ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fg ẹ̀kọ́ 1 àwọn ìbéèrè 1-3
  • Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?
  • Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Ilẹ̀ Ayé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
fg ẹ̀kọ́ 1 àwọn ìbéèrè 1-3

Ẹ̀KỌ́ 1

Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?

1. Ìròyìn wo ló wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Àwọn èèyàn yìí ń gbádùn ayé wọn

Ọlọ́run fẹ́ kí àwa èèyàn máa gbádùn ayé wa lórí ilẹ̀ ayé. Ó dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú kí nǹkan túbọ̀ dáa fún àwa èèyàn níbi gbogbo. Ó máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò.​—Ka Jeremáyà 29:11.

Kò sí ìjọba kankan tó ti ṣàṣeyọrí láti mú ìwà ipá, àìsàn àti ikú kúrò. Àmọ́, ìròyìn ayọ̀ kan wà o. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú gbogbo ìjọba èèyàn kúrò, á sì fi ìjọba tirẹ̀ rọ́pò wọn. Àwọn tó bá wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa gbádùn àlàáfíà àti ìlera tó jí pépé.​—Ka Àìsáyà 25:8; 33:24; Dáníẹ́lì 2:44.

2. Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè sọ ìròyìn ayọ̀ yìí fún àwọn èèyàn?

Ìgbà tí Ọlọ́run bá pa àwọn èèyàn búburú run ni ìyà tó ń jẹ aráyé máa tó dópin. (Sefanáyà 2:3) Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣòro tó ń bá aráyé fínra lákòókò wa yìí. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí fi hàn pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ ayé yìí.​—Ka 2 Tímótì 3:1-5.

3. Kí ló yẹ ká ṣe?

Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bíbélì dà bíi lẹ́tà látọ̀dọ̀ Bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sọ bá a ṣe lè gbádùn ìgbésí ayé wa báyìí àti bá a ṣe lè ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Òótọ́ ni pé inú àwọn kan lè má dùn sí bó o ṣe fẹ́ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ṣèlérí fún ọ lọ́jọ́ iwájú, o ò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí ẹ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.​—Ka Òwe 29:25; Ìfihàn 14:6, 7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́