ORÍ 3
“Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Mú Ipò Iwájú Láàárín Yín”
Ọ̀RỌ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yìí wà nínú Hébérù 13:7, a sì tún lè túmọ̀ rẹ̀ sí: “Ẹ máa rántí àwọn tó ń darí yín.” Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni àwọn olóòótọ́ àpọ́sítélì Jésù Kristi tí wọ́n jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí ti ń mú ipò iwájú, tí wọ́n sì ń pèsè ìtọ́sọ́nà fún ìjọ Kristẹni tuntun yìí. (Ìṣe 6:2-4) Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, àwọn míì tí wọn kì í ṣe àpọ́sítélì Jésù ti wà lára ìgbìmọ̀ olùdarí. Nígbà tí wọ́n ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́, “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù” ló wà nínú ìgbìmọ̀ yẹn. (Ìṣe 15:1, 2) Ojúṣe wọn ni láti bójú tó ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ àwọn Kristẹni níbi gbogbo. Wọ́n fi àwọn lẹ́tà àtàwọn ìpinnu wọn ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ, ìyẹn gbé àwọn ìjọ ró, ó sì mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wà níṣọ̀kan nínú èrò àti ìṣe wọn. Bí ìgbìmọ̀ olùdarí ṣe ń tọ́ wọn sọ́nà, àwọn ìjọ ń ṣègbọràn, wọ́n sì ń tẹrí ba, ìyẹn mú kí wọ́n rí ìbùkún Jèhófà, wọ́n sì ń pọ̀ sí i.—Ìṣe 8:1, 14, 15; 15:22-31; 16:4, 5; Héb. 13:17.
2 Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, ìpẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀. (2 Tẹs. 2:3-12) Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nínú àkàwé rẹ̀ nípa àlìkámà àti èpò, wọ́n gbin èpò (àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà) sí àárín àlìkámà (àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró). Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ni wọ́n fi dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè, ìyẹn “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 13:24-30, 36-43) Kristẹni ẹni àmì òróró kọ̀ọ̀kan ń gbádùn ojúure Jésù ní gbogbo àkókò yẹn, àmọ́ kò sí ìgbìmọ̀ olùdarí, kò sì dájú pé aṣojú kan wà ní ayé tí Jésù ń lò láti darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 28:20) Àmọ́, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé nǹkan máa yí pa dà ní àkókò ìkórè.
3 “Ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye?” Ìbéèrè yìí ni Jésù Kristi fi bẹ̀rẹ̀ àkàwé, tàbí àpèjúwe kan tó jẹ́ ara “àmì” tó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n á fi mọ̀ pé àwọn wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 24:3, 42-47) Jésù sọ pé ọwọ́ ẹrú olóòótọ́ náà máa dí gan-an bó ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fáwọn èèyàn Ọlọ́run “ní àkókò tó yẹ.” Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo ni Jésù lò láti mú ipò iwájú, àwùjọ àwọn ọkùnrin ló lò. Bákan náà, ní ìparí ètò àwọn nǹkan yìí, ẹrú olóòótọ́ tí Jésù ń lò kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo.
BÁ A ṢE LÈ MỌ “ẸRÚ OLÓÒÓTỌ́ ÀTI OLÓYE” NÁÀ
4 Ta ni Jésù yàn pé kó máa bọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun? Ó bọ́gbọ́n mu pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n wà ní ayé ló máa lò. Bíbélì pè wọ́n ní “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” tí a yàn láti “ ‘kéde káàkiri àwọn ọlá ńlá’ Ẹni tó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pét. 2:9; Mál. 2:7; Ìfi. 12:17) Ṣé gbogbo ẹni àmì òróró tó wà láyé ló jẹ́ ẹrú olóòótọ́? Rárá. Nígbà tí Jésù pèsè oúnjẹ lọ́nà ìyanu, tó sì fi bọ́ àwọn ọkùnrin tó tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé, ó pín in fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì ní kí wọ́n pín in fún àwọn èèyàn náà. (Mát. 14:19) Ó lo àwọn èèyàn díẹ̀ láti bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Bó ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa lónìí náà nìyẹn.
