ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 35
  • Jèhófà Fún Wọn Ní Òfin Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Fún Wọn Ní Òfin Rẹ̀
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Ṣèlérí fún Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Igbó Tí Ń Jó
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Bí Ohun Tí Mósè Gbélé Ayé Ṣe Ṣe Kàn Ọ́
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 35
Mósè ń gba òfin Ọlọ́run ní Òkè Sínáì

ÌTÀN 35

Jèhófà Fún Wọn Ní Òfin Rẹ̀

NÍ NǸKAN bí oṣù méjì lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, wọ́n dé Òkè Sínáì tá a tún ń pè ní Hórébù. Ibí yìí kan náà ni Jèhófà ti bá Mósè sọ̀rọ̀ láti inú igbó tó ń jó. Fún ìgbà díẹ̀, àwọn èèyàn náà pa àgọ́ wọ́n sì dúró níbẹ̀.

Mósè gun orí òkè lọ, àwọn èèyàn náà sì dúró sí ìsàlẹ̀. Jèhófà sọ fún Mósè lórí òkè níbẹ̀ pé Òun fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe ìgbọràn sí Òun kí wọ́n sì jẹ́ èèyàn pàtàkì fún Òun. Nígbà tí Mósè sọ̀ kalẹ̀, ó sọ ohun tí Jèhófà wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn èèyàn náà sì sọ pé àwọn máa ṣe ìgbọràn sí Jèhófà, nítorí wọ́n fẹ́ láti jẹ́ èèyàn rẹ̀.

Jèhófà wá ṣe ohun ìyanu kan. Ó mú kí orí òkè náà rú èéfín, ó sì jẹ́ kí ààrá ńlá kan sán. Ó wá bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ pé: ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín tó mú yín jáde láti ilẹ̀ Íjíbítì.’ Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ sin ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.’

Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin mẹ́sàn-án mìíràn sí i. Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà gidigidi. Wọ́n wí fún Mósè pé: ‘Ìwọ ni kó o máa bá wa sọ̀rọ̀, nítorí ẹ̀rù ń bà wá pé bí Ọlọ́run bá ń bá wa sọ̀rọ̀ a máa kú.’

Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: ‘Gun òkè tọ̀ mí wá. Èmi óò fún ọ ní wàláà òkúta méjì tí mo ti kọ àwọn òfin tí mo fẹ́ kí àwọn èèyàn náà máa tẹ̀ lé sí.’ Nítorí náà, Mósè tún padà lọ sórí òkè náà. Ogójì ọ̀sán àti ogójì òru ló fi wà níbẹ̀.

Ọlọ́run ní òfin tó pọ̀ púpọ̀ láti fún àwọn èèyàn rẹ̀. Mósè kọ àwọn òfin wọ̀nyí sílẹ̀. Ọlọ́run tún fún Mósè ní wàláà òkúta méjì. Orí wàláà wọ̀nyí ni Ọlọ́run tìkára rẹ̀ kọ òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó sọ fún àwọn èèyàn náà sí. Èyí ni à ń pè ní Òfin Mẹ́wàá.

Òfin Mẹ́wàá yìí ṣe pàtàkì. Ọ̀pọ̀ òfin mìíràn tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pàtàkì pẹ̀lú. Ọ̀kan nínú àwọn òfin náà wí pé: ‘Kí ìwọ kí ó fi gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo iyè inú rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.’ Òmíràn wí pé: ‘Kí ìwọ kí ó fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, sọ pé èyí ni òfin méjì tó tóbi jù lọ nínú gbogbo òfin tí Jèhófà fi fún Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀. Nínú àwọn àkòrí tó wà níwájú, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Ọmọ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fi kọ́ni la máa kọ́.

Ẹ́kísódù 19:1-25; 20:1-21; 24:12-18; 31:18; Diutarónómì 6:4-6; Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:36-40.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́