ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • hf apá 9 1-2
  • Ẹ Jọ Máa Sin Jèhófà Nínú Ìdílé Yín

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jọ Máa Sin Jèhófà Nínú Ìdílé Yín
  • Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1 TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ
  • 2 Ẹ MÁA ṢE ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Ìjọsìn Ìdílé—Ǹjẹ́ O Lè Mú Kó Túbọ̀ Gbádùn Mọ́ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Á sì Sún Mọ́ Yín”
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
hf apá 9 1-2
Tọkọtaya kan jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

APÁ KẸSÀN-ÁN

Ẹ Jọ Máa Sin Jèhófà Nínú Ìdílé Yín

“Ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”​—Ìṣípayá 14:7

Àwọn ohun tí o kọ́ nínú ìwé yìí ti jẹ́ kí o rí i pé ọ̀pọ̀ ìlànà tó lè ran ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ wà nínú Bíbélì. Jèhófà fẹ́ kí o máa láyọ̀. Ó ṣèlérí pé tí o bá fi ìjọsìn rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́, ‘gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó fi kún un fún ọ.’ (Mátíù 6:​33) Ó wù ú gan-an pé kí o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Máa lo gbogbo àǹfààní tí o bá ní láti mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ lágbára. Èyí ni àǹfààní tó dára jù lọ tí èèyàn lè ní.​—Mátíù 22:​37, 38.

1 TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ

Tọkọtaya kan jọ ń wàásù ní òde-ẹ̀rí

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:“‘Èmi yóò . . . jẹ́ baba yín, ẹ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’ ni Jèhófà . . . wí.” (2 Kọ́ríńtì 6:​18) Ọlọ́run fẹ́ kí o di ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́. Ọ̀nà kan tí a lè gbà di ọ̀rẹ́ Jèhófà ni pé ká máa gbàdúrà sí i. Jèhófà gbà wá níyànjú pé ká “máa gbàdúrà ní àìsinmi.” (1 Tẹsalóníkà 5:​17, Bíbélì Mímọ́) Ó máa ń wù ú láti fetí sílẹ̀ tí o bá ń sọ èrò inú rẹ lọ́hùn-ún àtàwọn ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn. (Fílípì 4:6) Tí o bá ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ, wọ́n á mọ bí o ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó.

Láfikún sí bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó tún yẹ kí o máa tẹ́tí sí i. O lè tẹ́tí sí Ọlọ́run tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìwé tàbí ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì. (Sáàmù 1:​1, 2) Máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí o bá kọ́. (Sáàmù 77:​11, 12) Lára ọ̀nà tí o lè gbà máa tẹ́tí sí Ọlọ́run ni pé kí o máa wá sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí ­Jèhófà déédéé.​—Sáàmù 122:​1-4.

Ọ̀nà pàtàkì míì tí o lè gbà mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run dára sí i ni pé kí o máa bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Bí o bá túbọ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn.​—Mátíù 28:​19, 20.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Máa wá àyè láti gbàdúrà kí o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́

  • Nínú ìdílé yín, ẹ máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú eré ìnàjú àti fàájì

2 Ẹ MÁA ṢE ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ

Bàbá kan ń múra ìjọsìn ìdílé sílẹ̀, wọ́n wá ń gbádùn ìjọsìn ìdílé náà

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ó yẹ kí ẹ ṣètò bí ẹ ó ṣe máa jọsìn Ọlọ́run nínú ìdílé yín, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé ètò náà. (Jẹ́nẹ́sísì 18:19) Àmọ́ kò mọ síbẹ̀ o. Ó tún yẹ kí o máa rántí Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lójoojúmọ́. O lè mú kí ìdílé rẹ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ “nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:​6, 7) Pinnu pé wàá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóṣúà tó sọ pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”​—Jóṣúà 24:15.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, kí ẹ̀kọ́ náà sì dá lórí àwọn ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín nílò

Ìyá kan ń kàwé fún ọmọkùnrin rẹ̀; ìdílé kan ń ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìtàn inú Bíbélì; bàbá kan ń kọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́

ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ JÈHÓFÀ MÁA Ń NÍ AYỌ̀

Kò sí ohun tó dára ju ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run lọ. Inú rẹ̀ máa ń dùn bó ṣe ń rí ìwọ àti ìdílé rẹ tí ẹ̀ ń sìn ín tọkàntọkàn. Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ ó sì túbọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Máàkù 12:30; Éfésù 5:1) Bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá fi Ọlọ́run ṣe ẹnì kẹta yín, èyí á jẹ́ kí ẹ lẹ̀ túbọ̀ ṣera yín lọ́kan. (Oníwàásù 4:​12; Aísáyà 48:17) Ìwọ àti ìdílé rẹ lè ní ayọ̀ títí láé, bí ẹ ṣe ń mọ̀ pé ‘Jèhófà Ọlọ́run ti bù kún yín.’​—Diutarónómì 12:7.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Ìgbà wo ni èmi àti ọkọ tàbí aya mi jọ gbàdúrà kẹ́yìn?

  • Kí ni èmi àti ìdílé mi lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tó máa mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára?

ÌMỌ̀RÀN PÀTÀKÌ FÚN Ẹ̀YIN OLÓRÍ ÌDÍLÉ

  • Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ìjọsìn ìdílé yín lọ́wọ́

  • Kó tó di àkókò tí ẹ máa ṣe é, jẹ́ kí ìdílé rẹ mọ ohun tí ẹ máa jíròrò, kí wọ́n lè múra sílẹ̀

  • Rí i dájú pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ pésẹ̀

  • Ṣe é lọ́nà tí ara fi máa tu gbogbo wọn, tí wọ́n á sì gbádùn rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́