5 Torí náà, “ìríjú olóòótọ́ náà, tó jẹ́ olóye,” ni ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní tààràtà tí wọ́n sì ń pín in lásìkò tí Kristi wà níhìn-ín. (Lúùkù 12:42) Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn arákùnrin tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní oríléeṣẹ́ wa. Lónìí, àwọn arákùnrin yìí ló para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
6 Kristi ń lo ìgbìmọ̀ yìí láti jẹ́ ká mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣẹ, wọ́n sì máa ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó bọ́ sákòókò lórí bó ṣe yẹ ká máa lo àwọn ìlànà Bíbélì nígbèésí ayé wa. À ń rí oúnjẹ tẹ̀mí yìí gbà ní ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò wa. (Àìsá. 43:10; Gál. 6:16) Lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ìríjú tàbí ẹrú tí ọ̀gá rẹ̀ fọkàn tán ló máa ń bójú tó ilé ọ̀gá rẹ̀. Lọ́nà kan náà, ojúṣe ẹrú olóòótọ́ àti olóye yìí ni pé kó máa bójú tó agbo ilé ìgbàgbọ́. Torí náà, ẹrú olóòótọ́ ló tún ń bójú tó àwọn ilé àti irinṣẹ́ tí ètò náà ń lò títí kan iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ń ṣètò àwọn àpéjọ àyíká àti ti agbègbè, àwọn ló ń yan àwọn alábòójútó sípò nínú ètò Ọlọ́run, wọ́n ń bójú tó bá a ṣe ń tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, gbogbo àwọn nǹkan yìí ló sì ń ṣe “àwọn ará ilé” láǹfààní.—Mát. 24:45.
7 Àwọn wo ni “àwọn ará ilé”? Ní kúkúrú, àwọn tí ẹrú náà ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún ni. Ní ìbẹ̀rẹ̀, ẹni àmì òróró ni gbogbo àwọn ará ilé náà. Nígbà tó yá, ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ “àgùntàn mìíràn” dara pọ̀ mọ́ àwọn ará ilé náà. (Jòh. 10:16) Àwùjọ méjèèjì, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ló ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú olóòótọ́ ń pèsè.
8 Nígbà ìpọ́njú ńlá, tí Jésù bá wá láti ṣèdájọ́ ayé búburú yìí, ó máa yan ẹrú olóòótọ́ náà sípò “pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀.” (Mát. 24:46, 47) Àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́ máa gba èrè wọn ní ọ̀run. Àwọn àtàwọn tó kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní sí ẹrú olóòótọ́ àti olóye mọ́ lórí ilẹ̀ ayé, síbẹ̀, Jèhófà àti Jésù máa yan àwọn “olórí” láti máa darí àwọn tó wà lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà.—Sm. 45:16.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA “RÁNTÍ ÀWỌN TÓ Ń MÚ IPÒ IWÁJÚ”?
9 Ìdí púpọ̀ ló wà tó fi yẹ ká máa “rántí àwọn tó ń mú ipò iwájú” ká sì máa fọkàn tán wọn. Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí yín bí àwọn tó máa jíhìn, kí wọ́n lè ṣe é tayọ̀tayọ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn, torí èyí máa pa yín lára.” (Héb. 13:17) Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onígbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú ká sì máa tẹrí ba fún wọn torí pé àwọn ló ń bójú tó wa, wọ́n sì ń wá ire wa nípa tẹ̀mí.
10 Nínú 1 Kọ́ríńtì 16:14, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa fi ìfẹ́ ṣe gbogbo ohun tí ẹ bá ń ṣe.” Ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ tó ta yọ ló ń mú kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu tó kan àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 13:4-8 sọ nípa ìfẹ́ pé: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú. Kì í fọ́nnu, kì í gbéra ga, kì í hùwà tí kò bójú mu, kì í wá ire tirẹ̀ nìkan, kì í tètè bínú. Kì í di èèyàn sínú. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, àmọ́ ó máa ń yọ̀ lórí òtítọ́. Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó máa ń fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé.” Ìfẹ́ ló ń mú kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu tó ń ṣe àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láǹfààní, torí náà, kò sídìí fún wa láti ṣiyèméjì nípa ìtọ́sọ́nà tá à ń rí gbà. Yàtọ̀ síyẹn, ó wà lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa.
Ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹrí ba fún àwọn tó ń bójú tó wa, tí wọ́n sì ń wá ire wa nípa tẹ̀mí
11 Àwọn èèyàn aláìpé ni Jèhófà lò láti darí àwọn èèyàn rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, bó sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Kódà, ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń lo àwọn ẹ̀dá aláìpé láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Nóà kan ọkọ̀ áàkì ó sì wàásù nípa ìparun tó ń bọ̀ nígbà ayé rẹ̀. (Jẹ́n. 6:13, 14, 22; 2 Pét. 2:5) Mósè ni Jèhófà yàn pé kó kó àwọn èèyàn òun kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kís. 3:10) Àwọn èèyàn aláìpé ni Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì. (2 Tím. 3:16; 2 Pét. 1:21) Bí Jèhófà ṣe ń lo àwọn èèyàn aláìpé lónìí láti darí iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn kò ní ká má fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ètò Ọlọ́run nìyí torí a mọ̀ pé láìsí ìtìlẹ́yìn Jèhófà, kò sí bí ètò náà ṣe lè ṣàṣeyọrí èyíkéyìí. Ọ̀pọ̀ ìnira tí ẹrú olóòótọ́ náà ti fara dà àtàwọn ìrírí tó ní ti mú kó ṣe kedere pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí ètò rẹ̀. Jèhófà ti rọ̀jò ìbùkún sórí apá tó ṣeé fojú rí lára ètò rẹ̀ lónìí, ìdí nìyẹn tá a fi ń kọ́wọ́ tì í, tá a sì fọkàn tán an.
BÁ A ṢE Ń FI HÀN PÉ A FỌKÀN TÁN ÈTÒ ỌLỌ́RUN
12 Àwọn tá a yàn láti máa bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì nínú ìjọ ń fi hàn pé àwọn fọkàn tán ètò Ọlọ́run torí pé wọ́n ń fayọ̀ gba iṣẹ́ tá a yàn fún wọn, wọ́n sì ń bójú tó iṣẹ́ náà tọkàntọkàn. (Ìṣe 20:28) Akéde Ìjọba Ọlọ́run ni wá, torí náà à ń fi ìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé àti ìpadàbẹ̀wò, a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé wọn. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Ká lè jàǹfààní tó pọ̀ látinú oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ tí ẹrú olóòótọ́ náà ń pèsè fún wa, a máa ń múra àwọn ìpàdé Kristẹni sílẹ̀, a sì máa ń pésẹ̀ síbẹ̀, títí kan àwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè. A máa ń jàǹfààní gan-an látinú ìṣírí tá à ń fún ara wa láwọn ìpàdé yìí.—Héb. 10:24, 25.
13 Tá a bá ń fi àwọn ohun ìní wa ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn, ńṣe là ń fi hàn pé a fọkàn tán ètò náà. (Òwe 3:9, 10) Tá a bá rí i pé àwọn ará wa nílò àwọn nǹkan tara, a máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láìjáfara. (Gál. 6:10; 1 Tím. 6:18) Ìfẹ́ ará ló ń mú ká ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ìgbà la sì máa ń wá àǹfààní láti jẹ́ kí Jèhófà àti ètò rẹ̀ mọ̀ pé lóòótọ́ la mọrírì ìbùkún tá à ń rí.—Jòh. 13: 35.
14 Tá a bá ń kọ́wọ́ ti ìpinnu tí ètò Ọlọ́run ṣe, ìyẹn á fi hàn pé a fọkàn tán ètò náà. Ìyẹn sì gba pé ká máa fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ àwọn alábòójútó, irú bí àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà ìjọ. Àwọn arákùnrin yìí wà lára “àwọn tó ń mú ipò iwájú,” tí Bíbélì sọ pé ká máa ṣègbọràn sí ká sì máa tẹrí ba fún. (Héb. 13:7, 17) Bá ò tiẹ̀ lóye ohun tó mú kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu kan, a mọ̀ pé tá a bá kọ́wọ́ ti ìpinnu náà, ó máa ṣe wá láǹfààní tó máa wà pẹ́ títí. Ìyẹn á sì mú kí Jèhófà máa bù kún wa torí pé à ń ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. A tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé à ń tẹrí ba fún Ọ̀gá wa, Jésù Kristi.
15 Ó dá wa lójú, ó sì ṣe kedere pé ó yẹ ká fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Sátánì, ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí, ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà àti ètò rẹ̀. (2 Kọ́r. 4:4) Má ṣe jẹ́ kí Sátánì fi ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀ mú ẹ! (2 Kọ́r. 2:11) Ó mọ̀ pé “ìgbà díẹ̀ ló kù” kí wọ́n ju òun sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, ó sì ti pinnu láti mú gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà tọ́wọ́ rẹ̀ bá lè tẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. (Ìfi. 12:12) Àmọ́, bí ọwọ́ àtakò Sátánì ṣe túbọ̀ ń le sí i, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká fọkàn tán Jèhófà àtàwọn tó ń lò láti máa darí àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kí gbogbo ẹgbẹ́ ará wà ní ìṣọ̀kan.