Orin 149
A Dúpẹ́ fún Ìràpadà
Bíi Ti Orí Ìwé
Jèhófà, a dúró,
níwájú rẹ lónìí,
Torí o fi ìfẹ́ tó
ga jù lọ hàn sí wa.
Ọmọ rẹ tó kú fún wa ló,
jẹ́ ká níyè.
Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye
jù lọ ni èyí jẹ́.
(ÈGBÈ)
Ó f’ẹ̀mí rẹ̀ dá wa sílẹ̀.
Ẹ̀jẹ̀ iyebíye ló lò.
Títí ayé
laó máa dúpẹ́ fún ìràpadà yìí.
Tinú tinú ni Jésù
f’ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.
Ìfẹ́ ló mú kó fi ẹ̀mí
rẹ̀ pípé lé lẹ̀.
Ó jẹ́ ká nírètí nígbà
tírètí pin.
Aó níyè àìnípẹ̀kun,
aó bọ́ lọ́wọ́ ikú.
(ÈGBÈ)
Ó f’ẹ̀mí rẹ̀ dá wa sílẹ̀.
Ẹ̀jẹ̀ iyebíye ló lò.
Títí ayé
laó máa dúpẹ́ fún ìràpadà yìí.
(Tún wo Héb. 9:13, 14; 1 Pét. 1:18, 19.)