Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ẹ̀yin Ará Ọ̀wọ́n Tá A Jọ Jẹ́ Akéde Ìjọba Ọlọ́run:
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé a wà lára àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Ó yàn wá láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́” rẹ̀, ó sì gbé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà fún wa, ó ní ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa kọ́ni nípa Ìjọba rẹ̀ tó ti ń ṣàkóso. (1 Kọ́r. 3:9; Mát. 28:19, 20) Ká tó lè ṣiṣẹ́ tó kárí ayé yìí yanjú ní àlàáfíà àti níṣọ̀kan, ó ṣe pàtàkì pé ká wà létòlétò.—1 Kọ́r. 14:40.
Ìwé yìí máa jẹ́ kó o mọ bá a ṣe ṣètò àwọn nǹkan nínú ìjọ Kristẹni lónìí. Ó tún ṣàlàyé àwọn àǹfààní àtàwọn ojúṣe tó o ní bó o ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá mọyì àǹfààní yẹn, tó o sì ń ṣe àwọn ojúṣe rẹ, wàá lè “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.”—Ìṣe 16:4, 5; Gál. 6:5.
Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o fara balẹ̀ ka ìwé yìí. Ronú nípa bó o ṣe lè fi àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí sílò nígbèésí ayé rẹ. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi ni ẹ́, kí lo lè ṣe tí wàá fi tẹ̀ síwájú, kó o ṣèrìbọmi kí ìwọ náà lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Tó o bá sì ti ṣèrìbọmi, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tí wàá fi máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn rẹ kó o sì tún mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i? (1 Tím. 4:15) Kí ni ìwọ náà lè ṣe tí àlàáfíà á fi túbọ̀ jọba nínú ìjọ? (2 Kọ́r. 13:11) Wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí bó o ṣe ń ka ìwé yìí.
Tó o bá jẹ́ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, kí lo lè ṣe láti tẹ̀ síwájú kó o lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tó bá sì tún yá, kó o di alàgbà? Bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹni tuntun ṣe ń rọ́ wá sínú ètò Jèhófà, a nílò àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti múpò iwájú. Ìwé yìí ṣàlàyé bó o ṣe lè “sapá” kíwọ náà lè kúnjú ìwọ̀n, kó o sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—1 Tím. 3:1.
Àdúrà wa ni pé kí àlàyé inú ìwé yìí mú kó o rí àwọn àǹfààní àti ojúṣe tó o ní nínú ètò Jèhófà, kó o sì mọyì rẹ̀. A nífẹ̀ẹ́ gbogbo yín gan-an, ìgbà gbogbo la sì ń gbàdúrà pé kí ẹ̀yin náà wà lára àwọn tí yóò máa fayọ̀ sin Jèhófà Baba wa ọ̀run títí láé.—Sm. 37:10, 11; Àìsá. 65:21-25.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà