Ẹ̀KỌ́ 23
Wọ́n Ṣèlérí fún Jèhófà
Ní nǹkan bí oṣù méjì lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọ́n dé Òkè Sínáì, wọ́n sì pàgọ́ síbẹ̀. Jèhófà pe Mósè, Mósè sì lọ sórí òkè náà. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Mo ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là. Àmọ́ tí wọ́n bá gbọ́ràn sí mi lẹ́nu tí wọ́n sì pa òfin mi mọ́, wọ́n máa di èèyàn mi.’ Mósè sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà, ó sì lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí làwọn èèyàn náà sọ? Wọ́n ní: ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ fún wa la máa ṣe.’
Mósè tún pa dà sórí òkè náà. Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Mo máa bá yín sọ̀rọ̀ ní ojọ́ mẹ́ta sí i. Àmọ́, kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n má ṣe wá sórí Òkè Sínáì.’ Mósè sì lọ jíṣẹ́ fún wọn pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.
Nígbà tó di ọjọ́ kẹta, òkùnkùn bo orí òkè náà, mànàmáná sì ń kọ mànà. Wọ́n tún gbọ́ ìró fèrè àti àrá tó ń sán gan-an. Jèhófà sì sọ̀ kalẹ̀ sórí òkè náà nínú iná. Èyí mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gidigidi. Òkè náà mì tìtì, èéfín sì bò ó. Ìró fèrè náà wá ń lọ sókè sí i. Ọlọ́run wá sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni Jèhófà. Ẹ ò gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.’
Mósè pa dà lọ sórí òkè náà. Jèhófà sì fún un ní òfin tó dá lórí bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn òun àti ìwà tí wọ́n á máa hù. Mósè kọ òfin náà sílẹ̀, ó sì kà á fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n wá ṣèlérí pé: ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ fún wa la máa ṣe.’ Wọ́n ti ṣèlérí fún Ọlọ́run báyìí, ṣùgbọ́n ṣé wọ́n máa mú ìlérí wọn ṣẹ?
“Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”—Mátíù 22:37