹ̀dá ènìyàn lè mú Paradise wá bí? Jálẹ̀ ìtàn, títí di òní olónìí, oríṣiríṣi ìjọba ẹ̀dá ènìyàn ni ó ti wà. Àwọn kan ti gbìyànjú gidigidi láti tẹ́ àìní àwọn ènìyàn lọ́rùn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìṣòro túbọ̀ ń burú sí i. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ àti àwọn ilẹ̀ tí ó tòṣì, àwọn ìjọba ń bá ìlòkulò oògùn, ibùgbé tí kò dára, òṣì, ìwà ọ̀daràn, àìríṣẹ́ṣe, àti ogun, jìjàkadì.
Ká tilẹ̀ ní ìjọba lè yanjú àwọn kan nínú àwọn ìṣòro wọ̀nyí, wọn kò lè pèsè òmìnira pátápátá kúrò lọ́wọ́ àìsàn; bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè fi òpin sí ọjọ́ ogbó àti ikú. Ó dájú pé, ẹ̀dá ènìyàn kò lè mú Paradise wá sórí ilẹ̀ ayé yìí.
Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Bibeli sọ pé: “Ẹ máṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.” Nígbà náà, tà ni a ní láti gbẹ́kẹ̀ wa lé? Bibeli dáhùn pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní Ọlọrun [Jekọbu] fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ìrètí ẹni tí ń bẹ lọ́dọ̀ [Jehofa] Ọlọrun rẹ̀.” (Orin Dafidi 146:3‚ 5) Bí a bá gbẹ́kẹ̀ wa lé Jehofa Ọlọrun, a kì yóò já wa kulẹ̀ láé.
Ó dájú pé, Ẹni náà, tí ó ní ọgbọ́n àti agbára láti dá ilẹ̀ ayé, oòrùn, àti àwọn ìràwọ̀, lè sọ ayé di Paradise. Ó lè mú kí ẹ̀dá ènìyàn gbádùn ìgbésí ayé dídára jù. Jehofa Ọlọrun lè ṣe ohunkóhun tí ó bá là sílẹ̀ láti ṣe, yóò sì ṣe é. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọrun kò sí ìpolongo kankan tí yoo jẹ́ aláìṣeéṣe.” (Luku 1:37) Ṣùgbọ́n báwo ni Ọlọrun yóò ṣe mú ìgbésí ayé dídára jù wá?
Jehofa yóò mú ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ dára jù wá fún aráyé nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Kí sì ni Ìjọba Ọlọrun? Ó jẹ́ ìjọba gidi kan, tí ó ní Alákòóso tí Ọlọrun yàn sípò, Jesu Kristi. Ìjọba Ọlọrun wà ní ọ̀run, ṣùgbọ́n láìpẹ́, yóò mú àwọn ìbùkún àgbàyanu àti ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ dára sí i wá fún àwọn olùgbé Paradise orí ilẹ̀ ayé.—Isaiah 9:6, 7.
O lè ti mọ̀ nípa àdúrà àwòkọ́ṣe Jesu dáradára, tí a rí nínú Bibeli, nínú Matteu 6:9-13. Apá kan àdúrà náà sí Ọlọrun sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́-inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀-ayé pẹlu.” Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà náà, Ìjọba Ọlọrun yóò “dé” láti mú ète Jehofa Ọlọrun fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. Ète rẹ̀ sì tún ni pé kí ayé di Paradise.
Ìbéèrè kan tí ó kẹ́yìn, ni pé: Kí ni o ní láti ṣe láti lè gbádùn ìgbésí ayé dídára jù nínú Paradise tí ń bọ̀?
Ohun Tí O Ní Láti Ṣe
Jehofa Ọlọrun fi ìfẹ́ nawọ́ àǹfààní ìgbésí ayé dídára jù nínú Paradise sí gbogbo ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bibeli sọ fún wa pé: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dafidi 37:29) Ṣùgbọ́n kí ní ń sọ ènìyàn di olódodo lójú Ọlọrun?
Láti lè ṣe ohun tí ó wu Jehofa, a ní láti kọ́ púpọ̀ sí i nípa ohun tí ó fẹ́ kí a ṣe. Bí a bá gba ìmọ̀ Ọlọrun, tí a sì lò ó nínú ìgbésí ayé wa, a lè wà láàyè títí láé. Nínú àdúrà sí Ọlọrun, Jesu sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú, ati ti ẹni naa tí iwọ rán jáde, Jesu Kristi.”—Johannu 17:3.
Ìwé tí ń sọ fún wa nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Ó jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀bùn Jehofa tí ó ṣeyebíye jù lọ. Bibeli dà bíi lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ bàbá onífẹ̀ẹ́ sí àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sọ fún wa nípa ìlérí Ọlọrun láti mú ìgbésí ayé dídára jù wá fún aráyé, ó sì fi bí a ṣe lè rí i hàn wá. Bibeli jẹ́ kí a mọ ohun tí Ọlọrun ti ṣe ní ìgbà àtijọ́, àti ohun tí yóò ṣe ní ọjọ́ iwájú. Ó tún fún wa ní ìmọ̀ràn tí ó ṣeé mú lò nípa bí a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro wa pẹ̀lú àṣeyọrí nísinsìnyí. Ní tòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kọ́ wa bí a ṣe lè rí ìwọ̀n ayọ̀ díẹ̀ nínú ayé onídààmú yìí pàápàá.—2 Timoteu 3:16‚ 17.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò fi tayọ̀tayọ̀ ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé fún ọ lọ́fẹ̀ẹ́. Kọ́ bí o ṣe lè gbé ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ láyọ̀ nísinsìnyí, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ dára sí i ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fi hàn pé ìgbésí ayé dídára jù ti sún mọ́ tòsí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìjọba Ọlọrun yóò mú ìgbésí ayé dídára jù wá fún aráyé