ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yc ẹ̀kọ́ 14 ojú ìwé 30-31
  • Ìjọba Kan Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjọba Kan Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Gbé Inú Párádísè
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Kí Ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ìjọba Tó Máa Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Kọ́ Ọmọ Rẹ
yc ẹ̀kọ́ 14 ojú ìwé 30-31
Jésù Kristi ń ṣàkóso bí Ọba lé Párádísè orí ilẹ̀ ayé

Ẹ̀kọ́ 14

Ìjọba Kan Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé

Ǹjẹ́ o mọ Ìjọba yìí?— Bẹ́ẹ̀ ni o, Ìjọba Ọlọ́run ni, òun ló máa sọ ilẹ̀ ayé di párádísè. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ nípa Ìjọba yìí?—

Gbogbo ìlú ló máa ń ní ọba tàbí olórí. Ọba ló sì máa ń ṣàkóso lórí àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run?— Jésù Kristi ni. Ọ̀run ni ó ń gbé. Láìpẹ́, òun ni ó máa ṣàkóso gbogbo èèyàn lórí ilẹ̀ ayé! Ǹjẹ́ o rò pé inú wa máa dùn nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gbogbo ayé?—

Kí lò ń fojú sọ́nà fún nínú Párádísè?

Inú wa máa dùn gan-an! Torí pé nínú Párádísè, àwọn èèyàn ò ní máa jà mọ́, wọn kò sí ní máa jagun mọ́. Gbogbo èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ẹnì kankan ò ní ṣàìsàn, a ò sì ní kú mọ́. Ojú afọ́jú máa là, etí àwọn adití á là, àwọn tí kò lè rìn tẹ́lẹ̀ máa lè sáré, wọ́n á tún fò sókè. Oúnjẹ rẹpẹtẹ máa wà fún gbogbo èèyàn. Àwọn ẹranko máa di ọ̀rẹ́ ara wọn, wọ́n á tún di ọ̀rẹ́ àwa èèyàn. Àwọn tó ti kú máa jí dìde. Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú ìwé yìí máa tún pa dà wà láàyè, àwọn bíi Rèbékà, Ráhábù, Dáfídì àti Èlíjà. Ṣé wàá fẹ́ rí wọn nígbà tí wọ́n bá tún pà dà wà láàyè?—

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì fẹ́ kó o máa láyọ̀. Tó o bá ń bá a lọ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tí o sì ń ṣègbọràn sí i, ìwọ náà máa wà láàyè títí láé nínú párádísè! Ṣé wàá fẹ́ wà níbẹ̀?—

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ

  • Aísáyà 2:4; 11:6-9; 25:8; 33:24; 35:5, 6

  • Jòhánù 5:28, 29; 17:3

ÌBÉÈRÈ:

  • Tani Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

  • Àwọn wo ni Jésù máa Jọba lé lórí?

  • Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gbogbo ayé?

  • Tí o bá fẹ́ gbé títí láé nínú Párádísè, kí lo máa ṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́